ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/04 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 13
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 20
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 27
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 4
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 9/04 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Àkíyèsí: Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, a ó ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan nígbà àpéjọ àgbègbè. Kí àwọn ìjọ ṣe àyípadà tó bá yẹ láti fàyè sílẹ̀ fún lílọ sí Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn.” Níbi tó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀, kí ẹ lo ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí ẹ ó ṣe kẹ́yìn kẹ́ ẹ tó lọ sí àpéjọ náà láti tún sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìmọ̀ràn pàtàkì tó kan ìjọ yín nínú àkìbọnú ti oṣù yìí. Ní oṣù February 2005, a ó ṣètò Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kan láti fi ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì inú àpéjọ náà. Láti múra sílẹ̀ fún àtúnyẹ̀wò yẹn, gbogbo wa lè ṣàkọsílẹ̀ àwọn kókó pàtàkì ní àpéjọ náà, títí kan àwọn kókó pàtó tí àwa fúnra wa fẹ́ fi sílò nígbèésí ayé wa àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Èyí á jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí nípa ṣíṣàlàyé bá a ṣe fi àwọn ìmọ̀ràn wọ̀nyẹn sílò.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 13

Orin 43

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tí a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Báwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8 bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín, ẹ lò wọ́n láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ September 15 àti Jí! October 8 lọni. (Àbá kẹta ni ká lò láti fi Jí! October 8 lọni.) A tún lè fi ìwé ìròyìn lọni láwọn ọ̀nà mìíràn. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, ní ṣókí sọ ohun kan tó dára gan-an nínú ìfilọni náà.

15 min: “Jẹ́ Kí Ojú Rẹ Mú Ọ̀nà Kan.”a Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Tẹnu mọ́ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ bí àkókò bá ṣe wà sí.

18 min: “Ẹ Jẹ́ Ká Jọ Gbé Orúkọ Rẹ̀ Ga.”b Kí akọ̀wé ìjọ bójú tó o, kí ó sì lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Ka ìpínrọ̀ 4. Sọ àpéjọ àgbègbè tí a yan ìjọ yín sí. Àwọn àkókò ìtòlẹ́sẹẹsẹ wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 2004. Olùbánisọ̀rọ̀ tún lè mẹ́nu kan àwọn kókó mìíràn nínú àkìbọnú náà bó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Láti mú kí àwọn ará máa wọ̀nà fún ìjíròrò ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀, parí ọ̀rọ̀ rẹ nípa bíbéèrè ìbéèrè méjì tàbí mẹ́ta látinú àpilẹ̀kọ náà, “Oúnjẹ Tẹ̀mí ní Àkókò Yíyẹ,” èyí tá a máa gbé yẹ̀ wò ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀.

Orin 91 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 20

Orin 88

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó pàtàkì inú lẹ́tà láti ẹ̀ka ọ́fíìsì, èyí tó wà níwájú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù yìí. Rọ gbogbo àwọn ará pé kí wọ́n ka Númérì 16:1-35, kí wọ́n sì wo fídíò náà, Respect Jehovah’s Authority, láti múra sílẹ̀ fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ October 4.

15 min: Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè. Àsọyé. Ká lè túbọ̀ jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ látinú ètò Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tá a ṣe fún Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, a ti bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn àpilẹ̀kọ kan tó ní àkọlé náà, “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè” sínú àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ kọ̀ọ̀kan. Lo Ilé Ìṣọ́ September 15, 2004, ojú ìwé 24 sí 27 nígbà tó o bá ń bójú tó iṣẹ́ yìí, kó o sì tọ́ka sí àwọn ohun pàtàkì tó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí. Lẹ́yìn ṣíṣe àkópọ̀ àwọn ohun tó wà nínú ìwé Bíbélì kan, ìsọ̀rí tó ní àkọlé náà, “Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́” ṣàlàyé díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣòro láti lóye. Àlàyé tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa” á jẹ́ ká mọ bí ohun tó wà nínú ibi tá a kà náà ṣe wúlò fún wa. Sọ̀rọ̀ lórí àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ láti jẹ́ kí àwùjọ mọ bí àwọn àpilẹ̀kọ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Rọ gbogbo àwọn ará pé kí wọ́n lo àpilẹ̀kọ yìí dáadáa bá a ṣe máa bẹ̀rẹ̀ sí ka ìwé Diutarónómì lọ́sẹ̀ méjì sígbà tá a wà yìí.

20 min: “Oúnjẹ Tẹ̀mí ní Àkókò Yíyẹ.”c Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Nígbà tó o bá ń sọ̀rọ̀ lórí ìpínrọ̀ 2, sọ pé kí ẹnì kan tàbí méjì nínú àwùjọ sọ̀rọ̀ ṣókí lórí àpéjọ àgbègbè mánigbàgbé kan tí wọ́n lọ. Ka ìpínrọ̀ 3 àti 4. Láti mú kí àwọn ará máa wọ̀nà fún ìjíròrò ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀, parí ọ̀rọ̀ rẹ nípa bíbéèrè ìbéèrè méjì tàbí mẹ́ta látinú àpilẹ̀kọ náà, “Ẹ Jẹ́ Mímọ́ Nínú Gbogbo Ìwà Yín,” èyí tá a máa gbé yẹ̀ wò ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀.

Orin 80 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 27

Orin 221

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù September sílẹ̀. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ October 1 àti Jí! October 8 lọni. (Àbá kẹrin ni ká lò láti fi Jí! October 8 lọni.)

20 min: “Ẹ Jẹ́ Mímọ́ Nínú Gbogbo Ìwà Yín.”d Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Ka ìpínrọ̀ 4, 6, àti 7. Sọ pé kí àwùjọ sọ bí wọ́n ti ṣe kíyè sí i pé híhùwà rere ní àpéjọ àgbègbè ń mú ìyìn bá Jèhófà. Láti mú kí àwọn ará máa wọ̀nà fún ìjíròrò ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀, parí ọ̀rọ̀ rẹ nípa bíbéèrè ìbéèrè méjì tàbí mẹ́ta látinú àpilẹ̀kọ náà, “Ìrísí Tó Mọ́, Tó sì Gbayì,” èyí tá a máa gbé yẹ̀ wò ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀.

15 min: “Máa Lo Bíbélì Lọ́nà Tó Múná Dóko.”e Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Gbé ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 145, ìpínrọ̀ 2 àti 3. Fi àṣefihàn ṣókí méjì kún ìjíròrò yìí, kí ọ̀kan jẹ́ ìgbà tí akéde kọ́kọ́ wàásù fún onílé, kí èkejì sì jẹ́ ìpadàbẹ̀wò, láti jẹ́ kí àwọn ará mọ bá a ṣe lè fi àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí sílò.

Orin 38 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 4

Orin 5

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

20 min: “Múra Lọ́nà Tó Dára, Tó sì Gbayì.”f Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Bí àkókò bá ṣe wà sí, ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí, kó o sì ṣàlàyé wọn.

20 min: “A Gbọ́dọ̀ Bọ̀wọ̀ fún Ọlá Àṣẹ Jèhófà.” Ka Júúdà 11, kó o sì fi ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ mọ sí ìṣẹ́jú méjì tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn èyí, bẹ̀rẹ̀ sí jíròrò gbogbo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ pẹ̀lú àwùjọ. Tẹnu mọ́ kókó pàtàkì kan, ìyẹn ni pé tá a bá fẹ́ kí Jèhófà ṣe ojú rere sí wa, a kò gbọ́dọ̀ ní irú ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ tí Kórà ní, a sì gbọ́dọ̀ fara wé àwọn ọmọ rẹ̀, tí wọn kò fi ohunkóhun ṣáájú ìdúróṣinṣin wọn sí Jèhófà. Bí kò bá ṣeé ṣe, kí a lo àpilẹ̀kọ náà, “Ẹ Fi Ìdúróṣinṣin Tẹrí Ba fún Ọlá Àṣẹ Ọlọ́run.” Kí alàgbà sọ̀rọ̀ lórí àpilẹ̀kọ yìí, tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ August 1, 2002, ojú ìwé 9 sí 14.

Orin 99 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

f Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́