ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/01 ojú ìwé 3
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 1/01 ojú ìwé 3

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ìjọ bá ní, tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1986. February: Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbilọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tó ti pẹ́ tí ìjọ bá ní. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A óò sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. April: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Níbi tí wọ́n bá ti fi ìfẹ́ hàn nígbà ìpadàbẹ̀wò, a lè fi ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn lọni. Fi ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, kí o ní in lọ́kàn pé o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.

◼ Society ń fẹ́ àwọn ẹnjiníà, àwọn sọ̀fíọ̀ oníṣirò (quantity surveyors), àti àwọn olùyàwòrán ìgbékalẹ̀ ilé tí wọ́n tóótun tí wọ́n sì nírìírí lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé. Kí ẹnikẹ́ni tó bá ronú pé òun tóótun, tó sì fẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì kọ̀wé láti sọ fún Society. Kí lẹ́tà náà sọ nípa bí ẹni náà ṣe kàwé tó àti àwọn ìwé ẹ̀rí tó gbà. Àwọn tí kò tí ì ṣègbéyàwó tàbí tọkọtaya tí kò sọ́mọ tí wọ́n ń tọ́jú ni kó kọ̀wé, wọ́n sì gbọ́dọ̀ lè yọ̀ǹda ara wọn láti wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Kí àwọn tí kò ní lè wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe tán láti yọ̀ǹda ara wọn fún ìgbà díẹ̀ tàbí tí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fún àkókò díẹ̀ kọ̀wé sí Society pẹ̀lú.

◼ Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kíyè si pé Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2002 yóò jẹ́ ní Thursday, March 28, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀, kò sì ní jẹ́ ní ọjọ́ Friday, March 22 tí a fi hàn lẹ́yìn 2001 Calendar mọ́. A tètè fi tó yín létí kí àwọn arákùnrin lè ṣètò tó bá yẹ láti wá gbọ̀ngàn tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó bí ó bá lọ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìjọ ló ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, tó sì jẹ́ pé wọ́n gbọ́dọ̀ wá gbọ̀ngàn mìíràn. Kí àwọn alàgbà ṣàdéhùn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ gbọ̀ngàn náà láti rí i dájú pé kò ní sí àwọn mìíràn tí yóò ṣe nǹkan tí yóò ṣèdíwọ́ nínú gbọ̀ngàn náà kí ṣíṣe Ìṣe Ìrántí lè lọ wọ́ọ́rọ́wọ́ ní àlàáfíà àti létòlétò. Nítorí bí àṣeyẹ náà ti ṣe pàtàkì tó, bí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà bá fẹ́ yan ẹni tí yóò sọ ọ̀rọ̀ Ìṣe Ìrántí, kí wọ́n yan ọ̀kan lára àwọn alàgbà tó tóótun jù lọ dípò kí wọ́n máa tò ó láàárín ara wọn tàbí dípò kí wọ́n máa lo arákùnrin kan náà ní gbogbo ọdún. Àyàfi bí ó bá jẹ́ pé alàgbà dídáńgájíá kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró wà tó lè sọ àsọyé náà.

◼ Kí gbogbo akéde tó ti ṣe ṣèrìbọmi, tó bá wà ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ January 8 gba káàdì Advance Medical Directive/Release, kí wọ́n sì gba Identity Card (Káàdì Ìdánimọ̀) fún àwọn ọmọ wọn.

◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù February, tàbí ó pẹ́ tan láti March 4, àsọyé tuntun tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ fún gbogbo èèyàn yóò jẹ́, “Ọjọ́ Ìdájọ́—Ṣé Àkókò Ìbẹ̀rù Ni Àbí Àkókò Ayọ̀?”

◼ Ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí ní gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbí Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀! O lè ṣe ẹ̀dà rẹ̀, kí o sì fi í sínú ìwé tìrẹ kí o lè máa tètè rí i lò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́