Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní September: Ìfilọni àkànṣe ti àdìpọ̀ oríṣi ìwé méjì fún ₦40 àti àdìpọ̀ ìwé mẹ́rin fún ₦80, tí ẹ lè béèrè fún láti ẹ̀ka ilé iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú lẹ́tà wa ti March 23, 1998. Bákan náà, a lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé olójú ewé 192 ní èdè èyíkéyìí tí ìjọ lè ní lọ́wọ́, yàtọ̀ sí Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa àti Iwe-Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun lọni ní àkànṣe ọrẹ ₦20. Ẹ lè béèrè fún ẹ̀dínwó lórí àwọn ìwé wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú lẹ́tà wa. October: Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tàbí fún ìwé ìròyìn méjèèjì. November: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. December: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun àti Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. ÀKÍYÈSÍ: Kí àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé ìgbétáásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òun yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní September 1 tàbí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó lẹ́yìn náà. Ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe èyí.
◼ A ń rán àwọn alàgbà létí láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìtọ́ni tí a pèsè nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti April 15, 1991, ní ojú ìwé 21 sí 23, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn tí a yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tí wọ́n yọ ara wọn lẹ́gbẹ́, tí wọ́n lè fẹ́ pé kí a gba àwọn padà.
◼ Kí àwọn tí ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ fi gbogbo àsansílẹ̀ owó tuntun àti ìsọdituntun fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, títí kan àsansílẹ̀ owó tiwọn fúnra wọn ránṣẹ́ nípasẹ̀ ìjọ.
◼ Kì í ṣe Society ni ó ń kọ ìwé ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alábòójútó olùṣalága ṣètò fún ìfilọ̀ lóṣooṣù kí a tó fi ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ìjọ lóṣooṣù ránṣẹ́ sí Society kí gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ láti gba ìwé ti ara rẹ̀ lè sọ fún arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi àwọn ìtẹ̀jáde tí ó jẹ́ ìbéèrè àkànṣe sọ́kàn.
◼ A ti ṣe àwọn àtúnṣe tí ó tẹ̀ lé e yìí sí “Àwọn Ọ̀gangan Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ti 1998” tí ó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 1998. Kí alábòójútó olùṣalága ìjọ èyíkéyìí tí a ti yí déètì tàbí ọgangan àpéjọpọ̀ wọn padà jọ̀wọ́ ṣètò kí a ṣe ìfilọ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí ó tẹ̀ lé e lẹ́yìn tí a bá ti gba Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí.
November 6-8, 1998
Agbor 1 (Gẹ̀ẹ́sì) ME-11A; ME-15: J sí Z; ME-18: Elovie, Emu Obodoeti, Emu Uno, àti Umia.
November 20-22, 1998
Ibadan 3 (Yoruba) Àwọn ìjọ Y-10 tí a kò yàn sí Ìbàdàn 1; Y-12, 33.
December 4-6, 1998
Dálùwọ́n 6 (Yorùbá) Y-8, 29.