Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Fi Àpẹẹrẹ Rere Lélẹ̀ Fáwọn Ọmọ Yín
1 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé “baba [àti ìyá] olódodo yóò kún fún ìdùnnú láìsí àní-àní.” (Òwe 23:24, 25) Ìbùkún ńláǹlà mà lèyí jẹ́ fáwọn òbí tó fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ọmọ wọn o! Ẹnì kan tó jẹ́ mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sọ báyìí nípa àwọn òbí rẹ̀: “Òtítọ́ ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn, mo sì fẹ́ kó jẹ́ ohun pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé tèmi náà.” Ẹ̀kọ́ wo ló yẹ káwọn ọmọ rí kọ́ lára òbí wọn?
2 Ìwà Ọmọlúwàbí àti Ọ̀wọ̀ Jíjinlẹ̀: Ojúṣe àwọn òbí ni láti kọ́ àwọn ọmọ wọn níwà rere. A lè kọ́ ìwà ọmọlúwàbí nípa fífojúsílẹ̀ àti ṣíṣe àfarawé, kì í kàn-án ṣe kìkì nípa ìtọ́ni ọlọ́rọ̀ ẹnu. Fún ìdí yìí, irú ìwà wo lò ń hù? Ǹjẹ́ àwọn ọmọ rẹ máa ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ bíi “mo tọrọ gáfárà o,” “jọ̀wọ́,” àti “ẹ ṣé o” lẹ́nu rẹ? Nínú ìdílé, ǹjẹ́ ẹ ń bọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fára yín? Ǹjẹ́ ẹ máa ń tẹ́tí sílẹ̀ nígbà táwọn ẹlòmíràn bá ń sọ̀rọ̀? Ǹjẹ́ o máa ń fetí sílẹ̀ nígbà táwọn ọmọ rẹ bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀? Ṣé ìwà tí ẹ ń hù nìyí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ní kọ̀rọ̀ ilé yín?
3 Ìfẹ́ Jíjinlẹ̀ fún Nǹkan Tẹ̀mí àti Iṣẹ́ Aláápọn: Arákùnrin kan tó ti lò ju àádọ́ta ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún rántí pé: “Ìyá àti bàbá mi jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà ní ti ojú ribiribi tí wọ́n fi ń wo àwọn ìpàdé àti ìtara tí wọ́n ní fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.” Báwo lo ṣe ń fi han àwọn ọmọ rẹ pé ipò tẹ̀mí agboolé rẹ jẹ ẹ́ lọ́kàn? Ǹjẹ́ ẹ máa ń ka ẹsẹ ojoojúmọ́ papọ̀? Ǹjẹ́ ẹ ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé déédéé? Ǹjẹ́ àwọn ọmọ rẹ máa ń rí ẹ tí o ń ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde Society? Kí ni wọ́n máa ń gbọ́ nígbà tóo bá ń ṣojú ìdílé nínú àdúrà? Ǹjẹ́ o máa ń bá àwọn ọmọ rẹ sọ ọ̀rọ̀ tẹ̀mí tí ń gbéni ró, kí ẹ jùmọ̀ máa jíròrò àwọn nǹkan tó gbámúṣé nípa òtítọ́ àti nípa ìjọ? Ǹjẹ́ ara máa ń yá yín láti pésẹ̀ sí gbogbo ìpàdé àti láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá gẹ́gẹ́ bí ìdílé?
4 Ẹ̀yin òbí, ẹ ronú dáadáa lórí àpẹẹrẹ tí ẹ ń fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ yín o. Ẹ jẹ́ kí ó jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ, wọn yóò sì kà á sí ohun iyebíye jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Ìyàwó alábòójútó arìnrìn-àjò kan, tó ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún báyìí, sọ pé: “Mo ṣì ń jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ rere àwọn òbí mi onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni. Àdúrà mi àtọkànwá sì ni pé kí n máa bá a lọ ní fífojú ribiribi wo ogún yìí nípa lílò ó lọ́nà yíyẹ títí ayé.”