Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà Jẹ́ Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ
1 Jésù fi àwọn olùgbọ́ rẹ̀ wé oríṣi àwọn kọ́lékọ́lé méjì. Ọ̀kan kọ́ ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ lé orí àpáta ràbàtà ti ṣíṣe ìgbọràn sí Kristi, ó sì ṣeé ṣe fún un láti dúró láìka ìjì àtakò àti ìpọ́njú sí. Ẹnì kejì kọ́ tirẹ̀ sórí iyanrìn àìgbọràn tó kún fún ìmọtara-ẹni-nìkan, kò sì lè dúró nígbà tí pákáǹleke dé. (Mát. 7:24-27) Bí a ṣe ń gbé ní ìparí ètò àwọn nǹkan yìí, ọ̀pọ̀ ìjì ìpọ́njú ló ń bì lù wá. Àwọn ohun bíbanilẹ́rù, tí ń halẹ̀ mọ́ni, tó sì jẹ́ ti ìpọ́njú ńlá ń yára kóra jọ lọ́ọ̀ọ́kán. Ǹjẹ́ àá lè fara dà á dé òpin báyìí, tí ìgbàgbọ́ wa kò sì ní yingin? (Mát. 24:3, 13, 21) Ó sinmi púpọ̀ lórí bí a bá ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa nísinsìnyí. Nítorí náà, ó jẹ́ kánjúkánjú pé kí a bi ara wa léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ iṣẹ́ ìsìn onígbọràn sí Ọlọ́run ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé mi bíi Kristẹni ní gbogbo ọ̀ná bí?’
2 Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ kí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé wa? Ó túmọ̀ sí pé kí a jẹ́ kí Jèhófà jẹ́ àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa. Ó kan dídarí gbogbo àfiyèsí wa sí Ìjọba náà gẹ́gẹ́ bí olórí àníyàn wa. Ó kan ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run nínú gbogbo ìgbòkègbodò ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́. Ó béèrè pé kí a máa fi tọkàntọkàn ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìdílé, kí a sì máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìjọ, ká tún ṣe bẹ́ẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, ká sì máa fi wọ́n ṣe ohun àkọ́múṣe. (Oníw. 12:13; Mát. 6:33) Jíjẹ́ onígbọràn lọ́nà bẹ́ẹ̀ máa ń yọrí sí ìgbàgbọ́ lílágbára bí àpáta, tí kò ní bì wó lójú ìjì ìpọ́njú èyíkéyìí tó bá jà.
3 Inú wa dùn láti rí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí wọ́n ní ìgbọ́kànlé láti fi sísin Ọlọ́run ṣe ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé wọn, tí wọ́n sì ń fi ṣe olórí ìrètí wọn fún ọjọ́ ọ̀la, àní gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe. (Jòh. 4:34) Wọ́n ń tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run lọ́nà tó ṣe déédéé, èyí sì ń yọrí sí ìbùkún ńláǹlà fún wọn. Ìyá kan ṣàlàyé bí òun àti ọkọ rẹ̀ ṣe ṣàṣeyọrí láti tọ́ àwọn ọmọkùnrin wọn méjì dàgbà láti sin Jèhófà, ó wí pé: “A jẹ́ kí òtítọ́ jọba nínú ìgbésí ayé wa—a máa ń lọ sí gbogbo àpéjọpọ̀, a máa ń múra sílẹ̀, a sì máa ń lọ sí àwọn ìpàdé, a tún wá sọ lílọ sóde ẹ̀rí di ohun tí a ń ṣe déédéé nínú ìgbésí ayé wa.” Ọkọ rẹ̀ fi kún un pé: “Kì í ṣe apá kan ìgbésí ayé wa ni òtítọ́ jẹ́, ìgbésí ayé wa gan-an lòtítọ́ jẹ́. Àwọn nǹkan yòókù rọ̀gbà yí i ká ni.” Ǹjẹ́ ìwọ náà fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sí ipò kìíní nínú ìdílé rẹ?
4 Ẹ Ṣètò Gbígbéṣẹ́ fún Ọ̀sẹ̀ Kọ̀ọ̀kan: Ètò ìpàdé márùn-ún lọ́sẹ̀ ni ètò Jèhófà fi ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ lé ọ̀nà tẹ̀mí tó ṣe déédéé. Àwọn Kristẹni tí ń fi ìjọsìn Jèhófà ṣolórí nínú ìgbésí ayé wọn máa ń ṣètò iṣẹ́ wọn àti ọ̀ràn ìdílé wọn lọ́nà kan tí wọn yóò fi lè máa lọ sí gbogbo ìpàdé ṣíṣe kókó wọ̀nyí. Wọn kì í jẹ́ kí àwọn ọ̀ràn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ṣèdíwọ́ fún lílọ sí ìpàdé déédéé.—Fílí. 1:10; Héb. 10:25.
5 Àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú mọ̀ pé bó ti ṣe pàtàkì pé kí a máa jẹun déédéé ní àwọn àkókò kan lóòjọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe pàtàkì pé kí a ṣe ètò gúnmọ́ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti kíkẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé, ká sì tún máa múra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé. (Mát. 4:4) Ǹjẹ́ o lè ya ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tàbí ogún ìṣẹ́jú ó kéré tán, sọ́tọ̀ lóòjọ́ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́? Kókó pàtàkì náà ni pé kí o má ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan míì gba àkókò tí o yà sọ́tọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Sọ ọ́ di àṣà tó wúlò. Èyí lè béèrè pé kí o tètè máa jí lówùúrọ̀ ju bí o ṣe ń jí nísinsìnyí. Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún, tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì jákèjádò ayé máa ń tètè jí lówùúrọ̀ láti jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Dájúdájú, títètè jí ń béèrè pé ká máà pẹ́ púpọ̀ jù ká tó sún lálẹ́ kí ara wa lè yá gágá, kó sì mókun nígbà tí a bá jí lọ́jọ́ kejì.
6 Bí o bá jẹ́ olórí ìdílé, lo ìdánúṣe láti wéwèé, kí o sì ṣe ètò bí ìdílé rẹ yóò ṣe máa lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run. Àwọn ìdílé kan jọ máa ń ka Bíbélì, ìwé Yearbook, tàbí ìtẹ̀jáde mìíràn nígbà tí wọ́n ba ń sinmi lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́. Ọ̀pọ̀ òbí tí àwọn ọmọ wọ́n ti dàgbà di Kristẹni alágbára nípa tẹ̀mí sọ pé ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó mú kí àwọn ṣàṣeyọrí ni àṣà ìdílé àwọn láti ya ìrọ̀lẹ́ kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti jùmọ̀ gbádùn àkókò tí ń gbéni ró nípa tẹ̀mí. Bàbá kan tó ṣe irú ètò bẹ́ẹ̀ sọ pé: “Mo ronú pé ìdàgbàsókè àwọn ọmọ wa nípa tẹ̀mí lápá tó pọ̀ jù lọ jẹ́ nítorí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tí a máa ń ṣe déédéé ní alaalẹ́ ọjọ́ Wednesday, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn.” Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe batisí nígbà tí wọn ò tíì dàgbà púpọ̀, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún níkẹyìn. Ní àfikún sí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, ẹ lè fi àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá tàbí àwọn iṣẹ́ nínú ìpàdé dánra wò, ẹ sì lè jọ gbádùn àwọn ìgbòkègbodò mìíràn tó gbámúṣé.
7 Nínú àwọn ètò rẹ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ǹjẹ́ o ti ‘ra àkókò padà’ fún wíwàásù Ìjọba náà? (Kól. 4:5) Ọwọ́ ọ̀pọ̀ lára wa máa ń dí, a ní ẹrù iṣẹ́ tó jẹ́ ti ìdílé àti ti ìjọ láti bójú tó. Bí a ò bá ṣètò gúnmọ́ láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́ni lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, yóò rọrùn gidigidi fún àwọn nǹkan mìíràn láti ṣèdíwọ́ fún ìgbòkègbodò pàtàkì yìí. Ẹnì kan tó ní oko ńlá kan tó ti ń sin àwọn màlúù wí pé: “Ní nǹkan bí ọdún 1944, mo rí i pé ọ̀nà kan ṣoṣo tí mo fi lè máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn yóò jẹ́ nípa ṣíṣètò ọjọ́ kan pàtó fún un. Títí di òní olónìí, mo ṣì máa ń ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn.” Kristẹni alàgbà kan rí i pé ṣíṣètò gúnmọ́ fún ìjẹ́rìí ń mú kí òún lè ní ìpíndọ́gba wákàtí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lóṣù nínú iṣẹ́ ìwàásù. Bí iṣẹ́ ajé kan bá wà tó yẹ kó bójú tó lọ́jọ́ Saturday, á fi ìyẹn sí ẹ̀yìn ìgbà tó bá ṣe iṣẹ́ ìsìn pápá tán láàárọ̀. Ǹjẹ́ ìwọ àti ìdílé rẹ lè ṣètò ọjọ́ kan lọ́sẹ̀, ó kéré tán, fún iṣẹ́ ìsìn pápá, kí ẹ sì jẹ́ kí èyí jẹ́ apá kan ọ̀nà ìgbésí ayé yín nípa tẹ̀mí?—Fílí. 3:16.
8 Yẹ Ọ̀nà Tí Ò Ń Gbà Gbé Ìgbésí Ayé Rẹ Wò: Àwọn nǹkan wà tó máa ń ṣèdíwọ́ fún mímú kí a fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wa. Àwọn àyíká ipò tí a ò rí tẹ́lẹ̀ lè ṣèdíwọ́ fún ètò tí a ti fara balẹ̀ ṣe fún ìkẹ́kọ̀ọ́, àwọn ìpàdé, àti iṣẹ́ ìsìn. Elénìní wa, Sátánì, yóò sì ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti “dábùú ọ̀nà wa,” kó sì dabarú àwọn ìwéwèé wa. (1 Tẹs. 2:18; Éfé. 6:12, 13) Má ṣe jẹ́ kí àwọn ìdènà wọ̀nyí mú ẹ rẹ̀wẹ̀sì, nítorí èyí a jẹ́ kí o juwọ́ sílẹ̀. Ṣe gbogbo àtúnṣe tó bá pọndandan láti máa tẹ̀ lé ètò ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run tí o ṣe. Ìpinnu àti ìforítì pọndandan láti ṣàṣeparí nǹkan tó tọ́ láti ṣe.
9 A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìdarí ayé àti ipa búburú ti ẹran ara aláìpé wa gbé àwọn ìgbòkègbodò tí kì í ṣe tẹ̀mí lé wa lọ́wọ́ tó lè wá bẹ̀rẹ̀ sí gba púpọ̀ àkókò àti àfiyèsí wa. Ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò ara ẹni, ká bi ara ẹni ní àwọn ìbéèrè bíi: ‘Ǹjẹ́ mo ti di ẹni tí a lè sọ pé ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ kò wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tàbí ẹni tí kò pọkàn pọ̀ mọ́? Ǹjẹ́ mo ti bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn nǹkan ti ayé yìí tí ń kọjá lọ ṣe ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé mi? (1 Jòh. 2:15-17) Báwo ni àkókò tí mo ń lo ti pọ̀ tó, lórí àwọn ìlépa ti ara ẹni, ìrìn àjò afẹ́, ìgbòkègbodò eré ìdárayá, tàbí àwọn eré ìnàjú mìíràn—títí kan wíwo tẹlifíṣọ̀n tàbí ṣíṣàyẹ̀wò Íńtánẹ́ẹ̀tì—bí a bá fi wé àkókò tí mo ń lò lórí àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí?’
10 Bí o bá rí i pé àwọn ìgbòkègbodò tí kò pọndandan túbọ̀ ń gba ìgbésí ayé rẹ, kí ló yẹ kí o ṣe? Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe gbàdúrà pé kí a ‘tọ́’ àwọn arákùnrin òun “sọ́nà padà,” tàbí “kí á mú kí wọ́n wà lójú ìlà yíyẹ,” oò ṣe rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà fún ìrànwọ́ láti tún gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i? (2 Kọ́r. 13:9, 11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, New World Translation Reference Bible) Lẹ́yìn náà, múra tán láti ṣiṣẹ́ lórí ìpinnu rẹ, kí o sì ṣe àwọn ìyípadà pípọndandan. (1 Kọ́r. 9:26, 27) Jèhófà yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún yíyà sí ọ̀tún tàbí sí òsì nínú iṣẹ́ ìsìn onígbọràn sí i.—Fi wé Aísáyà 30:20, 21.
11 Jẹ́ Kí Ọwọ́ Rẹ Máa Dí Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Aláyọ̀ Ti Ọlọ́run: Ọ̀pọ̀ ló ń fi ìgbékútà wá ayọ̀ kiri, wọ́n á sì wá rí i pé bí òpin ìgbésí ayé àwọn ṣe ń sún mọ́, àwọn nǹkan ìní ti ara tí àwọ́n ti fi ìháragàgà lépa kò mú ayọ̀ pípẹ́ títí wá fáwọn. “Lílépa ẹ̀fúùfù” ló jẹ́. (Oníw. 2:11) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, nígbà tí a bá jẹ́ kí Jèhófà jẹ́ pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wa, ‘tí a gbé e sí iwájú wa nígbà gbogbo,’ a máa ń rí ìtẹ́lọ́rùn tó mìnrìngìndìn. (Sm. 16:8, 11) Èyí ń rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé Jèhófà gan-an ló mú kí a wà. (Ìṣí. 4:11) Láìsí Atóbilọ́lá Olùpète yìí, ìgbésí ayé ò ní nítumọ̀. Sísin Jèhófà ń fi ìgbòkègbodò tó gbámúṣé, tó ní ète nínú, tó sì ń ṣe àwa àti àwọn ẹlòmíràn láǹfààní lọ́nà pípẹ́títí kún ìgbésí ayé wa, bẹ́ẹ̀ ni, lọ́nà kan tí kò nípẹ̀kun.
12 Ó ṣe pàtàkì pé ká má ṣe di ẹni tí kò já nǹkan kúnra ká sì wá máa rò pé kò sí kánjúkánjú nínú ọ̀ràn òpin ayé Sátánì tí ń bọ̀ kánkán. Ojú ìwòye tí a ní nípa ọjọ́ ọ̀la ń ní ipa lórí bí a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́. Ní ọjọ́ Nóà, àwọn èèyàn tí kò gbà gbọ́ pé àkúnya omi kárí ayé yóò ṣẹlẹ̀, ‘kò fiyè sí i,’ àwọn ìlépa ti ara ẹni—jíjẹ, mímu, àti gbígbéyàwó—ni wọ́n fi ṣe ohun pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́ títí tí ìkún omi fi “gbá gbogbo wọn lọ.” (Mát. 24:37-39) Lónìí, gbogbo àwọn tó bá fi ayé yìí ṣe ohun pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn yóò rí i tí ohun tí wọ́n ń fojú sọ́nà fún lọ́jọ́ ọ̀la yóò parẹ́ mọ́ wọn lójú nínú ìparun títóbi jù lọ tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn, ìyẹn ni “ọjọ́ Jèhófà.”—2 Pét. 3:10-12.
13 Nígbà náà, máa fi Jèhófà, Ọlọ́run alààyè àti ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ ṣe ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ. Kò sí okòwò tí o lè dá sílẹ̀ ní ìgbésí ayé yìí tó ni Alátìlẹ́yìn tó ṣeé fọkàn tẹ̀ bíi Jèhófà. Kò lè purọ́—yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. (Títù 1:2) Kò lè kú—kò sí ohun tí a bá ṣe sọ́dọ̀ Jèhófà tí yóò ṣègbé. (Háb. 1:12; 2 Tím. 1:12) Ìgbésí ayé onígbọràn àti onígbàgbọ́ tí a ń gbé nísinsìnyí wulẹ̀ jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tí yóò wà títí ayérayé ni, nínú iṣẹ́ ìsìn onídùnnú ti Ọlọ́run wa aláyọ̀!—1 Tím. 1:11; 6:19.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]
“Kì í ṣe apá kan ìgbésí ayé wa ni òtítọ́ jẹ́, ìgbésí ayé wa gan-an lòtítọ́ jẹ́. Àwọn nǹkan yòókù rọ̀gbà yí i ká ni.”