Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” ti 1998
1 Òwe 10:29 rán wa létí pé “ọ̀nà Jèhófà jẹ́ odi agbára.” Ẹ wo bí ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọpọ̀ ọdún yìí ti bá a mu púpọ̀ tó—“Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́”! Báwo gan-an ni a óò ṣe ṣàlàyé ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí jálẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọlọ́jọ́ mẹ́ta náà? Gbogbo wa ń fi ìháragàgà gan-an fojú sọ́nà fún ohun tí a ti pèsè fún wa. A ó sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì.
2 Àwọn míṣọ́nnárì, òṣìṣẹ́ káyé, tàbí àwọn mìíràn tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ní ilẹ̀ òkèèrè lè wá sí àpéjọpọ̀ yín. Bóyá ó ṣeé ṣe kí o bá díẹ̀ lára àwọn àlejò wọ̀nyí pàdé. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà yóò gbé àwọn ìròyìn jáde nípa bí Jèhófà ṣe ń bù kún iṣẹ́ náà ní onírúurú ìpínlẹ̀.
3 Ó Yẹ Kí A Sapá Láti Pésẹ̀: Ọ̀pọ̀ lára àwọn ará wa ní ilẹ̀ Áfíríkà ti kojú ìnira nítorí ogun àti pákáǹleke tí ó ṣẹlẹ̀ ní àwọn apá ibi kan ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ń wo àwọn àpéjọpọ̀ àwọn ènìyàn Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ohun ìgbẹ́mìíró wọn. Àwọn kan ní láti rìnrìn àjò gígùn láti pésẹ̀ sí àpéjọpọ̀, síbẹ̀ wọn kò jẹ́ ronú kan pípa ọ̀kankan jẹ. Arákùnrin ẹni ọdún 73 kan ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Kóńgò (Zaire tẹ́lẹ̀ rí) fẹsẹ̀ rin 450 kìlómítà láti pésẹ̀ sí àpéjọpọ̀ kan. Ó débẹ̀ ní ọjọ́ 16 lẹ́yìn tí ó ti bẹ̀rẹ̀ ìrìn, ẹsẹ̀ rẹ̀ wú, ṣùgbọ́n ó láyọ̀ láti wà níbẹ̀. Lẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà, bí inú rẹ̀ ti dùn gidigidi, ti a sì fún un lókun nípa tẹ̀mí, ó fẹsẹ̀ rìn padà sílé. Ó ti ń ṣe èyí fún ọ̀pọ̀ ọdún!
4 Ní Mòsáńbíìkì, alábòójútó àgbègbè kan àti ìyàwó rẹ̀ gun òkè gíga kan wọ́n sì fẹsẹ̀ rìn gba àgbègbè ńlá kan tí ó dà bí aginjù kọjá láti pésẹ̀ sí àpéjọ àyíká kan. Wọ́n fi wákàtí 45 rin ìrìn àjò 90 kìlómítà náà. Àpẹẹrẹ tọkọtaya yìí tí ó dára púpọ̀, fún gbogbo àwọn tí ó pésẹ̀ níṣìírí gidigidi. Ọ̀pọ̀ ìdílé tí ó wà níbẹ̀ ti ṣe ìsapá tí ó jọ èyí láti pésẹ̀. Alábòójútó àgbègbè ròyìn pé àwọn ará kan, títí kan ẹnì kan tí ó jẹ́ ẹni 60 ọdún, fi ẹsẹ̀ rin 200 kìlómítà!
5 Ṣé o ti tọjú owó tí ẹ óò fi wọ ọkọ̀ lọ sí àpéjọpọ̀ àti èyí tí ẹ óò ná kí gbogbo ìdílé lè lọ? Pẹ̀lúpẹ̀lù, ṣé o ti bá ẹni tí ó gbà ọ́ síṣẹ́ ṣètò láti gba ìsinmi kí o lè pésẹ̀ sí gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àpéjọpọ̀ náà? Àwọn òbí tí wọ́n ní àwọn ọmọ tí ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọn yóò lọ sí ọ̀kan nínú àwọn àpéjọpọ̀ náà nígbà tí ilé ẹ̀kọ́ ṣì ń lọ lọ́wọ́, yẹ kí wọ́n fi tó àwọn olùkọ́ létí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé àwọn ọmọ náà kì yóò wá sí ilé ẹ̀kọ́ ní ọjọ́ Friday nítorí apá pàtàkì nínú ìjọsìn tí ó jẹ́ ti ẹ̀sìn wọn yìí. Ibo ni àpéjọpọ̀ tí ó sún mọ́ ọ jù lọ? Ní báyìí, akọ̀wé ìjọ yín yóò ti sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ fún yín nípa ìsọfúnni tí ó jẹ́ ti ìjọ yín.
6 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ọlọ́jọ́ Mẹ́ta: Lọ́dún yìí, ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò wáyé ní àpéjọpọ̀ 106 ní Nàìjíríà. Ní àfikún sí èdè Yorùbá, a óò ṣe àwọn àpéjọpọ̀ ní èdè Abua, Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà, Edo, Ègùn, Ẹ́fíìkì, Gẹ̀ẹ́sì, Gòkánà, Haúsá, Ìgbò, Ijaw, Ishan, Ísókó, Kana, Tiv, àti Urhobo.
7 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Friday ní agogo 9:20 òwúrọ̀ yóò sì parí ní ọjọ́ Sunday ní nǹkan bí agogo 3:30 ìrọ̀lẹ́. Ní ọjọ́ Saturday àti Sunday, ìtòlẹ́sẹẹsẹ yóò bẹ̀rẹ̀ ní agogo mẹ́sàn-án òwúrọ̀.
8 Bí a ti ń rìnrìn àjò lọ sí àpéjọpọ̀ tí a sì ń padà sílé, ó yẹ kí a máa wá àǹfààní láti jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà. Àwọn òṣìṣẹ́ ilé epo, akọ̀wé ilé ìtajà, agbowó ọ̀nà márosẹ̀, òṣìṣẹ́ ní hòtẹ́ẹ̀lì, àti àwọn tí ń gbé oúnjẹ fúnni nílé oúnjẹ lè ní ọkàn-ìfẹ́ nínú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. Múra sílẹ̀ fún èyí nípa kíkó ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́, ìwé pẹlẹbẹ, tàbí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn dání kí o bàa lè lo àwọn àǹfààní tí ó bá ṣí sílẹ̀ láti jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ pé a kò lè gba ọ̀nà mìíràn mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ wọn.—2 Tím. 3:17.
9 ‘Fiyè sí Bí O Ṣe Ń Fetí Sílẹ̀’: Ìwà ọgbọ́n ni yóò jẹ́ fún àwọn alápèéjọpọ̀ láti kọbi ara sí ìmọ̀ràn tí ó wà nínú Lúùkù 8:18. A fún gbogbo yín níṣìírí láti mú Bíbélì, ìwé orin àti ìwé tí a ń kọ nǹkan sí dání. Fetí sílẹ̀ dáadáa láti gbọ́ àwọn kókó láti inú ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan, kí o sì kọ àkọsílẹ̀ ṣókí. Bi ara rẹ léèrè nípa bí o ṣe lè fi àkójọ ọ̀rọ̀ náà sílò fúnra rẹ. Ní alaalẹ́ ní ọjọ́ àpéjọpọ̀ náà, kí o tó lọ sùn, èé ṣe tí ìwọ kò fi ṣàtúnyẹ̀wò àkọsílẹ̀ rẹ kí o sì ṣàyẹ̀wò kínníkínní nípa bí o ṣe ń tọ ọ̀nà ìgbésí ayé tí Jèhófà fẹ́ dáadáa tó.—Òwe 4:10-13.
10 A ti kíyè sí i pé ní àkókò ìjókòó, àwọn kan máa ń kúrò lábẹ́ gbọ̀ngàn àpéjọ tí wọn yóò sì lọ jókòó sínú ọkọ̀ wọn, wọ́n máa ń tipa báyìí pàdánù ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. A ti rí àwọn mìíràn tí wọ́n máa ń rìn gbéregbère káàkiri nígbà tí ó yẹ kí wọ́n jókòó lábẹ́ gbọ̀ngàn àpéjọ kí wọ́n sì máa fetí sílẹ̀. A ti rí àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n fi ibi àpéjọpọ̀ sílẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀sán. Àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní àwọn ìgbà tí ó ti kọjá ṣe àṣìṣe ńlá nínú ìgbésí ayé wọn nítorí pé wọn kò fetí sílẹ̀ dáadáa sí àwọn ìránnilétí tí Jèhófà ṣe. Dájúdájú, àwa yóò fẹ́ láti yẹra fún ṣíṣe àṣìṣe tí ó jọ èyí. (2 Ọba 17:13-15) “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti ṣètò ìtọ́ni tí gbogbo wa nílò. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí a “fún àwọn ohun tí a gbọ́ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ” ní àkókò ìjókòó kọ̀ọ̀kan ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà. A óò máa gbé ohun tí a lọ́kàn-ìfẹ́ pàtàkì sí jáde ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, títí kan ìsọfúnni tí ó dájú pé yóò ní ipa tí ń gbéni ró lórí ọ̀nà ìgbésí ayé wa ní ọjọ́ ọ̀la. Nípasẹ̀ ìfetísílẹ̀ wa, tí a sì ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àmúlò ohun tí Jèhófà pèsè nípa tẹ̀mí ní ọ̀wọ́ àpéjọpọ̀ tí ń bọ̀ yìí, a óò fi ẹsẹ̀ ìrètí wa múlẹ̀ gbọn-ingbọn-in, “kí a má bàa sú lọ láé” kúrò ní ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́.—Mát. 24:45; Héb. 2:1.
11 Ìmúra Tí Ń Bọlá fún Jèhófà: Ní àwọn àkókò lílekoko wọ̀nyí, ó yẹ kí a fiyè sílẹ̀ gidigidi ju ti àtẹ̀yìnwá lọ kí ẹ̀mí ayé yìí má bàa ní ipa lórí wa. (1 Kọ́r. 2:12) Ó yẹ kí ìwọṣọ àti ìmúra wa wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó sì yẹ kí ó fi iyì Ọlọ́run tí a ń jọ́sìn hàn. (1 Tím. 2:9, 10) A kò béèrè aṣọ olówó ńlá láti lè wà lára àwọn tí ń “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́.” (Títù 2:10) Kíyè sí ìmọ̀ràn tí ó gbéṣẹ́ jù lọ tí ó sì bá Ìwé Mímọ́ mu tí ó wà ní ojú ìwé 17 àti 18 nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 1997, ìpínrọ̀ 14 sí 18. Má ṣe fojú kéré ìjẹ́rìí alágbára tí a lè fúnni nípa mímúra ní ọ̀nà tí ń bọlá fún Jèhófà.
12 Ẹlẹ́rìí ẹni ọdún 16 kan ròyìn pé nígbà tí òun àti arákùnrin òun lọ sí ilé oúnjẹ kan ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan lẹ́yìn àkókò ìjókòó, àwọn ṣàkíyèsí pé àwọn kan lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n wà níbẹ̀ ti pààrọ̀ aṣọ wọn sí èyí tí kò bójú mu. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ àwọn oníbàárà ilé oúnjẹ náà hùwà padà lọ́nà rere nígbà tí wọ́n rí Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n múra lọ́nà mímọ́ tónítóní tí ó bójú mu tí wọ́n sì lẹ káàdì àpéjọpọ̀ wọn mọ́ àyà. Èyí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti jẹ́rìí fún díẹ̀ lára àwọn oníbàárà náà.
13 Ìwà Tí Ń Fi Ìyìn fún Jèhófà: A mọ̀ pé ìwà wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni lè ní ipa lórí ojú tí àwọn ẹlòmíràn fi ń wo ìjọsìn tòótọ́. Nítorí náà, ó yẹ kí a máa fìgbà gbogbo hùwà ní ọ̀nà kan tí ó yẹ ìhìn rere tí ó sì ń mú ìyìn wá fún Jèhófà.—Fílí. 1:27.
14 Lọ́dún tó kọjá, a ṣe àpéjọpọ̀ àgbègbè ní àríwá Àǹgólà fún ìgbà àkọ́kọ́. Ní ọjọ́ kejì àpéjọpọ̀ náà, a rán ọlọ́pàá méjì láti àdúgbò náà wá sí ibi àpéjọpọ̀ náà láti rí i pé wàhálà kò ṣẹlẹ̀. Wọ́n wà níbẹ̀ látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Ní òpin ọjọ́ náà, wọ́n fi ìmọrírì wọn hàn nípa ohun tí wọ́n gbọ́ àti nípa ìwà ìṣe-nǹkan-létòletò tí wọ́n kíyè sí. Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Kí ni wọ́n tilẹ̀ rán wa wá ṣe níbí gan-an? A mọ̀ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fa wàhálà níbi ìkórajọpọ̀ wọn.”
15 Mẹ́ńbà ẹgbẹ́ òṣèlú kan ní orílẹ̀-èdè Áfíríkà kan sá lọ sí Yúróòpù nígbà tí a pa gbogbo mẹ́ńbà yòókù nínú ẹgbẹ́ rẹ̀. Ó ní ọ̀pọ̀ ìṣòro, ó sì rẹ̀wẹ̀sì. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí ó wá sí àpéjọpọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́, ó wú u lórí pé àwọn ènìyàn tí wọ́n ní onírúurú ipò àtilẹ̀wá pàdé pọ̀ ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan. A mú un gbà dájú pé ó ti rí òtítọ́, ó sì pinnu ní àkókò àpéjọpọ̀ yẹn láti fòpin sí gbogbo ìbáṣepọ̀ ìṣèlú tí ó ń ní. Lẹ́yìn ìgbà náà, a batisí rẹ̀, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì ń sin Jèhófà nísinsìnyí.
16 Báwo ni ìwà wa ní àwọn àpéjọpọ̀ lọ́dún yìí yóò ṣe ní ipa lórí àwọn tí ó lè jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí wọn yóò wá? Wọn yóò ha kíyè sí ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí ó máa ń fara hàn nígbà tí a bá ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùyọ̀ǹda ara ẹni bí? A óò ha wú wọn lórí nípa mímú kí àyíká wa mọ́ tónítóní àti nípa rírí i pé kí a tó kúrò ní ibi àpéjọpọ̀, àwa àti àwọn ọmọ wa ṣa ìdọ̀tí èyíkéyìí tí ó ṣeé ṣe kí ó wà níbi ìjókòó wa? Wọn yóò ha kíyè sí ìwà rere wa bí a ti ń rìnrìn àjò láti ibi tí a dé sí lọ sí ibi àpéjọpọ̀ àti láti ibẹ̀ padà sí ibi tí a dé sí? Wọn yóò ha kíyè sí i pé gẹ́gẹ́ bí òbí, a ń bójú tó àwọn ọmọ wa dáadáa nígbà gbogbo bí? Ẹ jẹ́ kí a rí i dájú pé a mú kí gbogbo àwọn tí ó bá ń wò wá ní èrò rere nípa wa bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó.
17 Kíkájú Ìnáwó Àpéjọpọ̀: Ìgbà gbogbo ni Society máa ń pèsè “ìjókòó lọ́fẹ̀ẹ́” ní àwọn àpéjọpọ̀. Nígbà náà, báwo ni a óò ṣe kájú ìnáwó àpéjọpọ̀? Yóò jẹ́ nípasẹ̀ ọrẹ ọlọ́làwọ́ tí àwọn tí ó wá bá ṣe. Ó dá wa lójú pé ẹ̀yin yóò fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn irú èyí tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fi hàn ní ìgbà àtijọ́ ní àfarawé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi. (2 Kọ́r. 8:7) A ń kíyè sára gidigidi láti rí i dájú pé a ń pa àwọn ọrẹ náà mọ́ dáadáa, a ń ṣàkọsílẹ̀ wọn, a sì ń lò wọ́n fún ète tí a sọ pé a óò lò wọ́n fún. Ọrẹ èyíkéyìí tí a óò bá ṣe nípasẹ̀ ìwé sọ̀wédowó, orúkọ “Watch Tower” ni kí ẹ kọ sórí rẹ̀ pe kí ó gbà á.
18 Àyè Ìjókòó: Ìtọ́sọ́nà tí a ti fúnni fún ọdún mélòó kan ni a óò máa fi sílò lọ, ìyẹn ni pé, O LÈ GBA ÀYÈ SÍLẸ̀ FÚN KÌKÌ MẸ́ŃBÀ ÌDÍLÉ RẸ ÀTI ẸNIKẸ́NI TÍ Ó BÁ Ọ WÁ NÍNÚ ỌKỌ̀ AYỌ́KẸ́LẸ́ RẸ. Ó dára láti rí i pé ipò nǹkan ti sunwọ̀n sí i dáadáa nípa ọ̀ràn yìí, èyí sì ti mú kí ẹ̀mí ìfẹ́ tí a ń fi hàn ní àwọn àpéjọpọ̀ pọ̀ sí i. Ní àwọn gbọ̀ngàn àpéjọ púpọ̀ jù lọ, ó máa ń rọrùn láti dé orí àwọn ìjókòó kan ju àwọn mìíràn lọ. Jọ̀wọ́ fi ìgbatẹnirò hàn, kí o sì fi àwọn ìjókòó tí ó túbọ̀ rọrùn sílẹ̀ fún àwọn àgbàlagbà àti àwọn mìíràn tí àyíká ipò wọn béèrè fún wọn. Rántí pé ‘ìfẹ́ kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.’—1 Kọ́r. 13:4, 5; Fílí. 2:4.
19 Àwọn Kámẹ́rà, Àwọn Agbohùn-Gbàwòrán-Sílẹ̀, àti Àwọn Agbohùnsílẹ̀-Sórí-Kásẹ́ẹ̀tì: O lè lo kámẹ́rà àti ohun èlò tí ń gba ohùn tàbí àwòrán sílẹ̀ ní àpéjọpọ̀. Ṣùgbọ́n, o kò gbọ́dọ̀ fi lílò tí o ń lò wọ́n pín ọkàn àwọn ẹlòmíràn níyà. Rírìn káàkiri ní àkókò ìjókòó láti ya àwòrán yóò ṣèdíwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ń gbìyànjú láti pọkàn pọ̀ sórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. A kò gbọ́dọ̀ so ohun èlò èyíkéyìí tí a fi ń gba ohùn tàbí àwòrán sílẹ̀ mọ́ iná tàbí mọ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́dọ̀ fi ohun èlò yìí dí àwọn ọ̀nà àbákọjá tí ó wà láàárín ìjókòó, àwọn ọ̀nà àrìnlọrìnbọ̀, tàbí kí a fi dí ojú àwọn ẹlòmíràn.
20 Ìtọ́jú Ojú Ẹsẹ̀: Ẹ̀ka Ìtọ́jú Ojú Ẹsẹ̀ wà fún ìtọ́jú pàjáwìrì nìkan. Jọ̀wọ́ mú asipirín-ìn, àwọn oògùn amóúnjẹ-dà, báńdéèjì, pín-ìnnì, àti àwọn ohun èlò bẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ tìrẹ wá, níwọ̀n bí irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ kì yóò ti sí ní àpéjọpọ̀. Kí àwọn tí wọ́n bá mọ̀ pé àwọn àrùn tí ń fi gìrì múni, àrùn àìtó ṣúgà lára, àrùn ọkàn-àyà, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lè kọ lu àwọn mú àwọn egbòogi tí ó pọndandan dání. Kí ọ̀kan lára àwọn mẹ́ńbà ìdílé wọn tàbí mẹ́ńbà ìjọ tí ó lóye ipò wọn tí ó sì lè bójú tó wọn bí ohun pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀ wà pẹ̀lú wọn nígbà gbogbo nítorí bí èyí bá ṣẹlẹ̀. Ìṣòro ti ṣẹlẹ̀ ní àwọn àpéjọpọ̀ nígbà tí a fi àwọn kan tí wọ́n ní ìṣòro àìlera wíwúwo sílẹ̀ ní àwọn nìkan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ àìsàn. Bí àwọn kan tí wọ́n ní àkànṣe àìní ní ti ìlera kò bá ní àwọn mẹ́ńbà ìdílé tí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́, a ní láti jẹ́ kí àwọn alàgbà ìjọ wọn mọ̀ nípa ipò náà, kí wọ́n sì ṣe àwọn ètò tí ó pọndandan láti ṣèrànwọ́. Kò ṣeé ṣe láti pèsè àwọn àkànṣe iyàrá ní àwọn àpéjọpọ̀ láti fi ṣe ibùwọ̀ fún àwọn tí wọ́n máa ń ṣàìsàn nítorí àyíká tí wọ́n bá wà tàbí tí wọ́n ní àwọn èèwọ̀ ara.
21 Oúnjẹ ní Àpéjọpọ̀: Kí olúkúlùkù tí ó wá sí àpéjọpọ̀ mú oúnjẹ tirẹ̀ wá dípò kíkúrò ní gbọ̀ngàn àpéjọ ní àkókò ìsinmi ráńpẹ́ ní ọ̀sán láti ra nǹkan níta. Ìpápánu díẹ̀ ti tó, èyí tí ń ṣara lóore tí ó sì rọrùn láti gbé dání. Àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1997, ìpínrọ̀ 18, fún wa ní òye díẹ̀ nípa ohun tí a lè mú wá. A kò fàyè gba àwọn ohun èlò ìkó-nǹkan-sí tí a fi gíláàsì ṣe àti ohun mímu ọlọ́tí líle ní gbọ̀ngàn àpéjọpọ̀. Àwọn kúlà tàbí àpò oúnjẹ ní láti kéré débi tí yóò fi lè wọ abẹ́ ìjókòó rẹ. A ti rí àwọn kan lára àwùjọ tí wọ́n ń jẹ tí wọ́n sì ń mu nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ń lọ lọ́wọ́. Èyí ń fi àìlọ́wọ̀ hàn fún àkókò náà.
22 Ẹ wo bí inú wa ṣe dùn tó pé Àpéjọpọ̀ “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” ti 1998 máa tó bẹ̀rẹ̀! Ìwọ ha ti ṣe gbogbo ètò láti wà níbẹ̀ bí? Kí Ọlọ́run pa ọ́ mọ́ nínú ìrìn àjò rẹ kí o sì padà sílé pẹ̀lú ìsọdọ̀tun tẹ̀mí, kí o pinnu láti máa tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìsìn ṣíṣeyebíye ti Jèhófà kí o sì máa rin ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́ fún ìbùkún rẹ ayérayé.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Ìránnilétí Àpéjọpọ̀
▪ Ìbatisí: Kí àwọn tí ó fẹ́ ṣe batisí wà lórí ìjókòó wọn ní apá tí a yà sọ́tọ̀ fún wọn ṣáájú kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ ní òwúrọ̀ Saturday. Olúkúlùkù ẹni tí ó wéwèé láti ṣe batisí ní láti mú aṣọ ìwẹ̀ tí ó bójú mu àti aṣọ ìnura wá. Ní ìgbà tí ó ti kọjá, àwọn kan ti wọ aṣọ tí kò yẹ tí ó sì tàbùkù sí àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Àwọn alàgbà ìjọ tí ń ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tí ó wà nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa pẹ̀lú àwọn tí ó fẹ́ ṣe batisí gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lóye kókó wọ̀nyí. Ìbatisí ní ìṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ ẹnì kan jẹ́ ọ̀ràn kan tí ó kanni gbọ̀ngbọ̀n, tí ó sì jẹ́ ti ara ẹni, láàárín ẹni náà àti Jèhófà. Nípa báyìí, kò bójú mu pé kí àwọn tí ó fẹ́ ṣe batisí wà mọ́ ara wọn tàbí kí wọ́n di ọwọ́ ara wọn mú nígbà tí a ń batisí wọn.
▪ Káàdì Àyà: Jọ̀wọ́, lẹ káàdì àyà ti 1998 mọ́ àyà nígbà gbogbo nígbà tí ó bá wà ní ìlú àpéjọpọ̀ náà àti nígbà tí o bá ń rìnrìn àjò lọ síbẹ̀ àti nígbà tí o bá ń darí bọ̀. Èyí sábà máa ń ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún wa láti jẹ́rìí lọ́nà rere. Kí o gba káàdì àyà àti ike rẹ̀ ní ìjọ rẹ, níwọ̀n bí wọn kì yóò ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àpéjọpọ̀ náà. Má ṣe dúró títí di ìgbà tí àpéjọpọ̀ bá ku ọjọ́ díẹ̀ kí o tó béèrè fún káàdì rẹ àti tí ìdílé rẹ. Rántí láti mú káàdì Advance Medical Directive/Release rẹ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ dání.
▪ Ilé Gbígbé: A tún ń béèrè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbogbòò ní ti ilé ibùwọ̀ tí àpéjọpọ̀ pèsè. Bí a bá ré ìṣètò Society kọjá, tí a sì gba ilé ibùwọ̀ tí àpéjọpọ̀ ti gbà tẹ́lẹ̀, a ń jin iṣẹ́ àṣekára àwọn arákùnrin wa lẹ́sẹ̀ ni, àwọn tí ó jẹ́ pé wọ́n dúnàádúrà fún iye owó tí ó dára gan-an. BÍ O BÁ NÍ ÌṢÒRO LÓRÍ ILÉ IBÙWỌ̀, jọ̀wọ́, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti mú un wá sí àfiyèsí alábòójútó Ẹ̀ka Ilé Gbígbé ní àpéjọpọ̀ náà, kí ó bàa lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yanjú ọ̀ràn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Akọ̀wé ìjọ ní láti rí i dájú pé àwọn fọ́ọ̀mù Special Needs Room Request ni a tètè fi ṣọwọ́ sí àdírẹ́sì àpéjọpọ̀ tí ó yẹ. Bí o bá ní láti fagi lé wíwọ̀ sí ilé ibùwọ̀ kan tí a ṣètò nípasẹ̀ ètò fún àwọn àìní àkànṣe, o ní láti fi tó onílé náà àti Ẹ̀ka Ilé Gbígbé àpéjọpọ̀ náà létí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kí a bàa lè yan iyàrá náà fún ẹlòmíràn.
▪ Iṣẹ́ Ìsìn Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni: Ìwọ ha lè ya àkókò díẹ̀ sọ́tọ̀ ní àpéjọpọ̀ náà láti ṣèrànwọ́ nínú ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ bí? Sísin àwọn arákùnrin rẹ, bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ fún kìkì wákàtí díẹ̀, yóò ṣèrànwọ́ gidigidi yóò sì mú ìtẹ́lọ́rùn ti ara ẹni púpọ̀ wá. Bí o bá lè ṣèrànwọ́, jọ̀wọ́, fara hàn ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni ti àpéjọpọ̀ náà. Àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọdún 16 pẹ̀lú lè ṣe ìtìlẹ́yìn dáadáa nípa ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú òbí wọn tàbí pẹ̀lú àgbàlagbà mìíràn tí ó ṣeé fi ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́.
▪ Ìkìlọ̀: Rí i dájú pé o ti ọkọ̀ rẹ pa nígbà gbogbo, má sì ṣe fi ohunkóhun tí ojú lè tó sílẹ̀ láti dẹ ẹnì kan wò láti jalè. Àwọn olè àti àwọn jáwójáwó máa ń fojú sun àwọn ìkórajọpọ̀ ńlá. Kò bọ́gbọ́n mu láti fi ohunkóhun tí ó ṣe iyebíye sílẹ̀ lórí ìjókòó rẹ. Kò lè dá ọ lójú pé gbogbo ẹni tí ó wà ní àyíká rẹ ni ó jẹ́ Kristẹni. Èé ṣe tí ìwọ yóò fi dán àwọn ẹlòmíràn wò? A ti rí ìròyìn gbà nípa ìgbìdánwò àwọn ará ìta kan láti tan àwọn ọmọdé lọ. JẸ́ KÍ ÀWỌN ỌMỌ RẸ WÀ LỌ́DỌ̀ RẸ NÍGBÀ GBOGBO.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n àti ti fídíò tí ó wà ní ọ̀pọ̀ hòtẹ́ẹ̀lì sábà máa ń gbé àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè jáde. Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọdé lo tẹlifíṣọ̀n tí ó wà nínú iyàrá láìbójútó wọn.