ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/99 ojú ìwé 5-6
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 12/99 ojú ìwé 5-6

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run

Àtúnyẹ̀wò láìṣí ìwé wò fún àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún àwọn ọ̀sẹ̀ September 6 sí December 20, 1999. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.

[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ńbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́ka tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]

Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:

1. Jèhófà fàyè gba pé kí ènìyàn dá ṣàkóso ara rẹ̀ láti lè fi hàn pé ọ̀nà tí Òun ń gbà ṣàkóso tọ̀nà, ó sì jẹ́ òdodo nígbà gbogbo. (Diu. 32:4; Jóòbù 34:10-12; Jer. 10:23) [w97-YR 2/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 3]

2. Bíbélì fi hàn pé gbogbo àròyé ni Ọlọ́run kà léèwọ̀. [w97-YR 12/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 3 àti 4]

3. Àwọn òbí máa ń ní ojú ìwòye yíyẹ nípa ipò ìbátan wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn tó ti ṣègbéyàwó nípa títẹ́wọ́gba ìlànà Ọlọ́run nípa ipò orí àti ètò nǹkan. (Jẹ́n. 2:24; 1 Kọ́r. 11:3; 14:33, 40) [fy-YR ojú ìwé 164 ìpínrọ̀ 6]

4. Máàkù 6:31-34 fi hàn pé àìsàn àti ipò òṣì àwọn èèyàn nìkan ló mú kí Jésù káàánú wọn. [w97-YR 12/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1]

5. Bí Kristẹni kan to jẹ́ ti ẹgbẹ́ àgùntàn mìíràn kò bá lè lọ sí Ìṣe Ìrántí ikú Jésù, ó yẹ kó ṣayẹyẹ rẹ̀ ní oṣù kan lẹ́yìn náà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tó wà ní Númérì 9:10, 11. (Jòh. 10:16) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w93-YR 2/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 9.]

6. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí àgbà tó jẹ́ Kristẹni kì yóò gba ẹrù iṣẹ́ bàbá àti ìyá láti gbin òtítọ́ Bíbélì sínú àwọn ọmọ, àwọn òbí àgbà lè ṣèrànwọ́ wíwúlò nípa fífi kún ìtẹ̀síwájú ọmọ kan nípa tẹ̀mí. (Diu. 6:7; 2 Tím. 1:5; 3:14, 15) [fy-YR ojú ìwé 168 ìpínrọ̀ 15]

7. Òwe 6:30 fi hàn pé a lè fàyè gba olè jíjà tàbí gbà pé ó tọ̀nà lábẹ́ àwọn àyíká ipò kan. [g97-YR 11/8 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 2]

8. Ní ọdún 1530, William Tyndale lẹni àkọ́kọ́ tó lo orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, nínú ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. [w97-YR 9/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 3]

9. Lónìí, ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ jẹ́ ìpèsè tí Ọlọ́run ṣe fún dídáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ikú nítorí rírú òfin ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀. (Núm. 35:11) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 11/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 8.]

10. Diutarónómì jẹ́ àlàyé àwọn kókó kan pàtó nínú Òfin, ó kìlọ̀ lòdì sí ìsìn èké, ó sì gba àwọn èèyàn Ọlọ́run níyànjú láti jẹ́ olóòótọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w84-YR 8/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 2.]

Dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí:

11. Kí ni ìṣù búrẹ́dì méjì tó ní ìwúkàrà tí àlùfáà àgbà fi rúbọ nígbà Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ṣàpẹẹrẹ? (Léf. 23:15-17) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w98-YR 3/1 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 21.]

12. Ìgbà wo ni Júbílì Kristẹni bẹ̀rẹ̀, irú òmìnira wo ló sì mú wá nígbà náà? (Léf. 25:10) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 5/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 14.]

13. Nǹkan mẹ́ta wo ni àkọsílẹ̀ ìwé Númérì tẹnu mọ́? [w84-YR 4/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 1]

14. Ọ̀nà wo ni Mósè gbà jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú fífi hàn pé òun ò lẹ́mìí owú? (Núm. 11:29) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 9/15 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 11.]

15. Báwo ni ọ̀ràn Kórà, Dátánì, àti Ábírámù ṣe fi hàn pé rírí nǹkan sójú ò sọ pé kéèyàn gbà gbọ́? [w97-YR 3/15 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 2]

16. Apá méjì wo tí a ti lè bọlá fún àwọn òbí wa àgbà ni a ṣàlàyé ní Mátíù 15:3-6 àti 1 Tímótì 5:4? [fy-YR ojú ìwé 173 sí 175 ìpínrọ̀ 2 sí 5]

17. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la tẹnu mọ́ ní Númérì 26:64, 65? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo g95-YR 8/8 ojú ìwé 10 àti 11 ìpínrọ̀ 5 sí 8.]

18. Báwo ni àpẹẹrẹ Fíníhásì ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tí ìyàsímímọ́ fún Jèhófà túmọ̀ sí? (Núm. 25:11) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 3/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 12 àti 13.]

19. Báwo lẹnì kan tó wà nínú ìlú ààbò amápẹẹrẹṣẹ ṣe lè “kúrò ní ààlà” ìlú ńlá náà? (Núm. 35:26) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 11/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 20.]

20. Ọ̀nà wo ni Ìwé Àfọwọ́kọ Alábala ti Sinaiticus fi ṣàǹfààní gan-an fún ìtumọ̀ Bíbélì? [w97-YR 10/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 2]

Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ táa nílò láti parí ọ̀kọ̀ọ̀kan gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:

21. Jèhófà fàyè gba ibi láti wà láti lè fìdí òtítọ́ pàtàkì náà múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo pé, òun nìkan ṣoṣo ni __________________________ àti pé, __________________________ sí àwọn òfin òun ṣe pàtàkì kí àlàáfíà àti ayọ̀ tó lè máa wà títí lọ fún gbogbo ìṣẹ̀dá òun. (Sm. 1:1-3; Òwe 3:5, 6; Oníw. 8:9) [w97-YR 2/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 4]

22. Ìwé Léfítíkù tẹ òtítọ́ náà mọ́ wa lọ́kàn pé Ọlọ́run wa ń béèrè __________________________ lọ́dọ̀ àwọn __________________________ rẹ̀. [w84-YR 2/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 9]

23. Ní ìbámu pẹ̀lú Sáàmù 144:15b, ayọ̀ tòótọ́ jẹ́ ipò ọkàn-àyà, tí a gbé karí ojúlówó __________________________ àti __________________________ rere pẹ̀lú Jèhófà. [w97-YR 3/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 7]

24. Bíbélì tó jẹyọ láti inú ìtumọ̀ Bíbélì Lédè Hébérù sí èdè Gíríìkì tí ọ̀pọ̀ ń sọ, èyí tí a parí ní nǹkan bí ọdún 150 ṣááju Sànmánì Tiwa la wá mọ̀ sí __________________________ ; Ìtumọ̀ Bíbélì sí èdè Látìn láti ọwọ́ Jerome la wá mọ̀ sí __________________________ __________________________ tí ìtumọ̀ rẹ̀ parí ní nǹkan bí ọdún 400 Sànmánì Tiwa. [w97-YR 8/15 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1; ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 4]

25. Nípa lílo ìtàn Báláámù àti Kórà bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ nínú ìwé Númérì, Júúdà kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni láti ṣọ́ra fún ìdẹkùn __________________________ àti __________________________. [w84-YR 4/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1 àti 3]

Mú ìdáhùn tó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:

26. Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, ní ọjọ́ tí a ń pè ní (Àjọyọ̀ Àwọn Àtíbàbà; Ọjọ́ Ètùtù; Ìrékọjá), gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, títí kan àwọn àtìpó tí ń jọ́sìn Jèhófà, ní láti (ṣíwọ́ iṣẹ́ gbogbo; san ìdá mẹ́wàá; mú ẹbọ àkọ́so wa) kí wọ́n sì gbààwẹ̀. (Léf. 16:29-31) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w96-YR 7/1 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 12.]

27. Ọ̀kan lára góńgó Ìgbìmọ̀ Ìtumọ̀ Bíbélì Lédè Ayé Tuntun ni láti mú ìtumọ̀ kan jáde tó (jẹ́ ṣangiliti bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó; jẹ́ sísọ èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ lọ́rọ̀ mìíràn; wà ní ìbámu pẹ̀lú òye ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn kan) kí òǹkàwé lè túbọ̀ mọ adùn àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn èrò tí ó so mọ́ ọn. [w97-YR 10/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 5]

28. Ní ìbámu pẹ̀lú Hébérù 13:19, àdúrà tí kò dáwọ́ dúró tí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni bá ń gbà lè mú kí ìyàtọ̀ wà ní ti (ohun tí Ọlọ́run fàyè gbà; ìgbà tí Ọlọ́run yóò gbégbèésẹ̀; ọ̀nà tí Ọlọ́run yóò gbà bójú tó àwọn ọ̀ràn). [w97-YR 4/15 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 1]

29. ‘Okùn tín-ín-rín aláwọ̀ búlúù lókè ìṣẹ́tí apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ’ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ohun tí a béèrè lọ́wọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí (ohun ọ̀ṣọ́ mímọ́; àmì ìwọ̀ntúnwọ̀nsì; ìránnilétí tí wọ́n lè fojú rí pé kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn Jèhófà). (Núm. 15:38, 39) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w84-YR 4/15 ojú ìwé 19 àti 20 ìpínrọ̀ 16.]

30. (Oṣù méjì; ọdún kan; ọdún méjì) ni àkókò tí ìwé Diutarónómì kárí, a sì parí kíkọ rẹ̀ ní ọdún (1513; 1473; 1467) ṣááju Sànmánì Tiwa. [w84-YR 8/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 2]

So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e yìí mọ́ àwọn gbólóhùn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ìsàlẹ̀ yìí:

Núm. 16:41, 49; Mát. 19:9; Lúùkù 2:36-38; Kól. 2:8; 3:14

31. Ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ kì í ṣamọ̀nà sí ipò àkànṣe ìjẹ́mímọ́ kan tàbí ìlàlóye gidi. [g97-YR 10/8 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 4]

32. Àgbèrè ni ìpìlẹ̀ kan ṣoṣo tí Ìwé Mímọ́ fúnni fún ìkọ̀sílẹ̀, pẹ̀lú ṣíṣeé ṣe láti fẹ́ ẹlòmíràn. [fy-YR ojú ìwé 159 ìpínrọ̀ 15]

33. Jíjẹ́ aláápọn nínú ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run, àní ni ọjọ́ ogbó pàápàá, lè ranni lọ́wọ́ láti kojú ikú ọkọ tàbí aya ẹni. [fy-YR ojú ìwé 171 ìpínrọ̀ 21]

34. Ṣíṣàríwísí ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣèdájọ́ òdodo nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ tó yàn sípò lè yọrí sí ìjábá. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w96-YR 6/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 13.]

35. Ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan máa ń so tọkọtaya pọ̀, ó sì ń mú kí wọ́n fẹ́ láti ṣe ohun tó dára jù lọ fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ wọn. [fy-YR ojú ìwé 187 ìpínrọ̀ 11]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́