Àwọn Ìbùyẹ̀rì Ìmọ́lẹ̀—Ńlá àti Kékeré Apá Kejì
“Nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa fi lè rí ìmọ́lẹ̀.”—ORIN DAFIDI 36:9, NW.
1. Ìsapá wo ni a kọ́kọ́ ṣe láti lóye àmì ìṣàpẹẹrẹ inú ìwé Ìṣípayá?
ÌWÉ Ìṣípayá nínú Bibeli ti ru ìfẹ́ ìtọpinpin àwọn Kristian sókè láti ìgbà ìjímìjí. Ó pèsè àpẹẹrẹ àtàtà nípa bí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ náà ṣe ń mọ́lẹ̀yòò síi nígbà gbogbo. Ní 1917, àwọn ènìyàn Jehofa tẹ àlàyé kan jáde nípa Ìṣípayá nínú ìwé náà The Finished Mystery. Ó fi pẹ̀lú àìbẹ̀rù táṣìírí àwọn aṣáájú ìsìn Kristẹndọm àti àwọn aṣáájú òṣèlú, ṣùgbọ́n púpọ̀ nínú àwọn àlàyé rẹ̀ ni a yá láti inú onírúurú orísun. Síbẹ̀, The Finished Mystery ṣèrànwọ́ láti dán ìṣòtítọ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wò nípa ipa-ọ̀nà tí Jehofa ń lò.
2. Ìmọ́lẹ̀ wo ni ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Ìbí Orílẹ̀-Èdè Náà” tàn sórí ìwé Ìṣípayá?
2 Ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí ó pe àfiyèsí tàn sórí ìwé Ìṣípayá pẹ̀lú ìtẹ̀jáde ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Ìbí Orílẹ̀-Èdè Náà” nínú Ilé-Ìṣọ́nà (Gẹ̀ẹ́sì) March 1, 1925. Èrò wa tẹ́lẹ̀ ni pé Ìṣípayá orí 12 ṣàpèjúwe ogun kan láàárín Romu abọ̀rìṣà àti Katoliki, tí ọmọkùnrin náà sì ń ṣojú fún ipò póòpù. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà fi hàn pé Ìṣípayá 11:15-18 ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìtumọ̀ orí 12, ní fífi hàn pé ó níí ṣe pẹ̀lú ìbí Ìjọba Ọlọrun.
3. Ìtẹ̀jáde wo ni ó tan ìmọ́lẹ̀ tí ó mọ́lẹ̀ síi sórí Ìṣípayá?
3 Gbogbo èyí yọrí sí òye ṣíṣe kedere síi nípa Ìṣípayá tí ó wá pẹ̀lú ìtẹ̀jáde náà Light, ní ìdìpọ̀ méjì, ní 1930. Síbẹ̀ àwọn ìyọ́mọ́ púpọ̀ síi fara hàn nínú ìwé “Babylon the Great Has Fallen!” God’s Kingdom Rules! (1963) àti “Then Is Finished the Mystery of God” (1969). Síbẹ̀, ohun púpọ̀ síi ṣì wà láti kọ́ nípa àsọtẹ́lẹ̀ ìwé Ìṣípayá. Bẹ́ẹ̀ni, ìmọ́lẹ̀ títànyòò tàn sórí rẹ̀ ní 1988, pẹ̀lú ìtẹ̀jáde náà Revelation—Its Grand Climax At Hand! Kọ́kọ́rọ́ náà sí ìlàlóye tí ń tẹ̀síwájú yìí ni a lè sọ pé ó jẹ́ òkodoro òtítọ́ náà pé àsọtẹ́lẹ̀ Ìṣípayá ní ìmúṣẹ ní “ọjọ́ Oluwa,” tí ó bẹ̀rẹ̀ ní 1914. (Ìṣípayá 1:10) Ìwé Ìṣípayá ni a óò lè lóye ní kedere síwájú síi bí ọjọ́ náà ṣe ń tẹ̀síwájú.
“Àwọn Aláṣẹ Tí Ó Wà Ní Ipò Gíga” Ṣe Kedere
4, 5. (a) Ojú wo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli fi wo Romu 13:1? (b) Kí ni a rí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé ó jẹ́ ipò tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu nípa “àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga”?
4 A rí ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ títànyòò kan ní 1962 ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Romu 13:1, tí ó sọ pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn kí ó foríbalẹ̀ fún àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga [“awọn aláṣẹ onípò gíga,” Ìtumọ̀ Ayé Titun].” (King James Version) Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ní ìjímìjí lóye pé “àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga” tí a mẹ́nukàn níbẹ̀ tọ́ka sí àwọn aláṣẹ ayé. Bí wọ́n ṣe lóye ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ yìí sí ni pé bí a bá fipá mú Kristian kan lákòókò ogun, yóò di ọ̀ranyàn fún un láti gbé aṣọ ogun wọ̀, kí ó gbé ìbọn lé èjìká, kí ó sì lọ sí ojú-ogun, sínú iyàrà. Èrò wọn ni pé bí Kristian kan kò bá lè pa ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó bá di kàrá-ǹ-gídá yóò di dandan fún un láti yìnbọn sí afẹ́fẹ́.a
5 Ile-Iṣọ Na January 1 àti ti February 1, 1964, tan ìmọ́lẹ̀ tí ó se kedere sórí kókó-ẹ̀kọ́ náà ní jíjíròrò àwọn ọ̀rọ̀ Jesu ní Matteu 22:21 pé: “Ẹ san awọn ohun ti Kesari padà fún Kesari, ṣugbọn awọn ohun ti Ọlọrun fún Ọlọrun.” Àwọn ọ̀rọ̀ aposteli náà ní Ìṣe 5:29 bá a mu gẹ́ẹ́ pé: “Awa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò awọn ènìyàn.” Àwọn Kristian wà lábẹ́ ìtẹríba fún Kesari—“àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga”—kìkì níwọ̀n bí èyí kò bá ti béèrè pé kí Kristian kan ṣe ohun tí ó lòdì sí òfin Ọlọrun. Wíwà lábẹ́ ìtẹríba sí Kesari ní a rí pé ó ní ààlà, kì í ṣe pátápátá gbáà. Àwọn Kristian ń san kìkì ohun tí kò bá forígbárí pẹ̀lú ohun tí Ọlọrun béèrè fún padà fún Kesari. Ẹ wo bí ó ti tẹ́nilọ́rùn tó láti ní òye tí ó ṣe kedere lórí kókó-ẹ̀kọ́ yìí!
Àwọn Ìbùyẹ̀rì Ìmọ́lẹ̀ Lórí Àwọn Ọ̀ràn Ìṣètò
6. (a) Láti lè yẹra fún ètò ìṣàkóso nípasẹ̀ àwọn ẹgbẹ́ àlùfáà tí ó gbilẹ̀ ní Kristẹndọm, ìlànà wo ni a múlò? (b) Kí ni a wá rí nígbẹ̀yìn gbẹ́yín pé ó jẹ́ ọ̀nà tí ó tọ́ láti gbà yan àwọn wọnnì tí wọ́n ń ṣàbójútó ìjọ?
6 Ìbéèrè dìde nípa àwọn tí ó yẹ kí ó ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà àti díákónì nínú ìjọ. Láti lè yẹra fún ètò ìṣàkóso nípasẹ̀ ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà tí ó gbilẹ̀ ní Kristẹndọm, a parí èrò sí pé a níláti dìbò yan àwọn wọ̀nyí lọ́nà ti dẹmọ nípa ìbò àwọn mẹ́ḿbà inú ìjọ kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n ìmọ́lẹ̀ tí ń mọ́lẹ̀ síi tí ó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà September 1 àti ti October 15, 1932 (Gẹ̀ẹ́sì), fi hàn pé Ìwé Mímọ́ kò ní ìpìlẹ̀ fún àwọn alàgbà tí a dìbò yàn. Nítorí náà a fi ìgbìmọ̀ iṣẹ́-ìsìn rọ́pò àwọn wọ̀nyí, Society sì yan olùṣekòkáárí iṣẹ́-ìsìn.
7. Ìtẹ̀síwájú wo ni àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀nà tí a gbà ń yan àwọn ìránṣẹ́ sípò nínú ìjọ yọrí sí?
7 Ilé-Ìṣọ́nà June 1 àti 15, 1938 (Gẹ̀ẹ́sì), ní nínú àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí ń fi hàn pé àwọn ìránṣẹ́ nínú ìjọ ni, a kò gbọ́dọ̀ dìbò yàn, ṣùgbọ́n kí a yàn sípò, ìyẹn ni pé, kí a yàn wọn sípò lọ́nà tí ó bá ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun mu. Ní 1971 ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ mìíràn fi hàn pé ìjọ kọ̀ọ̀kan ni a kò níláti máa darí nípasẹ̀ kìkì ìránṣẹ́ ìjọ kanṣoṣo. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan níláti ní ẹgbẹ́ àwọn alàgbà, tàbí àwọn alábòójútó, tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yanṣẹ́ fún. Nítorí náà nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ tí ń mọ́lẹ̀ síi ni ohun tí ó ti lé ní 40 ọdún, ó han gbangba pé àwọn alàgbà àti àwọn díákónì bákan náà, tí a mọ̀ nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́, ni a níláti yàn sípò nípasẹ̀ “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú,” nípasẹ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso rẹ̀. (Matteu 24:45-47) Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní àkókò àwọn aposteli. Àwọn ọkùnrin bí Timoteu àti Titu ni a yàn sípò gẹ́gẹ́ bí alàgbà nípasẹ̀ ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti ọ̀rúndún kìn-ínní. (1 Timoteu 3:1-7; 5:22; Titu 1:5-9) Gbogbo èyí jẹ́ ní ìmúṣẹ tí ń pe àfiyèsí sí ohun tí a sọ ní Isaiah 60:17 pé: “Nípò idẹ èmi óò mú wúrà wá, nípò irin èmi óò mú fàdákà wá, àti nípò igi, idẹ, àti nípò òkúta, irin: èmi óò ṣe àwọn ìjòyè rẹ̀ ní àlàáfíà, àti àwọn akóniṣiṣẹ́ rẹ ní òdodo.”
8. (a) Ìtẹ̀síwájú wo ni òtítọ́ tí ń pọ̀ síi ní ọ̀nà tí Society gbà ń ṣiṣẹ́ yọrí sí? (b) Àwọn ìgbìmọ̀ wo ni Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ní, kí sì ni pápá agbègbè ìgbòkègbodò tàbí àbójútó tí ìkọ̀ọ̀kan wọn ń ṣiṣẹ́ lé lórí?
8 Ọ̀ràn nípa ọ̀nà tí Watch Tower Society ń gbà ṣiṣẹ́ wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Fún ọ̀pọ̀ ọdún kò sí ìyàtọ̀ láàárín Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti ìgbìmọ̀ olùdarí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, ọwọ́ ààrẹ sì ni àwọn ọ̀ràn tí ó pọ̀ jùlọ wà. Gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn nínú 1977 Yearbook of Jehovah’s Witnesses (ojú-ìwé 258 sí 259), ní 1976 Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ mẹ́fà, ọ̀kọ̀ọ̀kan èyí tí a yanṣẹ́ pàtó fún nínú iṣẹ́ kárí-ayé náà. Ìgbìmọ̀ Àbójútó Ọ̀ràn Àwọn Òṣìṣẹ́ ń rí sí àwọn ọ̀ràn tí ó jẹmọ́ ti òṣìṣẹ́, títíkan ire gbogbo àwọn tí ń ṣiṣẹ́sìn ní ìdílé Beteli kárí-ayé. Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde ń yanjú gbogbo ọ̀ràn tí kò jẹmọ́ ti ìsìn àti ti òfin, irú bíi dúkìá àti ìtẹ̀wé. Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́-Ìsìn ń bójútó iṣẹ́ ìjẹ́rìí ó sì ń ṣàbójútó àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àti ìgbòkègbodò àwọn akéde ìjọ. Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ni ó ni ẹrù-iṣẹ́ fún àwọn ìpàdé ìjọ, àwọn ọjọ́ àpéjọ àkànṣe, àwọn àpéjọ àyíká, àti àpéjọpọ̀ àgbègbè àti ti àgbáyé bákan náà sì ni onírúurú àwọn ilé-ẹ̀kọ́ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa tẹ̀mí ti àwọn ènìyàn Ọlọrun. Ìgbìmọ̀ Ìwé-Kíkọ ń ṣàbójútó ìmúrasílẹ̀ àti títúmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde ní onírúurú, ní rírí i dájú pé ohun gbogbo wà ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́. Ìgbìmọ̀ Alága ń bójútó àwọn ọ̀ràn pàjáwìrì àti ọ̀ràn kánjúkánjú mìíràn.b Bákan náà ní 1970, àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka ti Watch Tower Society ni ìgbìmọ̀ kan bẹ̀rẹ̀ sí darí dípò alábòójútó kan.
Ìmọ́lẹ̀ Tí Ó Níí Ṣe Pẹ̀lú Ìwàhíhù Kristian
9. Báwo ni ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ṣe nípa lórí ipò-ìbátan àwọn Kristian pẹ̀lú àwọn alákòóso ayé?
9 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ ti níí ṣe pẹ̀lú ìwàhíhù Kristian. Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa ọ̀ràn àìdásí tọ̀tún tòsì. Ìmọ́lẹ̀ kan ní pàtàkì bùyẹ̀rì sórí kókó-ẹ̀kọ́ yìí nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Àìdásí Tọ̀túntòsì” tí ó jáde nínú Ilé-Ìṣọ́nà (Gẹ̀ẹ́sì) November 1, 1939. Ẹ wo bí ìyẹn ti bọ́ sákòókò tó, pé ó dé lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé II bẹ̀rẹ̀! Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà ṣàlàyé àìdásí tọ̀tún tòsì ó sì fi hàn pé àwọn Kristian kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ nínú àlámọ̀rí òṣèlú tàbí ìforígbárí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. (Mika 4:3, 5; Johannu 17:14, 16) Èyí jẹ́ kókó abájọ kan tí àwọn orílẹ̀-èdè fi kórìíra wọn. (Matteu 24:9) Ìja-ogun tí Israeli ìgbàanì jà kò pèsè àpẹẹrẹ ìṣáájú kankan fún àwọn Kristian, gẹ́gẹ́ bí Jesu ṣe mú un ṣe kedere ní Matteu 26:52. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, kò sí orílẹ̀-èdè ti òṣèlú kankan lónìí tí ó jẹ́ ti ìṣàkóso Ọlọrun, tí Ọlọrun ń ṣàkóso, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní Israeli ìgbàanì.
10. Kí ni àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ ṣípayá nípa ojú tí àwọn Kristian níláti fi wo ẹ̀jẹ̀?
10 Ìmọ́lẹ̀ tún tàn sórí ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀. Àwọn kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ronú pé ìkàléèwọ̀ lòdìsí ẹ̀jẹ̀, tí a ṣe nínú Ìṣe 15:28, 29, ní a fimọ sọ́dọ̀ àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ Kristian. Bí ó ti wù kí ó rí, Ìṣe 21:25 fi hàn pé ní àkókò àwọn aposteli àṣẹ yìí ni a lò pẹ̀lú fún àwọn orílẹ̀-èdè tí ó di onígbàgbọ́. Nítorí náà ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀ kan gbogbo àwọn Kristian, gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn nínú Ilé-Ìṣọ́nà (Gẹ̀ẹ́sì) July 1, 1945. Èyí túmọ̀ sí ju wíwulẹ̀ kọ̀ láti jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹranko, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú ohun díndín ẹlẹ́jẹ̀, ṣùgbọ́n ní títakété sí ẹ̀jẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú ọ̀ràn ti ìfàjẹ̀sínilára.
11. Kí ni a rí nípa ojú-ìwòye Kristian nípa lílo tábà?
11 Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ìmọ́lẹ̀ tí ń pọ̀ síi, àwọn ìwà tí a wulẹ̀ ń fojú tí kò tọ́ wò lásán ni a wá kà sí ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Àpẹẹrẹ kan nípa èyí jẹ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú lílo tábà. Nínú ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower ti August 1, 1895, Arákùnrin Russell darí àfiyèsí sí 1 Korinti 10:31 àti 2 Korinti 7:1 ó sì kọ̀wé pé: “Èmi kò rí bí yóò ṣe mú ògo wá fún Ọlọrun, tàbí bí yóò ṣe ṣàǹfààní fún òun alára, bí Kristian èyíkéyìí bá ń lo tábà ní ọ̀nà èyíkéyìí.” Láti 1973 a ti lóye rẹ̀ ní kedere pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ń lo tábà tí ó lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ní 1976 a mú un ṣe kedere pé kò sí Ẹlẹ́rìí kan tí a lè gbàsíṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ tẹ́tẹ́ kí ó sì máa bá a nìṣó ní wíwà nínú ìjọ.
Àwọn Ìyọ́mọ́ Mìíràn
12. (a) Kí ni ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ ṣípayá nípa iye àwọn kọ́kọ́rọ́ Ìjọba náà tí a fi lé Peteru lọ́wọ́? (b) Kí ni àwọn àyíká ipò tí ó wà nígbà tí Peteru lo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kọ́kọ́rọ́ náà?
12 Ìmọ́lẹ̀ tí ó túbọ̀ mọ́lẹ̀ síi tún wà nípa iye kọ́kọ́rọ́ ìṣàpẹẹrẹ tí Jesu fún Peteru. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli gbà pé Peteru gba kọ́kọ́rọ́ méjì tí ó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti di ajogún Ìjọba—ọ̀kan fún àwọn Júù, ni a lò ní Pentekosti 33 C. E., àti èkejì fún àwọn Kèfèrí, tí a kọ́kọ́ lò ní 36 C.E. nígbà tí Peteru wàásù fún Korneliu. (Ìṣe 2:14-41; 10:34-48) Nígbà tí ó ṣe, a rí i pé ó ní ẹgbẹ́ kẹta nínú—àwọn ará Samaria. Peteru lo kọ́kọ́rọ́ kejì nígbà tí ó ń ṣí àǹfààní Ìjọba náà sílẹ̀ fún wọn. (Ìṣe 8:14-17) Nípa bẹ́ẹ̀, kọ́kọ́rọ́ kẹta ni a lò nígbà tí Peteru wàásù fún Korneliu.—Ilé-Ìṣọ́nà, April 1, 1980, ojú-ìwé 19 sí 25, 28.
13. Kí ni àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ ṣípayá nípa àwọn agbo àgùtàn tí a mẹ́nukàn nínú Johannu orí 10?
13 Láti inú ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ mìíràn, a rí i pé kì í ṣe kìkì agbo àgùtàn méjì ni Jesu tọ́ka sí bíkòṣe mẹ́ta. (Johannu, orí 10) Àwọn wọ̀nyí ni (1) agbo àgùtàn ti àwọn Júù èyí tí Johannu Oníbatisí jẹ́ olùṣọ́nà fún, (2) agbo àwọn ẹni-àmì-òróró ti ajogún Ìjọba, àti (3) agbo ti “awọn àgùtàn mìíràn,” tí wọ́n ní ìrètí ilẹ̀-ayé.—Johannu 10:2, 3, 15, 16; Ilé-Ìṣọ́nà, August 15, 1984, ojú-ìwé 10 sí 20.
14. Báwo ni ìmọ́lẹ̀ tí ó mọ́lẹ̀ síi ṣe mú ọ̀ràn ṣe kedere nípa ìbẹ̀rẹ̀ Jubeli amápẹẹrẹṣẹ?
14 Òye nípa Jubeli amápẹẹrẹṣẹ pẹ̀lú gba àwọn ìmúṣe kedere díẹ̀ síi. Lábẹ́ Òfin, gbogbo àádọ́ta, àádọ́ta ọdún máa ń jẹ́ Jubeli pípabambarì, nínú èyí tí a ti máa ń dá nǹkan padà fún ẹni tí ó ni wọ́n tẹ́lẹ̀. (Lefitiku 25:10) Ó ti pẹ́ tí a ti lóye pé èyí jẹ́ òjìji ìṣáájú fún Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún ti Kristi. Bí ó ti wù kí ó rí, láìpẹ́ yìí, a rí i pé Jubeli amápẹẹrẹṣẹ náà níti gidi bẹ̀rẹ̀ ní Pentekosti 33 C.E., nígbà tí àwọn wọnnì tí wọ́n gba ẹ̀mí mímọ́ tí a tú jáde di òmìnira kúrò lọ́wọ́ òǹdè májẹ̀mú Òfin Mose.—Ilé-Ìṣọ́nà, January 1, 1987, ojú-ìwé 18 sí 28.
Ìmọ́lẹ̀ Tí Ó Mọ́lẹ̀ Síi Lórí Èdè-Ìsọ̀rọ̀
15. Ìmọ́lẹ̀ wo ni a tàn sórí ìlò ọ̀rọ̀ náà “wéwèé”?
15 “Oníwàásù wádìí àti rí ọ̀rọ̀ dídùn èyí tí a kọ, ohun ìdúróṣinṣin ni, àní ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (Oniwasu 12:10) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni a lè mú bá kókó-ẹ̀kọ́ wa lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí mú, nítorí pé kì í ṣe sórí kìkì irú àwọn ọ̀ràn tí ó ṣe pàtàkì bẹ́ẹ̀ nìkan bí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àti ìwàhíhù ni ìmọ́lẹ̀ ti tàn sí ṣùgbọ́n bákan náà sórí èdè-ìsọ̀rọ̀ àwọn Kristian àti ìtúmọ̀ rẹ̀ pípéye. Fún àpẹẹrẹ, láàárín àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí jùlọ ni ìdìpọ̀ kìn-ínní ìwé Studies in the Scriptures, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní The Divine Plan of the Ages (Ìwéwèé Ọlọrun Láti Àtayébáyé). Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó ṣe, a rí i pé kìkì ẹ̀dá ènìyàn nìkan ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé ó máa ń wéwèé. (Owe 19:21) Ìwé Mímọ́ kò sọ nípa Jehofa rí pé ó ń wéwèé. Kò sí ìdí kankan fún un láti wéwèé. Ohunkóhun tí ó bá pète dájú pè yóò kẹ́sẹjárí nítorí ọgbọ́n àti agbára ńláǹlà rẹ̀, àní bí a ṣe kà á ní Efesu 1:9, 10 pàápàá pé: “Ní ìbámu pẹlu ìdùnnú rere rẹ̀ èyí tí oun pète ninu ara rẹ̀ fún iṣẹ́ àbójútó kan ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ awọn àkókò tí a yànkalẹ̀.” Nítorí náà kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni a ń rí i pé ọ̀rọ̀ náà “ètè” yẹ wẹ́kú jù nígbà tí a bá ń tọ́ka sí Jehofa.
16. Kí ni a rí ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ pé ó jẹ́ òye tí ó tọ̀nà nípa Luku 2:14?
16 Lẹ́yìn náà ọ̀ràn níní òye tí ó ṣe kedere síi nípa Luku 2:14 jẹyọ. Gẹ́gẹ́ bí King James Version ṣe sọ, ó kà pé: “Ògo ni fún Ọlọrun lókè ọ̀run, àti ní ayè àlàáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.” A rí i pé èyí kò sọ èrò tí ó tọ́ jáde, nítorí pé Ọlọrun kò fí ìfẹ́rere rẹ̀ hàn sí àwọn ènìyàn búburú. Nítorí náà àwọn Ẹlẹ́rìí wo ọ̀ràn yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn àlàáfíà láàárín àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìfẹ́rere sí Ọlọrun. Nítorí náà wọ́n ń bá a lọ láti máa tọ́ka sí àwọn wọnnì tí wọ́n lọ́kàn-ìfẹ́ nínú Bibeli gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni ìfẹ́rere. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ a lóye pé ohun tí ó wémọ́ jẹ́ ìfẹ́rere, kì í ṣe níhà ọ̀dọ̀ ẹ̀dá ènìyàn, bíkòṣe níhà ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Nípa bẹ́ẹ̀, àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé ti Ìtumọ̀ Ayé Titun lórí Luku 2:14 sọ̀rọ̀ nípa “ẹni tí [Ọlọrun] tẹ́wọ́gbà.” Gbogbo àwọn Kristian tí wọ́n ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wọn ní ìfẹ́rere ti Ọlọrun.
17, 18. Kí ni Jehofa yóò dáláre, kí ni òun yóò sì sọdimímọ́?
17 Bákan náà, fún àkókò pípẹ́, àwọn Ẹlẹ́rìí ti sọ̀rọ̀ nípa ìdáláre orúkọ Jehofa. Ṣùgbọ́n Satani ha gbé ìbéèrè dìde sí orúkọ Jehofa bí? Nípa ọ̀ràn yìí, èyíkéyìí nínú àwọn aṣojú Satani ha ti ṣe bẹ́ẹ̀ bí, bí ẹni pé Jehofa kò ní ẹ̀tọ́ sí orúkọ yẹn? Rárá, dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́. Kì í ṣe orúkọ Jehofa ni a pèníjà tí ó sì nílò dídáláre. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society lọ́ọ́lọ́ọ́ kò fi sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jehofa bí èyí tí ó ń di dídáláre. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ipò ọba aláṣẹ Jehofa bí èyí tí ó ń di dídáláre àti nípa orúkọ rẹ̀ bí èyí tí ó ń di sísọdimímọ́. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Jesu ni kí a gbàdúrà fún: “Kí orúkọ rẹ di sísọdimímọ́.” (Matteu 6:9) Léraléra, Jehofa sọ pé òun yóò sọ orúkọ òun di mímọ́, èyí tí àwọn ọmọ Israeli kò pèníjà ṣùgbọ́n tí wọ́n ti sọ di aláìmọ́.—Esekieli 20:9, 14, 22; 36:23.
18 Ó dùnmọ́ni nínú pé, ní 1971, ìwé náà “The Nations Shall Know That I Am Jehovah”—How? mu ìyàtọ̀ yìí ṣe kedere: “Jesu Kristi jà . . . fún ìdáláre Ipò Ọba Aláṣẹ àgbáyé Jehofa àti fún ìyìnlógo orúkọ Jehofa.” (Ojú-ìwé 364 sí 365) Ní 1973, ìwé God’s Kingdom of a Thousand Years Has Approached sọ pé: “‘Ìpọ́njú ńlá’ tí ń bọ̀ ni àkókò fún Jehofa Ọlọrun Olodumare láti dá ipò ọba aláṣẹ àgbáyé rẹ̀ láre kí ó sì sọ orúkọ yíyẹ rẹ̀ di mímọ́.” (Ojú-ìwé 409) Lẹ́yìn náà, ní 1975, ìwé Man’s Salvation out of World Distress at Hand! sọ pé: “Ìṣẹ̀lẹ̀ títóbi jùlọ nínú ìtàn àgbáyé ni a óò ti ṣàṣeparí nígbà náà, ìdáláre ipò ọba aláṣẹ àgbáyé Jehofa àti ìsọdimímọ́ orúkọ mímọ́ ọlọ́wọ̀ rẹ̀.”—Ojú-ìwé 281.
19, 20. Báwo ni a ṣe lè fi ìmọrírì wa hàn fún àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí?
19 Ẹ wo bí a ṣe bùkún àwọn ènìyàn Jehofa tó láti máa yọ̀ ṣìnkìn nínú ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí yìí! Ní ìyàtọ̀ gédégédé, òkùnkùn tẹ̀mí nínú èyí tí àwọn aṣáájú ìsìn Kristẹndọm bá ara wọn ni ọ̀rọ̀ tí àlùfáà yìí sọ mú ṣe kedere: “Èéṣe tí ẹ̀ṣẹ̀ fi wà? Èéṣe tí ìjìyà fi wà? Èéṣe ti Èṣù fi wà? Àwọn ìbéèrè tí mo fẹ́ bi Oluwa nìyí nígbà tí mo bá dé ọ̀run.” Ṣùgbọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lè sọ ohun tí ó fa sábàbí fún un: Nítorí àríyànjiyàn ẹ̀tọ́ ipò ọba aláṣẹ Jehofa àti ìbéèrè náà pé bóyá ẹ̀dá ènìyàn lè di ìwàtítọ́ wọn mú sí Ọlọrun láìka àtakò Èṣù sí ni.
20 Jálẹ̀ ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ ńlà àti kékeré ti ń mọ́lẹ̀ sí ipa-ọ̀nà àwọn ìránṣẹ́ olùṣèyàsímímọ́ fún Jehofa. Èyí ti jẹ́ ní ìmúṣẹ irú àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ bí Orin Dafidi 97:11 àti Owe 4:18. Ṣùgbọ́n ẹ máṣe jẹ́ kí a gbàgbé láé pé rírìn nínú ìmọ́lẹ̀ túmọ̀ sí níní ìmọrírì fún ìmọ́lẹ̀ tí ó mọ́lẹ̀ síi àti gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i, ìmọ́lẹ̀ tí ń mọ́lẹ̀ síi wémọ́ ìwàhíhù wa àti iṣẹ́ ìwàásù tí a paláṣẹ fún wa.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní ìhùwàpadà sí ojú-ìwòye yìí, Ilé-Ìṣọ́nà June 1 àti ti June 15, 1929 (Gẹ̀ẹ́sì), túmọ̀ “àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga” gẹ́gẹ́ bí Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi. Ojú-ìwòye yìí gan-an ni a túnṣe ní 1962.
b Ilé-Ìṣọ́nà April 15, 1992, kéde pé àwọn arákùnrin tí a yàn ní pàtàkì lára “awọn àgùtàn mìíràn” ni a ti yanṣẹ́ fún láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ìgbìmọ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, èyí tí ó bá ti àwọn Netinimu ọjọ́ Esra mu.—Johannu 10:16; Esra 2:58.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Ìmọ́lẹ̀ wo ni a ti tàn sórí kókó-ẹ̀kọ́ náà “àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga”?
◻ Àwọn ìdàgbàsókè ìṣètò wo ni àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ ti yọrí sí?
◻ Báwo ni ìmọ́lẹ̀ tí ń mọ́lẹ̀ síi ṣe nípa lórí ìwà Kristian?
◻ Àwọn ìyọ́mọ́ wo nínú òye wa nípa àwọn kókó Ìwé Mímọ́ kan ní ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí ti mú wá?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn kọ́kọ́rọ́ tí ó wà ní ojú-ìwé 24: A gbé àwòràn náà karí fọ́tò tí a yà ní Cooper-Hewitt, National Design Museum, Smithsonian Institution