Àwọn Ohun Tí Fídíò The Bible—Its Power in Your Life Ń Tẹ̀ Mọ́ni Lọ́kàn
Láti dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí, sọ̀rọ̀ látọkànwá nípa àwọn ohun tí ìsọfúnni tó wà nínú fídíò yìí tẹ̀ mọ́ ọ lọ́kàn. (1a) Kí ni ohun tó fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lágbára láti ṣàtúnṣe ìgbésí ayé wọn tó fi sunwọ̀n sí i? (Héb. 4:12) (1b) Kí ni ohun tó pọndandan láti lè rí agbára yìí gbà kí èèyàn sì lò ó nínú ìgbésí ayé ẹni? (2) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo la tọ́ka sí láti ran àwọn tọkọtaya lọ́wọ́ (a) láti mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ wọn túbọ̀ dán mọ́rán àti (b) láti máa ṣèkáwọ́ ìbínú wọn? (3) Báwo ni ojú tí Kristẹni fi ń wo ìgbéyàwó ṣe ń mú kí ìgbésí ayé ìdílé sunwọ̀n sí i? (Éfé. 5:28, 29) (4) Báwo ni Jèhófà Ọlọ́run ṣe fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ ní ti fífún àwọn ọmọ ní ohun mẹ́ta tí wọ́n ń fẹ́ tí wọ́n sì nílò, báwo sì ni àwọn òbí lónìí ṣe lè ṣe ohun kan náà? (Máàkù 1:9-11) (5) Èé ṣe tí àwọn òbí fi gbọ́dọ̀ fúnra wọn fi Bíbélì kọ́ àwọn ọmọ wọn, kí ló sì fi hàn pé ó yẹ kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé? (Diu. 6:6, 7) (6) Báwo ni àwọn òbí ṣe lè mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé máa gbádùn mọ́ni? (7) Yàtọ̀ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí tún ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń sún àwọn òbí láti máa pèsè fún àwọn ọmọ wọn? (8) Báwo ni ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe lè ran àwọn ìdílé lọ́wọ́ láti rọ́gbọ́n dá sí ọ̀ràn ìṣúnná owó? (9) Àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ló jẹ́ pé bí a bá fi wọ́n sílò, wọ́n lè ṣèrànwọ́ láti dín ìṣòro àìlera kù? (10) Báwo ni ìlànà inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe mú ìyàtọ̀ bá ìgbésí ayé rẹ? (11) Kí nìdí tí wíwo fídíò yìí ṣe lè fún ẹnì kan tí o bá sọ̀rọ̀ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ níṣìírí láti tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé?