ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/04 ojú ìwé 3
  • ‘Ẹ Jẹ́ Ká Jọ Gbé Orúkọ Rẹ̀ Ga’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ẹ Jẹ́ Ká Jọ Gbé Orúkọ Rẹ̀ Ga’
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Máa Gbé Jèhófà Lárugẹ Nínú Ìjọ Ńlá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • A Péjọ Pọ̀ Láti Yin Jèhófà Lógo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ṣó O Ti Múra Tán Láti Jẹ Àsè Tẹ̀mí?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Máa Fojú Sọ́nà fún Jèhófà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 9/04 ojú ìwé 3

‘Ẹ Jẹ́ Ká Jọ Gbé Orúkọ Rẹ̀ Ga’

1. Àǹfààní wo ni àwa àtàwọn ará wa máa ní láti jọ gbé orúkọ Ọlọ́run ga, kí la sì lè ṣe báyìí láti múra sílẹ̀?

1 Onísáàmù kọrin pé: “Ẹ gbé Jèhófà ga lọ́lá pẹ̀lú mi, ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ ga.” (Sm. 34:3) Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn” tí ń bọ̀ lọ́nà yóò fún àwa àtàwọn arákùnrin àti arábìnrin wa láti ọ̀pọ̀ ìjọ láǹfààní láti jọ gbé orúkọ Jèhófà ga. Ǹjẹ́ o ti ṣètò ibi tó o máa dé sí, ọkọ̀ tó o máa wọ̀ lọ àti bí wàá ṣe gbàyè kúrò lẹ́nu iṣẹ́ kó o lè wà níbẹ̀? Ó yẹ ká tètè ṣètò àwọn nǹkan wọ̀nyí.—Òwe 21:5.

2. Kí nìdí tó fi dára pé ká ṣètò láti tètè dé sí ilẹ̀ àpéjọ?

2 Dídé sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ: Ọ̀pọ̀ nǹkan la máa ń bójú tó nígbà tá a bá ń lọ sí àpéjọ. Bá a bá tètè kúrò nílé, á rọrùn fún wa láti wá nǹkan ṣe bí ohun ìdíwọ́ tá ò rò tẹ́lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, a ó sì lè tètè rí ibi tá a máa jókòó sí ká bàa lè fi tọkàntọkàn kópa nínú orin àti àdúrà ìbẹ̀rẹ̀. (Sm. 69:30) Ní ìṣẹ́jú díẹ̀ kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀, alága yóò ti jókòó lórí pèpéle nígbà tí orin Ìjọba Ọlọ́run tí a fi ń mọ̀ pé ìpàdé ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ á máa dún. Ó yẹ kí gbogbo wa ti wà lórí ìjókòó nígbà náà kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ lè bẹ̀rẹ̀ létòlétò.—1 Kọ́r. 14:33, 40.

3. Àwọn wo la lè gbàyè ìjókòó sílẹ̀ fún ní àpéjọ?

3 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká jẹ́ ‘kí gbogbo àlámọ̀rí wa máa ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́.’ (1 Kọ́r. 16:14) Àwọn tó bá ọ wọkọ̀ wá tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń gbé ilé kan náà nìkan ni kó o gbàyè ìjókòó sílẹ̀ fún.—1 Kọ́r. 13:5; Fílí. 2:4.

4. Àwọn ètò wo la ṣe fún àkókò ìsinmi ọ̀sán, báwo lèyí sì ṣe máa ṣe wá láǹfààní?

4 O lè jẹ oúnjẹ ọ̀sán rẹ nínú gbọ̀ngàn àpéjọ. Jọ̀wọ́ má ṣe da ìdọ̀tí sílẹ̀, tàbí kó o fi ohun tá a fi pọ́n oúnjẹ sílẹ̀ níbẹ̀. Jíjẹun nínú gbọ̀ngàn àpéjọ yóò fún gbogbo wa láǹfààní láti gbádùn ìfararora tí ń gbéni ró, yóò sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti wà lórí ìjókòó láti ìbẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán. Bó bá pọn dandan pé kó o lo ohun tí wọ́n ń gbé oúnjẹ sí, èyí tó kéré tó ṣeé gbé sábẹ́ ìjókòó ni kó o lò. A ò gbà kí ẹnikẹ́ni lo kúlà gbẹ̀ǹgbẹ̀ àtàwọn ohun èlò onígíláàsì nínú gbọ̀ngàn àpéjọ. Bákan náà, a kò gba ọtí líle láàyè nílẹ̀ àpéjọ. Láwọn ìgbà kan sẹ́yìn, a ṣàkíyèsí pé ńṣe làwọn kan ń dáná nínú ilé tí wọ́n dé sí nílẹ̀ àpéjọ nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́. Èyí fi hàn pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò mọrírì àwọn ohun tẹ̀mí.—Lúùkù 10:38-42.

5. Báwo la ṣe lè múra ọkàn wa sílẹ̀ fún ìtọ́ni tá a máa rí gbà?

5 Àsè Tẹ̀mí Ń Dúró Dè Wá: Jèhóṣáfátì Ọba “múra ọkàn-àyà [rẹ̀] sílẹ̀ láti wá Ọlọ́run tòótọ́.” (2 Kíró. 19:3) Báwo la ṣe lè múra ọkàn wa sílẹ̀ ká tó lọ sí àpéjọ? Nínú àpilẹ̀kọ tó wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn Jí! ti September 8, 2004, wàá rí ìtọ́wò àsè tẹ̀mí tá a máa gbádùn. O ò ṣe gbé àpilẹ̀kọ náà yẹ̀ wò, kó o lè túbọ̀ máa wọ̀nà fún àsè tẹ̀mí tí Jèhófà ti pèsè sílẹ̀ fún wa? Ohun mìíràn tó yẹ ká ṣe láti múra ọkàn wa sílẹ̀ ni pé ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìtọ́ni tá a máa rí gbà, ká sì lè fi í sílò.—Sm. 25:4, 5.

6. Kí là ń yán hànhàn fún, kí sì nìdí?

6 Gbogbo wa là ń yán hànhàn láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nítorí a mọ̀ pé ipasẹ̀ rẹ̀ la fi lè dàgbà dé ìgbàlà. (1 Pét. 2:2) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká rí i pé a lọ sí Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn” ká bàa lè ‘jọ gbé orúkọ Jèhófà ga.’—Sm. 34:3.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]

Àwọn Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga

◼ Tètè múra sílẹ̀

◼ Fi ìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíràn

◼ Múra ọkàn rẹ sílẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́