ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 9/15 ojú ìwé 26-28
  • Lìdíà—Aláájò Àlejò Olùjọ́sìn Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lìdíà—Aláájò Àlejò Olùjọ́sìn Ọlọ́run
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹni Tí Ń Ta Ohun Aláwọ̀ Àlùkò”
  • Ìwàásù Pọ́ọ̀lù ní Fílípì
  • “Olùjọ́sìn Ọlọ́run”
  • ‘Ó Mú Kí A Wá Ṣáá Ni’
  • Àwọn Ará ní Fílípì
  • Àwòkọ́ṣe—Lìdíà
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • “Sọdá Wá sí Makedóníà”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Bí A Ṣe Lè Ní Ayọ̀
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • ‘Àlàáfíà Ọlọ́run Ta Gbogbo Ìrònú Yọ’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 9/15 ojú ìwé 26-28

Lìdíà—Aláájò Àlejò Olùjọ́sìn Ọlọ́run

ÁTI àkókò ìgbàanì, àwọn ìráńṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ náà ti fi ara wọn hàn yàtọ̀ nítorí aájò àlejò wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 18:1-8; 19:1-3) Bí a ti túmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìfẹ́ fún, ìyọ́nú fún, tàbí inú rere sí àlejò,” aájò àlejò tí ń wá láti inú ọkàn-àyà tòótọ́ jẹ́ àmì ìsìn Kristẹni tòótọ́ lónìí pàápàá. Ní tòótọ́, ó jẹ́ ohun àbéèrèfún fún gbogbo ẹni tí yóò bá jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tí ó tẹ́wọ́ gbà.—Hébérù 13:2; Pétérù Kìíní 4:9.

Ẹnì kan tí ó fi aájò àlejò hàn lọ́nà àwòfiṣàpẹẹrẹ ni Lìdíà. Ó ‘ṣáà mú’ kí àwọn míṣọ́nnárì Kristẹni tí ń ṣèbẹ̀wò sí Fílípì dé sí ilé rẹ̀. (Ìṣe 16:15) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣókí ni a mẹ́nu ba Lìdíà nínú Ìwé Mímọ́, ohun díẹ̀ tí a sọ nípa rẹ̀ lè jẹ́ ìṣírí fún wa. Lọ́nà wo? Ta ni Lìdíà? Kí ni a mọ̀ nípa rẹ̀?

“Ẹni Tí Ń Ta Ohun Aláwọ̀ Àlùkò”

Lìdíà gbé ní Fílípì, olú ìlú Makedóníà. Ṣùgbọ́n, Tíátírà ni ó ti wá, ìlú ńlá kan ní ẹkùn Lìdíà, ní ìwọ̀ oòrùn Éṣíà Kékeré. Fún ìdí yìí, àwọn kan sọ pé “Lìdíà” jẹ́ orúkọ ìnagijẹ tí a fún un ní Fílípì. Lọ́nà míràn, ó jẹ́ “ará Lìdíà,” gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti lè pe obìnrin tí Jésù Kristi jẹ́rìí fún ní “obìnrin ará Samáríà.” (Jòhánù 4:9) Lìdíà ń ta “ohun aláwọ̀ àlùkò” tàbí àwọn ohun èlò tí a pa láró yìí. (Ìṣe 16:12, 14) Àwọn àkọlé tí àwọn awalẹ̀pìtàn wà jáde láti inú ilẹ̀ jẹ́rìí sí i pé àwọn aláró wà ní Tíátírà àti ní Fílípì. Ó lè jẹ́ pé Lìdíà ṣí lọ nítorí iṣẹ́ rẹ̀, yálà láti máa bá iṣẹ́ rẹ̀ nìṣó tàbí gẹ́gẹ́ bí aṣojú ilé iṣẹ́ àwọn aláró ará Tíátírà.

A lè rí aró àlùkò láti inú onírúurú nǹkan. Èyí tí ó wọ́n jù lọ ní a ń mú jáde láti ara irú ìgbín òkun kan. Gẹ́gẹ́ bí akéwì ará Róòmù ọ̀rúndún kìíní, Martial ṣe sọ, ẹ̀wù àwọ̀lékè tí ó ní àwọ̀ àlùkò tí ó dára jù lọ láti Tírè (ọ̀gangan mìíràn tí a ti ń pèsè ohun èlò yìí) lè náni tó 10,000 owó sesterces, tàbí 2,500 dínárì, tí í ṣe iye owó alágbàṣe kan fún 2,500 ọjọ́. Ní kedere, irú ẹ̀wù bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun aláfẹ́ tí ó jẹ́ pé ẹni díẹ̀ ni ó lè ní in. Nítorí náà, Lìdíà ti lè rí towó ṣe. Ohun yòó wù kí ọ̀ràn náà jẹ́, ó ṣeé ṣe fún un láti fi aájò àlejò hàn sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀—Lúùkù, Sílà, Tímótì, àti bóyá, àwọn mìíràn.

Ìwàásù Pọ́ọ̀lù ní Fílípì

Ní nǹkan bí 50 ọdún Sànmánì Tiwa, Pọ́ọ̀lù dé Europe fún ìgbà àkọ́kọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i wàásù ní Fílípì.a Nígbà tí ó bá dé ìlú tuntun kan, ó jẹ́ àṣà Pọ́ọ̀lù láti ṣèbẹ̀wò sí sínágọ́gù láti kọ́kọ́ wàásù fún àwọn Júù àti aláwọ̀ṣe tí wọ́n péjọ síbẹ̀. (Fi wé Ìṣe 13:4, 5, 13, 14; 14:1.) Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti sọ, òfin Róòmù kà á léèwọ̀ fún àwọn Júù láti ṣe ìsìn wọn láàárín “àwọn ibi ìyàsọ́tọ̀ mímọ́” ti Fílípì. Nítorí náà, lẹ́yìn lílo “àwọn ọjọ́ díẹ̀” níbẹ̀, ní ọjọ́ Sábáàtì, àwọn míṣọ́nnárì náà wá ibì kan lẹ́bàá odò kan lẹ́yìn òde ìlú náà níbi ti ‘wọn ronú pé ibi àdúrà wà.’ (Ìṣe 16:12, 13) Dájúdájú, èyí jẹ́ Odò Gangites. Níbẹ̀, àwọn míṣọ́nnárì rí kìkì àwọn obìnrin, tí Lìdíà jẹ́ ọ̀kan lára wọn.

“Olùjọ́sìn Ọlọ́run”

Lìdíà jẹ́ “olùjọ́sìn Ọlọ́run,” ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ aláwọ̀ṣe Ìsìn Àwọn Júù bí ó ti ń wá òtítọ́ ìsìn kiri. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní iṣẹ́ tí ń mówó wọlé, Lìdíà kì í ṣe onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ya àkókò sọ́tọ̀ fún àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí. “Jèhófà . . . ṣí ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ gbayawu láti fiyè sí àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ,” Lìdíà sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Ní tòótọ́, “a batisí òun àti agbo ilé rẹ̀.”—Ìṣe 16:14, 15.

Bíbélì kò dárúkọ àwọn mẹ́ḿbà agbo ilé Lìdíà yòó kù. Níwọ̀n bí a kò ti mẹ́nu ba ọkọ, ó ti lè jẹ́ aláìlọ́kọ tàbí opó. Ó ṣeé ṣe kí “agbo ilé rẹ̀” ní àwọn ìbátan rẹ̀ nínú, ṣùgbọ́n a tún lè lo ọ̀rọ̀ náà fún àwọn ẹrú tàbí ìránṣẹ́. Bí ó ti wù kí ọ̀ràn náà rí, Lìdíà fi ìtara ṣàjọpín àwọn nǹkan tí ó ti kọ́ pẹ̀lú àwọn tí ń bá a gbé. Ẹ sì wo ìdùnnú tí yóò ní nígbà tí wọ́n gbà gbọ́, tí wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ìgbàgbọ́ tòótọ́!

‘Ó Mú Kí A Wá Ṣáá Ni’

Kí wọ́n tó pàdé Lìdíà, bóyá àwọn míṣọ́nnárì náà ti ní láti ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ibùgbé tí wọ́n wá fúnra wọn. Ṣùgbọ́n, ó láyọ̀ láti fún wọn ní ibùgbé mìíràn. Ṣùgbọ́n, òkodoro òtítọ́ náà pé ó ṣáà ń bẹ̀ wọ́n, túmọ̀ sí pé Pọ́ọ̀lù àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kọ́kọ́ kọ̀. Èé ṣe? Pọ́ọ̀lù fẹ́ láti ‘mú ìhìn rere wá láìgba owó, kí ó má baà lo ọlá àṣẹ rẹ̀ nínú ìhìn rere ní ìlòkúlò’ kí ó má baà sì di ẹrù ìnira fún ẹnikẹ́ni. (Kọ́ríńtì Kìíní 9:18; Kọ́ríńtì Kejì 12:14) Ṣùgbọ́n Lúùkù fi kún un pé: “Wàyí o nígbà tí a batisí òun àti agbo ilé rẹ̀, ó wí pẹ̀lú ìpàrọwà pé: ‘Bí ẹ bá kà mí sí olùṣòtítọ́ sí Jèhófà, ẹ wọ inú ilé mi kí ẹ sì dúró níbẹ̀.’ Ó sì mú kí a wá ṣáá ni.” (Ìṣe 16:15) Lìdíà ṣàníyàn jù lọ nípa jíjẹ́ olùṣòtítọ́ sí Jèhófà, ó sì hàn gbangba pé fífi aájò àlejò hàn jẹ́ ẹ̀rí ìgbàgbọ́ rẹ̀. (Fi wé Pétérù Kìíní 4:9.) Ẹ wo àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá tí èyí jẹ́! Àwa pẹ̀lú ha ń lo àwọn ohun ìní wa láti gbé ire ìhìn rere lárugẹ bí?

Àwọn Ará ní Fílípì

Nígbà tí a dá Pọ́ọ̀lù àti Sílà sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó kan ọmọdébìnrin ẹrú, tí ó ní ẹ̀mí èṣù, wọ́n padà sí ilé Lìdíà, níbi tí wọ́n ti rí àwọn ará mélòó kan. (Ìṣe 16:40) Àwọn onígbàgbọ́ tí ó wà nínú ìjọ Fílípì tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ti lè lo ilé Lìdíà gẹ́gẹ́ bí ibi ìpàdé déédéé. Ó bọ́gbọ́n mú láti ronú pé ilé rẹ̀ ń bá a nìṣó láti jẹ́ ibùdó ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run ní ìlú ńlá náà.

Aájò àlejò ọlọ́yàyà tí Lìdíà fi hàn ní ìbẹ̀rẹ̀ fẹ̀rí hàn pé ó jẹ́ àmì ànímọ́ ìjọ lódindi. Láìka ipò òṣì wọn sí, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ará Fílípì fi ohun tí Pọ́ọ̀lù nílò ránṣẹ́ sí i, àpọ́sítélì náà sì fi ìmoore hàn.—Kọ́ríńtì Kejì 8:1, 2; 11:9; Fílípì 4:10, 15, 16.

A kò mẹ́nu kan Lìdíà nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù fi ránṣẹ́ sí àwọn ará Fílípì ní nǹkan bíi 60 ọdún sí ọdún 61 Sànmánì Tiwa. Ìwé Mímọ́ kò sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a sọ ní Ìṣe orí 16. Síbẹ̀síbẹ̀, mímẹ́nu kan akíkanjú obìnrin yìí ní ṣókí mú kí a fẹ́ láti “máa tẹ̀ lé ìlà ipa ọ̀nà aájò àlejò.” (Róòmù 12:13) Ẹ wo bí a ti kún fún ọpẹ́ tó fún níní àwọn Kristẹni gẹ́gẹ́ bí Lìdíà láàárín wa! Ẹ̀mí wọn ṣe bẹbẹ láti mú kí ìjọ tani jí, kí ó sì fani mọ́ra, sí ògo Jèhófà Ọlọ́run.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lára àwọn ìlú tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ní Makedóníà, Fílípì ní ìfiwéra, jẹ́ ìpínlẹ̀ ọlọ́rọ̀, tí ó jẹ́ ti ológun, tí jus italicum (Òfin Ítálì) ń ṣàkóso. Òfin yìí fún àwọn ará Fílípì lẹ́tọ̀ọ́ tí ó jọ ti èyí tí àwọn ará Róòmù ń gbádùn.—Ìṣe 16:9, 12, 21.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]

Ìgbésí Ayé Àwọn Júù ní Fílípì

Ìgbésí ayé ní Fílípì kò rọrùn fún àwọn Júù àti aláwọ̀ṣe nínú Ìsìn Àwọn Júù. Àwọn èrò kan tí ń ta ko ìsìn àwọn Júù ti lè wà, nítorí kété ṣáájú kí Pọ́ọ̀lù tó ṣèbẹ̀wò, Olú Ọba Claudius ti lé àwọn Júù dà nù ní Róòmù.—Fi wé Ìṣe 18:2.

Lọ́nà tí ó pabambarì, a wọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà lọ síwájú àwọn adájọ́ lẹ́yìn mímú ọmọdébìnrin ẹrú náà, tí ó ní ẹ̀mí ìwoṣẹ́ lára dá. Olúwa rẹ̀, tí a fi orísun iṣẹ́ rẹ̀ tí ń mówó wọlé dù nísinsìnyí, lo àǹfààní ẹ̀tanú àwọn ọmọ ilú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nípa fífi ìbínú kéde pé: “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń yọ ìlú ńlá wa lẹ́nu gan-an ni, ní ti pé Júù ni wọ́n, wọ́n sì ń kéde gbangba àwọn àṣà tí kò bófin mu fún wa láti tẹ́wọ́ gbà tàbí láti sọ dàṣà, nítorí pé a jẹ́ ará Róòmù.” Nítorí èyí, a fi ọ̀pá lu Pọ́ọ̀lù àti Sílà, a sì sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. (Ìṣe 16:16-24) Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, jíjọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run àwọn Júù ní gbangba, ń béèrè fún ìgboyà. Ṣùgbọ́n, ẹ̀rí fi hàn pé Lìdíà kò janpata pé òún yàtọ̀.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àwọn àwókù ní Fílípì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́