Máa Ṣọ́ Bí O Ṣe Ń Lo Àkókò Rẹ Lójú Méjèèjì
1. Ìṣòro wo làwọn ènìyàn níbi gbogbo ń dojú kọ lóde òní?
1 Lóde òní tí àwọn èèyàn ń lo oríṣiríṣi ohun èlò amúṣẹ́yá láti fi dín àkókò àti wàhálà lórí iṣẹ́ wọn kù, ọ̀pọ̀ èèyàn rí i pé iṣẹ́ tó wà níwájú àwọn ń pọ̀ sí i, àkókò ò sì tó láti ṣe wọ́n. Ṣé ó máa ń jẹ́ ìṣòro fún ọ láti máa tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ nípa tẹ̀mí déédéé? Ǹjẹ́ ó máa ń wù ọ́ pé kó o rí àkókò púpọ̀ sí i láti lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́? Báwo la ṣe lè lo àkókò wa lọ́nà tó dára jù?—Sm. 90:12; Fílí. 1:9-11.
2, 3. Ìṣòro wo ló ń jẹ yọ látinú ìtẹ̀síwájú nínú ètò ìbánisọ̀rọ̀, báwo la sì ṣe lè gbé ipò wa yẹ̀ wò lẹ́nìkọ̀ọ̀kan?
2 Mọ Àwọn Nǹkan Tó Ń Fi Àkókò Rẹ Ṣòfò: Lóòrèkóòrè, ó yẹ kí gbogbo wa máa ṣàkíyèsí bá a ṣe ń lo àkókò wa. Bíbélì rọ̀ wá pé: “Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.” (Éfé. 5:15, 16) Ronú lórí ìṣòro tó ń jẹ yọ látinú ìtẹ̀síwájú nínú ètò ìbánisọ̀rọ̀. Lóòótọ́ kọ̀ǹpútà àtàwọn ohun abánáṣiṣẹ́ mìíràn bẹ́ẹ̀ ní ìwúlò tiwọn, síbẹ̀ wọ́n lè di ìdẹkùn fún wa tá ò bá ṣọ́ bá a ṣe ń lo àkókò wa.—1 Kọ́r. 7:29, 31.
3 Ó yẹ kí olúkúlùkù wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé kì í ṣe pé ojoojúmọ́ ni mo máa ń fi àkókò mi ṣòfò lórí kíkà àti dídáhùn àwọn ìranù lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà táwọn kan bá kọ sí mi? Ṣé kì í ṣe pé mo kàn ṣáà máa ń tẹ àwọn èèyàn láago tàbí mo kàn ṣáà máa ń tẹ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí wọn lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù alágbèérìn láti fi máa bá wọn sọ àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì? (1 Tím. 5:13) Ṣé mo kàn ṣáà máa ń ṣí ibi ìkó-ìsọfúnni-sí kiri lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láìnídìí tàbí mo kàn máa ń gbé tẹlifíṣọ̀n láti ìkànnì kan sí èkejì ṣáá? Ṣé eré orí kọ̀ǹpútà tàbí àwọn eré ìdárayá mìíràn bíi lúdò àti bọ́ọ̀lù gbígbá kò ti wá gbà mí lọ́kàn débi pé ó ń gba àkókò tó yẹ kí n fi máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ṣé kò fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ ni mo máa ń lọ sí ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó tàbí àwọn ayẹyẹ mìíràn?’ Fífi gbogbo àkókò wa ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ba ipò tẹ̀mí wa jẹ́ tá ò sì ní fura.—Òwe 12:11.
4. Ìyípadà wo ni ọ̀dọ́ kan ṣe, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?
4 Bá A Ṣe Lè Lo Àkókò Lọ́nà Tó Mọ́gbọ́n Dání: Àwọn ohun abánáṣiṣẹ́ bíi rédíò, tẹlifíṣọ̀n àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, àtàwọn ohun ìdárayá mìíràn máa ń fẹ́ gba àkókò wa àti ìrònú wa. Ọ̀dọ́ kan tí eré orí kọ̀ǹpútà ti gbà lọ́kàn sọ pé: “Nígbà míì tí mo bá ṣe eré orí kọ̀ǹpútà kí n tó lọ sí òde ẹ̀rí tàbí ìpàdé Kristẹni, ó máa ń ṣòro fún mi láti pọkàn pọ̀. Mo máa ń ro bí màá ṣe padà lọ ṣe eré yẹn yanjú tí mo bá délé. Ìdákẹ́kọ̀ọ́ mi kò lọ déédéé mọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni Bíbélì kíkà. Ayọ̀ tí mo ń rí nínú sísin Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù.” Nígbà tó rí i pé ó yẹ kí òun ṣe àwọn ìyípadà nínú ìgbésí ayé òun, ó yọ gbogbo eré orí kọ̀ǹpútà rẹ̀ dà nù. Ó sọ pé: “Ohun tí mo ṣe yẹn kò rọrùn. Àwọn eré yẹn ti gbà mí lọ́kàn kọjá bí mo ṣe rò lọ. Àmọ́ ńṣe ló dà bí ẹni pé mo ja àjàṣẹ́gun kan nítorí mo mọ̀ pé fún àǹfààní ara mi ni ṣíṣe tí mo ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́.”—Mát. 5:29, 30.
5. Báwo la ṣe lè ra àkókò padà láti ṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí, àǹfààní wo la ó sì jẹ tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀?
5 Ó lè pọn dandan pé kí ìwọ náà ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tí o bá rí àwọn apá ibi tó yẹ kó o ti ṣàtúnṣe. Ǹjẹ́ o lè dín ọgbọ̀n ìṣẹ́jú kù lára àkókò tí ò ń lò lójoojúmọ́ lórí àwọn nǹkan tí ò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan? Àkókò tó máa gbà ọ̀ láti ka Bíbélì láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin lọ́dún kò ju ìyẹn náà lọ. Ó dájú pé wàá jàǹfààní nípa tẹ̀mí gan-an tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀! (Sm. 19: 7-11; 119:97-100) Ya àkókò pàtó sọ́tọ̀ fún Bíbélì kíkà, mímúra ìpàdé sílẹ̀ àti jíjáde òde ẹ̀rí. (1 Kọ́r. 15:58) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ kó o lè kápá àwọn nǹkan tó ń fàkókò rẹ ṣòfò yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti “máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.”—Éfé. 5:17.