ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • fy orí 14 ojú ìwé 163-172
  • Dídàgbà Pọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dídàgbà Pọ̀
  • Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ MÚ ARA YÍN BÁ ÒMÌNIRA ÀWỌN ỌMỌ YÍN MU
  • FÍFÚN ÌDÈ ÌGBÉYÀWÓ YÍN LÓKUN LẸ́Ẹ̀KAN SÍ I
  • GBÁDÙN ÀWỌN ỌMỌ-ỌMỌ RẸ
  • YÍWỌ́ PADÀ BÍ O TI Ń DARÚGBÓ
  • KÍKOJÚ ÀDÁNÙ ALÁBÀÁṢÈGBÉYÀWÓ RẸ
  • ỌLỌRUN MỌYÌ WỌN NÍ ỌJỌ́ OGBÓ
  • Ayọ̀ Àti Ìpèníjà Tó Wà Nínú Jíjẹ́—Òbí Àgbà
    Jí!—1999
  • Nígbà Tí Àwọn Òbí Àgbà Bá Tún ń tọ́mọ
    Jí!—1999
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí N Sún Mọ́ Àwọn Òbí Mi Àgbà?
    Jí!—2001
  • Wá Ọjọ́ Ọ̀la Wíwà Pẹ́ Títí fún Ìdílé Rẹ
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
Àwọn Míì
Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
fy orí 14 ojú ìwé 163-172

ORÍ KẸRÌNLÁ

Dídàgbà Pọ̀

1, 2. (a) Àwọn ìyípadà wo ní ń wáyé bí ènìyàn ti ń sún mọ́ ọjọ́ ogbó? (b) Báwo ni àwọn ènìyàn oníwà-bí-Ọlọ́run ní àkókò tí a kọ Bibeli ṣe rí ìtẹ́lọ́rùn ní ọjọ́ ogbó?

Ọ̀PỌ̀ ìyípadà máa ń wáyé bí a ti ń dàgbà. Àìlera ara ń tán wa lókun. Ìrísí ẹni nínú dígí ń fi ìhunjọ àkọ̀tun àti ìyípadà díẹ̀díẹ̀ nínú àwọ̀ irun​—títí kan ìpàdánù irun pàápàá, hàn. A lè di ẹni tí ń tètè gbàgbé nǹkan. A máa ń mú ìbátan tuntun dàgbà nígbà tí àwọn ọmọ bá ṣègbéyàwó, àti nígbà tí a bá ní àwọn ọmọ-ọmọ. Fún àwọn kan, ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ń yọrí sí ìlànà ìṣiṣẹ́ déédéé ojoojúmọ́ tí ó yàtọ̀ nínú ìgbésí ayé.

2 Ní tòótọ́, dídarúgbó jẹ́ àdánwò ńlá. (Oniwasu 12:​1-8) Síbẹ̀, ronú nípa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ní àwọn àkókò tí a kọ Bibeli. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n jèrè ọgbọ́n àti òye, tí ó mú ìtẹ́lọ́rùn ńlá wá fún wọn ní ọjọ́ ogbó. (Genesisi 25:8; 35:29; Jobu 12:12; 42:17) Báwo ni wọ́n ṣe ṣàṣeyọrí nínú dídarúgbó tayọ̀tayọ̀? Dájúdájú, ó jẹ́ nípa gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tí àwa lónìí rí àkọsílẹ̀ wọn nínú Bibeli.​—Orin Dafidi 119:105; 2 Timoteu 3:​16, 17.

3. Ìmọ̀ràn wo ni Paulu fún àwọn àgbà ọkùnrin àti obìnrin?

3 Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí Titu, aposteli Paulu fún àwọn àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí ní ìmọ̀ràn yíyè kooro. Ó kọ̀wé pé: “Kí awọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì ninu àṣà-ìhùwà, oníwà-àgbà, ẹni tí ó yèkooro ní èrò-inú, onílera ninu ìgbàgbọ́, ninu ìfẹ́, ninu ìfaradà. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ kí awọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí ní ọ̀wọ̀ onífọkànsìn ninu ìhùwàsí, kì í ṣe afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n máṣe di ẹrú fún ọ̀pọ̀ ọtí-wáìnì, kí wọ́n jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere.” (Titu 2:2, 3) Kíkọbiara sí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìpènijà dídàgbà.

Ẹ MÚ ARA YÍN BÁ ÒMÌNIRA ÀWỌN ỌMỌ YÍN MU

4, 5. Báwo ni ọ̀pọ̀ òbí ṣe ń hùwà padà nígbà tí àwọn ọmọ wọ́n bá fi ilé sílẹ̀, báwo sì ni àwọn kan ṣe ń mú ara wọn bá ipò tuntun náà mu?

4 Yíyí ẹrù iṣẹ́ padà ń béèrè fún ìmọwọ́ọ́yípadà. Ẹ wo bí èyí ti já sí òtítọ́ tó nígbà tí àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà bá fi ilé sílẹ̀ láti ṣègbéyàwó! Fún ọ̀pọ̀ òbí, èyí jẹ́ ìránnilétí àkọ́kọ́ pé wọ́n ti ń dàgbà. Bí wọ́n tilẹ̀ dunnú pé àwọn ọmọ wọn ti dàgbà, àwọn òbí sábà máa ń ṣàníyàn nípa bóyá wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti múra àwọn ọmọ sílẹ̀ fún wíwà lómìnira. Ojú sì lè máa ro wọ́n.

5 Ó yéni pé àwọn òbí ṣì máa ń ṣàníyàn nípa ire àwọn ọmọ wọn, àní lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ti fi ilé sílẹ̀ pàápàá. Ìyá kan sọ pé: “Bí ó bá kàn tilẹ̀ jẹ́ pé mo ń gbúròó wọn déédéé, láti fọkàn mi balẹ̀ pé gbogbo nǹkan ń lọ déédéé fún wọn​—inú mi ì bá dùn.” Bàbá kan ròyìn pé: “Nígbà tí ọmọbìnrin wa fi ilé sílẹ̀, kò rọrùn fún wa rárá. Ó ṣí àlàfo ńlá sílẹ̀ nínú ìdílé wa, nítorí pé a jọ máa ń ṣe gbogbo nǹkan pọ̀ ni.” Báwo ni àwọn òbí wọ̀nyí ṣe kojú àìsí àwọn ọmọ wọn nílé? Lọ́pọ̀ ọ̀ràn, nípa ṣíṣàníyàn nípa àwọn ẹlòmíràn àti ríràn wọ́n lọ́wọ́.

6. Kí ní ń ṣèrànwọ́ láti pa ipò ìbátan ìdílé mọ́ sí àyè tí ó yẹ ẹ́?

6 Nígbà tí àwọn ọmọ bá ṣègbéyàwó, ẹrù iṣẹ́ àwọn òbí máa ń yí padà. Genesisi 2:24 sọ pé: “Nítorí náà ni ọkùnrin yóò ṣe máa fi bàbá òun ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fi ara mọ́ aya rẹ̀: wọn ó sì di ara kan.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Títẹ́wọ́ gba ìlànà Ọlọrun nípa ipò orí àti ètò nǹkan yóò ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti ní ojú ìwòye yíyẹ nípa àwọn nǹkan.​—1 Korinti 11:3; 14:​33, 40.

7. Ìṣarasíhùwà dídára wo ni bàbá kan mú dàgbà nígbà tí àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ fi ilé sílẹ̀ láti ṣègbéyàwó?

7 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọbìnrin méjèèjì tí tọkọtaya kan ní ṣègbéyàwó, tí wọ́n sì fi ilé sílẹ̀, tọkọtaya náà nímọ̀lára àlàfo ṣíṣí sílẹ̀ nínú ìgbésí ayé wọn. Lákọ̀ọ́kọ́, ọkọ kórìíra àwọn ọkọ àwọn ọmọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, bí ó ti ń ronú lórí ìlànà ipò orí, ó lóye pé àwọn ọkọ àwọn ọmọbìnrin òun ni wọ́n ni ojúṣe bíbójú tó agbo ilé wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Nítorí náà, nígbà tí àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ béèrè ìmọ̀ràn, ó béèrè lọ́wọ́ wọn nípa èrò àwọn ọkọ wọn, ó sì rí i dájú pé òún ti èrò àwọn ọkọ wọn lẹ́yìn bí ó ti lè ṣeé ṣe tó. Nísinsìnyí, àwọn ọkọ àwọn ọmọ rẹ̀ kà á sí ọ̀rẹ́, wọ́n sì ń tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn rẹ̀.

8, 9. Báwo ni àwọn òbí kan ṣe mú ara wọn bá òmìnira àwọn ọmọ wọn tí ó ti dàgbà mu?

8 Bí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé ara wọn níyàwó, bí wọn kò tilẹ̀ ṣe ohun tí ó lòdì sí Ìwé Mímọ́, bá kùnà láti ṣe ohun tí àwọn òbí wọ́n rò pé ó dára jù lọ ńkọ́? Tọkọtaya kan, tí wọ́n ní àwọn ọmọ tí ó ti ṣègbéyàwó, ṣàlàyé pé: “A máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà gbogbo láti mọ ojú ìwòye Jehofa, ṣùgbọ́n bí a kò bá tilẹ̀ fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ìpinnu wọn, a máa ń tẹ́wọ́ gbà á, a sì máa ń tì wọ́n lẹ́yìn, a sì ń fún wọn níṣìírí.”

9 Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Asia, ó máa ń ṣòro gidigidi fún àwọn ìyá kan láti tẹ́wọ́ gba òmìnira àwọn ọmọ wọn ọkùnrin. Bí ó ti wù kí ó rí, bí wọ́n bá bọ̀wọ̀ fún ètò àti ipò orí Kristian, wọ́n máa ń rí i pé gbún-úngbùn-ùngbún pẹ̀lú àwọn ìyàwó àwọn ọmọ wọn máa ń dín kù. Kristian obìnrin kan rí i pé fífi tí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fi ilé sílẹ̀ ti jẹ́ “orísun ìmoore tí ń pọ̀ sí i.” Inú rẹ̀ dùn láti rí ìtóótun wọn láti bójú tó agbo ilé wọn tuntun. Èyí sì ti túmọ̀ sí mímú ẹrù ti ara àti ti èrò orí tí òun àti ọkọ rẹ̀ ní láti gbé bí wọ́n ti ń dàgbà sí i fúyẹ́.

FÍFÚN ÌDÈ ÌGBÉYÀWÓ YÍN LÓKUN LẸ́Ẹ̀KAN SÍ I

10, 11. Ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ wo ni yóò ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti yẹra fún díẹ̀ lára àwọn ọ̀fìn àkókò ìgòkè àgbà?

10 Onírúurú ọ̀nà ni àwọn ènìyàn ń gbà hùwà bí wọ́n ti ń gòkè àgbà. Àwọn ọkùnrin kan máa ń múra yàtọ̀ nínú ìgbìdánwò wọn láti fara hàn bí ọ̀dọ́. Ọ̀pọ̀ obìnrin ń dààmú nípa àwọn ìyípadà tí ìmọ́wọ́dúró nǹkan oṣù ń mú wá. Lọ́nà tí ń bani nínú jẹ́, àwọn kan tí ń gòkè àgbà máa ń mú alábàáṣègbéyàwó wọn bínú tàbí jowú nípa títage pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà kejì tí ó kéré púpọ̀ sí wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọkùnrin àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí, tí wọ́n jẹ́ oníwà-bí-Ọlọ́run, jẹ́ ẹni tí ó “yèkooro ní èrò-inú,” tí ń ki ọwọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bọṣọ. (1 Peteru 4:7) Àwọn obìnrin adàgbàdénú pẹ̀lú ń ṣiṣẹ́ kára láti pa ìdúróṣinṣin ìgbéyàwó wọn mọ́, nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ọkọ wọn àti ìfẹ́ láti wu Jehofa.

11 Lábẹ́ ìmísí, Ọba Lemueli ṣàkọsílẹ̀ ìyìn fún “obìnrin oníwà rere,” tí ó san ẹ̀san “rere” fún ọkọ rẹ̀ “kì í ṣe búburú ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Kristian ọkọ kan kò ní kùnà láti mọyì bí aya rẹ̀ ṣe ń làkàkà láti kojú àwọn ìdààmú èrò ìmọ̀lára èyíkéyìí tí ó ń nírìírí rẹ̀ bí ó ti ń gòkè àgbà. Ìfẹ́ rẹ̀ yóò sún un láti “fi ìyìn fún un.”​—Owe 31:​10, 12, 28.

12. Báwo ni tọkọtaya ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí bí ogbó ṣe ń dé?

12 Ní àwọn ọdún títọ́ ọmọ, tí ọwọ́ há gádígádí, ẹ̀yin méjèèjì lè ti fi tayọ̀tayọ̀ pa lílépa àwọn ohun tí ẹ fọkàn fẹ́ tì láti bójú tó àwọn àìní àwọn ọmọ yín. Nísinsìnyí tí wọ́n ti fi ilé sílẹ̀, ó ti tó àkókò láti yí ìgbésí ayé ìgbéyàwó yín padà. Ọkọ kan sọ pé: “Nígbà tí àwọn ọmọbìnrin mi fi ilé sílẹ̀, mo tún aya mi gbé.” Ọkọ mìíràn sọ pé: “A mójú tó ìlera ara wa lẹ́nì kíní-kejì, a sì ń rán ara wa létí àǹfààní eré ìmárale.” Nítorí kí wọ́n má baà nímọ̀lára ìdánìkanwà, òun àti aya rẹ̀ fi aájò àlejò hàn fún àwọn mẹ́ḿbà yòókù nínú ìjọ. Bẹ́ẹ̀ ni, fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn ń mú ìbùkún wá. Síwájú sí i, ó dùn mọ́ Jehofa nínú.​—Filippi 2:4; Heberu 13:​2, 16.

13. Ipa wo ni òtítọ́ inú àti àìlábòsí ń kó bí tọkọtaya kan ti ń dàgbà pọ̀?

13 Má ṣe jẹ́ kí àlàfo wà nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ láàárín ìwọ àti alábàáṣègbéyàwó rẹ. Ẹ tú inú yín jáde fún ara yín. (Owe 17:27) Ọkọ kan sọ pé: “A túbọ̀ ń lóye ara wa sí i nípa ṣíṣe aájò ara wa lẹ́nì kíní-kejì àti nípa gbígba ti ara wa rò.” Aya rẹ̀ gbà pẹ̀lú rẹ̀, ní sísọ pé: “Bí a ti ń dàgbà sí i, a ti wá gbádùn mímu tíì pa pọ̀, jíjíròrò, àti fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wa.” Jíjẹ́ olótìítọ́ inú àti aláìlábòsí lè ṣèrànwọ́ láti mú ìdè ìgbéyàwó yín lókun sí i, ní fífún un ní agbára láti dojú àtakò Satani, olùba ìgbéyàwó jẹ́, bolẹ̀.

GBÁDÙN ÀWỌN ỌMỌ-ỌMỌ RẸ

14. Ipa ṣíṣe kedere wo ni ìyá-ìyá Timoteu kó nínú ìdàgbàsókè Timoteu gẹ́gẹ́ bíi Kristian kan?

14 Àwọn ọmọ-ọmọ jẹ́ “adé” àwọn àgbàlagbà. (Owe 17:6) Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ àwọn ọmọ-ọmọ lè gbádùn mọ́ni gidigidi​—kí ó múni lórí yá, kí ó sì tuni lára. Bibeli sọ̀rọ̀ dáradára nípa Loide, ìyá àgbà kan tí òun àti ọmọbìnrin rẹ̀, Eunike, ṣàjọpín ìgbàgbọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ọmọ rẹ̀ jòjòló, Timoteu. Ọmọdé yìí dàgbà pẹ̀lú ìmọ̀ náà pé ìyá rẹ̀ àti ìyá-ìyá rẹ̀ ka òtítọ́ Bibeli sí pàtàkì.​—2 Timoteu 1:5; 3:14, 15.

15. Ní ti àwọn ọmọ-ọmọ, ipa ṣíṣeyebíye wo ni àwọn òbí àgbà lè kó, ṣùgbọ́n kí ni wọ́n ní láti yẹra fún?

15 Nígbà náà, níhìn-ín ni ibi tí àwọn òbí àgbà ti lè kópa tí ó ga lọ́lá. Ẹ̀yin òbí àgbà, ẹ ti ṣàjọpín ìmọ̀ yín nípa àwọn ète Jehofa pẹ̀lú àwọn ọmọ yín. Ẹ lè ṣe bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí pẹ̀lú ìran mìíràn! Inú ọ̀pọ̀ ọmọdé máa ń dùn láti gbọ́ àwọn ìtàn Bibeli lẹ́nu àwọn òbí wọn àgbà. Dájúdájú, ìwọ kò gba ẹrù iṣẹ́ tí bàbá ní láti gbin òtítọ́ Bibeli sínú àwọn ọmọ rẹ̀ mọ́ ọn lọ́wọ́. (Deuteronomi 6:7) Kàkà bẹ́ẹ̀, o ń ṣe kún un. Ǹjẹ́ kí àdúrà rẹ jẹ́ ti onipsalmu pé: “Nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo hewú, Ọlọrun má ṣe kọ̀ mí; títí èmi óò fi fi ipá rẹ hàn fún ìran yìí, àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn ará ẹ̀yìn.”​—Orin Dafidi 71:18; 78:​5, 6.

16. Báwo ni àwọn òbí àgbà ṣe lè yẹra fún jíjẹ́ okùnfà aáwọ̀ tí ń jẹ yọ nínú ìdílé wọn?

16 Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn òbí àgbà kan máa ń kẹ́ àwọn ọmọdé bà jẹ́, débi pé pákáǹleke ń dìde láàárín àwọn òbí àgbà náà àti àwọn ọmọ wọn tí ó ti dàgbà. Àmọ́ ṣáá o, inú rere àtọkànwá rẹ lè mú kí ó rọrùn fún àwọn ọmọ-ọmọ rẹ láti finú hàn ọ́, nígbà tí wọn kò bá nítẹ̀sí láti ṣí àwọn ọ̀ràn payá fún àwọn òbí wọn. Nígbà míràn, àwọn ọmọdé máa ń retí pé àwọn òbí wọn àgbà, tí ó gbọ̀jẹ̀gẹ́, yóò gbè sẹ́yìn wọn lòdì sí àwọn òbí wọn. Kí ni ó yẹ kí o ṣe? Lo ọgbọ́n, kí o sì fún àwọn ọmọ-ọmọ rẹ níṣìírí láti tú ọkàn wọn jáde fún àwọn òbí wọn. O lè ṣàlàyé pé èyí ń dùn mọ́ Jehofa nínú. (Efesu 6:​1-3) Bí ó bá pọn dandan, o lè fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ọmọdé náà nípa bíbá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀. Má fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ fún àwọn ọmọ-ọmọ rẹ nípa àwọn ohun tí o ti kọ́ láti àwọn ọdún yìí wá. Ìwà àìlábòsí àti òtítọ́ inú rẹ lè ṣàǹfààní fún wọn.

YÍWỌ́ PADÀ BÍ O TI Ń DARÚGBÓ

17. Irú ìpinnu tí onipsalmu ṣe wo ni ó yẹ kí àwọn Kristian àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí ṣe?

17 Bí o ti ń dàgbà sí i, ìwọ yóò rí i pé o kò lè ṣe gbogbo ohun tí o máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ tàbí gbogbo ohun tí o fẹ́ láti ṣe. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè ko dídarúgbó lójú? Nínú èrò inú rẹ, o lè rò pé ọmọ 30 ọdún ni ọ́, ṣùgbọ́n ìrísí rẹ lójú dígí ń fi hàn kedere pé o dàgbà ju ìyẹn lọ fíìfíì. Ma ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Onipsalmu náà rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jehofa pé: “Má ṣe ṣá mi tì nígbà ogbó; má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí agbára mi bá yẹ̀.” Pinnu láti ṣe irú ìpinnu kan náà tí onipsalmu ṣe. Ó sọ pé: “Èmi óò máa retí nígbà gbogbo, èmi óò sì máa fi ìyìn kún ìyìn rẹ.”​—Orin Dafidi 71:9, 14.

18. Báwo ni Kristian tí ó dàgbà dénú kan ṣe lè lo àkókò ìfẹ̀yìntì rẹ̀ lọ́nà tí ó ṣeyebíye?

18 Ọ̀pọ̀ ti múra sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú láti fi kún ìyìn wọn sí Jehofa lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́. Bàbá kan, tí ó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, sọ pé: “Mo wéwèé ṣáájú nípa ohun tí n óò ṣe nígbà tí ọmọbìnrin wa bá parí ẹ̀kọ́ rẹ̀. Mo pinnu pé n óò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún, mo sì ta òwò mi kí n lè lómìnira láti sin Jehofa ní kíkún sí i. Mo gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Ọlọrun.” Bí o bá ti ń sún mọ́ ọdún tí ìwọ yóò fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, rí ìtùnú nínú ìpolongo Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa pé: “Àní títí dé ogbó Èmi náà ni; àní títí dé ewú ni èmi óò rù yín.”​—Isaiah 46:4.

19. Ìmọ̀ràn wo ni a fún àwọn tí ń darúgbó?

19 Mímú ara ẹni bá ipò ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ mu lè má rọrùn. Aposteli Paulu gba àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí nímọ̀ràn láti jẹ́ “oníwọ̀ntúnwọ̀nsì ninu àṣà-ìhùwà.” Èyí ń béèrè fún ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ohun gbogbo, láìjuwọ́sílẹ̀ fún ìtẹ̀sí wíwá ìgbésí ayé gbẹ̀fẹ́. Àìní tí ó túbọ̀ ga lè wà fún ìlànà ìṣiṣẹ́ déédéé ojoojúmọ́ àti ìbára-ẹni-wí lẹ́yìn ìfẹ̀yìntì ju ṣáájú rẹ̀ lọ. Nígbà náà, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí, ‘kí o máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ lati ṣe nígbà gbogbo ninu iṣẹ́ Oluwa, ní mímọ̀ pé òpò rẹ kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹlu Oluwa.’ (1 Korinti 15:58) Mú ìgbòkègbodò rẹ gbòòrò síwájú sí i láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. (2 Korinti 6:13) Ọ̀pọ̀ Kristian ń ṣe èyí nípa fífi tìtaratìtara wàásù ìhìn rere bí agbára ọjọ́ ogbó wọn ti yọ̀ǹda fún wọn tó. Bí o ti ń dàgbà sí i, jẹ́ “onílera ninu ìgbàgbọ́, ninu ìfẹ́, ninu ìfaradà.”​—Titu 2:2.

KÍKOJÚ ÀDÁNÙ ALÁBÀÁṢÈGBÉYÀWÓ RẸ

20, 21. (a) Nínú ètò ìgbékalẹ̀ nǹkan ìsinsìnyí, kí ni yóò pín tọkọtaya níyà nígbẹ̀yìngbẹ́yín? (b) Báwo ni Anna ṣe pèsè àpẹẹrẹ dídára fún àwọn alábàáṣègbéyàwó tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀?

20 Ó ń bani nínú jẹ́, ṣùgbọ́n òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro ni pé, nínú ètò ìgbékalẹ̀ nǹkan ìsinsìnyí, ikú ń pín àwọn tọkọtaya níyà, nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Àwọn Kristian tí wọ́n pàdánù alábàáṣègbéyàwó wọ́n mọ̀ pé àwọn olólùfẹ́ wọn ń sùn, wọ́n sì ní ìdánilójú pé wọn yóò padà rí wọn. (Johannu 11:​11, 25) Ṣùgbọ́n àdánù náà ń múni kẹ́dùn síbẹ̀. Báwo ni ẹni náà tí ó kù lẹ́yìn ṣe lè kojú rẹ̀?a

21 Rírántí ohun tí ẹnì kan nínú Bibeli ṣe yóò ṣàǹfààní. Anna di opó lẹ́yìn ọdún méje péré tí ó wọlé ọkọ, ó sì ti pé ọmọ ọdún 84 nígbà tí a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. A lè ní ìdánilójú pé ó kẹ́dùn nígbà tí ó pàdánù ọkọ rẹ̀. Báwo ni ó ṣe kojú rẹ̀? Ó ń ṣiṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ sí Jehofa Ọlọrun nínú tẹ́ḿpìlì, tọ̀sán-tòru. (Luku 2:​36-38) Láìsí àníàní, ìgbé ayé iṣẹ́ ìsìn Anna, tí ó kún fún àdúrà, jẹ́ egbòogi fún ìbànújẹ́ àti ìdánìkanwà tí ó mọ̀ lára gẹ́gẹ́ bí opó kan.

22. Báwo ni àwọn opó kan ṣe kojú ìdánìkanwà?

22 Obìnrin ọlọ́dún 72, tí ó di opó ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ṣàlàyé pé: “Ìpèníjà gíga jù lọ fún mi jẹ́ àìní ẹnì kejì láti bá sọ̀rọ̀. Ọkọ mi mọ bí a ti ń fetí sílẹ̀. A máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìjọ àti ìpín wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian.” Opó mìíràn sọ pé: “Bí àkókò tilẹ̀ ń woni sàn, mo ti rí i pé ó túbọ̀ pé pérépéré láti sọ pé, ohun tí ènìyàn fi àkókò rẹ̀ ṣe ní ń ran ènìyàn lọ́wọ́ láti sàn. O wà ní ipò tí ó túbọ̀ dára láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.” Opó ọlọ́dún 67 kan gbà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí, ní sísọ pé: “Ọ̀nà dídára kan láti gbà kojú ọ̀fọ̀ jẹ́ láti fí ara rẹ fún àwọn ẹlòmíràn ní títù wọ́n nínú.”

ỌLỌRUN MỌYÌ WỌN NÍ ỌJỌ́ OGBÓ

23, 24. Ìtùnú ńlá wo ni Bibeli fún àwọn arúgbó, pàápàá àwọn opó?

23 Bí ikú tilẹ̀ mú alábàáṣègbéyàwó ààyò olùfẹ́ ẹni lọ, Jehofa jẹ́ adúrótini tí ó dájú. Ọba Dafidi ìgbàanì sọ pé: “Ohun kan ni èmi ń tọrọ ní ọ̀dọ̀ Oluwa, òun náà ni èmi óò máa wá kiri: kí èmi kí ó lè máa gbé inú ilé Oluwa ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi kí ó lè máa wo ẹwà Oluwa, kí èmi kí ó sì máa fi inú dídùn wo tẹ́ḿpìlì rẹ̀.”​—Orin Dafidi 27:4.

24 Aposteli Paulu rọni pé: “Bọlá fún awọn opó tí wọ́n jẹ́ opó níti gàsíkíá.” (1 Timoteu 5:3) Ìmọ̀ràn tí ó tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí, fi hàn pé àwọn opó yíyẹ, tí kò ní àwọn mọ̀lẹ́bí tí ó sún mọ́ wọn, lè ti nílò ìtìlẹ́yìn nípa ti ara láti ọ̀dọ̀ ìjọ. Bí ó ti wù kí ó rí, èrò tí ó wà nídìí ìtọ́ni náà láti “bọlá fún” ní èrò mímọyì wọn nínú. Ẹ wo irú ìtùnú tí àwọn opó lè rí gbà láti inú mímọ̀ pé Jehofa mọyì wọn, yóò sì tì wọ́n lẹ́yìn!​—Jakọbu 1:27.

25. Góńgó wo ni ó ṣì wà fún àwọn arúgbó?

25 Ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun mí sí polongo pé: “Ẹwà àwọn arúgbó ni ewú.” Ó jẹ́ ‘adé ògo, bí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.’ (Owe 16:31; 20:29) Nígbà náà, yálà alábàáṣègbéyàwó rẹ ṣì wà láàyè tàbí o ti padà sí ipò àpọ́n, máa bá a nìṣó láti fi iṣẹ́ ìsìn Jehofa ṣe àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ. Ìwọ yóò tipa báyìí ṣe orúkọ rere pẹ̀lú Ọlọrun nísinsìnyí, ìwọ yóò sì ní ìrètí ìyè ayérayé nínú ayé kan tí ìrora ọjọ́ ogbó kì yóò ti sí mọ́.​—Orin Dafidi 37:​3-5; Isaiah 65:20.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a  Fún ìjíròrò kíkún lórí kókó ẹ̀kọ́ yìí, wo ìwé pẹlẹbẹ náà, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN . . . TỌKỌTAYA BÍ WỌ́N TI Ń DARÚGBÓ?

Àwọn ọmọ-ọmọ jẹ́ “adé” àwọn arúgbó.​—Owe 17:6.

Ọjọ́ ogbó lè mú àfikún àǹfààní wá láti sin Jehofa.​—Orin Dafidi 71:​9, 14.

A rọ àwọn àgbàlagbà ọlọ́jọ́lórí láti jẹ́ “oníwọ̀ntúnwọ̀nsì ninu àṣà-ìhùwà.”​—Titu 2:2.

Bí àwọn tí ó pàdánù alábàáṣègbéyàwó wọn tilẹ̀ ń kẹ́dùn, wọ́n lè rí ìtùnú nínú Bibeli.​—Johannu 11:​11, 25.

Jehofa mọyì àwọn arúgbó tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́.—Owe 16:31.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 166]

Bí ẹ ti ń dàgbà, ẹ mú ìfẹ́ tí ẹ ni fún ara yín dá ara yín lójú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́