ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/14 ojú ìwé 2-3
  • “Pe Àwọn Ènìyàn Náà Jọpọ̀”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Pe Àwọn Ènìyàn Náà Jọpọ̀”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fetí Sílẹ̀ Kó O sì Kẹ́kọ̀ọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” ti 1998
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Wa Máa Ń Jẹ́ Ẹ̀rí Tó Lágbára sí Òtítọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” ti 1999
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
km 8/14 ojú ìwé 2-3

“Pe Àwọn Ènìyàn Náà Jọpọ̀”

1. Báwo ni àpéjọ àgbègbè àti àpéjọ àgbáyé ṣe jọra pẹ̀lú àwọn àpéjọ alárinrin táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì?

1 Láìpẹ́ lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, Jèhófà sọ fún Mósè pé kó “pe àwọn ènìyàn náà jọpọ̀” ní Òkè Sínáì láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Òun kí wọ́n lè bẹ̀rù Òun kí wọ́n sì fi ọ̀nà Òun kọ́ àwọn ọmọ wọn. (Diu. 4:10-13) Àkókò mánigbàgbé làwọn àpéjọ yẹn jẹ́, ó sì mú kí ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn náà lágbára gan-an! Ní àwọn oṣù díẹ̀ sí i, àwa èèyàn Jèhófà máa ṣe àpéjọ àgbègbè àti àpéjọ àgbáyé ká lè gba ìtọ́ni lọ́dọ̀ Jèhófà. Kí ló yẹ ká ṣe ká lè jàǹfààní ní kíkún?

2. Kí ló yẹ ká ṣe ká lè “wà ní sẹpẹ́” fún àwọn àpéjọ wa?

2 Ẹ “Wà ní Sẹpẹ́”: Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n “wà ní sẹpẹ́” fún àpéjọ mánigbàgbé yẹn tó wáyé ní Òkè Sínáì. (Ẹ́kís. 19:10, 11) Bákan náà, ó yẹ kí gbogbo àwọn tó máa lọ sí àpéjọ àgbègbè àti àpéjọ àgbáyé múra sílẹ̀ dáadáa, kì í kàn ṣe àwọn tó máa kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà nìkan ló yẹ kó múra sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ máa ní láti gbàyè níbi iṣẹ́ wọn. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ tìrẹ náà dà bíi ti Nehemáyà. Ó fẹ́ gbàyè lọ́dọ̀ Ọba Atasásítà kó lè lọ tún odi Jerúsálẹ́mù kọ́, àmọ́ ó mọ̀ pé ọba lè má fara mọ́ ọn. Nehemáyà gbàdúrà, ó lo ìgboyà, ó sì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ohun tó fẹ́. Ọba fún un láyè láti lọ, ó sì tún ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìkọ́lé náà! (Neh. 2:1-9) Yàtọ̀ sí pé kó o gba ààyè lẹ́nu iṣẹ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ, ǹjẹ́ o ti ṣètò bó o ṣe máa dé ibi tí ẹ ó ti ṣe àpéjọ náà àti ilé tó o máa dé sí? Inú àwọn alàgbà yóò dùn láti pèsè ìrànwọ́ fún ẹnikẹ́ni tó bá nílò ìrànlọ́wọ́. Ṣètò láti tètè dé kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó bẹ̀rẹ̀, kí o sì múra tán láti fún àwọn ohun tó o máa gbọ́ ní “àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.”—Héb. 2:1.

3. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè múra ọkàn wa sílẹ̀ fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà?

3 Nǹkan míì tó yẹ ká ṣe tó máa fi hàn pé a ti wà ní sẹpẹ́ ni pé ká múra ọkàn wa sílẹ̀ ká lè fetí sílẹ̀ ká sì kẹ́kọ̀ọ́. (Ẹ́sírà 7:10) Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àgbègbè ti wà lórí Ìkànnì jw.org, ó sì ní àwọn àkòrí àsọyé kọ̀ọ̀kan àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó kín àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àsọyé náà lẹ́yìn. Èyí á jẹ́ kẹ́ ẹ lè jíròrò àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí nígbà ìjọsìn ìdílé yín tó bá ku ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tẹ́ ẹ máa lọ sí àpéjọ àgbègbè tá a yan ìjọ yín sí. Àwọn akéde kan máa ń tẹ ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó wà lórí ìkànnì wa jáde láti lè fi ṣe àkọsílẹ̀ ṣókí nígbà tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́.

4. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn nígbà àpéjọ?

4 ‘Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ’: Ọ̀kan lára ìdí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi máa ń péjọ pọ̀ ní Òkè Sínáì ni pé, kí àwọn òbí ní Ísírẹ́lì lè “kọ́ àwọn ọmọ wọn.” (Diu. 4:10) Àpéjọ àgbègbè àti àpéjọ àgbáyé máa fún àwọn òbí láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti ṣe bákan náà. Kí àwọn òbí jókòó ti àwọn ọmọ wọn nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá ń lọ lọ́wọ́ kí àwọn ọmọ wọn lè pọkàn pọ̀. Lẹ́yìn àpéjọ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àti nígbà ìjọsìn ìdílé, kí àwọn ìdílé jíròrò àwọn ohun tí wọ́n gbádùn nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà pa pọ̀.

5. Àǹfààní wo ló máa tibẹ̀ jáde tá a bá lọ sí àpéjọ àgbègbè tó ń bọ̀ yìí?

5 Àpéjọ alárinrin tó wáyé ní Òkè Sínáì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọyì àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n ní láti jẹ́ èèyàn Ọlọ́run. (Diu. 4:7, 8) Àpéjọ àgbègbè wa tó ń bọ̀ yìí á ṣe wá láǹfààní lọ́nà kan náà. Ọjọ́ mẹ́ta gbáko la máa fi jáde kúrò nínú ayé Sátánì tó dà bí aginjù tó léwu gan-an yìí, tí a ó sì rí ìtura nípa tẹ̀mí gbà àti ìbákẹ́gbẹ́ tó ń ṣeni láǹfààní nínú Párádísè wa nípa tẹ̀mí. (Aísá. 35:7-9) Bí ọjọ́ Jèhófà ṣe ń sún mọ́lé, ǹjẹ́ kí á má ṣe kọ àǹfààní tá a ní yìí sílẹ̀ láti péjọ ká sì gba pàṣípààrọ̀ ìṣírí!—Héb. 10:24, 25.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́