Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Pọkàn Pọ̀?
“Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ń jókòó nípàdé láìkọ́ nǹkan kan níbẹ̀. Ọkàn mi kì í wulẹ̀ sí níbẹ̀ ni.”—Matthew.
ǸJẸ́ o ti jókòó ní kíláàsì tàbí ní ìpàdé Kristẹni rí, kí o sì wá rí i lójijì pé o kò tilẹ̀ mọ ohun tí a ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Kò burú, bí ìrònú rẹ bá máa ń lọ látorí ọ̀ràn kan sí òmíràn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìwọ nìkan kọ́ ló ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpilẹ̀kọ kan tí a ti kọ rí ṣe sọ, àìlèpọkànpọ̀ lọ títí wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́.a Ṣùgbọ́n bí o bá sapá díẹ̀, tí o sì tún èrò rẹ pa, o lè kọ́ láti túbọ̀ máa pọkàn pọ̀ sí i.
Ní Ọkàn Ìfẹ́ sí Ohun Tí O Ń Kọ́
Ronú nípa eléré ìdárayá kan. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wí pé: “Olúkúlùkù ènìyàn tí ń kó ipa nínú ìdíje a máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ohun gbogbo.” Bí eléré ìdárayá kan bá jẹ́ kí ohun kan gba òun lọ́kàn ní ìṣẹ́jú kan péré, ó lè pàdánù ìdíje náà. Kí ó má bàa pàdánù, ó gbọ́dọ̀ kọ́ láti pọkàn pọ̀—kó kọtí ikún sí ariwo tí àwọn èrò ń pa, kó má ka ìrora àti àárẹ̀ tirẹ̀ sí, kí ó má sì ronú nípa ìkùnà rárá. Àmọ́, kí ló ń sún àwọn eléré ìdárayá láti sakun lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ bẹ́ẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, wọ́n ń ṣe é “kí wọ́n lè gba adé tí ó lè díbàjẹ́”—àwọn ife ẹ̀yẹ àti àmì ẹ̀yẹ tí a ń fún àwọn olùborí.—1 Kọ́ríńtì 9:25.
Lọ́nà kan náà, ó yẹ kí o ní ìsúnniṣe láti pọkàn pọ̀! Ìwé Study Is Hard Work, tí William H. Armstrong kọ, sọ pé: “Ojúṣe akẹ́kọ̀ọ́ ni láti lọ́kàn ìfẹ́ sí ohun tó ń kọ́. Kò sí ẹni tó lè bá ọ lọ́kàn ìfẹ́ sí ẹ̀kọ́ rẹ, ẹnikẹ́ni kò sì lè mú kí ọkàn ìfẹ́ tí o ní pọ̀ sí i láìjẹ́ pé o fẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ìmọ̀ ni kókó pàtàkì jù lọ tí o fi lè lóye ohun tí ń lọ láyìíká rẹ. Bí ohun tí o mọ̀ bá ṣe pọ̀ tó ni ohun tí o lè kọ́ pọ̀ tó. Òwe 14:6 sọ pé: “Sí olóye, ìmọ̀ jẹ́ ohun rírọrùn.” Ó ṣeé ṣe kí o máà rántí gbogbo ohun tí o kọ́ nílé ìwé, ṣùgbọ́n ó kéré tán, ilé ìwé ń ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní agbára láti ronú, kí o sì lo agbára náà. (Fi wé Òwe 1:4.) Níní ìrònú tí a dá lẹ́kọ̀ọ́ àti agbára láti pọkàn pọ̀ yóò ṣe ọ́ láǹfààní jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ.
Àwọn Olùkọ́ Tí Nǹkan Sú, Tó Tún Ń Fi Nǹkan Súni
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọ̀dọ́langba kan ń ṣàròyé pé àwọn olùkọ́ wọn pàápàá ń ṣàìlọ́kàn ìfẹ́. Ọ̀dọ́ kan tí ń jẹ́ Jesse sọ pé: “Àwọn olùkọ́ wulẹ̀ ń dúró níwájú, wọ́n ń sọ nǹkan, wọ́n ń fúnni níṣẹ́, wọ́n sì ń yọ̀ǹda ẹni. Mo rò pé àgunlá ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́. Àwọn olùkọ́ kò fọwọ́ pàtàkì mú un, nítorí náà, a kò rí ìdí tó fi yẹ ká pọkàn pọ̀.”
Ṣé ó wá yẹ kí o parí rẹ̀ sí pé pípọkànpọ̀ jẹ́ fífi àkókò ṣòfò? Dandan kọ́. O lè jẹ́ pé ọ̀pọ̀ olùkọ́ wulẹ̀ bá ara wọn nípò ẹni tí kò ṣu, tí kò tọ̀, tí kò kúrò nílé póò ni. Ọ̀dọ́langba kan tí ń jẹ́ Collin sọ pé: “Kò sẹ́ni tí ń fetí sí àwọn olùkọ́, nítorí náà, àwọn olùkọ́ rò pé kò sẹ́ni tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́. Wọn ò fi agbára ṣiṣẹ́ mọ́, wọn ò sì fi ọ̀yàyà kọ́ni.”
O jẹ́ mọ̀ pé o lè ṣe nǹkan tí yóò dẹ́kun kí nǹkan máa rí báyìí. Lọ́nà wo? Nípa wíwulẹ̀ pọkàn pọ̀ ni. Ó lè jẹ́ níní akẹ́kọ̀ọ́ kan ṣoṣo tó lọ́kàn ìfẹ́ ni yóò mú kí olùkọ́ kan tí nǹkan ti sú tún ní ọkàn ìfẹ́ lọ́tun nínú iṣẹ́ rẹ̀. Òtítọ́ ni pé àwọn olùkọ́ kan kò wulẹ̀ mọ bí a ṣe ń mú kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa lọ́kàn ìfẹ́ nìṣó. Àmọ́, kí o tó jẹ́ kí èrò rẹ lọ sórí àwọn fàájì àfinúrò, bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ olùkọ́ mọ ohun tí ó ń sọ?’ Bó bá mọ̀ ọ́n, pinnu láti kọ́ nǹkan lọ́dọ̀ rẹ̀. Tẹ́tí sí i dáradára—pọkàn pọ̀! Máa dá sí àwọn ìfọ̀rọ̀wérọ̀ inú iyàrá ìkàwé. Máa béèrè àwọn ìbéèrè pàtó. Ìwé How to Study in High School wí pé: “Ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ti rí i pé ó ṣàǹfààní láti ṣàkọsílẹ̀ àwọn àwòrán, ọ̀rọ̀, ìtumọ̀ ọ̀rọ̀, àti àwọn kókó pàtàkì tí olùkọ́ bá kọ sára pátákó, tàbí tí ó tẹnu mọ́ ní àwọn ọ̀nà mìíràn.”
Níní “Àfiyèsí Tí Ó Ju Ti Àtẹ̀yìnwá Lọ”
Bí ó ti wù kí ó rí, o lè jàǹfààní púpọ̀ sí i nípa títẹ́tísílẹ̀ ní àwọn ìpàdé Kristẹni. Jesse gbà pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ọ̀dọ́ kì í fiyè sí àwọn nǹkan bí ìpàdé nítorí pé wọn kò mọ bí àwọn ìpàdé ṣe ṣe pàtàkì tó.” A pàṣẹ fún wa nínú Hébérù 2:1 pé kí a “fún àwọn ohun tí a gbọ́ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, kí a má bàa sú lọ láé.” Nígbà tí o bá dé láti ìpàdé, ǹjẹ́ o lè rántí kókó kan láti inú ọ̀rọ̀ tí asọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan sọ níbẹ̀? Àbí ó máa ń ṣẹlẹ̀ pé o kò tilẹ̀ lè rántí àwọn tó sọ̀rọ̀ gan-an pàápàá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan?
Lẹ́ẹ̀kan sí i, gbogbo rẹ̀ sinmi lórí bí o bá ṣe mọ̀ pé ohun tí o ń kọ́ ṣe pàtàkì tó. O jẹ́ mọ̀ pé ó kan ìwàláàyè rẹ pàápàá! (Jòhánù 17:3) Ohun mìíràn láti ronú lé nìyí: Nígbà tí o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o ń kọ́ láti ronú bí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ṣe ń ronú! (Aísáyà 55:8, 9) Nígbà tí o bá sì ń ṣe ohun tí o kọ́, o ń fi ohun tí Bíbélì pè ní “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ ara rẹ láṣọ. (Kólósè 3:9, 10) Ní òdìkejì, bí o kò bá ń pọkàn pọ̀, o lè má lè mú ìgbésí ayé rẹ sunwọ̀n sí i; wàá sì dí ìdàgbàsókè rẹ nípa tẹ̀mí lọ́wọ́. Jèhófà mọ̀ pé gbogbo wa ní ìtẹ̀sí láti jẹ́ kí ọkàn wa pínyà. Nítorí náà, ó rọ̀ wá pé: “Ẹ fetí sí mi dáadáa . . . Ẹ dẹ etí sílẹ̀, kí ẹ sì wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ fetí sílẹ̀, ọkàn yín yóò sì máa wà láàyè nìṣó.”—Aísáyà 55:2, 3.
Bí Àwọn Ìpàdé Ṣe Lè Ṣàǹfààní fún Ọ Jù
Síbẹ̀ náà, fífiyè sí àwọn ìpàdé lè kọ́kọ́ ṣòro. Ṣùgbọ́n, àwọn olùwádìí sọ pé, bí a bá ṣe ń fi ìpọkànpọ̀ dánra wò tó ni ọpọlọ wa ṣe ń jáfáfá tó ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Matthew, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀, borí ìṣòro ọkàn rẹ̀ tí kì í papọ̀ nípàdé. Ó wí pé: “Mo rí i pé, ó yẹ kí ń kọ́ ara mi lẹ́kọ̀ọ́ láti máa pọkàn pọ̀. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ó sunwọ̀n sí i, ó sì ń ṣeé ṣe láti pọkàn pọ̀ fún àkókò púpọ̀ sí i.” Matthew tún sọ kókó tó ṣe pàtàkì jù ní mímú kí ìpàdé dùn mọ́ ọn. Ó wí pé: “Mo máa ń múra sílẹ̀.” Bákan náà, ọ̀dọ́ kan tí ń jẹ́ Charese sọ pé: “Nígbà tí mo bá múra sílẹ̀, mo túbọ̀ ń nímọ̀lára pé mo wà nípàdé. Ó jọ pé àwọn ọ̀rọ̀ náà ń wọ̀ mí lọ́kàn sí i, wọ́n sì túbọ̀ ń nítumọ̀ sí mi.”
Ó tún ṣe pàtàkì láti máa mú àwọn èrò tí ń pín ọkàn níyà kúrò lọ́kàn. Lóòótọ́, o lè ní àwọn ìdààmú tó jẹ́ ojúlówó nínú ìrònú rẹ: ìdánwò tí o máa ṣe lọ́sẹ̀ tí ń bọ̀, èdè àìyédè tí ń dààmú rẹ, àwọn ìnáwó kan tí o ní láti gbé ṣe láìpẹ́. Àmọ́ Jésù fúnni ní ìmọ̀ràn yìí: “Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀? Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un.” (Mátíù 6:27, 34) Pípọkànpọ̀ ní àwọn ìpàdé yóò mú àwọn ìṣòro rẹ kúrò, yóò sì tún fún ọ lágbára ọ̀tun nípa tẹ̀mí, tí yóò jẹ́ kí o lè túbọ̀ kápá àwọn ìṣòro.—Fi wé 2 Kọ́ríńtì 4:16.
Títẹ́tísílẹ̀ dáradára tún lè jẹ́ kí o pọkàn pọ̀. Matthew wí pé: “Mo ń gbìyànjú láti fọkàn ro ohun tí asọ̀rọ̀ yóò fà yọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí n sì rí bí ó ṣe ṣe é.” Bi ara rẹ léèrè pé, ‘Àwọn kókó pàtàkì wo la ń jíròrò? Báwo ni mo ṣe lè lo àwọn ohun tí a ń kọ́?’ Ríronú nípa ohun tí ó kàn tí asọ̀rọ̀ yóò sọ tún lè jẹ́ kí o pọkàn pọ̀. Gbìyànjú láti máa bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ṣàkíyèsí àwọn kókó tó ń fà yọ láti inú Ìwé Mímọ́. Ronú lórí àwọn kókó pàtàkì tó ń sọ, kí o sì ṣàkópọ̀ wọn. Ṣàkọsílẹ̀ ṣókí, tó nítumọ̀. Nígbà tí ọ̀rọ̀ kan bá jẹ́ èyí tí àwùjọ lè lóhùn sí, ìwọ náà, lóhùn sí i! Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè mú kí o máa fún èrò rẹ níṣẹ́ ṣe, kí ìrònú rẹ sì pa pọ̀ sọ́nà kan.
A gbà pé títẹ́tísílẹ̀ lè ṣòro gan-an bí asọ̀rọ̀ kan kò bá fìtara sọ̀rọ̀ tàbí tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá ń falẹ̀. Rántí ohun tí àwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní sọ nípa bí wọ́n ṣe rí ìsọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sí pé: “Wíwàníhìn-ín òun alára jẹ́ aláìlera, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ní láárí.” (2 Kọ́ríńtì 10:10) Ṣùgbọ́n ìdáhùn Pọ́ọ̀lù lórí irú àríwísí bẹ́ẹ̀ ni pé: “Bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjáfáfá nínú ọ̀rọ̀ sísọ, dájúdájú, èmi kò jẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú ìmọ̀.” (2 Kọ́ríńtì 11:6) Òtítọ́ ni, ká ní àwọn olùgbọ́ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ti fiyè sí kókó ohun tí ó ń sọ dípò ìjáfáfá rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ sísọ, wọ́n ti lè kọ́ ọ̀pọ̀ “ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 2:10) Lọ́nà kan náà, bí o bá pọkàn pọ̀, tí o sì fetí sílẹ̀, o lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ asọ̀rọ̀ “tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń falẹ̀” pàápàá. A ò sì lè sọ. Ó tilẹ̀ lè mẹ́nu ba àwọn àlàyé ọ̀rọ̀ tàbí kí ó lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan lọ́nà tí ìwọ fúnra rẹ kò ronú kàn rí.
Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Lúùkù 8:18 ṣàkópọ̀ irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ dáradára pé: “Ẹ máa fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.” Ní tòótọ́, kíkọ́ láti fiyè sí nǹkan—kí a má ṣe pín ọkàn wa níyà—yóò gba ìsapá àti ìdánrawò. Àmọ́ láìpẹ́, wàá jàǹfààní gidigidi. Kíkọ́ láti pọkàn pọ̀ lè mú kí o túbọ̀ máa ṣe dáradára nílé ìwé, lọ́nà tó sì ṣe pàtàkì jù, o lè máa dàgbà nípa tẹ̀mí!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . N Kò Ṣe Lè Pọkàn Pọ̀?,” nínú ìtẹ̀jáde wa ti July 22, 1998.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Níní ọkàn ìfẹ́ sí ohun tí o gbọ́ jẹ́ kókó pàtàkì kan láti mú ọ pọkàn pọ̀