Àwọn Ìdílé Kristian Ń Ran Àwọn Àgbàlagbà Lọ́wọ́
“Máṣe ṣá mi tì ní ìgbà ogbó; máṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí agbára mi bá yẹ̀.”—ORIN DAFIDI 71:9.
1. Báwo ni a ṣe ń bá àwọn àgbàlagbà nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ lò?
“ÀWỌN ìwádìíkiri fihàn pé mẹ́fà nínú méje (86%) àwọn àgbàlagbà tí a lò ní ìlòkulò ni ìdílé tiwọn fúnraawọn bá lò lọ́nà tí kò dára,” ni ìwé The Wall Street Journal sọ. Ìwé-ìròyìn Modern Maturity sọ pé: “Lílo àwọn àgbàlagbà nílòkulò ni kìkì [ìwà-ipá ìdílé] tí ó dé kẹ́yìn tí ó kù kí ó wá ọ̀nà jáde kúrò nínú ìyẹ̀wù bọ́ sójú ìwé-ìròyìn orílẹ̀-èdè.” Bẹ́ẹ̀ni, àwọn àgbàlagbà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣẹ̀dálẹ̀ ti di ẹran-ìjẹ ìloninílòkulò àti ìpatì búburújáì. Àkókò tiwa nítòótọ́ ni ìgbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ jẹ́ “olùfẹ́ ti araawọn, . . . aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́, aláìnífẹ̀ẹ́.”—2 Timoteu 3:1-3.
2. Ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu, ojú wo ni Jehofa fi ń wo àwọn àgbàlagbà?
2 Síbẹ̀, bí ó ṣe yẹ kí á bá àwọn àgbàlagbà lò kọ́ nìyẹn ní Israeli ìgbàanì. Òfin sọ pé: “Kí ìwọ kí ó sì dìde dúró níwájú orí-ewú, kí o sì bọ̀wọ̀ fún ojú arúgbó, kí o sì bẹ̀rù Ọlọrun rẹ: Èmi ni OLUWA.” Ìwé àwọn òwe ọlọgbọ́n tí a mísí gbà wá nímọ̀ràn pé: “Fetísí ti baba rẹ tí ó bí ọ, má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí ó bá gbó.” Ó pàṣẹ pé: “Ọmọ mi, gbọ́ ẹ̀kọ́ baba rẹ, kí ìwọ kí ó má sì kọ òfin ìyá rẹ sílẹ̀.” Òfin Mose kọ́ni ní ọ̀wọ̀ àti ìkàsí fún àwọn àgbà lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ní kedere, Jehofa fẹ́ pé kí á ḅọlá fún àwọn àgbàlagbà.—Lefitiku 19:32; Owe 1:8; 23:22.
Títọ́jú Àwọn Àgbàlagbà ní Àwọn Àkókò tí A Kọ Bibeli
3. Báwo ni Josefu ṣe fi ìyọ́nú hàn fún baba rẹ̀ arúgbó?
3 Ọ̀wọ̀ ni a níláti fihàn kìí ṣe nínú àwọn ọ̀rọ̀ nìkan ṣùgbọ́n nínú àwọn ìṣesí onígbatẹnirò pẹ̀lú. Josefu fi ìyọ́nú ńláǹlà hàn fún baba rẹ̀ tí ó jẹ́ àgbàlagbà. Ó fẹ́ kí Jakobu rin ìrìn-àjò láti Kenaani wá sí Egipti, ibi tí ó jìnnà ju ọ̀ọ́dúnrún kìlómítà (igba ibùsọ̀) lọ. Nítorí náà Josefu fi “kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru ohun rere Egipti, àti abo-kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru ọkà àti àkàrà àti oúnjẹ fún baba rẹ̀ ní ọ̀nà” ránṣẹ́ sí Jakobu. Nígbà tí Jakobu dé sí Goṣeni, Josefu lọ bá a “òun sì rọ̀ mọ́ ọn ní ọrùn, ó sì sọkún sí i ní ọrùn pẹ́títí.” Josefu da ìfẹ́ni jíjinlẹ̀ bo baba rẹ̀. Ẹ wo irú àpẹẹrẹ tí ń runisókè nípa ìdàníyàn fún àwọn àgbàlagbà tí èyí jẹ́!—Genesisi 45:23; 46:5, 29.
4. Èéṣe tí Rutu fi jẹ́ àpẹẹrẹ rere láti tẹ̀lé?
4 Àwòkọ́ṣe mèremère mìíràn láti tẹ̀lé nípa inúrere fún àwọn àgbàlagbà ni Rutu. Bí òun tilẹ̀ jẹ́ Kèfèrí kan, ó dìrọ̀ mọ́ Naomi, ìyakọ rẹ̀ opó tíí ṣe Ju, tí ó sì jẹ́ àgbàlagbà. Ó fi àwọn ènìyàn tirẹ̀ fúnraarẹ̀ sílẹ̀ ó sì dágbálé ewu ṣíṣaláìrí ọkọ mìíràn fẹ́. Nígbà tí Naomi rọ̀ ọ́ láti padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, Rutu dáhùn pẹ̀lú díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ tí ó dára jùlọ nínú Bibeli pé: “Máṣe rọ̀ mí láti fi ọ́ sílẹ̀, tàbí láti padà kúrò lẹ́hìn rẹ: nítorí ibi tí ìwọ́ bá lọ, ni èmi ó lọ; ibi tí ìwọ bá sì wọ̀, ni èmi ó wọ̀: àwọn ènìyàn rẹ ni yóò máa ṣe ènìyàn mi, Ọlọrun rẹ ni yóò sì máa ṣe Ọlọrun mi: Ibi tí ìwọ bá kú ni èmi ó kú sí, níbẹ̀ ni a ó sì sin mí: kí OLUWA kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ohun kan bíkòṣe ikú bá ya ìwọ àti èmi.” (Rutu 1:16, 17) Rutu tún fi àwọn ànímọ́ rere hàn nígbà tí ó múratán láti fẹ́ Boasi tí ó jẹ́ àgbàlagbà lábẹ́ ìṣètò ìgbéyàwó ìṣúnilópó.—Rutu, orí 2 si 4.
5. Àwọn ànímọ́ wo ni Jesu fihàn ní bíbá àwọn ènìyàn lò?
5 Jesu fi àpẹẹrẹ tí ó jọra lélẹ̀ nínú àwọn ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn. Òun jẹ́ onísùúrù, oníyọ̀ọ́nú, onínúure, àti atunilára. Ó ní ọkàn-ìfẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan nínú ọkùnrin aláìní kan tí ó ti jẹ́ abirùn, tí kò lè rìn, fún ọdun méjìdínlógójì ó sì wò ó sàn. Ó fi ìgbatẹnirò hàn fún àwọn opó. (Luku 7:11-15; Johannu 5:1-9) Àní nígbà ìroragógó ti ikú onírora rẹ̀ lórí òpó-igi ìdálóró pàápàá, ó rí i dájú pé ìyá rẹ̀, bóyá tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá ẹni àádọ́ta ọdún, ni a óò bójútó. Àyàfi sí àwọn ọ̀tá rẹ̀ alágàbàgebè, Jesu jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ atunilára fún gbogbo ènìyàn. Nípa báyìí, òun lè sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣíṣẹ̀ẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi ó sì fi ìsinmi fún yín. Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi; ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.”—Matteu 9:36; 11:28, 29; Johannu 19:25-27.
Àwọn Wo Ni Ìgbatẹnirò Tọ́ Sí?
6. (a) Àwọn wo ní wọ́n lẹ́tọ̀ọ́sí àkànṣe àbójútó? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni a lè béèrè lọ́wọ́ araawa?
6 Níwọ̀n bí Jehofa Ọlọrun àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, ti fi irú àwọn àpẹẹrẹ rere bẹ́ẹ̀ lélẹ̀ nínú ọ̀ràn títọ́jú ẹni, ó wulẹ̀ yẹ pé kí àwọn Kristian olùṣèyàsímímọ́ ṣàfarawé àpẹẹrẹ wọn. Láàárín wa a ní àwọn kan tí wọ́n ti ṣíṣẹ̀ẹ́ tí a sì ti di ẹrù wíwúwo lé lórí fún ọ̀pọ̀ ọdún—àwọn arúgbó arákùnrin àti arábìnrin àgbàlagbà tí wọ́n ti wọnú àwọn ọdún ìjórẹ̀yìn ìgbésí-ayé wọn. Àwọn kan lè jẹ́ òbí wa tàbí òbí wa àgbà. Àwa ha fọwọ́ yẹpẹrẹ mú wọn bí? Àwá ha jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún wọn tí a sì ń kẹ́ wọn gẹ̀gẹ̀ bí? Tàbí àwá ha mọrírì ìrírí àti ọgbọ́n wọn gbígbòòrò nítòótọ́ bí? Lóòótọ́, àwọn kan lè dán sùúrù wa wò pẹ̀lú àwọn àṣà-yíyọyẹ́ àti àwọn ìwà tí kò ṣàìwọ́pọ̀ fún ọjọ́ ogbó. Ṣùgbọ́n béèrè lọ́wọ́ araàrẹ, ‘Èmi yóò ha ṣe ohun kan tí ó yàtọ̀ lábẹ́ irú àwọn ipò wọ̀nyẹn bí?’
7. Kí ni ó ṣàkàwé àìní náà fún níní ìbánikẹ́dùn fún àwọn arúgbó?
7 Ìtàn kan tí ó wọni lọ́kàn wa láti Àárín-Gbùngbùn Ìlà-Oòrùn nípa ìyọ́nú ọ̀dọ́mọdébìnrin kan fún àwọn àgbàlagbà. Ìyá-àgbà ń ṣèrànlọ́wọ́ nínú ilé-ìdáná tí àwo kan sì ṣèèṣì jábọ́ ní ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì fọ́. Inú òun fúnraarẹ̀ bàjẹ́ nítorí àìjáfáfá rẹ̀; ọmọbìnrin rẹ̀ ni inú sì tilẹ̀ túbọ̀ bí. Ó wá pe ọmọdébìnrin tirẹ̀ kékere ó sì rán an lọ sí ilé-ìtajà àdúgbò láti ra abọ́ onígi kan tí kìí fọ́ fún ìyá-àgbà náà. Ọmọdébìnrin náà padà dé pẹ̀lú abọ́ onígi méjì. Ìyá rẹ̀ fi dandan béèrè pé: “Èéṣe tí o fi ra abọ́ méjì?” Ọmọbìnrin náà, pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀, dáhùn pé: “Ọ̀kan fún màmá-àgbà àti èkejì fún yín nígbà tí ẹ bá darúgbó.” Bẹ́ẹ̀ni, nínú ayé yìí gbogbo wa ni a dojúkọ ìfojúsọ́nà fún dídarúgbó. Àwa kò ha ní mọrírì jíjẹ́ ẹni tí a fi sùúrù àti inúrere bálò bí?—Orin Dafidi 71:9.
8, 9. (a) Irú ọwọ́ wo ni ó yẹ kí á fi mú àwọn àgbà tí wọ́n wà láàárín wa? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn wọnnì tí wọ́n di Kristian lẹ́nu àìpẹ́ yìí níláti rántí?
8 Máṣe gbàgbé pé púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa àgbàlagbà ní àkọsílẹ̀ ìgbòkègbodò Kristian olùṣòtítọ́ lẹ́yìn wọn. Wọ́n lẹ́tọ̀ọ́sí ọlá àti ìgbatẹnirò wa, ìrànlọ́wọ́ onínúure àti ìṣírí wa dájúdájú. Ọkùnrin ọlọgbọ́n náà fi ẹ̀tọ́ sọ pé: “Adé ògo ni orí-ewú, bí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.” Orí eléwú yẹn, ọkùnrin tàbí obìnrin, ni a sì níláti bọ̀wọ̀ fún. Díẹ̀ lára àwọn àgbàlagbà ọkùnrin àti obìnrin wọ̀nyí ṣì ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà olùṣòtítọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin sì ń báa lọ láti fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú àwọn ìjọ; àwọn kan ń ṣe iṣẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò.—Owe 16:31.
9 Paulu gba Timoteu nímọ̀ràn pé: “Máṣe bá alàgbà wí, ṣùgbọ́n kí o máa gbà á níyànjú bí baba; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bí arákùnrin; àwọn àgbà obìnrin bí ìyá; àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin bí arábìnrin nínú ìwà mímọ́.” (1 Timoteu 5:1, 2) Àwọn wọnnì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sínú ìjọ Kristian láti inú ayé aláìlọ́wọ̀ níláti fi àwọn ọ̀rọ̀ Paulu wọ̀nyí, tí a gbékarí ìfẹ́ sọ́kàn ní pàtàkì. Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ máṣe ṣàfarawé ìṣarasíhùwà búburú tí ẹ ti lè rí ní ilé-ẹ̀kọ́. Ẹ máṣe fìbínú hàn sí ìmọ̀ràn onínúure láti ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọn jẹ́ ágbàlagbà. (1 Korinti 13:4-8; Heberu 12:5, 6, 11) Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí àwọn àgbàlagbà nítorí ìlera tí kò dára tàbí àwọn ìṣoro ìnáwó bá nílò ìrànlọ́wọ́, ta ni ó ni ẹrù-iṣẹ́ àkọ́kọ́ láti ṣètìlẹyìn fún wọn?
Ipa ti Ìdílé Nínú Títọ́jú Àwọn Àgbàlagbà
10, 11. (a) Gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti wí, ta ni ó níláti mú ipò iwájú nínú títọ́jú àwọn àgbàlagbà? (b) Èéṣe tí kìí fií fìgbà gbogbo rọrùn láti tọ́jú àwọn àgbàlagbà?
10 Nínú ìjọ Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn ìṣòro dìde lórí ìtọ́jú àwọn opó. Báwo ni aposteli Paulu ṣe fihàn pé a níláti kájú irú àwọn àìní bẹ́ẹ̀? “Bọ̀wọ̀ fún àwọn opó tíí ṣe opó nítòótọ́. Ṣùgbọ́n bí opó kan bá ní ọmọ tàbí ọmọ-ọmọ, jẹ́ kí wọ́n tètè kọ́ àti ṣe ìtọ́jú ilé àwọn tìkáraawọn, kí wọn kí ó sì san oore àwọn òbí wọn padà: nítorí pé èyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọrun. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún àwọn ará ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ.”—1 Timoteu 5:3, 4, 8.
11 Ní àwọn àkókò àìní, àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí wọ́n súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí ni wọ́n níláti jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti ran àwọn àgbàlagbà wọn lọ́wọ́.a Ní ọ̀nà yìí, àwọn ọmọ tí wọ́n ti dàgbà lè fi ìmọrírì hàn fún àwọn ọdún ìfẹ́, iṣẹ́, àti ìtọ́jú tí àwọn òbí wọn ti pèsè. Èyí lè má rọrùn. Bí àwọn ènìyàn ti ń dàgbà síi, agbára wọn máa ń lọ sílẹ̀, àwọn kan sì tilẹ̀ lè di aláìlágbára mọ́. Àwọn mìíràn lè di adánìkànjọpọ́n àti afidandangbọ̀n béèrè, bóyá láìmọ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí a wà ní ọmọ-ọwọ́, àwa pẹ̀lú kò ha jẹ́ adánìkànjọpọ́n ti ń fi dandangbọ̀n béèrè bí? Àwọn òbí wa kò ha sì ní ìháragàgà láti ràn wá lọ́wọ́ bí? Nísinsìnyí nǹkan ti yípadà ní ọjọ́ ogbó wọn. Nítorí náà, kí ni wọ́n nílò? Ìyọ́nú àti sùúrù.—Fiwe 1 Tessalonika 2:7, 8.
12. Àwọn ànímọ́ wo ni a nílò fún títọ́jú àwọn àgbàlagbà—àti gbogbo àwọn mìíràn nínú ìjọ Kristian?
12 Aposteli Paulu fúnni ní ìmọ̀ràn tí ó ṣeéfisílò nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Nítorí náà, bí àyànfẹ́ Ọlọrun, ẹni mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nú wọ̀, ìṣeun, ìrẹ̀lẹ̀, inú tútù, ìpamọ́ra; ẹ máa faradà á fún ara yín, ẹ sì máa dáríji ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan: bí [Jehofa, NW] ti dáríjì yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó máa ṣe pẹ̀lú. Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tíí ṣe àmùrè ìwà pípé.” Bí ó bá yẹ kí a fi irú ìyọ́nú àti ìfẹ́ yìí hàn nínú ìjọ, kò ha yẹ kí á túbọ̀ fihàn sii nínú ìdílé bí?—Kolosse 3:12-14.
13. Àwọn wo ni, yàtọ̀ sí àwọn òbí tàbí òbí-àgbà tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà, ni wọ́n lè nílò ìrànlọ́wọ́?
13 Kìí ṣe àwọn òbí tàbí àwọn òbí-àgbà nìkan ni wọ́n lè nílò irú ìrànlọ́wọ́ yìí nígbà mìíràn ṣùgbọ́n àwọn ìbátan mìíràn tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà pẹ̀lú. Àwọn ẹni àgbà kan tí wọn kò ní àwọn ọmọ ti ṣiṣẹ́sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún nínú iṣẹ́-ìsìn òjíhìn-iṣẹ́-Ọlọ́run, iṣẹ́-òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò, àti ìgbòkègbodò alákòókò kíkún mìíràn. Wọ́n ti fi tòótọ́-tòótọ́ fi Ìjọba náà ṣe àkọ́kọ́ jálẹ̀ ìgbésí-ayé wọn. (Matteu 6:33) Kò ha ní yẹ, nígbà náà, láti fi ẹ̀mí ìtọ́jú ẹni hàn fún wọn bí? Dájúdájú a ní àpẹẹrẹ rere kan nínú ọ̀nà tí Watch Tower Society ń gbà bójútó àwọn mẹ́ḿbà Beteli rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ágbálagbà. Ní orílé-iṣẹ́ Beteli ní Brooklyn àti ní iye àwọn ẹ̀ka Society kan, àwọn arákùnrin àti arábìnrin mélòó kan ń gba àfiyèsí ojoojúmọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí a ti dálẹ́kọ̀ọ́ tí a yàn sẹ́nu òpò yìí. Wọ́n láyọ̀ láti ṣètọ́jú àwọn ẹni àgbà wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ẹni pé wọ́n jẹ́ òbí tàbí òbí-àgbà tiwọn fúnraawọn. Lákòókò kan-náà, wọ́n ń kọ́ ohun púpọ̀ láti inú ìrírí àwọn ẹni àgbà náà.—Owe 22:17.
Ipa ti Ìjọ Nínú Ṣíṣètọ́jú
14. Ìpèsè wo ni a ṣe fún àwọn àgbàlagbà nínú ìjọ Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀?
14 Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè lónìí ní ètò owó-ìfẹ̀hìntì ọjọ́-ogbó àti pẹ̀lú àbójútó ìṣègùn fún àwọn àgbàlagbà tí Orílẹ̀-èdè ń pèsè. Àwọn Kristian lè lo àwọn ìpèsè wọ̀nyí lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ níbi tí wọ́n bá ti lẹ́tọ̀ọ́ sí ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní, irú àwọn ìpèsè bẹ́ẹ̀ kò sí. Nítorí náà ìjọ Kristian gbé ìgbésẹ̀ pàtó láti ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn opó aláìní. Paulu pèsè ìdarí pé: “Máṣe kọ orúkọ ẹni tí ó bá dín ní ọgọ́ta ọdún sílẹ̀ [fún ìtìlẹyìn ìjọ] bí opó, tí ó ti jẹ́ obìnrin ọkọ kan, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ fún iṣẹ́ rere; bí ó bá ti ń tọ́ ọmọ rí, bí ó bá ti ń gba àlejò, bí ó bá ti ń wẹ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, bí ó bá ti ń ran àwọn olùpọ́njú lọ́wọ́, bí ó bá ti ń lépa iṣẹ́ rere gbogbo.” Nípa báyìí, Paulu fihàn pé ìjọ pẹ̀lú ní ipa kan nínú ríran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́. Àwọn obìnrin tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ohun tẹ̀mí tí wọn kò ní àwọn ọmọ tí wọ́n gbàgbọ́ tóótun fún irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀.—1 Timoteu 5:9, 10.
15. Èéṣe tí a fi lè nílò ìrànlọ́wọ́ kí a baá lè gba ìtìlẹ́yìn Orílẹ̀-èdè?
15 Níbi tí ìpèsè ti Orílẹ̀-èdè bá ti wà fún àwọn àgbàlagbà, ìwọ̀nyí sábà máa ń ní iṣẹ́ ìwé kíkọ tí ó lè jọbí èyí tí ń múni rẹ̀wẹ̀sì nínú. Nínú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ó yẹ fún àwọn alábòójútó nínú ìjọ láti ṣètò fún ìrànlọ́wọ́ tí a níláti fi fúnni kí àwọn àgbàlagbà baà lè kọ̀wé béèrè fún irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀, kí wọ́n rí i gbà, tàbí kí wọ́n tilẹ̀ mú un gbé pẹ́ẹ́lí síi. Nígbà mìíràn àyípadà nínú ipò-àyíká lè yọrísí owó-ìfẹ̀yìntì tí ó ga síi. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun gbígbéṣẹ́ mìíràn ni ó wà tí àwọn alábòójútó lè ṣètò fún kí àwọn àgbàlagbà bàa lè rí ìtọ́jú gbà. Kí ni díẹ̀ nínú ìwọ̀nyí?
16, 17. Ní àwọn ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wo ni a lè gbà fi ẹ̀mí àlejò-ṣíṣe hàn sí àwọn àgbàlagbà nínú ìjọ?
16 Fífi ẹ̀mí àlejò-ṣíṣe hàn jẹ́ àṣà kan tí ó ti wà láti àwọn àkókò tí a ti kọ Bibeli. Títí di òní yìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè Àárín Ìhà Ìlà-oòrùn, ẹ̀mí àlejò-ṣíṣe ni a máa ń fihàn sí àwọn àjèjì, ó kérétán dórí kókó pípèsè ife tíì tàbí kọfí kan. Kò yanilẹ́nu, nígbà náà, pé Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́; ẹ fi ara yín fún àlejò-ṣíṣe.” (Romu 12:13) Ọ̀rọ̀ Griki náà fún ẹ̀mí àlejò-ṣíṣe, phi·lo·xe·niʹa, lọ́nà olówuuru túmọ̀sí “ìfẹ́ (ìkúndùn fún, tàbí inúrere sí) àwọn àjèjì.” Bí Kristian bá níláti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlejò-ṣíṣe sí àjèjì, kò ha yẹ kí òun túbọ̀ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlejò-ṣíṣe sí àwọn wọnnì tí wọ́n bá a tan nínú ìgbàgbọ́ bí? Ìkésíni kan wá síbi oúnjẹ sábà máa ń dúró fún ìsinmi ìkínikáàbọ̀ nínú ìgbòkègbodò ẹnìkan tí ó ti dàgbà. Bí ìwọ bá ń fẹ́ ohùn ọgbọ́n àti ìrírí níbi ìkórajọpọ̀ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà rẹ, fi àwọn àgbàlagbà kún un.—Fiwe Luku 14:12-14.
17 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni ó wà tí a lè gbà fún àwọn ẹni àgbà níṣìírí. Bí a bá ṣètò ọkọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí lọ sí àpéjọ kan, àwọn ẹni àgbà kan tí inú wọn yóò dùn sí wíwọkọ̀ ha wà bí? Máṣe dúró di ìgbà tí wọ́n bá béèrè. Yọ̀ǹda láti gbé wọn. Ìrànlọ́wọ́ mìíràn tí ó bọ́gbọ́nmu ni láti bá wọn ra ọjà. Tàbí bí wọ́n bá lè lọ, àwa ha lè mú wọn dání pẹ̀lú wa nígbà tí a bá ń lọ fún ọjà-rírà bí? Ṣùgbọ́n rí i dájú pé àwọn ibi tí wọ́n ti lè sinmi kí wọ́n sì tu araawọn lára wà bí ìyẹn bá níláti pọndandan. Kò sí iyèméjì pé sùúrù àti inúrere ni a ó béèrè fún, ṣùgbọ́n ìmoore àgbàlagbà kan látọkànwá lè jẹ́ èyí tí ń mérè wá gan-an.—2 Korinti 1:11.
Ànímọ́ Ṣiṣeyebíye Rere fún Ìjọ
18. Èéṣe tí àwọn àgbà fi jẹ́ ìbùkún fún ìjọ?
18 Ẹ wo irú ìbùkún tí ó jẹ́ láti rí àwọn irun ewú àti irun funfun díẹ̀ (àti àwọn orí tí ó ti pá nítorí ọjọ́-ogbó) nínú ìjọ! Ó túmọ̀sí pé láàárín ìmí àti okunra àwọn ọ̀dọ́, a ní àbùwọ́n ọgbọ́n àti ìrírí—ànímọ́ ṣíṣeyebíye gidi kan fún ìjọ èyíkéyìí. Ìmọ̀ wọn dàbíi omi tí ń tunilára tí a níláti fà jáde láti inú kànga. Ńṣe ni ó rí gẹ́gẹ́ bí Owe 18:4 ti sọ ọ́: “Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn dàbí omi jíjìn, orísun ọgbọ́n bí odò ṣíṣàn.” Ó ti jẹ́ ìṣírí tó fún àwọn àgbà láti nímọ̀lára pé a fẹ́ wọn a sì mọrírì wọn!—Fiwe Orin Dafidi 92:14.
19. Báwo ni àwọn kan ṣe ṣe ìrúbọ fún àwọn òbí wọn tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà?
19 Àwọn kan nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún ti nímọ̀lára àìní náà láti fi àwọn àǹfààní wọn sílẹ̀ kí wọ́n baà lè pada sílé láti bójútó àwọn òbí tí wọ́n ti dàgbà, tí ara wọn kò sì dá. Wọ́n ti ṣe ìrúbọ kan fún àwọn wọnnì tí ó ti ṣèrúbọ fún wọn ṣaájú. Tọkọtaya kan, tí wọn jẹ́ òjíhìn-iṣẹ́-Ọlọ́run tí wọ́n ṣì wà nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún síbẹ̀, padà sílé láti bójútó àwọn òbí wọn àgbà. Èyí ni wọ́n ti ṣe fún èyí tí ó rékọjá ogún ọdún. Ní ọdún mẹ́rin sẹ́yìn ìyá ọkùnrin náà ni a níláti fi sí ilé ìtọ́jú. Ọkọ náà, tí ó ń súnmọ́ ẹni àádọ́rin ọdún nísinsìnyí, ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀ ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rùn-ún lójoojúmọ́. Ó ṣàlàyé pé: “Báwo ni mo ṣe lè pa á tì? Ìyá mi ni!” Nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn àwọn ìjọ àti àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan ti jáde wá tì wọ́n sì ti gbà láti bójútó àwọn àgbàlagbà kí àwọn ọmọ wọn baà lè máa báa lọ nínú iṣẹ́-àyànfúnni wọn. Irú ìfẹ́ àìmọtara-ẹni bẹ́ẹ̀ tún yẹ fún ìgbóríyìn ńláǹlà. Ipò kọ̀ọ̀kan ni a níláti bójútó lọ́nà ìfẹ̀rí-ọkàn ṣiṣẹ́ nítorí pé àwọn àgbàlagbà ni a kò níláti patì. Fihàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí rẹ tí wọ́n ti di àgbàlagbà.—Eksodu 20:12; Efesu 6:2, 3.
20. Àpẹẹrẹ wo ni Jehofa ti fifún wa níti títọ́jú àwọn àgbàlagbà?
20 Nítòótọ́, àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tí wọ́n ti darúgbó jẹ́ adé ẹwà fún ìdílé tàbí ìjọ kan. Jehofa sọ pé: “Àní títí dé ogbó Èmi náà ni; àní títí dé ewú ni èmi ó rù yín; èmi ti ṣe é, èmi ó sì gbé, nítòótọ́ èmi ó rù, èmi ó sì gbàlà.” Ǹjẹ́ kí a fi irú sùúrù àti àbójútó kan-náà hàn sí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tí wọn ti dàgbà nínú ìdílé Kristian.—Isaiah 46:4; Owe 16:31.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ìdámọ̀ràn lórí ohun tí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé lè ṣe láti ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́, wo Ilé-Ìṣọ́nà, June 1, 1987, ojú-ìwé 13 sí 18.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Àwọn àpẹẹrẹ Bibeli wo ni a ní fún títọ́jú àwọn àgbàlagbà?
◻ Irú ọwọ́ wo ni a níláti fi mú àwọn àgbàlagbà?
◻ Báwo ni àwọn mẹ́ḿbà ìdílé ṣe níláti bójútó àwọn àgbàlagbà olólùfẹ́ wọn?
◻ Kí ni ìjọ lè ṣe láti ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́?
◻ Èéṣe tí àwọn àgbàlagbà fi jẹ́ ìbùkún fún gbogbo wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Rutu fi inúrere àti ọ̀wọ̀ hàn fún Naomi àgbàlagbà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn àgbàlagbà jẹ́ mẹ́ḿbà ṣiṣeyebíye nínú ìjọ