Fetí Sílẹ̀ Kó O sì Kẹ́kọ̀ọ́
1. Kí nìdí tó fi gba ìsapá gidigidi ká tó lè fetí sílẹ̀ ká sì kẹ́kọ̀ọ́ ní àpéjọ àgbègbè?
1 A máa tó bẹ̀rẹ̀ àwọn àpéjọ àgbègbè ọdún 2013. Iṣẹ́ ti lọ gan-an lórí ṣíṣètò àwọn ẹ̀kọ́ tá a máa kọ́ ní àpéjọ náà sílẹ̀, ó sì máa wúlò fún àwọn èèyàn kárí ayé. Ǹjẹ́ o ti ṣètò bó o ṣe máa wà níbẹ̀ jálẹ̀ ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta? Ní irú àwọn àpéjọ ńlá yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè pín ọkàn wa níyà, torí náà, a ní láti sapá gidigidi kí ọkàn wa má bàa kúrò nínú ohun tó ń lọ lórí pèpéle. Torí pé àkókò tá a máa fi kẹ́kọ̀ọ́ ní àpéjọ náà máa pọ̀ ju ti ìpàdé ìjọ lọ, a ní láti pọkan pọ̀ fún àkókò tó gùn ju ti ìpàdé ìjọ lọ. Yàtọ̀ síyẹn, ìrìn-àjò àtàwọn nǹkan míì lè jẹ́ kó rẹ̀ wá díẹ̀. Kí ló máa jẹ́ ká wà lójú fò, ká fetí sílẹ̀, ká sì kẹ́kọ̀ọ́?—Diu. 31:12.
2. Báwo la ṣe lè múra ọkàn wa sílẹ̀ fún ohun tá a máa gbọ́ ní àpéjọ náà?
2 Kí Àpéjọ Náà Tó Bẹ̀rẹ̀: A ti gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà sórí Ìkànnì www.jw.org/yr. A sì ti fi àkòrí àwọn àsọyé tá a fẹ́ gbọ́ àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tí mú àsọyé kọ̀ọ̀kan jáde síbẹ̀. Tá a bá láǹfààní láti lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tá a sì yẹ àwọn ìṣọfúnni yìí wò ṣáájú àpéjọ náà, a ó lè múra ọkàn wa sílẹ̀ fún àwọn ohun tá a máa gbọ́ ní àpéjọ náà. (Ẹ́sírà 7:10) Ẹ ò ṣe wá àyè nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín láti jíròrò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà kẹ́ ẹ lè túbọ̀ múra ọkàn yín sílẹ̀?
3. Kí ló máa jẹ́ ká lè fetí sílẹ̀ dáadáa ní àpéjọ náà?
3 Nígbà Àpéjọ Náà: Tó bá ṣeé ṣe, ó máa dáa kó o ti lọ tọ̀ tàbí kó o ti lọ gbọnsẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀. Pa fóònù alágbèéká rẹ, kí ìpè tàbí àtẹ̀jíṣẹ́ tó bá wọlé má bàa dí ẹ lọ́wọ́, kó má bàa ṣe ẹ́ bíi pé kó o fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù rẹ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá ń lọ lọ́wọ́. Tó bá pọn dandan pé kí fóònù rẹ wà ní títàn, gbé e sí ìpè tí kò ní pín ọkàn àwọn ẹlòmíì níyà. Tó o bá ń lo kọ̀ǹpútà kékeré nígbà tí ọ̀rọ̀ ń lọ lọ́wọ́, jọ̀wọ́ má ṣe jẹ́ kó dí àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Kò dáa ká máa jẹun tàbí ká máa mu ohunkóhun nígbà tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́. (Oníw. 3:1) Olùbánisọ̀rọ̀ ni kó o máa wò. Tí wọ́n bá ń ka ẹsẹ Bíbélì, máa fojú bá a lọ nínú Bíbélì rẹ, kó o sì máa ṣe àkọsílẹ̀ ṣókí.
4. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè fetí sílẹ̀, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́?
4 A fẹ́ kí àwọn ọmọ wa fetí sílẹ̀ kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́. Ìwé Òwe 29:15 sọ pé: “Ọmọdékùnrin tí a jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ fàlàlà yóò máa kó ìtìjú bá ìyá rẹ̀.” Torí náà, á dáa kí ìdílé jókòó pa pọ̀, kí àwọn òbí lè rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn ń fetí sílẹ̀, wọn kò rìn kiri tàbí kí wọ́n máa rojọ́ tàbí kí wọ́n máa tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ lórí fóònù. Kódà tí ọjọ́ orí wọn bá ṣì kéré débi pé wọn ò lè fi bẹ́ẹ̀ lóye ohun tó ń lọ, ẹ lè kọ́ wọn láti máa wà lójúfò kí wọ́n sì máa jókòó jẹ́ẹ́.
5. Kí nìdí tó fi dáa pé ká ṣàtúnyẹ̀wò ohun tá a bá gbọ́ ní àpéjọ náà? Ọ̀nà wo la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀?
5 Lẹ́yìn Ìpàdé Ọjọ́ Kọ̀ọ̀kan: Má ṣe jẹ́ kó pẹ́ kó o tó wọlé. Kó o sì tètè sùn, kó o lè sinmi dáadáa. Tó o bá ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ohun tó o gbọ́ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, wàá lè máa rántí rẹ̀ dáadáa. Torí náà, nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ó dáa táwọn ìdílé bá fi ìṣẹ́jú díẹ̀ jíròrò ohun tí wọ́n gbọ́ lọ́jọ́ náà. Tó o bá lọ sílé oúnjẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, o lè mú ìwé tó o fi ṣàkọsílẹ̀ dání, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò kókó kan tàbí méjì lára àwọn ohun tẹ́ ẹ gbádùn. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé yín lẹ́yìn àpéjọ náà, ẹ lè jíròrò bẹ́ ẹ ṣe fẹ́ fi àwọn ohun tẹ́ ẹ gbọ́ ní àpéjọ náà sílò nínú ìdílé yín. Ẹ sì lè ya àkókò sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fi ka ìtẹ̀jáde tuntun tẹ́ ẹ gbà ní àpéjọ náà.
6. Ṣé kéèyàn sáà ti wá sí àpéjọ náà nìkan ti tó? Ṣàlàyé.
6 Téèyàn bá fẹ́ kí oúnjẹ ṣe òun láǹfààní dáadáa, ó gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, kó sì jẹ́ kí oúnjẹ náà dà nínú òun. Bákan náà ni oúnjẹ tẹ̀mí tá a fẹ́ jẹ ní àpéjọ àgbègbè wa. A máa jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ tá a bá pésẹ̀ síbẹ̀, tá a fetí sílẹ̀ dáadáa, tá a sì fi àwọn ohun tá a kọ́ níbẹ̀ sílò.