Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Oṣù September
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 6
Orin 190
7 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ táa yàn látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
18 min: “Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Ní Ìmọ̀ Pípéye.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹnu mọ́ àǹfààní bíbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ níbi tédè ẹ̀yin méjèèjì ti yéra. Ṣàṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tàbí méjì táa múra sílẹ̀ dáadáa.
20 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run’ ti 1999.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 9) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 6 àti 8. Tẹnu mọ́ àwọn ìdí táa fi gbọ́dọ̀ lọ ní gbogbo ọjọ́ tí àpéjọpọ̀ yìí yóò fi wáyé, títí kan gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Friday. Tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì títẹ̀lé ìtọ́ni Society pé kí kálùkù gbé oúnjẹ ọ̀sán tirẹ̀ wá ní gbogbo ọjọ́ àpéjọpọ̀.
Orin 19 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 13
Orin 171
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò àti ìrírí látinú iṣẹ́ ìsìn pápá.
15 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí Lọ́dún Tó Kọjá? Àsọyé látẹnu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì látinú ìròyìn ìjọ ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1999. Gbóríyìn fáwọn ará fún àṣeyọrí sí rere wọn. Mẹ́nu kan ibi tó ń béèrè àtúnṣe. Darí àfiyèsí sórí bí ìjọ ṣe ṣe sí nínú wíwá sípàdé àti ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gbé àwọn góńgó tó ṣeé lé bá kalẹ̀ fún ọdún tí ń bọ̀.
20 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run’ ti 1999.” (Ìpínrọ̀ 10 sí 21) Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 15 àti 16. Lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táa fà yọ tàbí táa tọ́ka sí láti fi tẹnu mọ́ ìdí tí ìwọṣọ, ìmúra, àti ìwà wa fi ń béèrè àfiyèsí gidigidi.
Orin 29 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 20
Orin 193
12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: “Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Fi Àpẹẹrẹ Rere Lélẹ̀ Fáwọn Ọmọ Yín.” Ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ráńpẹ́ látẹnu alàgbà kan, kí ìjíròrò àpilẹ̀kọ náà sì wá tẹ̀ lé e láàárín àwọn arákùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ òbí. Wọ́n sọ àníyàn ọkàn wọn nípa bí wọ́n ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn ìwà burúkú táwọn èèyàn ń hù níṣojú wọn níléèwé, lórí tẹlifíṣọ̀n, àtèyí tí ẹbí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí àti àwọn èèyàn mí-ìn ń hù. Àwọn arákùnrin wọ̀nyí sọ̀rọ̀ nípa ìwà àìbọ̀wọ̀fúnni, èdè ọmọọ̀ta àti ìmúra lọ́nà ti ayé, àti eré ìnàjú tí kò yẹ ọmọlúwàbí. Lẹ́yìn sísọ ọ̀rọ̀ tí ń múni ronú jinlẹ̀ nípa ìjẹ́pàtàkì fífi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀, wọ́n jíròrò àwọn ọ̀nà tí yóò jẹ́ ká túbọ̀ máa jí gìrì sí ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, wíwá sáwọn ìpàdé ìjọ, àti jíjáde iṣẹ́ ìsìn pápá.—Wo Ilé Ìṣọ́, July 1, 1999, ojú ìwé 8 sí 22, àti Jí!, February 22, 1992, ojú ìwé 8 sí 9.
18 min: Títọ́jú Orúkọ Rere Wa. Àsọyé látẹnu alàgbà. Àwọn ìwà ọmọlúwàbí wẹ́ẹ́wẹ̀ẹ̀wẹ́ táwọn èèyàn bá mọ̀ wá mọ́ ló ń fún wa lórúkọ rere. Iṣẹ́ ọwọ́ wa ló ń gbé wa níyì. Bẹ́ẹ̀ rèé, àṣìṣe kan ṣoṣo lè bà wá lórúkọ jẹ́. Ìwà òmùgọ̀ bín-ín-tín—bí ìbínúfùfù ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo, tàbí ìmutíyó, tàbí ìwà àìmọ́ takọtabo—ti tó láti fi orúkọ rere ẹni yí ẹrẹ̀. (Oníw. 10:1; Òwe 6:32; 14:17; 20:21) Ó mà kúkú ṣe pàtàkì o, pé ká sápa láti ní orúkọ rere, kí a sì máa ṣakitiyan láti tọ́jú orúkọ rere náà.—Fi wé Ìṣípayá 3:5.
Orin 175 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 27
Orin 141
15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá toṣù September sílẹ̀. Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí láti ṣètò fún níní ìpín kíkún nínú pípín ìwé ìròyìn lóṣù October. Ṣàtúnyẹ̀wò díẹ̀ lára àbá táa gbé jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1996, ojú ìwé 8 nípa báa ṣe ń múra ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀. Ní lílo àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́, mẹ́nu kan àwọn kókó tó dáa táa lè sọ̀rọ̀ lé lórí, kí o sì ṣàṣefihàn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tàbí méjì tó ṣe ṣókí.
15 min: Àpótí Ìbéèrè. Àsọyé látẹnu alàgbà.
15 min: “Ǹjẹ́ Iṣẹ́ Rẹ Ní Ète Nínú?” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Lò lára àlàyé tó wà nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 88 àti 89. Rọ gbogbo àwọn ará láti fara balẹ̀ ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn kúnnákúnná.
Orin 106 àti àdúrà ìparí.