ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 10/1 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Jẹ́ Kí Ọlọ́run Alààyè Tọ́ Ẹ Sọ́nà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àwọn Ìpín Tó Tara Èròjà Ẹ̀jẹ̀ Wá, Àtàwọn Ọ̀nà Kan Tí Wọ́n Ń Gbà Ṣiṣẹ́ Abẹ
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 10/1 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Yoo ha jẹ́ ohun yíyẹ lati gba abẹ́rẹ́ àjẹsára tabi awọn omi-abẹ́rẹ́ ìṣègùn kan tí ó ní “albumin” tí ó ti inú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn wá bí?

Kí a kúkú sọjú abẹ níkòó, Kristian kọ̀ọ̀kan ni ó gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu ti araarẹ̀ lórí èyí.

Awọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ń fi pẹlu ẹ̀tọ́ fẹ́ lati ṣègbọràn sí ìtọ́sọ́nà tí a rí ní Iṣe 15:​28, 29, lati takété sí ẹ̀jẹ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, awọn Kristian kò ní jẹ ẹran tí a kò dúńbú tabi awọn ohun àmújáde bíi sọ́séèjì ẹlẹ́jẹ̀. Ṣugbọn òfin Ọlọrun ṣeé fisílò ninu ọ̀ràn ìṣègùn. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa máa ń mú àkọsílẹ̀ kan rìn tí a kọ ọ́ sí pé wọn kọ ‘ìfàjẹ̀sínilára, ògidì ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa, sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ funfun, awọn èròjà pẹlẹbẹ inú ẹ̀jẹ̀, tabi omi inú ẹ̀jẹ̀.’ Bí ó ti wù kí ó rí, ti omi-abẹ́rẹ́ serum tí ó ní ìwọ̀n èròjà protein ẹlẹ́jẹ̀ díẹ̀ ninu ńkọ́?

Awọn Ẹlẹ́rìí ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ pé èyí jẹ́ ọ̀ràn kan tí ó jẹ́ ti ìpinnu ara-ẹni ní ìbámu pẹlu ẹ̀rí-ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí a ti fí Bibeli kọ́. Èyí ni a ṣàlàyé ninu “Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Onkawe” ti Ilé-Ìṣọ́nà ti June 1, 1990, èyí tí ó jíròrò omi-abẹ́rẹ́ serum tí oníṣègùn kan lè dámọ̀ràn rẹ̀ bí awọn àrùn kan bá ń yọ ẹnìkan lẹ́nu. Awọn èròjà mímúná ti irú omi-abẹ́rẹ́ bẹ́ẹ̀ kìí ṣe omi inú ẹ̀jẹ̀ fúnraarẹ̀ ṣugbọn èròjà agbóguntàrùn lati inú omi inú ẹ̀jẹ̀ awọn wọnnì tí ara wọn ti mú àjẹsára lòdìsí àrùn bẹ́ẹ̀ dàgbà. Awọn Kristian kan tí wọn ronú pé awọn lè fi pẹlu ẹ̀rí-ọkàn rere gba irú omi-abẹ́rẹ́ bẹ́ẹ̀ ti ṣàkíyèsí pé awọn èròjà agbóguntàrùn lati inú ẹ̀jẹ̀ obìnrin aboyún kan ń kọjá sí inú ẹ̀jẹ̀ ọmọ-ọwọ́ tí ó wà ninu ọlẹ̀ rẹ̀. “Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Onkawe” mẹ́nukan eléyìí, ó sì tún mẹ́nukan òtítọ́ naa pé albumin ń kọjá lati ara obìnrin aboyún kan sára ọmọ rẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ rí i pé èyí yẹ fún àfiyèsí, níwọ̀n bí awọn abẹ́rẹ́ àjẹsára kan tí a kò fi ẹ̀jẹ̀ ṣe ti lè ní ìwọ̀n ti albumin omi inú ẹ̀jẹ̀ tí ó kéré ní ìfiwéra, tí a lò nígbà tí a ń ṣe wọn tabi fikún un lati mú kí awọn èròjà naa ki mọ́ra. Ní lọ́ọ́lọ́ọ́ albumin níwọ̀ǹba ni a tún ń lò lati fi ṣe awọn omi-abẹ́rẹ́ omi-ìsúnniṣe oníkẹ́míkà EPO (erythropoietin). Awọn Ẹlẹ́rìí kan ti gba omi-abẹ́rẹ́ EPO nitori pé ó lè fikún ìmújáde sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ìtura bá oníṣègùn kan kúrò ninu ríronú pé ìfàjẹ̀sínilára lè pọndandan.

Awọn ìṣètò ìṣègùn mìíràn lè yọjú fún lílò lọ́jọ́ iwájú tí yoo ní ìwọ̀nba albumin ninu ní ìfiwéra, níwọ̀n bí awọn ilé-iṣẹ́ apòògùn ti ń mú awọn ohun titun sísunwọ̀n síi jáde tabi yí ìlànà àwòṣe awọn tí ó wà tẹ́lẹ̀ padà. Nipa bayii awọn Kristian lè fẹ́ lati gbé e yẹ̀wò bóyá albumin wà ninu abẹ́rẹ́ àjẹsára kan tabi omi-abẹ́rẹ́ mìíràn tí dókítà dámọ̀ràn. Bí wọn bá ń ṣiyèméjì tabi ní ìdí lati gbàgbọ́ pé albumin wà lára èròjà tí a fi ṣe é, wọn lè wádìí lọ́wọ́ oníṣègùn wọn.

Gẹ́gẹ́ bí a tí kíyèsi, ọ̀pọ̀ awọn Ẹlẹ́rìí kò kọ̀ lati gba omi-abẹ́rẹ́ tí ó ní ìwọ̀ǹba albumin díẹ̀ ninu. Síbẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ lati túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀ràn naa jinlẹ̀jinlẹ̀ ṣáájú ṣíṣe ìpinnu níláti gbé ìsọfúnni tí a gbé jáde ninu “Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Onkawe Wa” ti inú Ilé-Ìṣọ́nà June 1, 1990 yẹ̀wò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́