Àwọn Ìbùyẹ̀rì Ìmọ́lẹ̀—Ńlá àti Kékeré Apá Kìn-Ínní
“Ipa-ọ̀nà àwọn olóòótọ́ dàbí títàn ìmọ́lẹ̀, tí ó ń tàn síwájú àti síwájú títí di ọ̀sángangan.”—OWE 4:18.
1. Èéṣe tí a fi ṣípayá òtítọ́ náà ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀?
Ẹ̀RÍ ọgbọ́n àtọ̀runwá ni ó jẹ́ pé ní ìbámu pẹ̀lú Owe 14:18, ṣíṣí òtítọ́ tẹ̀mí payá ti ṣẹlẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀. Nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú, a rí bí ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ yìí ṣe ní ìmúṣẹ ní àkókò àwọn aposteli. Bí a bá ti ṣípayá èyí tí ó pọ̀ jù nínú òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ lẹ́ẹ̀kan náà ni, à bá má ti lóye rẹ̀ ìbá sì ti dàrú mọ́ wa lójú—ìyọrísí rẹ̀ ìbá ti dàbí jíjáde láti inú ihò tí ó ṣókùnkùn sínú oòrùn títànyòò. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, òtítọ́ tí a ṣípayá ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ń fún ìgbàgbọ́ àwọn Kristian lókun lọ́nà tí ń bá a nìṣó. Ó túbọ̀ ń mú kí ìrètí wọn máa tànyòò síi kí ipa-ọ̀nà tí wọ́n sì túbọ̀ máa ṣe kedere síi.
“Olùṣòtítọ́ ati Ọlọ́gbọ́n-Inú Ẹrú”
2. Ta ni Jesu fi hàn pé òun yóò lo láti mú ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí wá fún àwọn ọmọlẹ́yìn òun, àwọn wo sì ni irin-iṣẹ́ yẹn ní nínú?
2 Ní àkókò àwọn aposteli Jesu Kristi rí i pé ó tọ́ láti lo ọ̀nà tí ó rékọjá ti ẹ̀dá láti fún àwọn ọmọlẹ́yìn òun ní àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ àkọ́kọ́. A ní àpẹẹrẹ méjì nípa èyí: Pentekosti 33 C.E. àti ìyílọ́kànpadà Korneliu ní 36 C.E. Láti ìgbà yìí lọ, Kristi rí i pé ó tọ́ láti lo aṣojú tí ó jẹ́ ẹ̀dà ènìyàn, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti sọtẹ́lẹ̀: “Níti tòótọ́ ta ni olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú tí ọ̀gá rẹ̀ yànsípò lórí awọn ará ilé rẹ̀, lati fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu? Aláyọ̀ ni ẹrú naa bí ọ̀gá rẹ̀ nígbà tí ó bá dé bá rí i tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀! Ní òótọ́ ni mo wí fún yín, Oun yoo yàn án sípò lórí gbogbo awọn nǹkan ìní rẹ̀.” (Matteu 24:45-47) Ẹrú yìí kò lè jẹ́ ẹyọ ẹnì kan ṣoṣo nítorí pé ó níláti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí láti ìgbà tí ìjọ Kristian ti bẹ̀rẹ̀ ní Pentekosti títí di ìgbà tí Ọ̀gá náà, Jesu Kristi, wá fún ìjíhìn. Òkodoro òtítọ́ náà fi hàn pé ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú yìí ní nínú gbogbo àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwùjọ kan lórí ilẹ̀-ayé ní àkókò kan pàtó.
3. Àwọn wo ni ó wà lára mẹ́ḿbà àkọ́kọ́ ẹgbẹ́ ẹrú náà?
3 Àwọn wo ni ó kọ́kọ́ jẹ́ mẹ́ḿbá ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà? Ọ̀kan ni aposteli Peteru, ẹni tí ó kọbiara sí àṣẹ Jesu pé: “Máa bọ́ awọn àgùtàn mi kéékèèké.” (Johannu 21:17) Àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà àkọ́kọ́ ti ẹgbẹ́ ẹrú náà ní nínú Matteu, ẹni tí ó kọ Ìròyìnrere tí a fi orúkọ rẹ̀ mọ̀, àti Paulu, Jakọbu, àti Juda, àwọn tí wọ́n kọ àwọn lẹ́tà tí a mí sí. Aposteli Johannu, ẹni tí ó kọ ìwé Ìṣípayá, Ìròyìnrere rẹ̀, àti àwọn lẹ́tà rẹ̀, pẹ̀lú jẹ́ mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kọ̀wé ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ tí Jesu paláṣẹ fún wọn.
4. Àwọn wo ni “awọn ará ilé”?
4 Bí gbogbo àwọn ẹni-àmì-òróró gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwùjọ kan, láìka ibi yòówù tí wọ́n lè máa gbé lórí ilẹ̀-ayé sí, bá jẹ́ mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ ẹrú náà, àwọn wo ni “awọn ará ilé”? Ẹni-àmì-òróró ni wọ́n bákan náà ṣùgbọ́n tí a gbé yẹ̀wò láti ojú-ìwòye mìíràn tí ó yàtọ̀—gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan. Bẹ́ẹ̀ni, gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn yóò jẹ́ “ẹrú” tàbí wọn yóò jẹ́ “awọn ara ilé,” ó sinmi lórí bóyá wọ́n ń fúnni ní oúnjẹ tẹ̀mí tàbí wọ́n ń ṣàjọpín nínú rẹ̀. Láti ṣàpèjúwe: Gẹ́gẹ́ bì a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní 2 Peteru 3:15, 16, aposteli Peteru tọ́ka sí àwọn lẹ́tà Paulu. Nígbà tí ó ń kà wọ́n, Peteru yóò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ara ilé tí ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí Paulu pèsè gẹ́gẹ́ bí aṣojú ẹgbẹ́ ẹrú náà.
5. (a) Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí ẹrú náà láàárín àwọn ọ̀rúndún lẹ́yìn àwọn aposteli? (b) Àwọn ìdàgbàsókè wo ni ó wáyé ní apá tí ó kẹ́yìn apá ìdajì ọ̀rúndún kọkàndínlógún?
5 Nípa èyí, ìwé náà God’s Kingdom of a Thousand Years Has Approached sọ pé: “Nípa bí ẹgbẹ́ ‘olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú’ náà ṣe wáyé tí ó sì ṣiṣẹ́sìn jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún lẹ́yìn ikú àwọn aposteli Ọ̀gá náà Jesu Kristi, a kò ní àkọsílẹ̀ ìtàn nípa rẹ̀. Ó ṣe kedere pé ìran ẹgbẹ́ ‘ẹrú’ náà kan bọ́ ìran tí ó tẹ̀lé tirẹ̀. (2 Timoteu 2:2) Ṣùgbọ́n bí ọ̀rúndún kọkàndínlógún ti ń parí lọ àwọn ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọrun wà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ oúnjẹ tẹ̀mí ti Bibeli Mímọ́ tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́-ọkàn láti jẹ nínú rẹ̀ . . . A dá àwọn kíláàsì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli . . . sílẹ̀ wọ́n sì tẹ̀síwájú nínú òye nípa òtítọ́ ìpìlẹ̀ Ìwé Mímọ́ Ọlọ́wọ̀. Àwọn olóòótọ́-ọkàn aláìmọtara-ẹni-nìkan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọ̀nyí háragàgà láti ṣàjọpín àwọn apá ṣíṣekókó ti oúnjẹ tẹ̀mí wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Wọ́n ní ẹ̀mí ìṣòtítọ́ ti ‘ẹrú’ náà tí a yànsípò láti fún ‘awọn ara ilé’ ní ‘oúnjẹ’ tẹ̀mí tí wọ́n nílò ‘ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu.’ Wọ́n jẹ́ ‘ọlọ́gbọ́n-inú’ ní fífòyemọ̀ pé àkókò tí ó tọ́ tí ó sì bẹ́tọ̀ọ́mu nìyẹn àti àwọn ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti pín oúnjẹ náà. Wọ́n sakun láti pín in.”—Ojú-ìwé 344 sí 345.a
Àwọn Ìbùyẹ̀rì Ìmọ́lẹ̀ Àkọ́kọ́ ní Àkókò Òde-Òní
6. Òkodoro òtítọ́ wo ni ó tayọ gédégbé ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ṣíṣí òtítọ́ náà payá ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀?
6 Òkodoro òtítọ́ kan tí ó tayọ gédégbé ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí Jehofa lò láti mú ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tí ń mọ́lẹ̀ síi ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ yìí wá ni pé wọn kò gba ìyìn fún ara wọn. Ìṣarasíhùwà C. T. Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ ti Watch Tower Society, ni pé ó dùn mọ́ Oluwa nínú láti lo ẹbun wọn tí kò ṣàrà ọ̀tọ̀. Nípa àwọn ọ̀rọ̀ èébú tí a sún àwọn ọ̀tá rẹ̀ láti lò, Arákùnrin Russell mú kí ó di mímọ̀ pé òun kò tí ì bá “Ọmọlẹ́yìn Russell” kankan pàdé rí àti pé kò sí ohunkóhun tí ń jẹ́ “Ìgbàgbọ́ Russell.” Ọlọrun ni a fi gbogbo ìyìn fún.
7. Ẹ̀rí wo ni Arákùnrin Russell àti àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ fúnni níti pé nítòótọ́ ni àwọn darapọ̀ mọ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà?
7 Bí a bá fi ìyọrísí rẹ̀ gbé e yẹ̀wò, kò lè sí iyèméjì pé ẹ̀mí mímọ́ Jehofa ń darí akitiyan Arákùnrin Russell àti àwọn wọnnì tí ń kẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Wọ́n fi ẹ̀rí hàn pé àwọn jẹ́ ara ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àwùjọ àlùfáà ti àkókò náà jẹ́wọ́ pé àwọn gbàgbọ́ pé Bibeli jẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun mí sí àti pé Jesu jẹ́ Ọmọkùnrin Ọlọrun, wọ́n fọwọ́ sí àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Babiloni, tí ó jẹ́ èké, irú bí Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn ẹ̀dá ènìyàn, àti ìdálóró ayérayé. Ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí Jesu, níti tòótọ́ ẹ̀mí mímọ́ àti ìsapá àfìrẹ̀lẹ̀ṣe tí Arákùnrin Russell àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe ni ó mú kí òtítọ́ mọ́lẹ̀ síi ju ti ìgbàkígbà rí lọ. (Johannu 16:13) Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ẹni-àmì-òróró yẹn fi ẹ̀rí hàn pé àwọn jẹ́ apákan ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà níti tòótọ́, ẹni tí iṣẹ́ tí a fàṣẹ yàn fún un jẹ́ láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn ará ilé Ọ̀gá náà. Ìsapá wọn jẹ́ àrànṣe ńláǹlà ní kíkó àwọn ẹni-àmì-òróró jọ.
8. Òkodoro òtítọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ wo nípa Jehofa, Bibeli, Jesu Kristi, àti ẹ̀mí mímọ́ ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lóye ní kedere?
8 Bí Jehofa ṣe fi àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ fojúrere ńláǹlà hàn sí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìjímìjí wọ̀nyí, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, yẹ fún àfiyèsí. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọ́n fi ẹ̀rí tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ hàn pé Ẹlẹ́dàá ń bẹ àti pé ó ní orúkọ títayọlọ́lá náà Jehofa. (Orin Dafidi 83:18; Romu 1:20) Wọ́n rí i pé Jehofa ní àwọn ànímọ́ mẹ́rin pàtàkì—agbára, ìdájọ́-òdodo, ọgbọ́n, àti ìfẹ́. (Genesisi 17:1; Deuteronomi 32:4; Romu 11:33; 1 Johannu 4:8) Àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró wọ̀nyí fi ẹ̀rí hàn ní kedere pé Bibeli jẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun mí sí òhun sì ni òtítọ́. (Johannu 17:17; 2 Timoteu 3:16, 17) Síwájú síi, wọ́n gbà pé Ọmọkùnrin Ọlọrun, Jesu Kristi, ni a dá àti pé ó fi ìwàláàyè rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún gbogbo aráyé. (Matteu 20:28; Kolosse 1:15) Ẹ̀mí mímọ́, kàkà tí ìbá fi jẹ́ ẹni kẹta nínú Mẹ́talọ́kan, ni wọ́n rí gẹ́gẹ́ bí ipá agbékánkán ṣiṣẹ́ Ọlọrun.—Ìṣe 2:17.
9. (a) Àwọn òtítọ́ wo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lóye ní kedere nípa irú ẹni tí ènìyàn jẹ́ àti kádàrá tí Bibeli nawọ́ rẹ̀ jáde? (b) Àwọn òtítọ́ mìíràn wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jehofa rí kedere?
9 Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rí i ní kedere pé ènìyàn kò ní àìleèkú ọkàn ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọkàn tí ó lè kú. Wọ́n mọ̀ pé “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú,” kì í ṣe ìdálóró ayérayé, kò sí ibì kankan tí ó jẹ́ hẹ́ẹ̀lì tí iná ti ń jó. (Romu 5:12; 6:23; Genesisi 2:7; Esekieli 18:4) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọ́n rí i ní kedere pé kì í ṣe pé àbá èrò-orí ẹfolúṣọ̀n kò bá ìwé mímọ́ mu nìkan ni ṣùgbọ́n a sọ ọ́ láìní ẹ̀rí ìpìlẹ̀ òtítọ́ kankan. (Genesisi, orí 1 àti 2) Àwọn pẹ̀lú fòyemọ̀ pé kádàrá méjì ni Bibeli nawọ́ rẹ̀ jáde—ti ọ̀run fún 144,000 ẹni-àmì-òróró àwọn ọmọlẹ́yìn tí ń tẹ̀lé ipasẹ̀ Kristi àti ilẹ̀-ayé tí a sọ di paradise fun àìmọye “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “awọn àgùtàn mìíràn.” (Ìṣípayá 7:9; 14:1; Johannu 10:16) Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ wọ̀nyẹn mọ̀ pé ilẹ̀-ayé yóò wà títíláé a kì yóò sì jó o run, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsìn ti fi kọ́ni. (Oniwasu 1:4; Luku 23:43) Wọ́n tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ìpadàbọ̀ Kristi yóò jẹ́ àìṣeé fojúrí àti pé nígbà náà òun yóò mú ìdájọ́ ṣẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò sì mú paradise ilẹ̀-ayé wá.—Ìṣe 10:42; Romu 8:19-21; 1 Peteru 3:18.
10. Àwọn òtítọ́ wo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kọ́ nípa ìbatisí, fífi ìyàtọ̀ sí àwùjọ àlùfáà àti ọmọ ìjọ, àti Ìṣe-Ìrántí ikú Kristi?
10 Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kẹ́kọ̀ọ́ pé ìbatisí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu kì í ṣe ọ̀ràn bíbu omi wọ́n àwọn ọmọ-ọwọ́ lórí ṣùgbọ́n pé ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Jesu ní Matteu 28:19, 20, ó jẹ́ ríri àwọn aláìgbàgbọ́ tí a ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bọmi. Wọ́n wá rí i pé kò sí ìpìlẹ̀ Ìwé Mímọ́ kankan fún fífi ìyàtọ̀ sáàárín àwùjọ àlùfáà àti àwọn ọmọ ìjọ. (Matteu 23:8-10) Ní ìyàtọ̀ gedegbe, gbogbo Kristian gbọ́dọ̀ jẹ́ oníwàásù ìhìnrere náà. (Ìṣe 1:8) Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli mọrírì pé a níláti máa ṣe Ìṣe Ìrántí ikú Kristi lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, ní Nisan 14. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n rí i pé Easter jẹ́ họlidé àwọn abọ̀rìṣà. Ní àfikún síi, àwọn ẹni-àmì-òróró wọ̀nyẹn ní ìdánilójú pé Ọlọrun ń ti iṣẹ́ wọn lẹ́yìn débi pé wọ́n kò gba ìdáwó rí. (Matteu 10:8) Láti ìgbà ìjímìjí, wọ́n lóye pé àwọn Kristian níláti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Bibeli, èyí tí ó ní nínú mímú àwọn èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun dàgbà.—Galatia 5:22, 23.
Àwọn Ìbùyẹ̀rì Ìmọ́lẹ̀ Tí Ń Mọ́lẹ̀ Síi
11. Ìmọ́lẹ̀ wo ni ó tàn sórí iṣẹ́ tí a paláṣẹ fún àwọn Kristian àti òwe àkàwé Jesu nípa àwọn àgùtàn àti ewúrẹ́?
11 Ní pàtàkì láti 1919 ni a ti ń bùkún àwọn ìránṣẹ́ Jehofa pẹ̀lú àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí ń mọ́lẹ̀ síi. Ẹ wo irú ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ títànyòò tí ó tàn ní àpéjọpọ̀ Cedar Point ní 1922 bí J. F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Society kejì, ṣe tẹnumọ́ kókó náà lọ́nà lílágbára pé olórí ojúṣe àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ni láti ‘fọnrere, fọnrere, fọnrere, Ọba náà àti ìjọba rẹ̀’! Ní ọdún tí ó tẹ̀lé e gan-an, ìmọ́lẹ̀ títànyòò náà tàn sórí òwe àkàwé ti àwọn àgùtàn àti ewúrẹ́. A rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí yóò ní ìmúṣẹ ní ọjọ́ Oluwa ti ìsinsìnyí, kì í ṣe ní ọjọ́-ọ̀la nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún, gẹ́gẹ́ bí a ti rò tẹ́lẹ̀. Lákòókò Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà àwọn arákùnrin Kristi kì yóò ṣàìsàn, bẹ́ẹ̀ sì ni a kì yóò fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà, Jehofa Ọlọrun, kì í ṣe Jesu Kristi, ni yóò ṣe ìdájọ́.—Matteu 25:31-46.
12. Ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ wo ni ó wá nípa Armageddoni?
12 Ní 1926 ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ mìíràn ni a ṣípayá pé ogun Armageddoni kì yóò jẹ́ ìyípadà tegbò tigaga ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, gẹ́gẹ́ bí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ṣe ronú nígbà kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ ogun kan nínú èyí tí Jehofa yóò ti fi agbára rẹ̀ hàn lọ́nà tí ó ṣe kedere tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ti gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ dájú pé òun ni Ọlọrun.—Ìṣípayá 16:14-16; 19:17-21.
Kérésìmesì—Họlidé Àwọn Abọ̀rìṣà
13. (a) Ìmọ́lẹ̀ wo ni ó tàn sórí ayẹyẹ Kérésìmesì? (b) Èéṣe tí a kò fi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí mọ́? (Fí àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé kún un.)
13 Kété lẹ́yìn náà, ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ kan mú kí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli dẹ́kun ṣíṣayẹyẹ Kérésìmesì. Ṣáájú àkókò yẹn Kérésìmesì ti fìgbà gbogbo jẹ́ ayẹyẹ tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli máa ń ṣe kárí-ayé, ayẹyẹ rẹ̀ ní orílé-iṣẹ́ ní Brooklyn sì máa ń jẹ́ àjọyọ̀ sísọkutuyọ̀yọ̀ gan-an. Ṣùgbọ́n nígbà náà a fòye mọ̀ pé níti gidi ṣíṣayẹyẹ December 25 jẹ́ àṣà àwọn abọ̀rìṣà, àwọn Kristẹndọm apẹ̀yìndà ni ó sì yàn án kí ó baà lè rọrùn láti yí àwọn abọ̀rìṣà lọ́kàn padà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a tún rí i pé kò lè jẹ́ àkókò òtútù ni a bí Jesu, níwọ̀n bí o tí jẹ́ pé ní àkókò ìbí rẹ̀, àwọn olùṣọ́ àgùtàn ń da agbo ẹran wọn ní pápá—ohun kan tí wọn kì bá ti lè ṣe ní òru ní apá ìparí oṣù December. (Luku 2:8) Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé a bí Jesu ní nǹkan bí October 1. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tún mọ̀ pé àwọn tí a ń fẹnu lásán pè ní ọkùnrin amòye tí wọ́n bẹ Jesu wò ní nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn ìbí rẹ̀ jẹ́ àwọn magi abọ̀rìṣà.b
Orúkọ Titun
14. Èéṣe tí orúkọ náà àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kò fi bá àwọn ènìyàn Jehofa mu tó?
14 Ní 1931 ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ṣí orúkọ kan tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu payá fún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọ̀nyẹn. Àwọn ènìyàn Jehofa ti lóye pé wọn kò lè tẹ́wọ́gba èyíkéyìí lára àwọn orúkọ ìnagijẹ tí àwọn mìíràn ti fún wọn, irú bí àwọn Ọmọlẹ́yìn Russell, Onígbàgbọ́ Ilẹ́ Ẹgbẹ̀rún Ọdún Fẹ́rẹ̀ẹ́ Mọ́, àti “onígbàgbọ́ kò-sí-hẹ́ẹ̀lì.”c Ṣùgbọ́n àwọn pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí mọrírì pé orúkọ náà tí àwọn ti yàn fúnra wọn—Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli Káàkiri Orílẹ̀-Èdè—kò bá wọ́n mu tó. Wọ́n ju kìkì àwọn tí ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ. Yàtọ̀ sí ìyẹn, àwọn púpọ̀ mìíràn tún wà tí wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ṣùgbọ́n tí wọn kò farajọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rárá.
15. Orúkọ wo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tẹ́wọ́gbà ní 1931, èésìtiṣe ti ó fi bá a mu wẹ́kú?
15 Báwo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ṣe wá rí orúkọ titun kan? Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún Ile-Iṣọ Na ti ń fi orúkọ Jehofa hàn ketekete. Nítorí náà, ó bá a mu wẹ́kú jùlọ pé kí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tẹ́wọ́gba orúkọ náà tí a rí ní Isaiah 43:10 (NW): “‘Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni ọ̀rọ̀ àsọjáde Jehofa, ‘àní ìránṣẹ́ mi ti mo ti yàn, kí ẹ̀yin kí ó baà lè mọ̀ kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi, àti kí ẹ̀yin kí ó lè lóye pé èmi ni Ẹni kan náà. Ṣáájú mi kò sí Ọlọrun kan tí a ṣe, àti lẹ́yìn mi kò tún ní sí ọ̀kankan.’”
Ìdáláre àti “Ogunlọ́gọ̀ Ńlá”
16. Èéṣe tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò kò fi lè tọ́ka sí àwọn Júù àbínibí tí wọ́n padà sí Palestine, ṣùgbọ́n àwọn wo ni wọ́n tọ́ka sí?
16 Nínú ìdìpọ̀ kejì ìwé Vindication, tí Watch Tower Society tẹ̀ jáde ní 1932, ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ ṣípayá pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò tí Isaiah, Jeremiah, Esekieli, àti àwọn wòlíì mìíràn ṣàkọsílẹ̀ kò tọ́ka sí àwọn Júù àbínibí (gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe rò nígbà kan), àwọn tí wọ́n ń padà sí Palestine pẹ̀lú àìgbàgbọ́ àti ète ìsúnniṣe òṣèlú. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò wọ̀nyí, èyí tí ó ní ìmúṣẹ ráńpẹ́ nígbà tí àwọn Júù padà láti ìgbèkùn Babiloni ní 537 B.C.E., ní ìmúṣẹ títóbi wọn nínú ìdáǹdè Israeli tẹ̀mí àti ìmúpadàbọ̀sípò wọn tí ó bẹ̀rẹ̀ ní 1919 àti nínú aásìkí tí ó yọrí sí nínú paradise tẹ̀mí tí àwọn ìránṣẹ́ Jehofa tòótọ́ ń gbádùn lónìí.
17, 18. (a) Nígbà tí ó ṣe, nípasẹ̀ ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ kan, kí ni a fi hàn pé ó jẹ́ olórí ète Jehofa? (b) Irú ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ wo nípa Ìṣípayá 7:9-17 ni ó ṣẹlẹ̀ ní 1935?
17 Nígbà tí ó ṣe, àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ ṣípayá pé olórí ète Jehofa, kì í ṣe ìgbàlà ẹ̀dá ènìyàn, ṣùgbọ́n ìdáláre ipò ọba aláṣẹ rẹ̀. Ẹṣin-ọ̀rọ̀ Bibeli tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni a rí pé, kì í ṣe ìràpadà, bíkòṣe Ìjọba náà, nítorí pé yóò dá ipò ọba aláṣẹ Jehofa láre. Ẹ wo irú ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí ìyẹn jẹ́! Bí wọn yóò ṣe dé ọ̀run kì í ṣe ohun tí ó ṣe pàtàkì tí ó jẹ àwọn Kristian olùṣèyàsímímọ́ lógún mọ́.
18 Ní 1935 ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ títànyòò ṣípayá pé ogunlọ́gọ̀ ńlá tí a mẹ́nukàn nínú Ìṣípayá 7:9-17 kì í ṣe ẹgbẹ́ kejì tí yóò lọ sí ọ̀run. A ti rò ó tẹ́lẹ̀ pé àwọn wọnnì tí a mẹ́nukàn nínú àwọn ẹsẹ̀ wọ̀nyẹn jẹ́ àwọn kan lára àwọn ẹni-àmì-òróró tí wọn kò jẹ́ olùṣòtítọ́ délẹ̀délẹ̀ nítorí náà wọ́n ń dúró níwájú ìtẹ́ dípò kí wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ kí wọ́n máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Jesu Kristi. Ṣùgbọ́n kò sí ohun kankan tí ń jẹ́ jíjẹ́ olùṣòtítọ́ díẹ̀. Ẹnì kan yóò kúkú jẹ́ olùṣòtítọ́ tàbí aláìṣòtítọ́. Nítorí náà a rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí tọ́ka sí àìníye ogunlọ́gọ̀ ńlá láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè tí a ti ń kójọpọ̀ nísinsìnyí tí ìrètí wọn sì jẹ́ ti orí ilẹ̀-ayé. Àwọn ni “awọn àgùtàn” ti Matteu 25:31-46 àti “awọn àgùtàn mìíràn” ti Johannu 10:16.
Àgbélébùú —Kì í Ṣe Àmì Ìṣàpẹẹrẹ Kristian
19, 20. Èéṣe tí àgbélébùú kò fi lè jẹ́ àmì ìṣàpẹẹrẹ fún ìsìn Kristian tòótọ́?
19 Fún ọ̀pọ̀ ọdún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli fi àgbélébùú sí ipò pàtàkì gẹ́gẹ́ bí àmì ìṣàpẹẹrẹ ìsìn Kristian. Wọ́n tilẹ̀ ní ohun ọ̀ṣọ́ tí ó ní “àgbélébùú àti adé.” Gẹ́gẹ́ bí King James Version ṣe sọ, Jesu sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbé “àgbélébùú” wọn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì wá gbàgbọ́ pé orí àgbélébùú ni a kàn án mọ́. (Matteu 16:24; 27:32) Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún àmì àpẹẹrẹ yìí tún fara hàn lẹ́yìn èèpo ìwé ìròyìn Ile-Iṣọ Na.
20 Ìwé náà Ọrọ̀, tí Society tẹ̀ jáde ní 1936, mú un ṣe kedere pé Jesu Kristi ni a kàn mọ́, kì í ṣe àgbélébùú, bíkòṣe òpó dídúró ṣánṣán, tàbí òpó igi. Gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ kan ṣe sọ, ọ̀rọ̀ Griki náà (stau·rosʹ) tí a pè ní “àgbélébùú” nínú Bibeli King James Version “túmọ̀ sí, ní pàtàkì, òpó tàbí igi dídúró ṣánṣán. Ó yẹ kí a dá [a] mọ̀ yàtọ̀ sí àgbélébùú olópòó méjì tí ṣọ́ọ̀ṣì hùmọ̀ rẹ̀. . . . Èyí tí a mẹ́nukàn gbẹ̀yìn yìí pilẹ̀ ní Kaldea, a sì lò ó gẹ́gẹ́ bí àmì ìṣàpẹẹrẹ fún ọlọrun Tammusi.” Dípò sísọ ọ di òrìṣà, ohun tí a kan Jesu mọ́ ni a níláti wò pẹ̀lú ìkórìíra.
21. Kí ni a óò gbé yẹ̀wò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e?
21 Àwọn àpẹẹrẹ síwájú síi wà nípa àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ ńlá àti àwọn wọnnì tí a lè wò gẹ́gẹ́ bíi kékeré. Fún ìjíròrò àwọn wọ̀nyí, jọ̀wọ́ wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
b Nígbà tí ó ṣe, a rí i pé bí a kò bá ní máa ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ, a kò ní máa ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí kankan. Yàtọ̀ sí ìyẹn, yálà àwọn ọmọ Israeli tàbí àwọn Kristian ìjímìjí kò ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí. Bibeli mẹ́nukan ọjọ́ ìbí méjì péré, ọ̀kan jẹ́ ti Farao èkejì sì jẹ́ ti Herodu Antipa. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ni a fi ìpànìyàn bàjẹ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kì í ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí nítorí pé àwọn ayẹyẹ wọ̀nyí pilẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà ó sì ń gbé ọlọ́jọ́ ìbí ga.—Genesisi 40:20-22; Marku 6:21-28.
c Èyí jẹ́ àṣìṣe tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀ka ìsìn Kristẹndọm ṣe. Àwọn onísìn Luther jẹ́ orúkọ ìnagijẹ tí àwọn ọ̀tá Martin Luther fun àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, tí àwọn náà sì tẹ́wọ́gbà á. Bákan náà, àwọn onísìn Baptist tẹ́wọ́gba orúkọ ìnagijẹ náà tí àwọn ará-ìta fún wọn nítorí pé wọ́n wàásù ìbatisí nípa ìrìbọmi. Òmíràn tí ó farajọ ọ́ ni, àwọn onísìn Methodist tí wọ́n tẹ́wọ́gba orúkọ náà tí àwọn ará-ìta fún wọn. Nípa bí àwọn onísìn Society of Friends ṣe rí orúkọ wọn Quakers gbà, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà Quaker (amúniwárìrì) ni a ń lò ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àbùkù sí Fox [olùdásílẹ̀ rẹ̀], ẹni tí ó sọ fún adájọ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan pé kí ó ‘wárìrì fún Ọ̀rọ̀ Oluwa.’ Adájọ́ náà pè Fox ni ‘amúniwárìrì.’”
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Ta ni “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú,” àwọn wo sì ni “awọn ara ilé”?
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ àkọ́kọ́ ní àkókò òde-òní?
◻ Èéṣe tí orúkọ titun náà, Ẹlẹ́rìí Jehofa, fi bá a mu wẹ́kú?
◻ Àwọn òtítọ́ wo tí ó pe àfiyèsí ni a ṣípayá ní 1935?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
C. T. Russell àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ rẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí kálẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ìyìn lọ sọ́dọ̀ Jehofa