ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/96 ojú ìwé 1
  • Bí A Ṣe Lè Ra Àkókò Tí Ó Rọgbọ Padà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí A Ṣe Lè Ra Àkókò Tí Ó Rọgbọ Padà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ríra Àkókò Padà Láti Kàwé Àti Láti Kẹ́kọ̀ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Máa Ṣọ́ Bí O Ṣe Ń Lo Àkókò Rẹ Lójú Méjèèjì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Máa Fọgbọ́n Lo Àkókò Rẹ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà Jẹ́ Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 10/96 ojú ìwé 1

Bí A Ṣe Lè Ra Àkókò Tí Ó Rọgbọ Padà

1 Níní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ń mú ọwọ́ wa dí! (1 Kọr. 15:58) A mọ ìjẹ́pàtàki ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́, àti kíkẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé, kíka Bíbélì lójoojúmọ́, mímúra sílẹ̀ àti lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, àti nínípìn-ín déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Àwọn alábòójútó ní ẹrù iṣẹ́ ṣíṣolùṣọ́ àgùntàn, wọ́n sì ń bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ mìíràn nínú ìjọ. Àwọn kan ní ojúṣe wíwúwo ti ìdílé tàbí onírúurú àìgbọdọ̀máṣe mìíràn sí àwọn ẹlòmíràn. Láti ṣe ohun gbogbo dáradára, gbogbo wá nílò ìwàdéédéé àti ìṣèto ara ẹni tí ó dára.

2 Mọ Àwọn Ohun Àkọ́múṣe: Ṣíṣàṣeyọrí nínú ‘ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara wá’ sinmi lórí agbára ìfòyemọ̀ àti ìdájọ́ rere wa. (Efe. 5:15, 16) A gbọ́dọ̀ pinnu “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù,” kí a sì fi wọ́n ṣe àkọ́kọ́ nínú àwọn ohun àkọ́múṣe wa. (Flp. 1:10) Tọkọtaya kan ṣàpèjúwe agbo ilé wọn tí ń tẹ̀ lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run ní ọ̀nà yìí: “A ń fi òtítọ́ kún inú ìgbésí ayé wa . . . Òtítọ́ kì í wulẹ̀ ṣe apá kan ìgbésí ayé wa, òun gan-an ni ìgbésí ayé wa. Gbogbo ohun yòó kù rọ̀gbà yí i ká.” Fífi ìjọsìn àti iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé ẹní ṣe kókó.

3 Mọ Àwọn Ohun Tí Ń Jẹni Lákòókò: Wákàtí 168 ní ń bẹ nínú ọ̀sẹ̀ kan, ó sì ṣe pàtàkì pé kí á fi ọgbọ́n lo àkókò tí a ní. Láti lè ní àkókò tí ó pọ̀ tó fún àwọn ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run, a ní láti mọ àwọn ohun tí ń jẹni lákòókò, kí a sì dín wọn kù. Ìwádìí kan ṣí i payá pé, àgbàlagbà kan ní United States ń lo ohun tí ó lé ní 30 wákàtí lọ́sẹ̀ fún wíwo tẹlifíṣọ̀n! Fún àwọn mìíràn, wọ́n ń fi ọ̀pọ̀ àkókò ṣòfò ní kíka àwọn ìwé ayé. Àwọn kan lè rí i pé àwọ́n ń ya àkókò tí ó pọ̀ jù sọ́tọ̀ fún fàájì, ìgbòkègbodò àfipawọ́, eré ìnàjú, tàbí eré ìdárayá abẹ́ ilé. Ó lè ṣe pàtàkì pé kí á gbé ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ wa yẹ̀ wò, láti rí bí a ṣe lè lo àkókò wa lọ́nà tí ó túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Ó bọ́gbọ́n mu pé kí a díwọ̀n iye àkókò tí a ń lò fún àwọn ìgbòkègbodò tí kò ṣe pàtàkì.

4 Mú Ọ̀nà Ìgbàṣiṣẹ́ Tí Ó Dára Dàgbà: Ohun yòó wù kí àyíká ipò wá jẹ́, olúkúlùkù wá lè ra àkókò padà fún àwọn ìlépa tẹ̀mí. Àwọn kan ti rí i pé, títètè jí lóròòwúrọ̀ ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àṣeparí ohun púpọ̀. Bí ó bá ń gbà wá lákòókò láti dé ibi iṣẹ́ tàbí láti dúró de àwọn ẹlòmíràn, a lè lò lára àkókò yẹn fún Bíbélì kíkà, fún mímúra àwọn ìpàdé sílẹ̀, tàbí fún fífetí sí àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí Society pèsè sórí káṣẹ́ẹ̀tì. Àwọn ìdílé máa ń jàǹfààní gan-an nípa yíya àkókò pàtó, tí ó ṣe déédéé, sọ́tọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀. Bí mẹ́ḿbà ìdílé kọ̀ọ̀kán bá ń dé lákòókò síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé náà, a kò ní fi àkókò ẹnikẹ́ni ṣòfò.

5 Bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti ń kọjá, ó yẹ kí a túbọ̀ máa rí i dájú sí i pé, “àkókò tí ó ṣẹ́ kù sílẹ̀ ti dín kù.” (1 Kọr. 7:29) Ìgbésí ayé wá sinmi lórí bí a bá ṣe lo àkókò iyebíye tí ó ṣẹ́ kù. A óò bù kún wa bí a bá ra àkókò tí ó rọgbọ padà, kí a baà lè máa bá a lọ láti fi ire Ìjọba ṣe àkọ́kọ́!—Mat. 6:33.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́