Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 20
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 20
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 10 ìpínrọ̀ 18 sí 23 àti àpótí tó wà lójú ìwé 107
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 19-22
No. 1: 2 Àwọn Ọba 20:1-11
No. 2: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Onínú Tútù? (Mát. 5:5)
No. 3: Ohun Tí Jíjọ́sìn Ère Máa Ń Yọrí Sí (td 9B)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí Lọ́dún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Kọjá? Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó sọ àsọyé yìí. Sọ̀rọ̀ nípa bí ìjọ yín ṣe ṣe sí lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, kó o tẹnu mọ́ àwọn àṣeyọrí tẹ́ ẹ ṣe, kó o sì gbóríyìn fún àwọn ará. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n ní àwọn ìrírí tó ta yọ. Mẹ́nu ba apá ibì kan tàbí méjì tó yẹ kí ìjọ yín ṣiṣẹ́ lé lórí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tá a wà yìí, kó o sì sọ àwọn ohun tẹ́ ẹ lè ṣe láti tẹ̀ síwájú.
10 min: “Ìtọ́ni fún Àwọn Tó Ń Ṣiṣẹ́ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn.” Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí.
10 min: Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kó Lè Di Akéde. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 82. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu òbí kan tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere, tó sì ní ọmọ kékeré tó ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Báwo ni òbí náà ṣe ran ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ tó fi tẹ̀ síwájú, tó sì wá kúnjú ìwọ̀n láti di akéde?