“Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣe Bẹ́ẹ̀, Láìjẹ́ Pé Ẹnì Kan Fi Mí Mọ̀nà?”
1 Nígbà tí Fílípì ajíhìnrere bi ìwẹ̀fà ará Etiópíà náà léèrè bó bá lóye ohun tó ń kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ọkùnrin náà dáhùn pé: “Ní ti tòótọ́, báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kan fi mí mọ̀nà?” Fílípì fi tayọ̀tayọ̀ ràn án lọ́wọ́ láti lóye ìhìn rere nípa Jésù, èyí sì mú kí ọkùnrin náà ṣe ìrìbọmi lójú ẹsẹ̀. (Ìṣe 8:26-38) Ṣe ni Fílípì ń ṣègbọràn sí iṣẹ́ tí Kristi gbé léni lọ́wọ́ pé ká ‘sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ká máa batisí wọn, ká sì máa kọ́ wọn.’—Mát. 28:19, 20.
2 A gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí àṣẹ náà láti sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn bí Fílípì ti ṣe. Ṣùgbọ́n, láàárín àwọn ènìyàn tí a ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a kì í sábà rí irú ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí tó yára kánkán tí ìwẹ̀fà ará Etiópíà yẹn ní. Ọkùnrin yẹn, tó jẹ́ Júù aláwọ̀ṣe tó mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa, ní ọkàn-àyà ìgbàṣe, ohun tó kàn kù ni pé kó gbà pé Jésù ni Mèsáyà náà táa ṣèlérí. Ìṣòro ló máa ń jẹ́ bó bá jẹ́ pé àwọn tí a ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ kò mọ̀ nípa Bíbélì, bí a bá ti fi àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké ṣì wọ́n lọ́nà, tàbí bí àwọn ìṣòro lílékenkà bá ti dẹrù pa wọ́n lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí nínú títọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ́nà débi ṣíṣe ìyàsímímọ́ àti batisí?
3 Fòye Mọ Àìní Tẹ̀mí Tí Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní: Báwo ló ṣe yẹ kí àkókò ti a lè fi bá àwọn èèyàn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ gùn tó, nígbà tí a bá ń lo ìwé pẹlẹbẹ Béèrè àti ìwé Ìmọ̀? Ó ṣe pàtàkì láti mú kí bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń yá sí bá àyíká ipò àti òye akẹ́kọ̀ọ́ mu. A kò ní tìtorí pé kí ó lè yá, ká má wàá jẹ́ kí akéde náà ní òye ní kedere. Olúkúlùkù akẹ́kọ̀ọ́ ló yẹ kó ní ìpìlẹ̀ lílágbára fún ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí. Nítorí náà, ó dáa ká má ṣe sáré kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó wà nínú ìwé Ìmọ̀ pẹ̀lú èrò pé a fẹ́ gbìyànjú láti parí ìwé náà láàárín oṣù mẹ́fà. Ó lè gbà ju oṣù mẹ́fà láti ran àwọn kan lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú débi ṣíṣe batisí. Bí o ṣe ń bá wọn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, lo àkókò tó bá yẹ láti ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti lóye ohun tí ó ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí ó sì fi í sílò. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó lè gbà tó ọ̀sẹ̀ méjì tàbí mẹ́ta kẹ́ẹ tó lè parí orí kan nínú ìwé Ìmọ̀. Èyí yóò jẹ́ kí ẹ lè ka ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí, yóò sì jẹ́ kí ẹ lè ṣàlàyé wọn.—Róòmù 12:2.
4 Ṣùgbọ́n, ká ní nígbà tí ẹ parí ìwé Ìmọ̀, o wòye pé ó yẹ kí o túbọ̀ mú kí òye tí akẹ́kọ̀ọ́ náà ní nípa òtítọ́ túbọ̀ kún rẹ́rẹ́ ńkọ́, tàbí pé a kò tíì sún un dáadáa láti mú ìdúró rẹ̀ fún òtítọ́, kí ó sì ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run? (1 Kọ́r. 14:20) Kí lo tún lè ṣe láti tọ́ ọ sí ọ̀nà tó lọ sí ìyè?—Mát. 7:14.
5 Bójú Tó Àwọn Àìní Tẹ̀mí Tí Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní: Bó bá hàn kedere pé ẹnì kan ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ni, tí ẹni náà sì ń fi ìmọrírì hàn fún ohun tó ń kẹ́kọ̀ọ́, nígbà náà, ẹ máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà nìṣó nínú ìwé mìíràn lẹ́yìn tí ẹ bá ti parí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè àti ìwé Ìmọ̀. Kò pọndandan pé gbogbo ìgbà la gbọ́dọ̀ ṣe èyí, ṣùgbọ́n nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, ẹ lè máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ nìṣó nínú ìwé Alafia ati Ãbò Tõtọ—Lati Orisun Wo?, Isopọṣọkan ninu Ijọsin, tàbí ìwé Lilaaja. Bí ìjọ kò bá ní ìwé wọ̀nyí lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ akéde ló ní ìwé tó yẹ ká lò wọ̀nyí. Nínú gbogbo ọ̀ràn, ìwé pẹlẹbẹ Béèrè àti ìwé Ìmọ̀ ni a óò kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́. Kí o ka iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti iye ìpadàbẹ̀wò tí o bá ṣe àti àkókò tí o lò, kí o sì ròyìn wọn, kódà bí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ṣe batisí kí ẹ tó parí ìwé kejì.
6 Ṣé èyí túmọ̀ sí pé ká tún wá ṣèrànwọ́ fún àwọn táa batisí ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ìwé kan ni wọ́n kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ ìwé kejì? Kò pọndandan. Ṣùgbọ́n, bí wọ́n bá ti lọ di aláìṣiṣẹ́mọ́ tàbí tí wọn ò tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́, wọ́n lè ronú pé àwọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan nílò ìrànwọ́ láti túbọ̀ máa fi òtítọ́ sílò lọ́nà púpọ̀ sí i nínú ìgbésí ayé wọn. Kí á bá alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sọ̀rọ̀ kó tó di pé a bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ padà pẹ̀lú akéde kan tó ti ṣe batisí. Àmọ́ bí o bá mọ àwọn kan tó ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ sẹ́yìn, ṣùgbọ́n tí wọn kò tẹ̀ síwájú dórí ìyàsímímọ́ àti batisí, o lè lo ìdánúṣe láti wádìí bóyá wọ́n á fẹ́ láti tún bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
7 Bí a bá fún olúkúlùkù àwọn olùfìfẹ́hàn tí a ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ní àfiyèsí, yóò fi hàn pé a ní ìfẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Ète wa ni láti ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà púpọ̀ sí i. Nígbà náà, yóò lè tẹ́wọ́ gba òtítọ́ lọ́nà tó ṣe pàtó, yóò ní ìmọ̀ tó pọ̀ tó nípa rẹ̀, yóò ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, yóò sì fẹ̀rí ìyàsímímọ́ yẹn hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi.—Sm. 40:8; Éfé. 3:17-19.
8 Ǹjẹ́ o rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ìwẹ̀fà ará Etiópíà yẹn ṣe ìrìbọmi? “Ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀” gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn tuntun fún Jésù Kristi. (Ìṣe 8:39, 40) Ǹjẹ́ kí àwa àti àwọn tí a ṣàṣeyọrí láti mú mọ ọ̀nà òtítọ́ máa rí ìdùnnú ńláǹlà nínú sísin Jèhófà Ọlọ́run, nísinsìnyí àti títí láé!