ORÍ KẸẸ̀Ẹ́DÓGÚN
Bíbọlá fún Àwọn Òbí Wa Àgbàlagbà
1. Gbèsè kí ni a jẹ àwọn òbí wa, nítorí èyí, báwo ni ó ṣe yẹ kí a nímọ̀lára, kí a sì hùwà sí wọn?
ỌKÙNRIN ọlọgbọ́n ìgbàanì gbani nímọ̀ràn pé: “Fetí sí ti bàbá rẹ tí ó bí ọ, má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí ó bá gbó.” (Owe 23:22) Ìwọ lè sọ pé, ‘Èmi ki yóò ṣe ìyẹn láé!’ Dípò gígan ìyá wa—tàbí bàbá wa—ọ̀pọ̀ nínú wa ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún wọn. A mọ̀ pé a jẹ wọ́n ní gbèsè ohun púpọ̀. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn òbí wa fún wa ní ìwàláàyè. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa ni Orísun ìwàláàyè, láìsí àwọn òbí wa, a kì bá tí wà láàyè. Kò sí ohun tí a lè fún àwọn òbí wa tí ó lè ṣeyebíye tó ìwàláàyè fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ronú nípa ìfara-ẹni-rúbọ, aájò alánìíyàn, ìnáwó, àti àbójútó onífẹ̀ẹ́ tí títọ́ ọmọ láti ọmọdé jòjòló di àgbàlagbà ń náni. Ẹ wo bí ó ti lọ́gbọ́n nínú tó nígbà náà, pé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbani nímọ̀ràn pé: “Bọlá fún baba rẹ ati ìyá rẹ . . . kí nǹkan lè lọ dáadáa fún ọ kí iwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀-ayé”!—Efesu 6:2, 3.
MÍMỌ ÀWỌN ÀÌNÍ TI ÈRÒ ÌMỌ̀LÁRA
2. Báwo ni àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà ṣe lè san “ìsanfidípò yíyẹ” fún àwọn òbí wọn?
2 Aposteli Paulu kọ̀wé sí àwọn Kristian pé: “Kí [awọn ọmọ tabi awọn ọmọ-ọmọ] kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ lati máa fi ìfọkànsin Ọlọrun ṣèwàhù ninu agbo ilé tiwọn kí wọ́n sì máa san ìsanfidípò yíyẹ fún awọn òbí wọn ati awọn òbí wọn àgbà, nitori tí èyí ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọrun.” (1 Timoteu 5:4) Àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà ń pèsè “ìsanfidípò yíyẹ” yìí nípa fífi ìmọrírì hàn fún àwọn ọdún onífẹ̀ẹ́, oníṣẹ́ àṣekára, àti aláájò tí àwọn òbí wọn àti àwọn òbí wọn àgbà ti lò lé wọn lórí. Ọ̀nà kan tí àwọn ọmọ lè gbà ṣe èyí jẹ́ nípa mímọ̀ pé, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yòókù, àwọn àgbàlagbà nílò ìfẹ́ àti ìmúdánilójú—gidigidi gan-an. Gẹ́gẹ́ bíi gbogbo wa, wọ́n ní láti mọ̀ pé a kà wọ́n sí pàtàkì. Wọ́n ní láti nímọ̀lára pé ìgbésí ayé wọn nítumọ̀.
3. Báwo ni a ṣe lè bọlá fún àwọn òbí wa àti àwọn òbí wa àgbà?
3 Nítorí náà, a lè bọlá fún àwọn òbí wa àti àwọn òbí wa àgbà nípa jíjẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. (1 Korinti 16:14) Bí àwọn òbí wa kì í bá bá wa gbé, a gbọ́dọ̀ rántí pé gbígbúròó wa ṣe pàtàkì púpọ̀ fún wọn. Lẹ́tà amóríyá gágá, ìkésíni lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù, tàbí ìbẹ̀wò lè dá kún ayọ̀ wọn gidigidi. Miyo, tí ń gbé ní Japan, kọ̀wé nígbà tí ó wà ní ẹni ọdún 82 pé: “Ọmọbìnrin mi [tí ọkọ rẹ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ arìnrìn àjò] máa ń sọ fún mi pé: ‘Màmá, jọ̀wọ́ bá wa “rìnrìn àjò.”’ Ó ń fi orúkọ ìjọ àti nọ́ḿbà tẹlifóònù ibi tí mo ti lè kàn sí wọn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ránṣẹ́ sí mi. Mo lè ṣí àwòrán ilẹ̀ tí mo ní, kí n sì sọ pé: ‘Ibí yìí ni wọ́n wà nísinsìnyí!’ Gbogbo ìgbà ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa fún fífi irú ọmọ báyìí ta mí lọ́rẹ.”
ṢÍṢÈRÀNWỌ́ NÍPA BÍBÓJÚ TÓ ÀWỌN ÀÌNÍ TI ARA
4. Báwo ni òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ìsìn àwọn Júù ṣe fún ìwà ìkà gbáà sí àwọn òbí àgbàlagbà níṣìírí?
4 Bíbọlá fún àwọn òbí ẹni ha kan bíbójú tó àwọn àìní wọn nípa ti ara pẹ̀lú bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ó kàn án. Ní ọjọ́ Jesu, àwọn aṣáájú ìsìn Júù gbé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ náà lárugẹ pé, bí ẹnì kan bá sọ kedere pé owó tàbí ohun ìní òún jẹ́ “ẹ̀bùn tí a yàsímímọ́ fún Ọlọrun,” kò sí lábẹ́ ojúṣe lílò ó láti bójú tó àwọn òbí rẹ̀ mọ́. (Matteu 15:3-6) Ẹ wo irú ìwà ìkà gbáà tí èyí jẹ́! Ní ti gidi, ń ṣe ni àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn ń ki àwọn ènìyàn láyà láti ṣàìbọlá fún àwọn òbí wọn, ṣùgbọ́n láti fojú tín-ínrín wọn nípa fífi ìmọtara-ẹni-nìkan sẹ́ ipò àìní wọn. Àwa kò fẹ́ ṣe èyí láé!—Deuteronomi 27:16.
5. Láìka ìpèsè tí ìjọba ṣe ní àwọn orílẹ̀-èdè kan sí, èé ṣe tí bíbọlá fún àwọn òbí ẹni fi kan gbígbọ́ bùkátà lórí wọn nígbà míràn?
5 Ní ọ̀pọ̀ órílẹ̀-èdè lónìí, àwọn ètò ìṣètìlẹ́yìn tí ìjọba dá sílẹ̀ ń bójú tó díẹ̀ lára àwọn ohun ti ara tí àwọn àgbàlagbà ṣaláìní, irú bí oúnjẹ, aṣọ, àti ibùgbé. Ní àfikún sí ìyẹn, ó ti lè ṣeé ṣe fún àwọn àgbàlagbà náà fúnra wọn láti tọ́jú àwọn ohun ti ara díẹ̀ pamọ́ fún ọjọ́ ogbó wọn. Ṣùgbọ́n bí àwọn ìpèsè wọ̀nyí bá tán tàbí bí wọ́n bá ṣàìtó, àwọn ọmọ ń bọlá fún àwọn òbí wọn nípa ṣíṣe ohun tí wọ́n lè ṣe láti bójú tó àwọn àìní àwọn òbí wọn. Ní ti gidi, bíbójú tó àwọn òbí ọlọ́jọ́lórí jẹ́ ẹ̀rí ìfọkànsin Ọlọrun, ìyẹn ni pé, ìfọkànsìn ẹni sí Jehofa Ọlọrun, Olùdásílẹ̀ ètò ìdílé.
ÌFẸ́ ÀTI ÌFARA-ẸNI-RÚBỌ
6. Àwọn ètò ibùgbé wo ni àwọn kan ti ṣe láti lè bójú tó àìní àwọn òbí wọn?
6 Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà ti fi pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfara-ẹni-rúbọ bójú tó àìní àwọn òbí wọn tí ó ṣaláìlera. Àwọn kan ti mú àwọn òbí wọn wá láti gbé pẹ̀lú wọn tàbí ṣí lọ sí ìtòsí wọn. Àwọn mìíràn ti ṣí lọ sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, irú ètò bẹ́ẹ̀ ti já sí ìbùkún fún àwọn òbí àti àwọn ọmọ.
7. Èé ṣe tí ó fi dára láti má ṣe tètè sáré ṣèpinnu jù nínú ọ̀ràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn òbí àgbàlagbà?
7 Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà míràn, irú ìṣílọ bẹ́ẹ̀ kì í yọrí sí rere. Èé ṣe? Bóyá nítorí pé a ti tètè sáré ṣèpinnu jù tàbí pé orí ìmọ̀lára nìkan ni a gbé ìpinnu náà kà. Pẹ̀lú ọgbọ́n, Bibeli kìlọ̀ pé: “Amòye ènìyàn wo ọ̀nà ara rẹ̀ rere.” (Owe 14:15) Fún àpẹẹrẹ, ká sọ pé ìyá rẹ, àgbàlagbà, níṣòro dídágbé, tí o sì rò pé ó lè ṣe é láǹfààní láti wá gbé pẹ̀lú rẹ. Bí o ti ń fi òye wo ọ̀nà ara rẹ, o lè gbé àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò: Kí ni àwọn àìní rẹ̀ ní ti gidi? Àwọn ìṣètò àdáni tàbí ti ìjọba, tí ó pèsè ojútùú àfirọ́pò ṣíṣètẹ́wọ́gbà ha wà bí? Òún ha fẹ́ láti ṣí lọ bí? Bí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ni èyí yóò ṣe nípa lórí ìgbésí ayé rẹ̀? Òun yóò ha ní láti fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ sẹ́yìn bí? Báwo ni èyí yóò ṣe nípa lórí èrò ìmọ̀lára rẹ̀? O ha ti jíròrò gbogbo nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú rẹ̀ bí? Báwo ni irú ìṣílọ bẹ́ẹ̀ yóò ṣe nípa lórí rẹ, lórí alábàáṣègbéyàwó rẹ, lórí àwọn ọmọ rẹ? Bí ìyá rẹ bá nílò àbójútó, ta ni yóò pèsè rẹ̀? Ẹ ha lè pín ẹrù iṣẹ́ náà bí? O ha ti jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ọ̀ràn náà kàn gbọ̀ngbọ̀n bí?
8. Àwọn wo ni ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti bá fikùn lukùn nígbà tí o bá ń pinnu bí o ṣe lè ran àwọn òbí rẹ àgbàlagbà lọ́wọ́?
8 Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé gbogbo àwọn ọmọ inú ìdílé ni ẹrù iṣẹ́ àbójútó náà já lé lórí, ó lè bọ́gbọ́n mu láti pe ìpàdé gbogbo ìdílé, kí gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé lè ṣàjọpín nínu ṣíṣe ìpinnu. Bíbá àwọn alàgbà inú ìjọ Kristian tàbí àwọn ọ̀rẹ́ tí ó ti dojú kọ irú ipò kan náà sọ̀rọ̀ lè ṣèrànwọ́ pẹ̀lú. Bibeli kìlọ̀ pé: “Láìsí ìgbìmọ̀, èrò a dasán, ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìmọ̀, wọn a fi ìdí múlẹ̀.”—Owe 15:22.
JẸ́ AFỌ̀RÀN-RORA-ẸNI-WÒ ÀTI OLÓYE
9, 10. (a) Láìka ọjọ́ ogbó wọn sí, ìgbatẹnirò wo ni ó yẹ kí a fi hàn sí àwọn àgbàlagbà? (b) Láìka ìgbésẹ̀ tí ọmọ tí ó ti dàgbà gbé nítorí àwọn òbí rẹ̀ sí, kí ni ó yẹ kí ó máa fún wọn nígbà gbogbo?
9 Bíbọlá fún àwọn òbí wa àgbàlagbà ń béèrè ẹ̀mí ìfọ̀ràn-rora-ẹni-wò àti òye. Bí wàhálà ọjọ́ ogbó ti ń yọjú, ó túbọ̀ lè máa nira fún àwọn àgbàlagbà láti rìn, jẹun, àti láti rántí nǹkan. Wọ́n lè nílò ìrànlọ́wọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ máa ń ṣàníyàn jù nípa ààbò àwọn òbí wọn, wọ́n sì máa ń gbìyànjú láti pèsè ìtọ́sọ́nà. Ṣùgbọ́n, àgbàlagbà ni àwọn arúgbó, pẹ̀lú àìmọye ọdún tí wọ́n ti fi to ọgbọ́n àti ìrírí jọ pelemọ, pẹ̀lú àìmọye ọdún tí wọ́n ti fi bójú tó ara wọn, tí wọ́n sì ti dá ṣèpinnu. Iyì àti ọ̀wọ̀ ara ẹni wọn lè ti rọ̀ mọ́ ipa wọn gẹ́gẹ́ bí òbí àti àgbàlagbà kan. Àwọn òbí tí wọ́n ronú pé àwọ́n ní láti fi ara àwọn sábẹ́ àkóso àwọn ọmọ wọn lè soríkọ́ tàbí bínú. Àwọn kan máa ń kọ̀, wọ́n sì máa ń ta ko ohun tí wọ́n lè rí gẹ́gẹ́ bí ìsapá láti já òmìnira wọn gbà kúrò lọ́wọ́ wọn.
10 Kò sí ojútùú rírọrùn sí irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìwà inú rere láti yọ̀ǹda fún àwọn òbí àgbàlagbà láti bójú tó ara wọn, kí wọ́n sì dá ṣèpinnu dé ìwọ̀n tí ó bá ṣeé ṣe. Kì í ṣe ìwà ọlọgbọ́n láti pinnu ohun tí ó dára jù lọ fún àwọn òbí rẹ láìkọ́kọ́ jíròrò pẹ̀lú wọn ná. Wọ́n lè ti pàdánù ohun púpọ̀ nítorí ọjọ́ ogbó. Má dù wọ́n ni ohun tí ó kù fún wọn. Ìwọ́ lè rí i pé, bí o bá ti ń yẹra tó láti ṣàkóso àwọn òbí rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ipò ìbátan rẹ pẹ̀lú wọn yóò ṣe máa sunwọ̀n sí i. Inú wọn yóò dùn, inú ìwọ pẹ̀lú yóò sì dùn. Bí o tilẹ̀ ní láti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin lórí àwọn nǹkan kan fún ire wọn, bíbọlá fún àwọn òbí rẹ ń béèrè pé kí o fún wọn ní iyì àti ọ̀wọ̀ tí ó yẹ wọ́n. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbani nímọ̀ràn pé: “Kí ìwọ kí ó sì dìde dúró níwájú orí ewú, kí o sì bọ̀wọ̀ fún ojú arúgbó.”—Lefitiku 19:32.
PÍPA Ẹ̀MÍ ÌRÒNÚ YÍYẸ MỌ́
11-13. Bí ọmọ tí ó ti dàgbà kò bá ní ipò ìbátan tí ó dára pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ láti ilẹ̀ wá, báwo ni ó ṣì ṣe lè bójú tó ìpènijà ṣíṣaájò wọn ní ọjọ́ ogbó wọn?
11 Nígbà míràn, ìṣòro tí àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà ń dojú kọ nínú bíbọlá fún àwọn òbí wọn tí ó ti darúgbó ní í ṣe pẹ̀lú ipò ìbátan tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn òbí wọn nígbà tí wọ́n wà ní kékeré. Bóyá bàbá rẹ kò fi ọ̀yàyà àti ìfẹ́ hàn sí ọ, ìyá rẹ jẹ gàba lé ọ lórí, ó sì rorò. O ṣì lè ní ìjákulẹ̀, ìbínú, tàbí ìrora, nítorí wọn kì í ṣe irú òbí tí o fẹ́ kí wọ́n jẹ́. O ha lè ṣẹ́pá irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ bí?a
12 Basse, tí a tọ́ dàgbà ní Finland, ròyìn pé: “Ọkọ ìyá mi ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olóyè SS ní Nazi Germany. Ó máa ń tètè bínú, kò sì ṣeé sún mọ́ ní àkókò yìí. Ó lu ìyá mi bolẹ̀ ní àìmọye ìgbà lójú mi. Nígbà kan, nígbà tí inú rẹ̀ ru sí mi, ó fi bẹ́líìtì rẹ̀ làkàlàkà, ó sì fi irin rẹ̀ gbá mí lójú. Ó gbá mi débi pé mo tàkìtì lórí ibùsùn.”
13 Síbẹ̀, ó ní àwọn ànímọ́ mìíràn. Basse fi kún un pé: “Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ó ṣiṣẹ́ kára, kò sì yẹ gbígbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀ sílẹ̀. Kò hùwà sí mi bíi bàbá rí, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé a ti ṣá a lọ́gbẹ́ nípa ti èrò ìmọ̀lára. Ní kékeré ni ìyá rẹ̀ ti tì í síta. Gbogbo ìgbà ni ó máa ń jà, ó sì wọnú ogun gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́kùnrin kan. Mo lè lóye rẹ̀ dé ìwọ̀n àyè kan, n kò sì dá a lẹ́bi. Nígbà tí mo dàgbà, tí ara bàbá mi kò sì yá, mo fẹ́ láti ṣèrànlọ́wọ́ fún un débi tí agbára mi mọ, títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Kò rọrùn rárá, ṣùgbọ́n mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe. Mo gbìyànjú láti jẹ́ ọmọ rere títí dé òpin, mo sì rò pé ó gbà pé mo ṣe bẹ́ẹ̀.”
14. Ẹsẹ ìwé mímọ́ wo ni ó ṣeé mú lò nínú gbogbo ipò, títí kan àwọn tí ń dìde nínú bíbójú tó àwọn òbí àgbàlagbà?
14 Nínú ọ̀ràn ìdílé, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú àwọn ọ̀ràn yòókù, ìmọ̀ràn Bibeli náà ṣeé mú lò pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inúrere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú, ìwàtútù, ati ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nìkínní kejì kí ẹ sì máa dáríji ara yín fàlàlà lẹ́nìkínní kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní èrèdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jehofa ti dáríjì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹlu máa ṣe.”—Kolosse 3:12, 13.
ÀWỌN TÍ Ń BÓJÚ TÓNI NÍLÒ ÀBÓJÚTÓ PẸ̀LÚ
15. Èé ṣe tí bíbójú tó àwọn òbí fi ń múni soríkọ́ nígbà míràn?
15 Ṣíṣaájò òbí tí ó ṣaláìlera jẹ́ iṣẹ́ ńlá, tí ó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsapá, ẹrù iṣẹ́, àti àkókò gígùn. Ṣùgbọ́n ọ̀ràn nípa èrò ìmọ̀lára ni ó nira jù lọ. Ó ń soni lórí kọ́ láti máa wo àwọn òbí rẹ bí wọ́n ti ń pàdánù ìlera, agbára ìrántí, àti òmìnira wọn. Sandy, tí ó wá láti Puerto Rico, ròyìn pé: “Ìyá mi ni igi lẹ́yìn ọgbà nínú ìdílé wa. Ó ń roni lára gan-an láti rí bí ó ṣe ń jìyà, tí a sì ní láti ṣaájò rẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í tiro; láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ó di ẹni tí ń fi ọ̀pá rìn, lẹ́yìn náà, ó lo irin ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin tí arọ ń rọ̀ lé láti fi rìn, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó di ẹni tí ń lo kẹ̀kẹ́ arọ. Láti ìgbà náà wá ipò rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í burú sí i, títí tí ó fi kú. Ó ní àrùn jẹjẹrẹ inú egungun, ó sì nílò àbójútó déédéé—tọ̀sán-tòru. A máa ń wẹ̀ fún un, a ń fi oúnjẹ nù ún, a sì máa ń kàwé fún un. Kò rọrùn rárá—pàápàá ní ti èrò ìmọ̀lára. Nígbà tí ó hàn sí mi pé ìyá mi ń kú lọ, mo sunkún, nítorí pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gidi gan-an.”
16, 17. Ìmọ̀ràn wo ni ó lè ran abójútóni lọ́wọ́ láti ní ojú ìwòye tí ó wà déédéé nípa àwọn nǹkan?
16 Bí o bá bá ara rẹ nínú irú ipò kan náà, kí ni o lè ṣe láti kojú rẹ̀? Fífetí sí Jehofa nípa kíka Bibeli àti bíbá a sọ̀rọ̀ nínú àdúrà yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ gidigidi. (Filippi 4:6, 7) Ní ọ̀nà ti ara, rí i dájú pé o ń jẹ àwọn oúnjẹ tí ó ní àwọn èròjà tí ń ṣara lóore, kí o sì máa gbìyànjú láti sùn dáadáa. Nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò wà ní ipò tí ó túbọ̀ dára, nípa ti èrò ìmọ̀lára àti ti ara, láti ṣaájò àyànfẹ́ rẹ. Bóyá o lè ṣètò láti ní ìsinmi díẹ̀ lẹ́nu ìlànà ìṣiṣẹ́ déédéé ojoojúmọ́ rẹ. Bí kò bá tilẹ̀ ṣeé ṣe fún ọ láti lọludé lọ, ó ṣì bọ́gbọ́n mu láti ṣètò àkókò díẹ̀ láti fi sinmi. Láti lè rí àyè lọ sinmi, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti ṣètò fún ẹnì kan láti dúró ti òbí rẹ tí ń ṣòjòjò náà.
17 Kò ṣàjèjì fún àwọn àgbàlagbà tí wọ́n jẹ́ abójútóni láti retí ohun tí agbára wọn kò ká lọ́wọ́ ara wọn. Ṣùgbọ́n, má ṣe dá ara rẹ lẹ́bi fún ohun tí o kò lè ṣe. Ní àwọn ipò àyíká kan, o lè ní láti gbé àyànfẹ́ rẹ lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó. Bí o bá jẹ́ abójútóni, àwọn góńgó tí agbára rẹ lè ka ni kí o gbé kalẹ̀. O gbọ́dọ̀ wà déédéé nípa àìní àwọn ọmọ rẹ, alábàáṣègbéyàwó rẹ, àti ti ara rẹ pẹ̀lú, kì í ṣe ti àwọn òbí rẹ nìkan.
OKUN TÍ Ó RÉ KỌJÁ TI Ẹ̀DÁ
18, 19. Ìlérí ìtìlẹyìn wo ni Jehofa ṣe, ìrírí wo ni ó sì fi hàn pé ó ń pa ìlérí yìí mọ́?
18 Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, Jehofa fi tìfẹ́tìfẹ́ pèsè ìtọ́sọ́nà tí ó lè ṣèrànwọ́ gidigidi fún ẹnì kan nínú bíbojú tó àwọn òbí tí ń darúgbó, ṣùgbọ́n ìyẹn nìkan kọ́ ni ìrànlọ́wọ́ tí ó pèsè. Lábẹ́ ìmísí, onipsalmu náà kọ̀wé pé: “Oluwa wà létí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí ń ké pè é. . . . Yóò gbọ́ igbe wọn pẹ̀lú yóò sì gbà wọ́n.” Jehofa yóò gba àwọn olùṣòtítọ́, tàbí dá wọn sí, la àwọn ipò tí ó nira jù lọ pàápàá kọjá.—Orin Dafidi 145:18, 19.
19 Myrna, ní ilẹ̀ Philippines, nírìírí èyí nígbà tí ó ń ṣaájò ìyá rẹ̀, tí àrùn ẹ̀gbà sọ di aláìlèdáṣe-ohunkóhun. Myrna kọ̀wé pé: “Kò sí ohun tí ń múni soríkọ́ tó rírí àyànfẹ́ rẹ tí ń jìyà, tí kò ṣeé ṣe fún un láti sọ ibi tí ń dùn ún fún ọ. Ń ṣe ni ó dà bíi pé mo rí i tí ó ń rọra rì sínú omi, tí n kò sì lè ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń kúnlẹ̀ àdúrà tí mo sì máa ń sọ fún Jehofa nípa bí ó ti rẹ̀ mí tó. Mo ké jáde bíi Dafidi, tí ó fi taratara bẹ Jehofa láti fi omijé òun sínú ìgò, kí ó sì rántí òun. [Orin Dafidi 56:8] Gẹ́gẹ́ bí Jehofa sì ti ṣèlérí, ó fún mi ní agbára tí mo nílò. ‘Oluwa ni aláfẹ̀yìntì mi.’”—Orin Dafidi 18:18.
20. Àwọn ìlérí Bibeli wo ní ń ran àwọn abójútóni lọ́wọ́ láti pa ojú ìwòye nǹkan yóò dára mọ́, bí ẹni tí wọ́n ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀ tilẹ̀ kú?
20 A máa ń sọ pé, ṣíṣaájò àwọn òbí ọlọ́jọ́lórí jẹ́ “ìtàn tí kì í ní ìgbẹ̀yìn tí ó dára.” Láìka ìsapá tí ó dára jù lọ ní bíbójú tó wọn sí, àwọn arúgbó wa lè kú, gẹ́gẹ́ bí ìyá Myrna ti ṣe. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jehofa mọ̀ pé ikú kì í ṣe òpin ìtàn náà. Aposteli Paulu sọ pé: “Mo sì ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọrun . . . pé àjíǹde awọn olódodo ati awọn aláìṣòdodo yoo wà.” (Ìṣe 24:15) Àwọn tí ó ti pàdánù àwọn òbí wọn àgbàlagbà nínú ikú ń rí ìtùnú gbà nínú ìrètí àjíǹde pa pọ̀ pẹ̀lú ìlérí ayé tuntun aládùn kan, tí yóò ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, nínú èyí tí “ikú kì yoo sì sí mọ́.”—Ìṣípayá 21:4.
21. Ire wo ní ń jẹ yọ láti inú bíbọlá fún àwọn òbí wa àgbàlagbà?
21 Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún àwọn òbí wọn, bí àwọn wọ̀nyí tilẹ̀ lè ti darúgbó. (Owe 23:22-24) Wọ́n ń bọlá fún wọn. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń nírìírí ohun tí òwe onímìísí náà sọ, pé: “Bàbá rẹ àti ìyá rẹ yóò yọ̀, inú ẹni tí ó bí ọ yóò dùn.” (Owe 23:25) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwọn tí ń bọlá fún àwọn òbí wọn àgbàlagbà ń mú inú Jehofa Ọlọrun dùn, wọ́n sì tún ń bọlá fún un.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kì í ṣe àwọn ipò tí àwọn òbí ti jẹ̀bi ṣíṣi agbára àti ìgbẹ́kẹ̀lé tí a ní nínú wọn lò pátápátá, débi tí a lè sọ pé wọ́n jẹ̀bi ìwà ọ̀daràn, ni a ń sọ níhìn-ín.
BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN . . . WA LÁTI BỌLÁ FÚN ÀWỌN ÒBÍ WA ÀGBÀLAGBÀ?
A gbọ́dọ̀ san àsanfidípò yíyẹ fún àwọn òbí wa àti àwọn òbí wa àgbà.—1 Timoteu 5:4.
Gbogbo àwọn àlámọ̀rí wa gbọ́dọ̀ máa ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́.—1 Korinti 16:14.
A kò gbọdọ̀ sáré jù láti ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì.—Owe 14:15.
A gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wa àgbàlagbà, àní bí wọ́n bá tilẹ̀ ń ṣàìsàn, tí wọ́n sì ń gbó lọ pàápàá.—Lefitiku 19:32.
Kì í ṣe títí gbére ni a óò máa dojú kọ dídarúgbó, kí a sì kú.—Ìṣípayá 21:4.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 179]
Kì í ṣe ìwà ọlọgbọ́n láti pinnu fún òbí kan láìkọ́kọ́ bá a sọ̀rọ̀ ná