Àbá Kan
September jẹ́ oṣù mìíràn tí a óò fi àwọn ìtẹ̀jáde àdìpọ̀ lọ gbogbo ènìyàn ní ẹ̀dínwó. O lè fi kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ nípa dídi ojúlùmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí tí ìjọ rẹ ní lọ́wọ́. Wà lójúfò láti dámọ̀ràn wọn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn mìíràn tí ó bá fi ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú kókó ẹ̀kọ́ kan pàtó. Àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ tí a lè gbà gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ ni a lè rí nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù June, July, àti August. Ó dára pé kí o ṣàtúnyẹ̀wò wọn láti ṣe àṣeyọrí tí ó dára jù lọ nínú fífi wọ́n sóde.