Àpótí Ìbéèrè
◼ Ó ha yẹ kí àwùjọ pàtẹ́wọ́ fún gbogbo ẹni tí ó ṣiṣẹ́ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun tàbí nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn bí?
1 Àwọn àwùjọ tí ó jẹ́ àwọn ènìyàn Jehofa jẹ́ onímọrírì ní tòótọ́. Ó jẹ́ ohun tí ó dára pé wọ́n fẹ́ fi ìmọrírì náà hàn fún ìsapá àwọn ará wọn àti àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbé kalẹ̀ lórí pèpéle. Ní ọjọ́ wa, ní àwọn ibì kan nínú ayé, a máa ń fi irú ìmọrírì bẹ́ẹ̀ hàn nípa pípàtẹ́wọ́. Ṣùgbọ́n, ó yẹ kí àtẹ́wọ́ pípa jẹ́ ohun àìgbèròtẹ́lẹ̀, tí ó wá láti inú ọkàn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó sábà máa ń jẹ́ fífi ìmọrírì hàn fún ohun kan tí ó gọntíọ. Àti pẹ̀lú, ní àwọn àpéjọ ńlá, títí kan àwọn àpéjọ àyíká, níbi tí a ti ń ṣètò fún àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ àkànṣe, tí àwọn arákùnrin wa sì ń lo ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá láti múra iṣẹ́ wọn sílẹ̀, àwọn àwùjọ máa ń pàtẹ́wọ́ láàárín ọ̀rọ̀, kì í ṣe nígbà tí ọ̀rọ̀ bá parí nìkan.
2 Ṣùgbọ́n, èyí ha ní láti rí bẹ́ẹ̀ ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa bí? Dájúdájú, kò sí òfin kankan tí ó dè é, bí ó bá ṣẹlẹ̀ láìgbèròtẹ́lẹ̀, tí ó sì wá láti inú ìmọrírì àtọkànwá. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ìlànà wa, a kì í pàtẹ́wọ́ fún àwọn tí ó ṣiṣẹ́ wọ̀nyí, nítorí pé, fún ohun kan, ó lè di ohun afaraṣe-máfọkànṣe, kí ò sì máà nítumọ̀.
3 Bí ó ti wù kí ó rí, ohun kan wà tí gbogbo àwa tí a wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa lè ṣe láti fi ojúlówó ìmọrírì hàn fún ìsapá ẹni tí ń bá wa sọ̀rọ̀, èyí sì jẹ́ láti wà lójúfò nígbà tí ọ̀rọ̀ náà ń lọ lọ́wọ́, ní títẹjú mọ́ ọn, àti ní fífi hàn pé a ń tẹ̀ lé e, a sì ń jàǹfààní nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, nípa ìrí ojú wa. Síwájú sí i, ó máa ń ṣeé ṣe lọ́pọ̀ ìgbà láti bá olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé, láti sọ fún un pé a gbádùn ìgbékalẹ̀ rẹ̀.