ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/00 ojú ìwé 4-5
  • Fetí sí Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìkéde Ọlọ́wọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fetí sí Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìkéde Ọlọ́wọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ẹ Fetí Sílẹ̀ Kí Ẹ sì Gba Ìtọ́ni Púpọ̀ Sí I’
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Fetí Sílẹ̀ Kó O sì Kẹ́kọ̀ọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti 1997
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” ti 1999
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 9/00 ojú ìwé 4-5

Fetí sí Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìkéde Ọlọ́wọ̀

1 Kì í ṣe gbogbo ohun táwọn èèyàn bá sọ ló ń fẹ́ àfiyèsí àkànṣe. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ọlọ́run bá sọ̀rọ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí a fetí sílẹ̀. (Diu. 28:1, 2) Inú wa dùn pé, àwọn akọ̀wé tí Ọlọ́run mí sí ṣàkọsílẹ̀ “àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run” fún àǹfààní wa. (Róòmù 3:2) Àpéjọpọ̀ àgbègbè tó ń bọ̀ yóò pèsè àǹfààní oníyebíye láti lè gbọ́ àwọn ìkéde ọlọ́wọ̀ wọ̀nyí, bí wọn yóò ṣe máa kà wọ́n, tí wọn yóò sì máa jíròrò wọn. Báwo lo ṣe lè fetí sílẹ̀ ní pàtàkì?

2 Tètè Dé Lówùúrọ̀ Ọjọ́ Kọ̀ọ̀kan: Finú wòye bí inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti dùn tó nígbà tí wọ́n sọ fún wọn pé kí wọ́n pàdé Jèhófà lórí Òkè Sínáì láti gbọ́ Òfin rẹ̀! (Ẹ́kís. 19:10, 11, 16-19) Bó bá jẹ́ pé báyìí ni gbígba ìtọ́ni Jèhófà ní àpéjọpọ̀ àgbègbè ṣe ń rí lára ìwọ náà, wàá ṣètò láti tètè dé lójoojúmọ́. A kò lè fetí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọn yóò sọ bí a bá ń pẹ́ẹ́ dé, tí a sì ń ṣèdíwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn níbi tí a ti ń wá ìjókòó kiri. Agogo mẹ́sàn-án kọjá ogún ìṣẹ́jú ni ìpàdé yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Friday, yóò sì bẹ̀rẹ̀ ní agogo mẹ́sàn-án ní ọjọ́ Saturday àti Sunday.

3 Kódà àwọn kan tó tètè dé pàápàá kì í sí lórí ìjókòó wọn nígbà tí ìpàdé bá bẹ̀rẹ̀. Kí ló fà á? Ńṣe ni wọ́n máa ń dúró títí di ìgbà tí alága bá pe orin ìbẹ̀rẹ̀ kí wọ́n tó ṣíwọ́ títàkúrọ̀sọ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn, tí wọ́n á sì wá bẹ̀rẹ̀ sí lọ síbi ìjókòó wọn. A gbọ́dọ̀ kíyè sí i pé, ní ìṣẹ́jú mélòó kan kí a tó kọ orin ìbẹ̀rẹ̀ ìpàdé kọ̀ọ̀kan, alága yóò ti jókòó sórí pèpéle tí orin Ìjọba Ọlọ́run tí a fi ń mọ̀ pé ìpàdé ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bẹ̀rẹ̀ yóò sì máa dún. Àmì tí a fi ń mọ̀ pé ó ti tó àkókò láti lọ jókòó nìyí! Lẹ́yìn náà, bí wọ́n bá wá pe orin ìbẹ̀rẹ̀, a óò ti wà ní sẹpẹ́ láti dara pọ̀ ní kíkọ orin ìyìn sí Jèhófà.

4 Ẹ Máa Fetí Sílẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé Tó Ṣọ̀kan: Nígbà tí wọ́n ń ka àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ sétí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó pé jọ, àwọn ìdílé, títí kan “àwọn ọmọ kéékèèké” ló gbọ́dọ̀ fetí sílẹ̀, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́. (Diu. 31:12) Ní àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè wa, a kò gbọ́dọ̀ ‘jọ̀wọ́ àwọn ọmọ sílẹ̀ fàlàlà.’ (Òwe 29:15) Ẹ̀yin òbí, ẹ ṣètò kí gbogbo ìdílé yín jókòó pa pọ̀, káwọn ọ̀dọ́langba pẹ̀lú wà lọ́dọ̀ yín. Àwọn òbí kan máa ń dúró di ìgbà orin ìbẹ̀rẹ̀ kí wọ́n tó mú àwọn ọmọ wọn kéékèèké lọ sí ilé ìtura. Bó ti wù kí ó rí, agbára káká ni èyí yóò fi jẹ́ kí àwọn ọmọ mọ̀ pé orin àti àdúrà ṣe pàtàkì gidigidi nínú ìjọsìn wa. Ẹ ò rí i pé ó dára gidigidi pé bí a bá ní láti lọ sí ilé ìtura, kí á lọ ṣáájú kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, àyàfi bí lílọ lákòókò tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́ kò bá ṣeé yẹ̀ sílẹ̀!

5 Bí a bá sùn dáadáa lálẹ́, tí a kò sì jẹ oúnjẹ tó máa ń mú kí ara wúwo wá sí àpéjọpọ̀, yóò jẹ́ kí a lè fetí sílẹ̀. Pọkàn pọ̀ sórí ohun tí olùbánisọ̀rọ̀ ń sọ. Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ máa ro tìhín ro tọ̀hún. Máa fojú bá Bíbélì rẹ lọ nígbà tí wọ́n bá ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Kọ àkọsílẹ̀ ṣókíṣókí. Bí wọ́n bá ti ń sọ àsọyé kọ̀ọ̀kan tán, ṣàtúnyẹ̀wò ohun tí olùbánisọ̀rọ̀ sọ nínú ọkàn rẹ, kí o sì ronú nípa bí wàá ṣe fi ọ̀rọ̀ náà sílò. Lópin ọjọ́ náà, ẹ jíròrò ọ̀rọ̀ tí ẹ gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Kókó wo lẹnì kọ̀ọ̀kan gbádùn? Báwo ni ìdílé rẹ ṣe lè fi ìsọfúnni yìí sílò dáadáa?

6 Bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: Àwọn àpéjọpọ̀ máa ń fún wa ní àǹfààní dáradára láti bá àwọn ọ̀rẹ́ wa sọ̀rọ̀, kí a sì gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ tó ń gbéni ró. Bí a bá tètè dé, a óò ní àǹfààní láti tàkúrọ̀sọ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n o, àwọn kan máa ń sọ̀rọ̀ nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́, wọ́n máa ń ṣàṣìṣe ní ríronú pé èyí kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe ìdíwọ́ nínú gbọ̀ngàn ńlá. Kódà nígbà tí a bá ń ṣe ìpàdé ńlá, àkókò láti fetí sílẹ̀ ni èyí jẹ́, bí ìgbà tí a bá lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí lílo àwọn tẹlifóònù alágbèérìn, ẹ̀rọ kóńkóló tí a fi ń gba ìsọfúnni, ẹ̀rọ tí a fi ń gba ohùn àti àwòrán sílẹ̀, àti kámẹ́rà fa ìpínyà ọkàn nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́.

7 Nígbà tí Mósè ń gba Òfin látọ̀dọ̀ Jèhófà, “kò jẹ oúnjẹ, kò sì mu omi.” (Ẹ́kís. 34:28) Bákan náà, kò yẹ kí a máa jẹun tàbí kí a máa mu nǹkan nígbà tí wọ́n bá ń sọ ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ní àpéjọpọ̀. Bí kò bá jẹ́ pé ó la ọ̀ràn àìlera líle koko lọ, dúró títí di “ìgbà tí a yàn kalẹ̀” fún ìyẹn.—Oníw. 3:1.

8 Ní àwọn àpéjọpọ̀ kan, ìṣòro kan ṣì ń ṣẹlẹ̀ o, ìyẹn ni pé ọ̀pọ̀ arákùnrin àti arábìnrin títí kan àwọn ọmọdé ṣì máa ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri ní àwọn ọ̀nà àbákọjá nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. A óò fún àwọn olùtọ́jú èrò nítọ̀ọ́ni pé kí wọ́n sọ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé kí wọ́n padà lọ jókòó nínú gbọ̀ngàn. Kí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní onírúurú ẹ̀ka iṣẹ́ lọ jókòó láàárín àwùjọ ní gbàrà tí wọ́n bá ti parí iṣẹ́ wọn. Bí kì í bá ṣe pé a yan àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni láti ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́, kí wọ́n wà lórí ìjókòó wọn, kí wọ́n sì máa fetí sí ọ̀rọ̀ tó ń lọ lọ́wọ́. Wọn kò gbọ́dọ̀ dúró pẹ́ ní ibi tí a ti ń yanṣẹ́ fúnni, kí wọ́n máa bẹ ara wọn wò nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́.

9 A kò ní fẹ́ láti “yigbì ní gbígbọ́” nígbà tí a bá ń fetí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Héb. 5:11) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a pinnu pé a óò fi ọ̀wọ̀ tí ó yẹ hàn nípa fífetí sílẹ̀ dáadáa nígbà tí wọ́n bá ń jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Jèhófà ní àpéjọpọ̀ àgbègbè wa tí ń bọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́