ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 6/15 ojú ìwé 19-24
  • Jẹ́ Kí Ọlọ́run Alààyè Tọ́ Ẹ Sọ́nà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí Ọlọ́run Alààyè Tọ́ Ẹ Sọ́nà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lílo Ẹ̀jẹ̀ Bí Oògùn
  • Ipa Tí Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Ń Kó
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Àwọn Ìpín Tó Tara Èròjà Ẹ̀jẹ̀ Wá, Àtàwọn Ọ̀nà Kan Tí Wọ́n Ń Gbà Ṣiṣẹ́ Abẹ
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 6/15 ojú ìwé 19-24

Jẹ́ Kí Ọlọ́run Alààyè Tọ́ Ẹ Sọ́nà

“Yí padà . . . sọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè, ẹni tí ó ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti gbogbo ohun tí ń bẹ nínú wọn.”—ÌṢE 14:15.

1, 2. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé Jèhófà ni “Ọlọ́run alààyè”?

LẸ́YÌN tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wo ọkùnrin kan sàn ní Lísírà, Pọ́ọ̀lù mú kó dá àwọn tó wà níbẹ̀ lójú pé: “Àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn tí ó ní àwọn àìlera kan náà tí ẹ̀yin ní, a sì ń polongo ìhìn rere fún yín, kí ẹ lè yí padà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè, ẹni tí ó ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti gbogbo ohun tí ń bẹ nínú wọn.”—Ìṣe 14:15.

2 Ẹ ò rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run alààyè,” kì í ṣe òrìṣà aláìlẹ́mìí! (Jeremáyà 10:10; 1 Tẹsalóníkà 1:9, 10) Yàtọ̀ sí pé Jèhófà ń bẹ láàyè, òun tún ni Orísun ìwàláàyè wa. “Òun fúnra rẹ̀ ni ó fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo.” (Ìṣe 17:25) Ó fẹ́ ká gbádùn ayé wa nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú. Pọ́ọ̀lù fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé Ọlọ́run “kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ láìsí ẹ̀rí ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín ní òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà yín dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Ìṣe 14:17.

3. Kí nìdí tá a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run?

3 Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa fún wa ní ìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. (Sáàmù 147:8; Mátíù 5:45) Àwọn kan lè máà fẹ́ gbẹ́kẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run tí wọ́n bá rí i pé àwọn òfin kan tó wà nínú Bíbélì kò yé àwọn tàbí tó bá jọ pé àwọn òfin náà ti le jù lójú wọn. Síbẹ̀, ẹ̀rí fi hàn pé ó jẹ́ ìwà ọgbọ́n láti gbẹ́kẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ: Bí ọmọ Ísírẹ́lì kan ò bá tiẹ̀ lóye ìdí tá a fi ṣòfin pé wọn ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan òkú ẹran tàbí tèèyàn, onítọ̀hún yóò jàǹfààní tó bá pa òfin náà mọ́. Àǹfààní kan ni pé, pípa tó bá pa òfin náà mọ́ yóò jẹ́ kó sún mọ́ Ọlọ́run alààyè; èkejì sì ni pé ẹni náà ò ní kó àrùn.—Léfítíkù 5:2; 11:24.

4, 5. (a) Ṣáájú àkókò àwọn Kristẹni, ìtọ́ni wo ni Jèhófà fi lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé ìtọ́ni tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ kan àwọn Kristẹni?

4 Bákan náà ni ìtọ́sọ́nà tí Ọlọ́run fúnni lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ ṣe rí. Ó sọ fún Nóà pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀. Nígbà tó yá nínú Òfin Mósè, Ọlọ́run jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé orí pẹpẹ nìkan la ti gbọ́dọ̀ lo ẹ̀jẹ̀, ìyẹn fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Ọlọ́run tipa àwọn òfin wọ̀nyẹn ṣètò sílẹ̀ fún ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tí a óò lo ẹ̀jẹ̀ fún, ìyẹn láti gba àwọn èèyàn là nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù. (Hébérù 9:14) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún wa fi hàn pé ó ní ire wa lọ́kàn. Nígbà tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adam Clarke tó gbé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún ń ṣàlàyé Jẹ́nẹ́sísì 9:4, 19, ó kọ̀wé pé: “Àwọn Kristẹni tó ń gbé ní Ìlà Oòrùn ayé ṣì máa ń wonkoko mọ́ òfin [tá a fún Nóà] yìí. . . . Òfin Mósè kò fàyè gba jíjẹ ẹ̀jẹ̀ nítorí pé ó ń tọ́ka sí ẹ̀jẹ̀ tí a óò dà jáde fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ aráyé; àti pé ní àkókò àwọn Kristẹni, kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ nítorí wọ́n gbà pé ó dúró fún ẹ̀jẹ̀ tá a dà jáde fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.”

5 Ó lè jẹ́ pé ìhìn rere pàtàkì nípa Jésù ni ọ̀mọ̀wé yìí ń tọ́ka sí. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan rírán tí Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ láti wá kú fún wa àti láti da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde kí á lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16; Róòmù 5:8, 9) Ọ̀rọ̀ ọ̀mọ̀wé náà tún kan òfin tí Kristi fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà tó sọ pé kí wọ́n ta kété sí ẹ̀jẹ̀.

6. Ìtọ́ni wo ni wọ́n fún àwọn Kristẹni lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀, kí sì ni ìdí tá a fi fún wọn nítọ̀ọ́ni yìí?

6 Ẹ mọ̀ pé Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún òfin. Nígbà tí Jésù sì ti kú, kì í ṣe ọ̀ranyàn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa pa gbogbo òfin náà mọ́. (Róòmù 7:4, 6; Kólósè 2:13, 14, 17; Hébérù 8:6, 13) Àmọ́ nígbà tó ṣe, ìbéèrè kan jẹ yọ lórí ohun kan tó jẹ́ ọ̀ranyàn, ìyẹn ìdádọ̀dọ́ fún àwọn ọkùnrin. Ǹjẹ́ ó ṣì pọn dandan pé kí àwọn tí kì í ṣe Júù, tí wọ́n fẹ́ láti jàǹfààní látinú ẹ̀jẹ̀ Kristi máa dádọ̀dọ́, láti fi hàn pé wọ́n ṣì wà lábẹ́ Òfin Mósè? Ní ọdún 49 Sànmánì Tiwa, ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti Kristẹni rí sí ọ̀ràn náà. (Ìṣe, orí karùndínlógún) Nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run, àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin fẹnu kò pé àṣà ìdádọ̀dọ́ tó pọn dandan tẹ́lẹ̀ ti bá Òfin Mósè dópin. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni ṣì gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà kan tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀. Nínú lẹ́tà kan tí ẹgbẹ́ olùṣàkóso kọ sí àwọn ìjọ, wọ́n sọ pé: “Ẹ̀mí mímọ́ àti àwa fúnra wa ti fara mọ́ ṣíṣàìtún fi ẹrù ìnira kankan kún un fún yín, àyàfi nǹkan pípọndandan wọ̀nyí, láti máa ta kété sí àwọn ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà àti sí ẹ̀jẹ̀ àti sí ohun tí a fún lọ́rùn pa àti sí àgbèrè. Bí ẹ bá fi tìṣọ́ra-tìṣọ́ra pa ara yín mọ́ kúrò nínú nǹkan wọ̀nyí, ẹ óò láásìkí.”—Ìṣe 15:28, 29.

7. Báwo ló ṣe ṣe pàtàkì tó fún àwọn Kristẹni láti ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀’?

7 Ó ṣe kedere pé ẹgbẹ́ olùṣàkóso gbà pé bó ṣe ṣe pàtàkì ká yàgò fún ìṣekúṣe àti ìbọ̀rìṣà bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ṣe pàtàkì ká ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀.’ Èyí fi hàn pé òfin tó ka lílo ẹ̀jẹ̀ léèwọ̀ yìí kì í ṣe ohun tá à ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú. Àwọn Kristẹni tó bá ń bọ̀rìṣà tàbí tí wọ́n ń ṣe ìṣekúṣe tí wọn ò sì ronú pìwà dà kò lè “jogún ìjọba Ọlọ́run”; “ìpín tiwọn yóò . . . túmọ̀ sí ikú kejì.” (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Ìṣípayá 21:8; 22:15) Ẹ kíyè sí ìyàtọ̀ yìí pé: Ṣíṣàìkọbi-ara sí ìtọ́ni Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀ lè yọrí sí ikú ayérayé. Bíbọ̀wọ̀ fún ẹbọ ìràpadà Jésù lè yọrí sí ìyè àìnípẹ̀kun.

8. Kí ló fi hàn pé àwọn Kristẹni ìjímìjí fi ọwọ́ pàtàkì mu ìtọ́ni tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀?

8 Báwo làwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe lóye ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún wọn lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀, báwo ni wọ́n sì ṣe ń tẹ̀ lé e? Ẹ jẹ́ ká padà sí ọ̀rọ̀ tí Clarke sọ, ó ní: “Ní àkókò àwọn Kristẹni, kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ nítorí wọ́n gbà pé ó dúró fún ẹ̀jẹ̀ tá a dà jáde fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.” Àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn jẹ́rìí sí i pé àwọn Kristẹni ìjímìjí kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀ràn náà rárá. Òǹkọ̀wé ni, Tertullian kọ ọ́ pé: “Ẹ gbé ọ̀rọ̀ àwọn tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ yẹ̀ wò, wọ́n á gba ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀daràn burúkú níbi pápá ìwòran . . . wọ́n á gbé e lọ fí wo àrùn wárápá tó ń ṣe wọ́n.” Àwọn kèfèrí máa ń jẹ ẹ̀jẹ̀, àmọ́ Tertullian sọ pé àwọn Kristẹni “kì í tiẹ̀ fi ẹ̀jẹ̀ ẹran pàápàá sínú oúnjẹ [wọn] . . . Tó bá tiẹ̀ jẹ́ àkókò àdánwò lo fún àwọn Kristẹni ní ẹran gígún [sọ́séèjì] tí wọ́n po ẹ̀jẹ̀ mọ́. Ó dájú pé kò bófin mu fún wọn láti jẹ irú ẹran bẹ́ẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni o, bí wọ́n tilẹ̀ halẹ̀ ikú mọ́ àwọn Kristẹni, wọn ò ní jẹ ẹ̀jẹ̀. Ìtọ́ni Ọlọ́run ṣe pàtàkì sí wọn gan-an ni.

9. Kí ni nǹkan mìíràn tí títa kété sí ẹ̀jẹ̀ wé mọ́ yàtọ̀ sí pé ká má ṣe jẹ ẹ́ ní tààràtà?

9 Àwọn kan lè máa rò pé ohun tí ẹgbẹ́ olùṣàkóso wulẹ̀ ń sọ ni pé àwọn Kristẹni ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ tàbí kí wọ́n mu ú, tàbí kí wọn jẹ ẹran tí wọn ò dúńbú tàbí oúnjẹ tá a po ẹ̀jẹ̀ mọ́. Òótọ́ ni, ìyẹn gan-an lohun àkọ́kọ́ tí òfin tí Ọlọ́run fún Nóà ń sọ. Òfin tí àwọn àpọ́sítélì fi lélẹ̀ sọ pé káwọn Kristẹni ‘pa ara wọn mọ́ kúrò nínú ohun tí a fún lọ́rùn pa,’ ìyẹn ẹran tí ẹ̀jẹ̀ ṣẹ́ kù sí nínú. (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4; Ìṣe 21:25) Àmọ́, àwọn Kristẹni ìjímìjí mọ̀ pé àwọn nǹkan mìíràn ṣì wà tó wé mọ́ òfin yẹn. Nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń jẹ ẹ̀jẹ̀ fún ìtọ́jú ara. Tertullian sọ pé àwọn kèfèrí kan máa ń jẹ ẹ̀jẹ̀ tútù tìtorí pé wọ́n fẹ́ wo àìsàn wárápá tó ń ṣe wọ́n sàn. Ó sì ṣeé ṣe kí ọ̀nà mìíràn wà tí wọ́n gbà ń lo ẹ̀jẹ̀ láti fi wo àrùn tàbí tí wọ́n rò pé ó máa mú ara wọn le sí i. Nítorí náà, fún àwọn Kristẹni láti ta kété sí ẹ̀jẹ̀ kan pé kí wọ́n má ṣe lò ó fún ọ̀ràn “ìṣègùn.” Ìpinnu wọn nìyẹn bí ó tilẹ̀ máa fi ẹ̀mí wọn sínú ewu.

Lílo Ẹ̀jẹ̀ Bí Oògùn

10. Kí ni àwọn ọ̀nà kan tí wọ́n gbà ń lo ẹ̀jẹ̀ nínú ọ̀ràn ìṣègùn, ìbéèrè wo ló sì wá jẹ yọ nítorí ọ̀ràn náà?

10 Ó ti wá wọ́pọ̀ gan-an báyìí pé kí wọ́n máa lo ẹ̀jẹ̀ fún ọ̀ràn ìṣègùn. Ògidì ẹ̀jẹ̀ ni wọ́n máa ń fà séèyàn lára láyé ìgbà tí ìfàjẹ̀sínilára kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, ìyẹn ni pé tí wọ́n bá ti gba ẹ̀jẹ̀ lára ẹnì kan, wọ́n á tọ́jú ẹ̀jẹ̀ náà pa mọ̀ síbì kan, wọ́n á wá máa fà á sára ẹni tó ń gbàtọ́jú, èyí sì lè jẹ́ ẹnì tó fara gbọgbẹ́ lójú ogun. Àmọ́, bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn olùṣèwádìí mọ bí a ti ń pín ẹ̀jẹ̀ sí àwọn èròjà pàtàkì tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀. Fífa àwọn èròjà pàtàkì tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀ síni lára tí mú kó ṣeé ṣe fún àwọn oníṣègùn láti fa ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n gbà lára ẹnì kan sára ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbàtọ́jú, bíi kí wọ́n fa omi inú ẹ̀jẹ̀ sára ẹnì kan tó fara gbọgbẹ́ kí wọ́n sì fa sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ sára ẹlòmíràn. Ìwádìí tí kò dáwọ́ dúró tí wọ́n ń ṣe fi hàn pé ọ̀kan lára àwọn èròjà pàtàkì tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀, irú bi omi inú ẹ̀jẹ̀ ni a lè tú palẹ̀ sí ìpín kéékèèké tó pọ̀ gan-an tí wọ́n tún lè fà sí àwọn mìíràn tó ń gbàtọ́jú lára. Bí iṣẹ́ ìtúpalẹ̀ yìí ti ń bá a lọ ni wọ́n ń ròyìn àwọn ọ̀nà tuntun tí wọ́n ń gbà lo àwọn ìpín kéékèèké tí wọ́n ń rí nínú àwọn èròjà tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀. Kí ló wá yẹ kí Kristẹni ṣe nípa ìlò àwọn ìpín kéékèèké yìí? Ìpinnu wa ni pé a kí yóò gba ẹ̀jẹ̀ sára láé, àmọ́ ká ní pé dókítà ẹnì kan wá rọ̀ ọ́ pé kó gba ọ̀kan lára àwọn èròjà pàtàkì tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀, bóyá sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀. Tàbí kó jẹ́ pé ìpín kékeré lára àtúpalẹ̀ àwọn èròjà tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀ wà lára nǹkan tí wọ́n fi ń tọ́jú rẹ̀. Kí lohun tó yẹ kí ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe ní irú ipò yẹn, ní mímọ̀ pé ẹ̀jẹ̀ jẹ́ ohun ọlọ́wọ̀ àti pé ẹ̀jẹ̀ Kristi ló lè gbani là lọ́nà tó ga jù lọ?

11. Ìpinnu ọlọ́jọ́ pípẹ́ tó bá ọ̀rọ̀ ìṣègùn mu wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé?

11 Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ káwọn èèyàn mọ ìpinnu wọn lórí ọ̀rọ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n kọ àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association (November 27, 1981; àtúntẹ̀ rẹ̀ wà nínú ìwé pẹlẹbẹ How Can Blood Save Your Life? ojú ìwé 27 sí 29).a Wọ́n fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Jẹ́nẹ́sísì, Léfítíkù àti Ìṣe nínú àpilẹ̀kọ náà. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe èdè ìṣègùn ni wọ́n lò nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyẹn, síbẹ̀ ojú tí àwọn Ẹlẹ́rìí fi wo ohun táwọn ẹsẹ wọ̀nyẹn sọ ni pé a ò gbọ́dọ̀ gbẹ̀jẹ̀ sára, ì báà jẹ́ sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀, omi inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀ àti sẹ́ẹ̀lì pẹlẹbẹ inú ẹ̀jẹ̀.” Ìwé Emergency Care (Ìtọ́jú Pàjáwìrì) ti ọdún 2001, lábẹ́ àkòrí náà “Àwọn Ohun Tó Para Pọ̀ Di Ẹ̀jẹ̀,” sọ pé: “Àwọn èròjà pàtàkì bíi mélòó kan ló para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀, àwọn ni omi inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀ àti sẹ́ẹ̀lì pẹlẹbẹ inú ẹ̀jẹ̀.” Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ìṣègùn ṣe fi hàn, àwọn Ẹlẹ́rìí kì í gba ẹ̀jẹ̀ sára bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í gba èyíkéyìí lára èròjà pàtàkì mẹ́rin tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀ sára.

12. (a) Kí ni èrò wa nípa ìpín kékeré lára àtúpalẹ̀ àwọn èròjà pàtàkì tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀? (b) Ibo la ti lè rí àfikún ìsọfúnni lórí ọ̀ràn yìí?

12 Àpilẹ̀kọ lórí ọ̀ràn ìṣègùn yìí ń bá a lọ pé: “Ìsìn àwọn Ẹlẹ́rìí kò sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ lo [ìpín kékeré] lára àtúpalẹ̀ àwọn èròjà tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀, irú bíi èròjà albumin, immune globulins, àti hemophiliac; olúkúlùkù Ẹlẹ́rìí ló máa pinnu fúnra rẹ̀ bóyá kóun lò ó tàbí kóun má lò ó.” Láti ọdún 1981 làwọn èèyàn ti ya ìpín kéékèèké (inú àtúpalẹ̀ àwọn èròjà pàtàkì mẹ́rin tó para di ẹ̀jẹ̀) sọ́tọ̀ fún ọ̀ràn ìṣègùn. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ìsọfúnni tó wúlò lórí ọ̀rọ̀ yìí wà nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2000 nínú àpilẹ̀kọ náà “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé.” Fún àǹfààní ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn òǹkàwé ti ìsinsìnyí, a tún ìdáhùn náà tẹ̀ sí ojú ewé 29 sí 31 nínú ìwé ìròyìn yìí. Kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí ọ̀ràn yìí ló wà nínú àpilẹ̀kọ náà, àlàyé náà sì bọ́gbọ́n mu, síbẹ̀ wàá rí i pé àwọn ohun tí àpilẹ̀kọ náà sọ bá àwọn kókó pàtàkì tá a sọ lọ́dún 1981 mu.

Ipa Tí Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Ń Kó

13, 14. (a) Kí ni ẹ̀rí ọkàn, báwo ló sì ṣe kan ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀? (b) Ìtọ́ni wo ni Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ẹran jíjẹ, àmọ́ àwọn ìbéèrè wo ló ṣeé ṣe kó ti jẹ yọ?

13 Irú àwọn ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ń fẹ́ pé ká lo ẹ̀rí ọkàn wa nígbà tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu. Kí nìdí? Àwọn Kristẹni gbà pé ó yẹ káwọn máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, síbẹ̀ àwọn ipò kan wà tó jẹ́ pé àwa fúnra wa la máa pinnu ohun tó yẹ ká ṣe, ibi tí ọ̀rọ̀ ẹ̀rí ọkàn ti wọlé nìyẹn. Ẹ̀rí ọkàn jẹ́ nǹkan àdámọ́ni tá a lè máa fi yiiri ọ̀rọ̀ wò ká sì ṣe ìpinnu, àgàgà àwọn ọ̀rọ̀ tó bá wé mọ́ ìlànà ìwà rere. (Róòmù 2:14, 15) Àmọ́, bí ẹ̀rí ọkàn olúkálukú ṣe máa ń ṣiṣẹ́ yàtọ̀ síra.b Bíbélì sọ pé àwọn kan ní ‘ẹ̀rí-ọkàn aláìlera,’ tó túmọ̀ sí pé ẹ̀rí ọkàn àwọn mìíràn lágbára. (1 Kọ́ríńtì 8:12) Ìwọ̀n tí Kristẹni kọ̀ọ̀kan ti tẹ̀ síwájú dé nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run kò rí bákan náà, bẹ́ẹ̀ náà ni bí wọ́n ṣe ń lóye ohun tí Ọlọ́run sọ àti bí wọ́n ṣe ń lò ó nínú ìpinnu wọn máa ń yàtọ̀ síra. A lè fi ìtàn àwọn Júù àti ọ̀rọ̀ nípa ẹran jíjẹ ṣàpèjúwe èyí.

14 Bíbélì mú kó ṣe kedere pé ẹni tó bá jẹ́ onígbọràn sí Ọlọ́run kò ní jẹ ẹran tí a kò dúńbú. Ìtọ́ni yìí ṣe pàtàkì gan-an débi pé tí àwọn jagunjagun ọmọ Ísírẹ́lì bá jẹ ẹran tí á kò dúńbú àní nínú ipò pàjáwìrì pàápàá, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni wọ́n dá yẹn. (Diutarónómì 12:15, 16; 1 Sámúẹ́lì 14:31–35) Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí àwọn ìbéèrè kan ti jẹ yọ. Nígbà tọ́mọ Ísírẹ́lì kan bá pa àgùntàn, báwo ló ṣe gbọ́dọ̀ pẹ́ tó kó tó ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà nù? Ṣé ó pọn dandan kó la ọ̀fun ẹran náà kó lè ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà nù ni? Ǹjẹ́ ó pọn dandan kó dorí àgùntàn náà kodò, kó wá so ẹsẹ̀ rẹ̀ ẹ̀yìn mọ́ òkè? Tó bá tiẹ̀ so ó mókè, báwo ni kó ṣe pẹ́ tó? Báwo ló ṣe máa ro ẹ̀jẹ̀ màlúù tó bá tóbi dà nù? Kódà, lẹ́yìn tó ti ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà nù tán, ẹ̀jẹ̀ ṣì lè kù sára ẹran náà. Ǹjẹ́ ó máa lè jẹ irú ẹran bẹ́ẹ̀? Ta ló máa pinnu?

15. Báwo làwọn Júù kan ṣe hùwà padà lórí ọ̀rọ̀ ẹran jíjẹ, àmọ́ ìtọ́ni wo ni Ọlọ́run fún wọn?

15 Ká sọ pé ọmọ Júù onítara kan ló dojú kọ àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn. Ó lè rò pé ohun tó máa yọ òun ni pé kóun má jẹ ẹran tí wọ́n ń tà ní ìsọ̀ àwọn ẹlẹ́ran, ọmọ Júù míì lè máà fẹ́ jẹ ẹran tó bá mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti fi irú ẹran bẹ́ẹ̀ rúbọ sí òrìṣà. Ní ti àwọn Júù mìíràn, ó lè jẹ́ ìgbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ ro ẹ̀jẹ̀ ẹran náà dà nù ni wọ́n yóò tó fẹnu kàn án.c (Mátíù 23:23, 24) Báwo lo ṣe rí onírúurú ìṣarasíhùwà yìí sí? Láfikún sí i, níwọ̀n bí Ọlọ́run ò ti dìídì sọ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ó bójú mu pé káwọn Júù wá fi ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìbéèrè ránṣẹ́ sí ẹgbẹ́ àwọn rábì láti mọ ìpinnu wọn lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìbéèrè náà? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ìsìn àwọn Júù ni àṣà yìí ti bẹ̀rẹ̀, yóò múnú wa dùn láti mọ̀ pé Jèhófà ò fún àwọn olùjọsìn tòótọ́ ní ìtọ́ni pé kí wọ́n máa ṣe ìpinnu lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ lọ́nà yẹn. Ọlọ́run fún wọn ní ìtọ́ni pàtó nípa bí wọn ṣe máa pa ẹran tí ó mọ́ àti bí wọ́n á ṣe ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà nù, àmọ́ kò sọ jù bẹ́ẹ̀ lọ.—Jòhánù 8:32.

16. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni fi lè ní èrò tó yàtọ̀ síra nípa gbígba abẹ́rẹ́ tó jẹ́ ìpín kékeré lára ọ̀kan nínú àtúpalẹ̀ èròjà pàtàkì tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀?

16 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ní ìpínrọ̀ kọkànlá àti ìkejìlá, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gba ẹ̀jẹ̀ sára, a kì í sì í gba èyíkéyìí sára nínú èròjà pàtàkì mẹ́rin tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀, ìyẹn omi inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀, sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀ àti sẹ́ẹ̀lì pẹlẹbẹ inú ẹ̀jẹ̀. Àmọ́, ìpín kéékèèké tá a mú jáde nínú àtúpalẹ̀ àwọn èròjà pàtàkì tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀ ńkọ́, irú bíi aporó tó ń gbógun ti àrùn tàbí tá a lè fi poró ejò? (Wo ojú ìwé 30, ìpínrọ̀ 4 nínú ìwé ìròyìn yìí.) Àwọn kan gbà pé irú àwọn ìpín kékeré bẹ́ẹ̀ ti kúrò ní ẹ̀jẹ̀, torí náà wọ́n gbà pé òfin tó ní ká ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀’ kò kàn án. (Ìṣe 15:29; 21:25; ojú ìwé 31, ìpínrọ̀ 1) Àwọn fúnra wọn lo máa ru ẹrù ìpinnu tí wọ́n bá ṣe lórí ìyẹn. Ẹ̀rí ọkàn àwọn Kristẹni mìíràn sún wọn láti má ṣe lo ohunkóhun tó bá ti ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ (ì bá à jẹ́ ẹ̀jẹ̀ ẹran tàbí tèèyàn,) àní bó tilẹ̀ jẹ́ ìpín kékeré lára ọ̀kan nínú àtúpalẹ̀ èròjà pàtàkì tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀.d Síbẹ̀, àwọn mìíràn lè gbà kí wọ́n fún àwọn ní abẹ́rẹ́ èròjà protein tó jẹ́ ìpín kékeré lára àtúpalẹ̀ omi inú ẹ̀jẹ̀ kí wọ́n lè fi gbógun ti àrùn tàbí kí wọ́n fi poró ejò, àmọ́ wọ́n lè máà gba oríṣi ìpín kékeré mìíràn. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn oògùn kan tí wọ́n fi ọ̀kan lára èròjà pàtàkì inú ẹ̀jẹ̀ ṣe lè máa ṣiṣẹ́ kan náà tí ẹ̀jẹ̀ fúnra rẹ̀ ńṣe nínú ara, kó sì gbé ẹ̀mí rò, ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ Kristẹni fi gbà pé kò yẹ káwọn lo irú oògùn bẹ́ẹ̀.

17. (a) Báwo ni ẹ̀rí ọkàn wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá dojú kọ àwọn ìbéèrè nípa ìpín kéékèèké inú àtúpalẹ̀ àwọn èròjà tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ṣíṣe ìpinnu lórí ọ̀ràn yìí?

17 Ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀rí ọkàn wúlò gan-an nígbà tá a bá fẹ́ ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Ohun àkọ́kọ́ tó yẹ kó o ṣe ni pé kó o mọ ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ, kó o sì gbìyànjú láti mú ẹ̀rí ọkàn rẹ bá a mu. Èyí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó bá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run mu dípò tí wàá fi ní kí ẹnì kan ṣe ìpinnu fún ọ. (Sáàmù 25:4, 5) Tó bá kan ọ̀ràn lílo ìpín kékeré lára àtúpalẹ̀ èròjà ẹ̀jẹ̀, èrò àwọn kan ni pé, ‘Ọ̀ràn ẹ̀rí ọkàn ni, torí náà kó fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì.’ Èrò yẹn kò tọ̀nà. Nítorí pé a gbé ọ̀ràn kan ka ẹ̀rí ọkàn kò túmọ̀ sí pé ọ̀ràn ọ̀hún kò ṣe pàtàkì. Ọ̀ràn kékeré kọ́ o. Ìdí kan tí kì í fi í ṣe ọ̀ràn kékeré ni pé, ó lè nípa lórí àwọn mìíràn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò rí bíi tiwa. A lóye èyí látinú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù nípa ẹran tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti fi rúbọ sí òrìṣà, tí wọ́n wá lọ tà lọ́jà. Ó yẹ kí àwọn Kristẹni máa ṣàníyàn bí wọn ò ṣe ní ‘ṣá ẹ̀rí-ọkàn tí ó jẹ́ aláìlera lọ́gbẹ́.’ Tí Kristẹni kan bá mú ẹlòmíràn kọsẹ̀, ó lè ‘ṣe arákùnrin rẹ̀ tí Kristi tìtorí rẹ̀ kú lọ́ṣẹ́,’ kó sì ṣẹ̀ sí Kristi. Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé olúkúlùkù ló máa pinnu lórí ọ̀rọ̀ nípa ìpín kéékèèké inú àtúpalẹ̀ àwọn èròjà tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀, síbẹ̀ a ṣì ní láti fi ọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìpinnu náà.—1 Kọ́ríńtì 8:8, 11–13; 10:25–31.

18. Báwo làwọn Kristẹni ṣe lè yẹra fún sísọ ẹ̀rí ọkàn wọn dòkú tó bá kan ìpinnu lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀?

18 Kókó mìíràn tí a óò gbé yẹ̀ wò nínú ọ̀ràn yìí jẹ́ ká mọ bí ìpinnu lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ ṣe ṣe pàtàkì tó. Ipa tí irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ lè ní lórí rẹ nìyẹn. Tó o bá mọ̀ pé lílo ìpín kékeré lára àtúpalẹ̀ àwọn èròjà ẹ̀jẹ̀ yóò da ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó o ti fi Bíbélì tọ́ láàmú, má ṣaláìkọbi-ara sí ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá sọ fún ọ. Má sì ṣe tẹ ẹ̀rí ọkàn rẹ rì tìtorí pé ẹnì kan sọ fún ọ pé, “Gbà á, kò sóhun tó burú ńbẹ̀; ó ṣe tán ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbà á.” Rántí pé àìmọye èèyàn lónìí ni kì í fetí sí ẹ̀rí ọkàn wọn, tó bá sì yá, ẹ̀rí ọkàn wọn á wá di òkú, wọ́n á wá máa parọ́ tàbí kí wọ́n máa hùwà àìtọ́ mìíràn tí wọn ò sì ní kẹ́dùn rárá. Dájúdájú, àwọn Kristẹni kò ní fẹ́ tọ irú ọ̀nà yẹn.—2 Sámúẹ́lì 24:10; 1 Tímótì 4:1, 2.

19. Kí lohun àkọ́kọ́ tó yẹ ká fi sọ́kàn nígbà tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu ọ̀ràn ìṣègùn tó jẹ mọ́ ẹ̀jẹ̀?

19 Ní apá ìparí ìdáhùn tá a tún tẹ̀ sí ojú ìwé 29–31 sọ pé: “Ǹjẹ́ kókó náà pé èrò àti àwọn ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù mu lè yàtọ̀ síra túmọ̀ sí pé [ọ̀ràn] náà ò ṣe pàtàkì? Rárá o. Ó ṣe pàtàkì.” Ó tiẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an nítorí pé ọ̀ràn náà kan àjọse rẹ pẹ̀lú “Ọlọ́run alààyè.” Àjọṣe yìí nìkan ṣoṣo ló lè sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun, nípasẹ̀ agbára tí ẹ̀jẹ̀ Jésù ní láti gbà ọ́ là. Máa fi ojú pàtàkì wo ẹ̀jẹ̀ nítorí ohun tí Ọlọ́run ń tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe, ìyẹn láti gbani là. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé lọ́nà tó bá a mu pé: “Ẹ kò sì ní ìrètí kankan, ẹ sì wà ní ayé láìní Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù, ẹ̀yin tí ẹ jìnnà réré nígbà kan rí ti wá wà nítòsí nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Kristi.”—Éfésù 2:12, 13.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

b Nígbà kan báyìí, Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni mẹ́rin lọ sínú tẹ́ńpìlì láti lọ wẹ ara wọn mọ́ lọ́nà ayẹyẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Òfin tó ní káwọn èèyàn máa ṣe bẹ́ẹ̀ kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ mọ́, síbẹ̀ Pọ́ọ̀lù tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí àwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Jerúsálẹ́mù fún un. (Ìṣe 21:23–25) Síbẹ̀ àwọn Kristẹni kan lè sọ pé ní tàwọn o, àwọn ò ní lọ sí tẹ́ńpìlì tàbí káwọn tẹ̀ lé ààtò yẹn. Bí ẹ̀rí ọkàn àwọn èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́ yàtọ̀ síra nígbà yẹn lọ́hùn ún, bẹ́ẹ̀ gan-an ló ṣe rí lónìí.

c Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Judaica ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ “kúlẹ̀kúlẹ̀” òfin nípa ẹran “tó bófin mu láti jẹ.” Òfin náà sọ iye ìṣẹ́jú tí ẹran gbọ́dọ̀ lò nínú omi, bí wọ́n ṣe máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lórí pátákó, irú iyọ̀ tí wọ́n gbọ́dọ̀ fi pa á lára àti iye ìgbà tí wọ́n gbọ́dọ̀ fọ̀ ọ́ nínú omi tútù.

d Èròjà pàtàkì tí wọ́n túbọ̀ fi ń ṣe àwọn abẹ́rẹ́ kan ni àwọn èròjà àtọwọ́dá tí kì í ṣe látinú ẹ̀jẹ̀. Àmọ́, nígbà míì wọ́n lè fi ìpín bíńtín lára àtúpalẹ̀ èròjà pàtàkì inú ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, irú bi èròjà albumin.—Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ October 1, 1994.

Ǹjẹ́ O Lè Rántí?

• Ìtọ́ni wo lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ ni Ọlọ́run fún Nóà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn Kristẹni?

• Kí ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gbà rárá tó bá kan ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀?

• Ọ̀nà wo ni lílo àwọn ìpín kéékèèké inú àtúpalẹ̀ èròjà pàtàkì tó para di ẹ̀jẹ̀ gbà jẹ́ ọ̀ràn ẹ̀rí ọkàn, àmọ́ kí ni èyí kò túmọ̀ sí?

• Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run ni ohun àkọ́kọ́ tá a ní láti fi sọ́kàn nígbà tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu ọ̀ràn ìṣègùn tó jẹ mọ́ ẹ̀jẹ̀?

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 22]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÌPINNU WA LÓRÍ Ọ̀RÀN Ẹ̀JẸ̀

Ẹ̀JẸ̀

▾ ▾ ▾ ▾

ÈYÍ TÍ A Sẹ́ẹ̀lì pupa Sẹ́ẹ̀lì funfun Sẹ́ẹ̀lì pẹlẹbẹ Omi inú

KÒ NÍ GBÀ inú ẹ̀jẹ̀ inú ẹ̀jẹ̀ inú ẹ̀jẹ̀ ẹ̀jẹ̀

ÈYÍ TÍ ▾ ▾ ▾ ▾

KRISTẸNI Ìpín kéékèèké Ìpín kéékèèké Ìpín kéékèèké Ìpín kéékèèké

KỌ̀Ọ̀KAN inú àtúpalẹ̀ inú àtúpalẹ̀ inú àtúpalẹ̀ inú àtúpalẹ̀

MÁA PINNU sẹ́ẹ̀lì pupa sẹ́ẹ̀lì funfun sẹ́ẹ̀lì pẹlẹbẹ omi inú ẹ̀jẹ̀

inú ẹ̀jẹ̀ inú ẹ̀jẹ̀ inú ẹ̀jẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso fẹnu kò pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Má ṣaláìkọbi-ara sí ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá sọ fún ọ nígbà tó o bá fẹ́ ṣe ìpinnu lórí ọ̀rọ̀ ìpín kékeré kan lára àtúpalẹ̀ àwọn èròjà tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́