Ìgbà Tí Ìyà Kò Ní Sí Mọ́
ÌYÀ kì í ṣe apá kan ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún ìdílé ẹ̀dá ènìyàn. Òun kò pète rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò fẹ́ ẹ. Ìwọ lè béèrè pé: ‘Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni ó ṣe bẹ̀rẹ̀, èé sì ti ṣe tí Ọlọ́run fi fàyè gbà á láti máa bá a nìṣó títí di ìsinsìnyí?’—Fi wé Jákọ́bù 1:13.
Ìdáhùn náà ń bẹ nínú àkọsílẹ̀ tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ nínú ìtàn ènìyàn, Bíbélì, ní pàtàkì, ìwé Jẹ́nẹ́sísì. Ó sọ pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, tẹ̀ lé Sátánì Èṣù nínú ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run. Àwọn ìgbésẹ̀ wọn gbé àwọn àríyànjiyàn pàtàkì dìde tí ó kọlu ìpìlẹ̀ òfin àti àṣẹ àgbáyé gan-an. Nígbà tí wọ́n jà fún ẹ̀tọ́ láti pinnu ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ fúnra wọn, wọ́n pe ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run níjà. Wọ́n gbé ìbéèrè dìde sí ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti ṣàkóso àti láti jẹ́ onídàájọ́ kan ṣoṣo fún ohun “rere àti búburú.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17; 3:1-5.
Èé Ṣe Tí Kò Fi Mú Ìfẹ́ Inú Rẹ̀ Ṣẹ Lójú Ẹsẹ̀?
Ìwọ lè béèrè pé: ‘Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, èé ṣe tí Ọlọ́run kò fi mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ lójú ẹsẹ̀?’ Lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀ràn náà dà bí èyí tí ó rọrùn. Wọ́n wí pé: ‘Ọlọ́run ní agbára. Ó yẹ kí ó ti lò ó láti pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà run.’ (Orin Dáfídì 147:5) Ṣùgbọ́n, béèrè èyí lọ́wọ́ ara rẹ, ‘Èmi ha máa ń kan sáárá sí gbogbo àwọn tí ń lo agbára gíga lọ́lá wọn láti mú ìfẹ́ inú wọn ṣẹ, láìlọ́tìkọ̀ bí? Lọ́nà àdánidá, èmi kì í ha ń nímọ̀lára ìkórìíra pátápátá nígbà tí aláṣẹ bóo fẹ́ bóo kọ̀ kan bá lo àwọn ọmọ ogun panipani rẹ̀ láti pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run bí?’ Ọ̀pọ̀ ènìyàn onílàákàyè máa ń kórìíra irú ìwà bẹ́ẹ̀.
Ìwọ sọ pé: ‘Ẹẹh-ẹn, ṣùgbọ́n bí Ọlọ́run bá lo agbára yẹn, kò sí ẹni tí yóò gbé ìbéèrè dìde sí ìgbésẹ̀ rẹ̀.’ Ó ha dá ọ lójú bí? Kì í ha ń ṣe òtítọ́ pé àwọn ènìyàn máa ń gbé ìbéèrè dìde sí bí Ọlọ́run ṣe ń lo agbára rẹ̀? Wọ́n ń gbé ìbéèrè dìde sí ìdí tí òun kò fi lò ó ní àwọn ìgbà míràn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ri ní ti àyè tí ó fi gba ibi. Wọ́n sì ń gbé ìbéèrè dìde sí ìdí tí òun fi lò ó ní àwọn ìgbà míràn. Àní Ábúráhámù olùṣòtítọ́ pàápàá ní ìṣòro pẹ̀lú bí Ọlọ́run ṣe ń lo agbára rẹ̀ ní ìlòdìsí àwọn ọ̀tá Rẹ̀. Rántí ìgbà tí Ọlọ́run pinnu láti pa Sódómù run. Ábúráhámù bẹ̀rù lọ́nà tí ó lòdì pé, àwọn ènìyàn rere yóò kú pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú. Ó ké rara pé: “Ó dàri, tí ìwọ óò fi ṣe bí irú èyí, láti run olódodo pẹ̀lú ènìyàn búburú.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:25) Àní àwọn ènìyàn olóòótọ́ ọkàn bí Ábúráhámù pàápàá nílò ìdálójú pé a kò ní ṣi agbára tí kò láàlà lò.
Dájúdájú, Ọlọ́run lè pa Ádámù, Éfà, àti Sátánì run lọ́gán. Ṣùgbọ́n ronú nípa bí ìyẹn yóò ṣe nípa lórí àwọn áńgẹ́lì yòó kù tàbí àwọn ẹ̀dá ọjọ́ ọ̀la, tí wọ́n lè wá mọ̀ nípa ìgbésẹ̀ rẹ̀. Èyí kò ha lè mú kí wọn ní àwọn ìbéèrè amúnibínú lọ́kàn nípa ẹ̀tọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run? Èyí kò ha ní fi Ọlọ́run hàn pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn tí a fi kàn án, pé ní tòótọ́, òun jẹ́ aláṣẹ oníkùmọ̀, òṣìkà olùṣàkóso, gẹ́gẹ́ bí Nietzsche ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀, Ọlọ́run kan tí ń fi àìláàánú pa ẹnikẹ́ni tí ó bá ta kò ó run?
Èé Ṣe Tí Kò Fi Mú Kí Àwọn Ènìyàn Ṣe Ohun Tí Ó Tọ́?
Àwọn kan lè béèrè pé: ‘Ọlọ́run kò ha lè mú kí àwọn ènìyàn ṣe ohun tí ó tọ́ bí?’ Tóò, ronú nípa èyí pẹ̀lú. Jálẹ̀ ìtàn, àwọn ìjọba ti gbìyànjú láti mú kí àwọn ènìyàn tẹ̀ lé ọ̀nà ìrònú wọn. Àwọn ìjọba kan tàbí olùṣàkóso kan ti ṣe onírúurú ọ̀nà ìfọgbọ́ndarí ìrònú, bóyá nípa lílo egbòogi tàbí iṣẹ́ abẹ, ní fífi ẹ̀bùn àgbàyanu ti òmìnira ìfẹ́ inú du àwọn tí wọ́n fìyà jẹ. Àwa kò ha ṣìkẹ́ jíjẹ́ ẹ̀dá olómìnira ìwà híhù, kódà bí ẹ̀bùn yẹn tilẹ̀ jẹ́ èyí tí a lè ṣì lò bí? Àwa ha gbà kí ìjọba tàbí olùṣàkóso èyíkéyìí gbìyànjú láti gba ìyẹn lọ́wọ́ wa bí?
Bí Ọlọ́run kò bá fẹ́ lo agbára rẹ̀ láti mú òfin ṣẹ, kí ni ohun mìíràn tí ó lè ṣe? Jèhófà Ọlọ́run pinnu pé, ọ̀nà dídára jù lọ láti kojú ìṣọ̀tẹ̀ náà ni láti yọ̀ǹda sáà díẹ̀ fún àwọn tí wọ́n kọ òfin rẹ̀ láti wà lómìnira kúrò lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀. Èyí yóò yọ̀ǹda fún ìdílé ẹ̀dá ènìyàn, tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ádámù àti Éfà, láti ní àkókò kúkúrú tí wọn yóò fi ṣàkóso ara wọn láìjẹ́ pé wọ́n wà lábẹ́ òfin Ọlọ́run. Èé ṣe tí ó fi ṣe èyí? Nítorí pé, ó mọ̀ pé láìpẹ́, ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro yóò kóra jọ, ní jíjẹ́rìí sí i pé ọ̀nà ìṣàkóso rẹ̀ fìgbà gbogbo tọ̀nà, ó sì jẹ́ òdodo, àní nígbà tí ó bá lo agbára rẹ̀ tí kò láàlà pàápàá láti mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ, àti pé, bó pẹ́ bó yá, àjálù ni ìṣọ̀tẹ̀ èyíkéyìí sí i yóò yọrí sí.—Diutarónómì 32:4; Jóòbù 34:10-12; Jeremáyà 10:23.
Gbogbo Àwọn Òjìyà Tí Wọn Kò Mọwọ́ Mẹsẹ̀ Ńkọ́?
Ìwọ lè béèrè pé: ‘Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn òjìyà tí wọn kò mọwọ́ mẹsẹ̀ ńkọ́?’ ‘Fífẹ̀rí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan ní ti òfin hàn ha tó ohun tí wọ́n ń jẹ̀rora lé lórí bí?’ Tóò, Ọlọ́run kò fàyè gba ibi kìkì láti lè fẹ̀rí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan tí ó díjú ní ti òfin hàn. Ní òdì kejì pátápátá, ó jẹ́ láti fìdí òtítọ́ pàtàkì náà múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo pé, òun nìkan ṣoṣo ni ọba aláṣẹ àti pé, ṣíṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀ ṣe kókó fún àlàáfíà tí ń bá a nìṣó àti ayọ̀ fún gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀.
Ohun pàtàkì kan tí a ní láti fi sọ́kàn ni pé, Ọlọ́run mọ̀ pé òun lè mú ìpalára èyíkéyìí tí èyí lè mú wá bá ìdílé ẹ̀dá ènìyàn kúrò. Ó mọ̀ pé ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àtúbọ̀tán ìrora àti ìyà yóò ṣeni láǹfààní. Ronú nípa ìyá tí ó wa ọmọ rẹ̀ mọ́ra pinpin bí dókítà ṣe ń mú ọmọ náà jẹ̀rora nípa gígún un lábẹ́rẹ́ àjẹsára tí yóò dáàbò bò ó kúrò lọ́wọ́ àrùn kan tí ì bá ṣekú pa á. Kò sí ìyá tí ó fẹ́ kí ọmọ òun jẹ̀rora. Kò sí dókítà tí ó fẹ́ ṣokùnfà ìrora ọkàn fún aláìsàn tí ń gbàtọ́jú lọ́wọ́ rẹ̀. Ní àkókò náà, ọmọ náà kò lóye ìdí tí ó fi ń jẹ̀rora, ṣùgbọ́n lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn yóò lóye ìdí tí a fi fàyè gbà á.
Ìtura Gidi Ha Wà fún Àwọn Tí Ń Jìyà Bí?
Àwọn kan lè rò pé wíwulẹ̀ mọ àwọn nǹkan wọ̀nyí lè má fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìtura fún àwọn tí ń jìyà. Hans Küng sọ pé, àlàyé tí ó bọ́gbọ́n mu nípa wíwà tí ìyà wà “fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìrànwọ́ fún ẹni tí ń jìyà gan-an gẹ́gẹ́ bí àwíyé lórí èròjà oúnjẹ ti rí fún ẹni tí ebi ń pa.” Ó béèrè pé: “Gbogbo ìrònú olóye ha lè fún ẹni tí ìyà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pá lórí ní ìṣírí ní tòótọ́ bí?” Tóò, gbogbo “ìrònú olóye” ti àwọn tí wọ́n pa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, tì, kò tí ì fún àwọn tí ń jìyà níṣìírí. Irú ìrònú ènìyàn bẹ́ẹ̀ wulẹ̀ ti dá kún ìṣòro náà ni nípa dídọ́gbọ́n sọ pé, Ọlọ́run pète pé kí ènìyàn jìyà àti pé, a dá ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí àfonífojì ẹkún tàbí ibi ìdánrawò fún àwọn tí yóò jèrè ìyè ní ọ̀run nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ẹ wo irú ọ̀rọ̀ òdì tí èyí jẹ́!
Síbẹ̀, Bíbélì fúnra rẹ̀ fúnni ní ojúlówó orísun ìtùnú. Kì í ṣe kìkì pé ó pèsè àlàyé tí ó bára mu nípa bí ìjìyà ṣe wà nìkan ni, ṣùgbọ́n, ó tún gbé ìgbọ́kànlé ró nínú ìlérí tí ó dájú tí Ọlọ́run ṣe pé, òun yóò mú gbogbo ìpalára tí fífàyègba ìyà fún ìgbà díẹ̀ ti ṣokùnfà kúrò.
“Ìmúpadàbọ̀sípò Ohun Gbogbo”
Láìpẹ́ nísinsìnyí, Ọlọ́run yóò mú àwọn nǹkan pa dà bọ̀ sípò sí bí ó ṣe fẹ́ kí ó rí tẹ́lẹ̀ ṣáájú kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ tó ṣọ̀tẹ̀. Àkókò tí ó yàn kalẹ̀ fún ìṣàkóso òmìnira ti ẹ̀dá ènìyàn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin. A ń gbé ní àkókò náà nígbà tí òun yóò rán “Jésù” jáde, “ẹni tí ọ̀run, ní tòótọ́, gbọ́dọ̀ gbà sínú ara rẹ̀ títí di àwọn àkókò ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo èyí tí Ọlọ́run sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ ti ìgbà láéláé.”—Ìṣe 3:20, 21.
Kí ni Jésù Kristi yóò ṣe? Yóò mú gbogbo àwọn ọ̀tá Ọlọ́run kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (Tẹsalóníkà Kejì 1:6-10) Èyí kò ní jẹ́ ìfìyà-ikú-jẹni àkùgììrìṣe, irú èyí tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláṣẹ bóo fẹ́ bóo kọ̀ máa ń ṣe. Ẹ̀rí gègèrè-gegere tí ń ṣàfihàn àbájáde alájàálù tí ìṣàkóso tí kò dáńgájíá ti ẹ̀dá ènìyàn ti mú wá yóò fi hàn pé, ó tọ́ kí Ọlọ́run lo agbára rẹ̀ tí kò láàlà láìpẹ́ láti mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ. (Ìṣípayá 11:17, 18) Lákọ̀ọ́kọ́ ná, èyí yóò túmọ̀ sí “ìpọ́njú,” irú èyí tí ilẹ̀ ayé kò tí ì nírìírí rẹ̀ rí, èyí tí ó fẹ́ jọ ti Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, ṣùgbọ́n, ó tún lágbára jù ú lọ. (Mátíù 24:21, 29-31, 36-39) Àwọn tí wọ́n bá la “ìpọ́njú ńlá” yìí já yóò nírìírí “àwọn àsìkò títunilára,” nígbà tí wọ́n bá rí ìmúṣẹ gbogbo àwọn ìlérí Ọlọ́run tí a ṣe “láti ẹnu àwọn wòlíì mímọ́.” (Ìṣe 3:19; Ìṣípayá 7:14-17) Kí ni Ọlọ́run ṣèlérí?
Tóò, àwọn wòlíì Ọlọ́run ìgbàanì sọ pé, ìyà tí ogun àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ ń ṣokùnfà yóò dópin. Fún àpẹẹrẹ, Orin Dáfídì 46:9 (NW) sọ fún wa pé: “Ó fi òpin sí ogun títí dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé.” Kò ní sí àwọn òjìyà tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ mọ́ àti àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí ń múni káàánú, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò ní fi ipá báni lò pọ̀ mọ́, kò ní sí àwọn amúkùn-ún mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí àwọn tí a pa nínú ogun rírorò mọ́! Wòlíì Aísáyà, sọ pé: “Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.”—Aísáyà 2:4.
Àwọn wòlíì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ òpin tí yóò dé bá ìyà tí ìwà ọ̀daràn àti àìṣèdájọ́ òdodo ń ṣokùnfà. Òwe 2:21, 22 ṣèlérí pé: “Ẹni ìdúróṣinṣin ni yóò jókòó ní ilẹ̀ náà,” àti pé àwọn tí ń ṣokùnfà ìrora àti ìyà “ni a óò” sì “fà tu kúrò nínú rẹ̀.” “Ẹnì kan” kò ní “ṣe olórí ẹnì kejì fún ìfarapa rẹ̀” mọ́. (Oníwàásù 8:9) A óò mú gbogbo àwọn olùṣe búburú kúrò títí láé. (Orin Dáfídì 37:10, 38) Yóò ṣeé ṣe fún olúkúlùkù láti gbé ní àlàáfíà àti àìléwu, kí wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ ìyà.—Míkà 4:4.
Ní àfikún sí i, àwọn wòlíì náà tún ṣèlérí pé, òpin yóò dé bá ìyà tí àrùn nípa ti ara àti ti èrò ìmọ̀lára ń ṣokùnfà. (Aísáyà 33:24) Aísáyà ṣèlérí pé, àwọn afọ́jú, àwọn odi, àwọn abirùn, àti gbogbo àwọn tí àìsàn àti àrùn gbé dè ni a óò wò sàn. (Aísáyà 35:5, 6) Kódà Ọlọ́run yóò yí àbájáde ikú pa dà pátápátá. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé “gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú àwọn ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀ wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Nínú ìran rẹ̀ nípa “ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan,” a sọ fún àpọ́sítélì Jòhánù pé “Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:1-4) Rò ó wò ná! Kò ní sí ìrora mọ́, kò ní sí omijé mọ́, kò ní sí igbe ẹkún mọ́, kò ní sí ikú mọ́—ìyà kò ní sí mọ́!
Ọ̀ràn ìbànújẹ́ èyíkéyìí tí ó ti lè ṣẹlẹ̀ ní sáà díẹ̀ tí a fi fàyè gba ibi ni a óò tún ṣe. Àní agbára ìrántí ti ìrora àti ìyà ẹ̀dá ènìyàn—tí Ọlọ́run kò fìgbà kankan pète—ni a óò mú kúrò pátápátá. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A gbàgbé wàhálà ìṣáájú . . . A kì yóò sì rántí àwọn ti ìṣáájú.” (Aísáyà 65:16, 17) Ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ pé kí ìdílé ẹ̀dá ènìyàn pípé gbé lálàáfíà àti ayọ̀ kíkún lórí párádísè ilẹ̀ ayé kan yóò ní ìmúṣẹ ní kíkún. (Aísáyà 45:18) Ìgbọ́kànlé nínú ipò ọba aláṣẹ yóò jẹ́ pátápátá. Ẹ wo irú àǹfààní tí ó jẹ́ láti gbé ní àkókò tí Ọlọ́run yóò fòpin sí ìyà ẹ̀dá ènìyàn, ní àkókò tí yóò fi hàn pé òun kì í ṣe irú “òṣìkà olùṣàkóso, afàwọ̀rajà, ẹlẹ́tàn, aṣekúpani,” tí Nietzsche fẹ̀sùn kàn án pé ó jẹ́, ṣùgbọ́n pé òun ń fìgbà gbogbo jẹ́ onífẹ̀ẹ́, ọlọ́gbọ́n, àti onídàájọ́ òdodo nínú lílo agbára rẹ̀ tí kò láàlà!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
ÀWọn olùṣàkóso kan ti lo i̇̀fọgbọ́ndari̇́ èrò inú, ni̇́ fi̇́fi òmi̇̀nira i̇̀fẹ́ inú du àwọn ti̇́ wọ́n fi̇̀yà jẹ
[Credit Line]
UPI/Bettmann
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Nígbà tí ìyà kò bá sí mọ́, gbogbo mùtúmùwà yóò gbádùn ìwàláàyè dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́