Ǹjẹ́ Iṣẹ́ Rẹ Ní Ète Nínú?
1 Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó ní ète. (Aís. 55:10, 11) A rọ̀ wá láti fara wé e. (Éfé. 5:1) Dájúdájú, ó yẹ kí èyí fara hàn nínú bí a ṣe ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Nítorí náà, ìbéèrè yìí bójú mu: “Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ ní ète nínú?”
2 Iṣẹ́ ìwàásù tí o ń ṣe láti ilé dé ilé, iṣẹ́ ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà, àti pípín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, gbogbo rẹ̀ ló jẹ́ ara iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ní ète nínú. Ṣùgbọ́n má gbàgbé o, pé iṣẹ́ wa ò mọ sí wíwàásù nìkan, ó tún nasẹ̀ dé sísọni di ọmọlẹ́yìn pẹ̀lú. (Mát. 28:19, 20) Lẹ́yìn táa bá gbin àwọn irúgbìn òtítọ́ Ìjọba náà, ó yẹ ká padà lọ bomi rin wọ́n, kí a sì máa tọ́jú wọn déédéé bí a ti ń wojú Jèhófà pé kí ó mú ìbísí wá. (1 Kọ́r. 3:6) Ó yẹ kí ọ̀ràn ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò àti bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jẹ wá lógún.
3 Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò: Ó sábà máa ń jẹ́ ìwúrí tóo bá wẹ̀yìn wò, tóo rí nǹkan tóo ti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn, tóo sì sọ fún ara rẹ pé: “Mo parí ohun tí mo pète láti ṣe.” Gẹ́gẹ́ bó ti wà nínú 2 Tímótì 4:5, Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé: “Ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún.” Èyí kan fífi kún ìsapá rẹ nípa pípadà lọ bá gbogbo àwọn tó fìfẹ́ hàn. Nínú ìwéwèé rẹ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn, ṣètò àkókò pàtó fún ìpadàbẹ̀wò. Lépa góńgó bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tọ́kàn wọn fà sí òdodo. Ohun tó yẹ kó jẹ́ ète rẹ nìyí nígbàkigbà tóo bá ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.
4 Béèrè lọ́wọ́ àwọn akéde bó ti rí lára wọn nígbà tí wọ́n rí i tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ́n ṣèrìbọmi ní àpéjọ kan. Inú wọ́n dùn, bóyá bíi ti ẹni tó ṣèrìbọmi. Ète ọlọ́lá wọn kẹ́sẹ járí! Ọ̀kan lára àwọn olùsọni di ọmọ ẹ̀yìn sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn máa ń fi kún iye àwọn olùyin Jèhófà. Ó túmọ̀ sí ìyè fáwọn tó bá tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Mo kàn sáà máa ń fẹ́ láti fi òtítọ́ kọ́ àwọn ẹlòmíràn—iṣẹ́ tó gbayì ni! . . . Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti wá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà báyìí ti di ọ̀rẹ́ mi àtàtà.”
5 Sáà wo bó ti dùn tó láti lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà! Ayọ̀ ọ̀hún mà máa ń pọ̀ o! Irú èso bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ yọ táa bá ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà lọ́nà tó ní ète nínú.—Kól. 4:17.