Ọwọ́ Rẹ Ha Dí Jù Bí?
1 Paul gbà wá níyànjú pé kí a “máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ lati ṣe nígbà gbogbo ninu iṣẹ́ Oluwa.” (1 Kor. 15:58) A rọ̀ wá láti ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ ojoojúmọ́ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, kí a máa nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí a má máa pa ìpàdé jẹ, kí a sì máa bojú tó àwọn iṣẹ́ tí a yàn fún wa nínú ìjọ taápọntaápọn. Ní àfikún sí ìwọ̀nyẹn, a ní láti pèsè ìrànwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ wa. Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe a lè ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, nígbà míràn, ní ríronú pé a ní láti wá ọ̀nà láti dín ẹrù iṣẹ́ wa kù.
2 Àwọn ipò kan wà tí ó lè mú kí ó bọ́gbọ́n mu, kí ó sì lọ́gbọ́n nínú láti gé àwọn ìgbòkègbodò pàtó kan kúrò tàbí kí a dín wọn kù. Àwọn ènìyàn kan máa ń rò pé gbogbo ohun tí àwọn ẹlòmíràn bá fẹ́ kí wọ́n ṣe ló yẹ kí wọ́n ṣe. Àìwàdéédéé lọ́nà yìí lè fa ìkìmọ́lẹ̀ àti ìdààmú ọkàn tí ó lè ṣàkóbá fún ẹnì kan lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
3 Jẹ́ Ẹni Tí Ó Wà Déédéé: Àṣírí wíwà déédéé ń bẹ nínú fífi ìmọ̀ràn Paulu tí ó sọ pé kí á “wádìí dájú awọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” sílò. (Filip. 1:10) Ní ṣókí, ìyẹn túmọ̀ sí pé a ní láti máa pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì ní ti gidi, tí àkókò bá sì yọ̀ǹda, kí a wá bojú tó àwọn ohun mìíràn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Ó dájú pé àwọn ojúṣe ìdílé gba ìpò iwájú nínú àwọn nǹkan tí ó ṣe kókó. A ní láti bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ ti ara kan. Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu kọ́ wa pé a ní láti gbé àwọn ohun tí ó gba ipò iwájú karí ọ̀pá ìdiwọ̀n pé à ń fi Ìjọba náà sí ipò kíní. A gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe àwọn nǹkan tí yóò yọ̀ǹda fún wa láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa sí Jehofa ṣẹ.—Matt. 5:3; 6:33.
4 Tí a bá ní èyí lọ́kàn, a óò rí i dájú pé a gé gbogbo àwọn ìlépa ti ara ẹni tí kò pọn dandan, ìgbòkègbodò eré ìtura àṣejù, àti àwọn àdéhùn aláìníláárí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn kúrò nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa tí ó dí pinpin. Tí a bá ń wéwèé ìgbòkègbodò wa fún ọ̀sẹ̀ kan, a óò ya àkókò tí ó pọ̀ tó sọ́tọ̀ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, ìkópa tí ó bójú mu nínú iṣẹ́ ìsìn, lílọ sí àwọn ìpàdé, àti àwọn nǹkan mìíràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọ́sìn wa. A lè pín àkókò tí ó ṣẹ́kù láti fi ṣe àwọn ohun mìíràn, ní sísinmi lórí bí wọ́n ti ṣe pàtàkì tó nínú jíjẹ́ kí ọwọ́ wa tẹ lájorí góńgó wa tí jíjẹ́ Kristian tí ó wà déédéé, tí ń fi Ìjọba náà sí ipò kíní.
5 Bí a bá tilẹ̀ ṣe gbogbo ìwọ̀nyí, a ṣì lè nímọ̀lára pé ẹrù wa ń wọ̀ wá lọ́rùn. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a ní láti tẹ́wọ́ gba ìkésíni Jesu pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú emi yoo sì tù yín lára.” (Matt. 11:28) Bákan náà, gbẹ́kẹ̀ lé Jehofa, “ẹni tí ń bá wa gbé ẹrù wa lójoojúmọ́” tí ó sì ń fún aláàárẹ̀ ní agbára. Ó ṣèlérí pé òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ olódodo yẹ̀ láé. (Orin Da. 55:22, NW; 68:19; Isa. 40:29) A lè ní ìdánilójú pé yóò dáhùn àdúrà wa, yóò sì mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti tẹra mọ́ ìgbésí ayé aláápọn nínú ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọrun.
6 Bí ó ti dá wa lójú pé ọwọ́ wa yóò máa dí nínú lílépa àwọn ire Ìjọba tí ó níláárí, a lè rí ayọ̀ nínú mímọ̀ pé iṣẹ́ wa kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Oluwa.—1 Kor. 15:58.