Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 8
Orin 29
7 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
13 min: “Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn.”a Fi àlàyé tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ June 1, 1997, ojú ìwé 15, ìpínrọ̀ 12 àti 13 kún un. Fún gbogbo akéde níṣìírí láti lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti jẹ́rìí.
25 min: Àwọn Ìpèsè Onífẹ̀ẹ́ fún Ìtọ́jú Ìlera Wa. Àsọyé látẹnu alàgbà kan tí ó tóótun. Tẹnu mọ́ ọn pé kíkọ ọ̀rọ̀ sínú káàdì Advance Medical Directive/Release ni ọ̀nà tó dára jù lọ tí a lè fi dáàbò bo ara wa kí wọ́n máa bàa fa ẹ̀jẹ̀ sí wa lára. Tọ́ka sí lẹ́tà tí a kọ sí gbogbo ìjọ ní February 1, 1995. Tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì pé kí a máa mú káàdì Advance Medical Directive/Release dání nígbà gbogbo. Ka ìpínrọ̀ 1 àti 2, kí o sì ṣàlàyé wọn. A óò fún àwọn akéde tí wọ́n ti ṣe ìrìbọmi ní káàdì yìí bí ìpàdé tòní bá ti parí, ṣùgbọ́n kí ẹ MÁ ṢE buwọ́ lù ú lónìí. Kí ìjọ ní káàdì tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́ láti pín. Lẹ́yìn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tí ń bọ̀ ni a ó buwọ́ lu káàdì wọ̀nyí, ìgbà náà la óò jẹ́rìí sí wọn, ìgbà náà la ó sì kọ déètì sí wọn, olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ yóò sì ṣèrànwọ́ níbi tó bá ti pọndandan. Kí àwọn tí ń buwọ́ lu káàdì náà láti ṣe ẹlẹ́rìí jẹ́ kí ẹni tí ó ni káàdì náà buwọ́ lù ú níṣojú wọn. Kí àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rí i dájú pé gbogbo àwọn tí a pín sí àwùjọ wọn rí ìrànwọ́ tí wọ́n nílò gbà láti kọ ọ̀rọ̀ sínú káàdì Advance Medical Directive/Release. A óò fún àwọn òbí ní Identity Card (Káàdì Ìdánimọ̀) ti àwọn ọmọ wọn tí ìpàdé yìí bá parí. Àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi lè ṣe káàdì tiwọn, tí àwọn àtàwọn ọmọ wọn yóò máa lò, nípa títún àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò nínú àwọn káàdì yìí kọ láti bá ipò àti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ mu.
Orin 1 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 15
Orin 51
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
20 min: Ǹjẹ́ O Máa Ń Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́? Àsọyé àti àwọn ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò. Ṣàyẹ̀wò Ilé Ìṣọ́ December 15, 1996, ojú ìwé 17 àti 18, ìpínrọ̀ 12 sí 14, kí o ṣàlàyé bí jíjíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ojoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan ti bọ́gbọ́n mu tó. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn mẹ́ńbà ìdílé, tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn rántí ìjíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ojoojúmọ́ kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí tó sì ṣàǹfààní gidigidi, kí wọ́n sì sọ ìdí tó fi ṣàǹfààní. Tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ kí èyí jẹ́ ara ètò tí ìdílé ṣe fún kíkẹ́kọ̀ọ́ déédéé, tó wà fún fífún ìdílé wa lókun àti fún mímú kí ìdílé wa jẹ́ ògbóṣáṣá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.
Orin 67 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 22
Orin 90
7 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
18 min: Bí A Ṣe Lè Múra Àwọn Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀. Àsọyé àti àwọn àṣefihàn. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì nínú ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 2. Sọ bí a ṣe lè yan àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀, èyí tí yóò bá bí a ṣe lè gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀, àkópọ̀ ìwà wa, àti ìpínlẹ̀ wa mu jù lọ. Ṣàyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a lè lò pẹ̀lú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, kí o sì jẹ́ kí a ṣàṣefihàn ọ̀kan tàbí méjì nínú wọn. (Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti April 1997, ojú ìwé 8.) Fún gbogbo akéde níṣìírí láti lo àwọn àbá tí wọ́n fún wa nínú ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, àti nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa nígbà tí wọ́n bá ń kópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá.
20 min: “Máa Fetí Sílẹ̀ Dáadáa.” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ṣàyẹ̀wò àwọn kókó látinú Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ojú ìwé 28, ìpínrọ̀ 15 sí 17. Bí a ṣe lè rántí nǹkan tó ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti fi mọ bí a ṣe ń fetí sílẹ̀ dáadáa tó. Sọ pé kí àwùjọ sọ díẹ̀ lára àwọn kókó pàtàkì tí àwọn tó ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run jíròrò lónìí.
Orin 96 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 29
Orin 139
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù January sílẹ̀. Dárúkọ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù February, kí o sì sọ àwọn ìwé tí ìjọ ní lọ́wọ́.
15 min: Mọ Irú Ẹni Tí Ẹlẹ́dàá Jẹ́ Dunjú. Àsọyé tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́, June 15, 1999, ojú ìwé 24 sí 26.
20 min: “Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Gbin Àṣà Tó Dára Sínú Àwọn Ọmọ Yín.” Àsọyé àti fífi ọ̀rọ̀ wá àwọn òbí tí àwọn ọmọ wọn ń ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí lẹ́nu wò. Àwọn òbí sọ àwọn ohun tó gbéṣẹ́ tí àwọn ti ṣe láti mú kí àwọn ọmọ wọn máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Bí àkókò bá ti wà tó, fi àwọn àbá tó wà nínú ìwé Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 55 sí 59 kún un.
Orin 149 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 5
Orin 168
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: “Máa Ṣe É Tayọ̀tayọ̀.”b Ṣàlàyé ohun tó ń mú kí inú wa túbọ̀ máa dùn nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nínú ìwé Insight, Apá Kejì, ojú ìwé 120, ìpínrọ̀ 6 sí 8.
20 min: O Lè Rí Ohun Àṣenajú Tó Gbámúṣé. Àwùjọ ìdílé kan yóò jíròrò ìmọ̀ràn tí wọ́n fún wa nínú Jí! May 22, 1997. Bàbá ń ṣàníyàn nípa irú eré ìtura tó yẹ kí ìdílé wọn máa ṣe. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣàyẹ̀wò àkòrí náà, “Kí Ló Ti Ṣẹlẹ̀ sí Ohun Àṣenajú?” (ojú ìwé 4 sí 7), wọ́n darí àfiyèsí sí àwọn ohun àṣenajú tó gbámúṣé, tó sì lè ṣàǹfààní. Ṣàyẹ̀wò àkójọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 131 àti 132, lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Eré-Ìtura,” àti ojú ìwé 135 àti 136, lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Ẹ Maa Ṣe Ohun Gbogbo fun Ogo Ọlọrun.” Tẹnu mọ́ ọn pé ó jẹ́ ojúṣe àwọn òbí láti mú ipò iwájú, àti pé ó yẹ kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé fọwọ́ sowọ́ pọ̀ fún àǹfààní agbo ilé wọn.
Orin 190 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.