Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún June
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní June 3
Orin 181
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a ṣà yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn oṣooṣù fún iṣẹ́ ìsìn pápá ti orílẹ̀-èdè lápapọ̀ àti ti ìjọ.
15 min: “Fara Wé Ìgbàgbọ́ Wọn.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàyẹ̀wo àwọn ẹ̀rí ìgbàgbọ́, tí a kárí nínú àpótí tí ó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà, September 15, 1991, ojú ìwé 13. Fọ̀rọ̀ wá akéde kan tàbí méjì lẹ́nu wo láti mọ ohun tí ó ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa ìgbòkègbodò Ìjọba ṣíṣe déédéé mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún.
20 min: “Títan Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun Kálẹ̀.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 3) Kárí ìpínrọ̀ 1. (Fi àlàyé láti inú Ilé-Ìṣọ́nà, January 15, 1996, ojú ìwé 12 àti 13, ìpínrọ̀ 11 àti 12, kún un.) Ṣàlàyé pé a pète ọ̀nà ìgbékalẹ̀ tuntun tí ó wà fún ẹ̀yìn Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa láti ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ múra sílẹ̀ dáradára láti ṣiṣẹ́ lórí ìkésíni àkọ́kọ́. Níwọ̀n bí ó ti sábà máa ń bọ́gbọ́n mu láti ṣe ìpadàbẹ̀wò láàárín ọjọ́ kan tàbí méjì, dípò dídúró pẹ́, a óò jíròrò àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dábàá fún ìkésíni ilé dé ilé àti ti ìpadàbẹ̀wò ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kan náà. Ní ṣókí, ṣàyẹ̀wo ìpínrọ̀ 2 àti 3, tí àṣefihàn ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yóò sì tẹ̀ lé e. A óò kárí àwọn ìgbékalẹ̀ yòókù nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà nínú àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn méjì tí yóò tẹ̀ lé e.
Orin 143 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní June 10
Orin 63
7 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
8 min: Kíkọ́ Àwọn Ọmọ Lẹ́kọ̀ọ́ Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Pápá. Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà. Láti ìgbà ọmọdé, àwọn ọmọ wa gbọ́dọ̀ já fáfá pẹ̀lú wa nínú iṣẹ́ ìsìn. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti ìrírí tí wọ́n bá jèrè yóò pèsè ìpìlẹ̀ lílágbára fún ìgbàgbọ́ àti ìtara wọn ní àwọn ọdún ẹ̀yìnwá ọ̀la. Ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n mọrírì àìní náà láti fi ọwọ́ pàtàkì mu iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí wọ́n sì hùwà lọ́nà yíyẹ. Àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ yẹra fún ìwà jàgídíjàgan; iṣẹ́ ìsìn kì í ṣe àkókò fún eré ṣíṣe. Ó dára jù lọ pé kí wọ́n bá àgbàlagbà ṣiṣẹ́. A gbọ́dọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàjọpín nínú gbígbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú agbára wọn. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà, August 1, 1988, ojú ìwé 15, ìpínrọ̀ 20.) Àwọn òbí ní ẹrù iṣẹ́ láti pèsè àbójútó; wọn kò gbọdọ̀ rán àwọn ọmọ wọn lọ sí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn láìsí àgbàlagbà kan láti bójú tó wọn. Gbóríyìn fún àwọn ọmọ nígbà tí wọ́n bá ṣe dáradára.
10 min: “Títan Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun Kálẹ̀.” (Ìpínrọ̀ 4 àti 5) Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ṣókí, ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ fún ìkésíni àkọ́kọ́ àti ìpadàbẹ̀wò ní ìpínrọ̀ 4 àti 5. Fún àwọn akéde níṣìírí láti padà ṣiṣẹ́ lọ́gán lórí gbogbo ìwé Ìmọ̀ tí wọ́n bá fi sóde.
20 min: “Bí A Óò Ṣe Fi Ìwé Ìmọ̀ Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn.” Sọ ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ ṣókí tí a gbé karí ìpínrọ̀ 1 àti 2. Kárí ìpínrọ̀ 3 sí 11 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàlàyé pé a óò jíròrò èyí tí ó kù nínú àkìbọnú nínú Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní July àti August. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti tọ́jú rẹ̀.
Orin 92 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní June 17
Orin 157
7 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
12 min: “Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ Ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ Lè Dé Inú Ọkàn.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ké sí akéde kan tàbí méjì láti sọ àwọn ìrírí tí ń fúnni níṣìírí, tí ń fi bí wọ́n ṣe rí ìdáhùnpadà rere gbà nígbà tí wọ́n fi ìyọsíni ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ hàn.
13 min: “Títan Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun Kálẹ̀.” (Ìpínrọ̀ 6 sí 7) Tẹnu mọ́ àwọn góńgó fún ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò: Mú ọkàn-ìfẹ́ dàgbà, bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́, ṣètò gúnmọ́ láti padà wá. Lẹ́yìn ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìgbékalẹ̀ tí ó wà ní ìpínrọ̀ 6 àti 7, ní ṣókí jẹ́ kí a ṣàṣefihàn ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ní fífi bí a ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ hàn. Ka ìpínrọ̀ 17 ní ojú ìwé 14 nínú Ilé-Ìṣọ́nà, January 15, 1996.
13 min: “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Rí Ẹni Tí Yóò Fetí Sílẹ̀?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Jẹ́ kí àwọn akéde méjì jíròrò bí wọn yóò ṣe gbìyànjú láti túbọ̀ fi ọ̀yàyà hàn nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ní lílo díẹ̀ lára àwọn àbá tí a fúnni nínú Iwe-Amọna, ojú ìwé 165 sí 167, ìpínrọ̀ 10 sí 21.
Orin 211 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní June 24
Orin 6
7 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. La ètò iṣẹ́ ìsìn pápá fún òpin ọ̀sẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ.
18 min: Àìní àdúgbò. (Tàbí sọ ọ̀rọ̀ àsọyé lórí “Fífi Ọwọ́ Títọ̀nà Mú Ọ̀rọ̀ Òtítọ́,” tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà, January 1, 1996, ojú ìwé 29 sí 31.)
20 min: “Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Láti Ṣiṣẹ́ Sìn Lẹ́ẹ̀kan Sí I.” Ọ̀rọ̀ àsọyé àti ìjíròrò láti ẹnu alàgbà. Dábàá lílo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà, August 1, 1992, “Ẹ Yipada si ọdọ Mi, Emi ó sì Yipada si ọdọ Yin” láti fún àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ níṣìírí. Mẹ́nu ba díẹ̀ lára àwọn kókó pàtàkì.
Orin 71 àti àdúrà ìparí.