Máa Fetí Sílẹ̀ Dáadáa
1 Fífetí sílẹ̀ dáadáa gba pé kí èèyàn lè kó ara rẹ̀ níjàánu. Ó tún gba pé kí ẹni tó ń fetí sílẹ̀ náà fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́, kó sì jàǹfààní nínú ohun tó bá gbọ́. Nítorí náà, Jésù tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì láti “fiyè sí bí [a] ṣe ń fetí sílẹ̀.”—Lúùkù 8:18.
2 Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì nígbà tí a bá lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ, àti àpéjọpọ̀. Àkókò tí a gbọ́dọ̀ fetí sílẹ̀ dáadáa nìwọ̀nyí. (Héb. 2:1) Ìwọ̀nyí ni àwọn kókó díẹ̀ tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa fetí sílẹ̀ dáadáa ní àwọn àpéjọ Kristẹni.
◼ Mọrírì ìníyelórí àwọn ìpàdé. Wọ́n jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tí ‘Jèhófà ń gbà kọ́’ wa nípasẹ̀ “olóòótọ́ ìríjú náà.”—Aísá. 54:13; Lúùkù 12:42.
◼ Múra sílẹ̀ ṣáájú. Yẹ ohun tí wọ́n máa jíròrò wò, sì rí i dájú pé o mú Bíbélì tìrẹ àti ìtẹ̀jáde tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ dání.
◼ Nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́, sapá gidigidi láti pọkàn pọ̀. Yéé bá àwọn tó jókòó tì ọ́ sọ̀rọ̀, sì yéé wo nǹkan tí àwọn tó wà nínú àwùjọ ń ṣe. Má ṣe jẹ́ kí ìrònú nípa ohun tí o máa ṣe nígbà tí ìpàdé bá parí tàbí àwọn ọ̀ràn mìíràn tó jẹ́ tìrẹ mú kí ọkàn rẹ pínyà.
◼ Ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ ohun tí wọ́n sọ. Bi ara rẹ pé: ‘Báwo lèyí ṣe kàn mí? Ìgbà wo ni màá fi í sílò?’
◼ Kọ àkọsílẹ̀ ṣókí nípa àwọn kókó pàtàkì àti àwọn ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Èyí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pa ìrònú rẹ pọ̀ sórí ohun tí wọ́n ń jíròrò, yóò sì jẹ́ kí o lè rántí àwọn kókó pàtàkì nígbà tí o bá fẹ́ lò wọ́n.
3 Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Máa Fetí Sílẹ̀: Ìtọ́ni tẹ̀mí ṣe pàtàkì fún àwọn ọmọ. (Diu. 31:12) Nígbà àtijọ́, “gbogbo àwọn tí ó ní làákàyè tó láti fetí sílẹ̀” láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run ló gbọ́dọ̀ tẹ́tí sílẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ka Òfin Ọlọ́run sétíìgbọ́ wọn. (Neh. 8:1-3) Bí àwọn òbí bá ń fara balẹ̀ ní ìpàdé tí wọ́n sì ń fetí sílẹ̀ dáadáa, àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú yóò ṣe bẹ́ẹ̀. Kò bọ́gbọ́n mu láti mú ohun ìṣeré tàbí ìwé àwòrán tí ọmọdé á máa kùn wá sí ìpàdé láti mú inú àwọn ọmọ dùn. Kí wọ́n máa lọ sí ilé ìgbọ̀nsẹ̀ ṣáá láìjẹ́ pé ó pọndandan kì í jẹ́ kí wọ́n fetí sílẹ̀ pẹ̀lú. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí” àwọn òbí gbọ́dọ̀ sapá gidigidi láti rí i pé àwọn ọmọ wọn ń jókòó jẹ́ẹ́ tí wọ́n sì ń fetí sílẹ̀ ní àwọn ìpàdé.—Òwe 22:15.
4 Nípa fífetí sílẹ̀ dáadáa, a ń fi hàn pé a jẹ́ ọlọgbọ́n ní tòótọ́, a sì ń fẹ́ láti máa “gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i.”—Òwe 1:5.