Àpótí Ìbéèrè
◼ O ha ti múra sílẹ̀ de ìṣòro pàjáwìrì bí?
Nínú ayé ìgbàlódé yìí, “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” máa ń para pọ̀ dá ipò pàjáwìrì sílẹ̀ nínú ìtọ́jú ìṣègùn, títí kan fífagbára múni láti gba ẹ̀jẹ̀ sára. (Oníw. 9:11) Kí a bàa lè múra sílẹ̀ de irú ipò kàráǹgídá bẹ́ẹ̀, Jèhófà ti pèsè ìrànlọ́wọ́ lóríṣiríṣi ọ̀nà nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí a ṣe ipa tiwa. Àwọn kókó tó wà nísàlẹ̀ yìí yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́.
• Máa mú káàdì Advance Medical Directive/Release ti lọ́ọ́lọ́ọ́ dání nígbà gbogbo.
• Rí i dájú pé àwọn ọmọ rẹ ń mú Káàdì Ìdánimọ̀ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ dání.
• Ṣàtúnyẹ̀wò àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 1997, ṣe ìfidánrawò bóo ṣe lè bá àwọn dókítà àti adájọ́ fèrò wérò nípa irú ìtọ́jú tóo fẹ́ fọ́mọ rẹ.
• Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn àpilẹ̀kọ lórí àwọn èròjà inú ẹ̀jẹ̀ àti àwọn nǹkan táa lè lò dípò ẹ̀jẹ̀. (A dámọ̀ràn pé kí o wo: Ilé-Ìṣọ́nà, October 1, 1994, ojú ìwé 31; June 1, 1990, ojú ìwé 30 àti 31; March 1, 1989, ojú ìwé 30 àti 31; Jí!, December 8, 1994, ojú ìwé 23 sí 27; August 8, 1993, ojú ìwé 22 sí 25; April 22, 1992, ojú ìwé 10; àtàwọn àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, September 1992 àti August 1994. Kí wọ́n wà nínú fáìlì tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó.)
• Ṣe ìpinnu tó bá ẹ̀rí-ọkàn rẹ mu nípa bóyá o lè gbà kí wọ́n lo àwọn ẹ̀rọ tí ẹ̀jẹ̀ máa ń ṣàn gba inú wọn lóde ara tàbí bóyá wàá tẹ́wọ́ gba àwọn ohun kan tó ní èròjà tó tinú ẹ̀jẹ̀ wá.
• Kóo tó lọ sí ọsibítù, bí àyè ẹ̀ bá yọ, jẹ́ kí àwọn alàgbà mọ̀ kí wọ́n bàa lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, kí wọ́n sì kàn sí Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC) bó bá pọndandan. Bó bá jẹ́ ọmọdé ni, sọ fún àwọn alàgbà kí wọ́n tètè fi tó HLC létí.
Jẹ́ Kó Yé Wọn Pé O Ò Ní Gbẹ̀jẹ̀ Sẹ́ẹ̀: A ń gbọ́ pé àwọn ará kan máa ń dúró dìgbà tó máa fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ sórí kí wọ́n tó sọ fún dókítà tó ń tọ́jú wọn pé wọn ò fẹ́ gbẹ̀jẹ̀. Èyí kò gba tàwọn oníṣẹ́ ìṣègùn rò, wọ́n sì lè tìtorí èyí fa ẹ̀jẹ̀ sí ẹ lára. Bí àwọn dókítà bá mọ̀ pé àkọsílẹ̀ táa fọwọ́ sí wà tó ṣàlàyé yékéyéké nípa ìgbàgbọ́ àti ìpinnu rẹ, tó sì sọ ohun tóo fẹ́, èyí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹpá mọ́ṣẹ́ láìjáfara, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ní oríṣiríṣi ohun tí wọ́n lè lò fún ìtọ́jú tí kò ní wé mọ́ lílo ẹ̀jẹ̀.
Níwọ̀n bí ipò pàjáwìrì tó kan ọ̀ràn ìṣègùn ti lè ṣẹlẹ̀ nígbàkigbà, tó sì sábà máa ń jẹ nígbà tí o ò retí, gbé ìgbésẹ̀ nísinsìnyí láti dáàbò bo ara rẹ àtàwọn ọmọ rẹ kúrò lọ́wọ́ ìfàjẹ̀sínilára.—Òwe 16:20; 22:3.