Àwọn Alábòójútó Tí Ń Mú Ipò Iwájú—Alábòójútó Iṣẹ́ Ìsìn
1 Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ní ọkàn-ìfẹ́ gidigidi nínú gbogbo nǹkan tí ó jẹ mọ́ ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ ìjíhìnrere ní ìpínlẹ̀ tí a yàn fún ìjọ. Nípa báyìí, ó ń kó ipa pàtàkì nínú ríràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí ẹrù iṣẹ́ wa láti wàásù ìhìn rere náà. Gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere onítara, ó ń mú ipò iwájú nínú ṣíṣètò gbogbo àwọn ọ̀ràn tí ó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìsìn. Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ dídáńgájíá, ó ń ran akéde kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti mú kí ìgbéṣẹ́ wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ sunwọ̀n sí i.—Éfé. 4:11, 12.
2 Ní tààràtà, alàgbà yìí ni ó máa ń bójú tó iṣẹ́ àwọn ìránṣẹ́ tí a yàn láti máa bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ìwé ìròyìn, àti àwọn ìpínlẹ̀. Òun ni ó ni ẹrù iṣẹ́ láti rí i dájú pé ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ìwé ìròyìn, àti àwọn fọ́ọ̀mù iṣẹ́ ìsìn tí ó tó wà lọ́wọ́ lóṣooṣù fún ìlò wa. Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, ó máa ń ṣàyẹ̀wò fáìlì ìpínlẹ̀ láti mọ àwọn àdírẹ́sì ilé tí a sọ fún wa pé kí a má ṣèbẹ̀wò sí, ó sì máa ń yan àwọn arákùnrin tí ó tóótun láti bẹ àwọn ilé wọ̀nyí wò.
3 Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni ó ni ẹrù iṣẹ́ láti bójú tó onírúurú ẹ̀ka iṣẹ́ ìwàásù, títí kan ìjẹ́rìí ní ibi iṣẹ́ ajé, ní òpópónà, àti nípasẹ̀ tẹlifóònù. Ó máa ń wà lójúfò láti ṣe ètò tí ó gbéṣẹ́ láti pàdé fún iṣẹ́ ìsìn jálẹ̀ ọ̀sẹ̀, títí kan àkókò ọlidé. Ó máa ń fi ojúlówó ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú ìgbòkègbodò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó máa ń wá àwọn ọ̀nà láti fi ìrànwọ́ tẹ̀mí fún àwọn tí kò bá ṣe déédéé tàbí àwọn tí kò gbéṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ó máa ń ṣàníyàn gidigidi nípa iṣẹ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà, ó sì ń bójú tó ìṣètò Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́.
4 Gẹ́gẹ́ bí mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ, alábòójútó iṣẹ́ ìsìn máa ń dábàá àwọn ìyípadà yíyẹ nínú àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Nígbà tí ó bá ń bẹ àwùjọ rẹ wò, rí i dájú pé o wà níbẹ̀ kí o sì bá a jáde nínú iṣẹ́ ìsìn pápá.
5 Kí gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìjọ ṣe tán láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bá pèsè. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ìdáńgájíá wa nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn dára sí i, a óò sì rí ìdùnnú tí ó pọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.