ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Oníwàásù 10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Oníwàásù

      • Ìwà òmùgọ̀ díẹ̀ ń ba ọgbọ́n jẹ́ (1)

      • Ewu tó wà nínú àìmọṣẹ́ (2-11)

      • Ohun búburú tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn òmùgọ̀ (12-15)

      • Ìwà òmùgọ̀ àwọn alákòóso (16-20)

        • Ẹyẹ lè tún ọ̀rọ̀ rẹ sọ (20)

Oníwàásù 10:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 20:10, 12; 2Sa 12:9-11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 16

    Jí!,

    3/8/2001, ojú ìwé 16-17

Oníwàásù 10:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.”

  • *

    Ní Héb., “wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 14:8; 17:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 15

Oníwàásù 10:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọkàn á kù fún un.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 10:23
  • +Owe 13:16; 18:7

Oníwàásù 10:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹ̀mí; èémí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 8:2, 3
  • +1Sa 25:23, 24; Owe 25:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 16

Oníwàásù 10:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 26:21; 1Ọb 12:13, 14

Oníwàásù 10:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn ọlọ́rọ̀.”

Oníwàásù 10:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 30:21-23

Oníwàásù 10:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 26:27

Oníwàásù 10:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “yẹ kó ṣọ́ra pẹ̀lú rẹ̀.”

Oníwàásù 10:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!: Bá A Ṣe Lè Fọgbọ́n Lo Àkókò Wa

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2000, ojú ìwé 16

Oníwàásù 10:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹni tó láṣẹ ní ahọ́n.”

Oníwàásù 10:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 10:6, 8; Sm 37:30; Lk 4:22; Ef 4:29
  • +Sm 64:2, 8; Owe 10:14, 21; 14:3

Oníwàásù 10:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 25:10, 11

Oníwàásù 10:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 10:19; 15:2
  • +Owe 27:1; Onw 6:12; Jem 4:13, 14

Oníwàásù 10:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 15

Oníwàásù 10:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 13:7; 36:9

Oníwàásù 10:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 31:4, 5

Oníwàásù 10:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 21:25; 24:33, 34

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    5/1/1996, ojú ìwé 22

Oníwàásù 10:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Búrẹ́dì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 104:15; Onw 9:7
  • +Onw 7:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/1998, ojú ìwé 4

Oníwàásù 10:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “lórí ibùsùn rẹ.”

  • *

    Tàbí “ṣépè fún.”

  • *

    Ní Héb., “ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run.”

  • *

    Tàbí “iṣẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:28

Àwọn míì

Oníw. 10:1Nọ 20:10, 12; 2Sa 12:9-11
Oníw. 10:2Owe 14:8; 17:16
Oníw. 10:3Owe 10:23
Oníw. 10:3Owe 13:16; 18:7
Oníw. 10:4Onw 8:2, 3
Oníw. 10:41Sa 25:23, 24; Owe 25:15
Oníw. 10:51Sa 26:21; 1Ọb 12:13, 14
Oníw. 10:7Owe 30:21-23
Oníw. 10:8Owe 26:27
Oníw. 10:121Ọb 10:6, 8; Sm 37:30; Lk 4:22; Ef 4:29
Oníw. 10:12Sm 64:2, 8; Owe 10:14, 21; 14:3
Oníw. 10:131Sa 25:10, 11
Oníw. 10:14Owe 10:19; 15:2
Oníw. 10:14Owe 27:1; Onw 6:12; Jem 4:13, 14
Oníw. 10:162Kr 13:7; 36:9
Oníw. 10:17Owe 31:4, 5
Oníw. 10:18Owe 21:25; 24:33, 34
Oníw. 10:19Sm 104:15; Onw 9:7
Oníw. 10:19Onw 7:12
Oníw. 10:20Ẹk 22:28
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Oníwàásù 10:1-20

Oníwàásù

10 Bí òkú eṣinṣin ṣe ń ba òróró ẹni tó ń ṣe lọ́fínńdà jẹ́, tí á sì máa rùn, bẹ́ẹ̀ ni ìwà òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń ba ọgbọ́n àti ògo jẹ́.+

2 Ọkàn ọlọ́gbọ́n ń darí rẹ̀ sí ọ̀nà tí ó tọ́,* àmọ́ ọkàn òmùgọ̀ máa ń darí rẹ̀ sí ọ̀nà tí kò tọ́.*+ 3 Ibikíbi tí òmùgọ̀ bá rìn sí, kò ní lo làákàyè,*+ ó sì máa jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé òmùgọ̀ ni òun.+

4 Tí inú* alákòóso bá ru sí ọ, má ṣe kúrò níbi tí o wà,+ torí pé ìwà pẹ̀lẹ́ ń pẹ̀tù sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.+

5 Ohun kan wà tó ń kó ìdààmú báni tí mo ti rí lábẹ́ ọ̀run,* àṣìṣe tí àwọn tí agbára wà lọ́wọ́ wọn ń ṣe:+ 6 Àwọn òmùgọ̀ ló ń wà ní ọ̀pọ̀ ipò gíga, àmọ́ àwọn tó dáńgájíá* kì í kúrò ní ipò tó rẹlẹ̀.

7 Mo ti rí àwọn ìránṣẹ́ tó ń gun ẹṣin àmọ́ tí àwọn olórí ń fẹsẹ̀ rìn bí ìránṣẹ́.+

8 Ẹni tó ń gbẹ́ kòtò lè já sínú rẹ̀;+ ẹni tó sì ń wó ògiri olókùúta, ejò lè bù ú ṣán.

9 Ẹni tó ń gbẹ́ òkúta, òkúta náà lè ṣe é léṣe, ẹni tó sì ń la gẹdú, gẹdú náà lè ṣe é ní jàǹbá.*

10 Tí irinṣẹ́ kan kò bá mú, tí ẹni tó fẹ́ lò ó kò sì pọ́n ọn, ó máa ní láti lo agbára tó pọ̀ gan-an. Àmọ́ ọgbọ́n ń mú kéèyàn ṣe àṣeyọrí.

11 Tí ejò bá buni ṣán kí wọ́n tó tù ú lójú, kí làǹfààní atujú tó gbówọ́.*

12 Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n ń mú ire wá,+ àmọ́ ètè òmùgọ̀ ń fa ìparun rẹ̀.+ 13 Ọ̀rọ̀ tó kọ́kọ́ jáde lẹ́nu rẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀,+ èyí tó sì sọ gbẹ̀yìn jẹ́ ọ̀rọ̀ aṣiwèrè tó ń ṣekú pani. 14 Síbẹ̀, ńṣe ni òmùgọ̀ á máa sọ̀rọ̀ lọ.+

Èèyàn ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀; ta ló lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ fún un?+

15 Iṣẹ́ àṣekára òmùgọ̀ ń tán an lókun, torí kò tiẹ̀ mọ bó ṣe máa rí ọ̀nà tó máa gbà lọ sínú ìlú.

16 Ẹ wo bó ṣe máa burú tó fún ilẹ̀ kan tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọdékùnrin,+ tí àwọn ìjòyè rẹ̀ sì máa ń bẹ̀rẹ̀ àsè wọn ní àárọ̀! 17 Ẹ wo bó ṣe máa jẹ́ ohun ayọ̀ tó fún ilẹ̀ náà, tí ọba rẹ̀ bá jẹ́ ọmọ èèyàn pàtàkì, tí àwọn ìjòyè rẹ̀ sì ń jẹun ní àkókò tí ó tọ́ kí wọ́n lè lágbára, kì í ṣe kí wọ́n lè mutí yó!+

18 Ìwà ọ̀lẹ tó lé kenkà ló ń mú kí igi àjà tẹ̀, ọwọ́ tó dilẹ̀ sì ló ń mú kí ilé jò.+

19 Oúnjẹ* wà fún ẹ̀rín, wáìnì sì ń mú kí èèyàn gbádùn ayé;+ àmọ́ owó la fi ń ṣe ohun gbogbo tí a nílò.+

20 Kódà nínú èrò rẹ,* má ṣe bú* ọba,+ má sì bú olówó nínú yàrá rẹ; torí pé ẹyẹ kan* lè gbé ọ̀rọ̀* náà tàbí kí ohun tó ní ìyẹ́ tún ọ̀rọ̀ rẹ sọ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́