ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/99 ojú ìwé 2-7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • October 29-31, 1999
  • November 12-14, 1999
  • November 26-28, 1999
  • December 3-5, 1999
  • December 10-12, 1999
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 9/99 ojú ìwé 2-7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù September: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun fún ₦55; ẹlẹ́yìn fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún ₦50. October: Gbogbo èdè—Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí! November: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. December: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

◼ Nígbà tóo bá wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, o lè pàdé ẹnì kan tó jẹ́ adití. Bí àwùjọ tàbí ìjọ tí ń sọ èdè àwọn adití bá wà lágbègbè rẹ, kí o tẹ̀ lé ìtọ́ni táa pèsè nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 1998, ojú ìwé 3. Ó ṣàlàyé báa ṣe lè fi fọ́ọ̀mù Sign-Language Follow-up Slip kọ orúkọ àwọn èèyàn tí ń sọ èdè adití sílẹ̀, yálà ìpínlẹ̀ ìjọ rẹ ni wọ́n wà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ní gbogbo gbòò, a ní láti lò ó fún ète yìí, bí onítọ̀hún ò bá tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn Ìjọba náà. Lẹ́yìn tóo bá kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù Sign-Language Follow-up Slip, kí o fi lé akọ̀wé ìjọ lọ́wọ́ tàbí kí o fi sínú àpótí táà ń fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá sí nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí olúkúlùkù akéde bá wà lójúfò láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lọ́nà yìí, yóò ṣeé ṣe fáwọn ìjọ àti àwùjọ tí ń sọ èdè adití láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn adití tí ń bẹ lágbègbè wọn.

◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òun yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní September 1 tàbí bí ó bá ti lè yá tó lẹ́yìn ìgbà yẹn. Tẹ́ẹ bá ṣe é tán, ẹ ṣèfilọ̀ fún ìjọ pé ẹ ti ṣe é, lẹ́yìn tẹ́ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó tó tẹ̀ lé e.

◼ A ń rán àwọn alàgbà létí láti ṣiṣẹ́ lórí ìtọ́ni táa là kalẹ̀ nínú Ilé-ìṣọ́nà ti April 15, 1991, ní ojú ìwé 21 sí 23, tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn táa yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tí wọ́n yọ ara wọn lẹ́gbẹ́, tí wọ́n lè fẹ́ kí a gbà wọ́n padà.

◼ Kí àwọn tí ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ fi gbogbo àsansílẹ̀ owó tuntun àti èyí tí wọ́n fẹ́ tún ṣe fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, títí kan àsansílẹ̀ owó tiwọn, ránṣẹ́ nípasẹ̀ ìjọ.

◼ Kì í ṣe Society ló ń kọ ìwé ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alábòójútó olùṣalága ṣètò fún ìfilọ̀ lóṣooṣù kí a tó fi ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ìjọ lóṣooṣù ránṣẹ́ sí Society kí olúkúlùkù ẹni tó bá fẹ́ láti gba ìwé tirẹ̀ lè sọ fún arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rántí pé àwọn ìtẹ̀jáde kan wà tó jẹ́ ìbéèrè àkànṣe.

◼ Àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè àti ti Àgbáyé ti “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́,” táa ṣe lọ́dún 1998 ti já sí ìbùkún lóòótọ́ fún gbogbo àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀. Lára àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀ ni 2,764 àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn òṣìṣẹ́ káyé, tó láǹfààní láti rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn nítorí ìdáwó ọlọ́làwọ́ táwọn ìjọ ṣe. A mọrírì irú ìtìlẹyìn yìí gan-an ni. Nísinsìnyí táwọn àpéjọpọ̀ náà ti parí, a ó lo ìyókù owó tí a dá fún ète yìí láti fi ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé.

◼ A ti ṣe àwọn àtúnṣe tó tẹ̀ lé e yìí sí “Àwọn Ibi Tí A Óò Ti Ṣe Àpéjọpọ̀ Àgbègbè Ti 1999” tó jáde nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 1999. Kí alábòójútó olùṣalága ìjọ èyíkéyìí táa ti yí déètì tàbí ibi tí wọn yóò ti ṣe àpéjọpọ̀ wọn padà jọ̀wọ́ ṣètò kí a ṣe ìfilọ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí ó tẹ̀ lé e lẹ́yìn tí wọ́n bá ti gba Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí.

October 29-31, 1999

ÙBOGÒ 1 (Gẹ̀ẹ́sì) ME-8; ME-18: A sí O ÀYÀFI Emu Uno; ME-19: N sí Z

November 12-14, 1999

ENUGU 1 (Gẹ̀ẹ́sì) EE-12: Ayangba, Ogugu, Otukpa, àti Ubiadu; EE-17: Amanato, City Layout, Federal Housing, Hilltop, Ihe, Lakecity, Lakeside, Liberty, Odenigbo, àti Trans Ekulu; EE-19: Mainland, Ndiagu, Onuasata, Real Estate, Station (Agbani), Uhueze, Umunevo, Urban, àti Uwani

ÙBOGÒ 3 (Gẹ̀ẹ́sì) ME-6: A sí B; ME-7: A sí O; ME-9: Adjomo, Airport, Alegbo, Asheshe Layout, Bazunu Layout, àti Enerhen; ME-10 ÀYÀFI Enede, Farm Settlement, Igwete, Ishimili, Ndemili, Ogbe Onishe, Olieogo, àti Umuekum; ME-18: P sí Z; ME-19: A sí M

November 26-28, 1999

KATSINA ALA 2 (Gẹ̀ẹ́sì) EE-11A; EE-11C: A sí G; EE-12: Adoka Iso., Aliade, Etutekpe, Eupi, Igedde Central, Igumale, Ito Igedde, North Bank, South Bank, Ugbokolo, àti Ochi-Lagos; NE-6B: Jalingo

December 3-5, 1999

KATSINA ALA 3 (Gẹ̀ẹ́sì) EE-11B; EE-11C: H sí Z; EE-12: Àwọn ìjọ tí a kò yàn sí Katsina Ala 2 ÀYÀFI Ayangba, Otukpa, àti Ogugu

UYÓ 6 (Ẹ́fíìkì) EF-10: Afaha Ikot Ede, Afaha Offiong, Edeobom, Efa Iman, Ekpene Ituen, Etinan, Ikot Abasi Iman, Ikot Ante, Ikot Atang Esen, Ikot Eba, and Ikot Edibon; EF-15: Esuk Oron, Eteku, Ewet, àti Okpob

December 10-12, 1999

AGBOR 6 (Gẹ̀ẹ́sì) ME-10: Enede; ME-11A; ME-15: A sí N; ME-17: U sí Z; ME-18: Emu Uno

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:

Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀! —Yorùbá

The Guidance of God—Our Way to Paradise —Gẹ̀ẹ́sì

◼ Àwọn Kásẹ́ẹ̀tì Àfetígbọ́ Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:

Families—Make Daily Bible Reading Your Way of Life! (Àwòkẹ́kọ̀ọ́, kásẹ́ẹ̀tì kan) —Gẹ̀ẹ́sì

Marked for Survival —Gẹ̀ẹ́sì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́