Bi Awọn Kristian Ṣe Lè Ran Awọn Agbalagba Lọwọ
“ÀÁRẸ̀ kò . . . mú wa; ṣugbọn bi ọkunrin ti ode wa bá ń parun, sibẹ ọkunrin ti inu wa ń di titun ni ojoojumọ. . . . A kò . . . wo ohun ti a ń rí, bikoṣe ohun ti a kò rí: nitori ohun ti a ń rí ni ti ìgbà isinsinyi; ṣugbọn ohun ti a kò rí ni ti ayeraye.” Bẹẹ ni aposteli Paulu ṣe sọ ninu lẹta rẹ̀ keji si awọn ará Korinti.—2 Korinti 4:16-18.
Ni ìgbà laelae, awọn ọkunrin ati obinrin igbagbọ pa oju wọn mọ sori awọn ohun ti a kò rí, eyi ti o ní ninu gbogbo ohun ti Ọlọrun wọn, Jehofa, ti ṣeleri lati ṣe ni akoko rẹ̀. Ninu iwe Heberu, Paulu sọrọ nipa iru awọn ẹni bẹẹ lọna ti o ga, awọn ti wọn pa igbagbọ wọn mọ titi de oju iku—diẹ ninu wọn sì dagba di arugbo kùjọ́kùjọ́. Ó tọka si wọn gẹgẹ bi apẹẹrẹ fun wa, ni sisọ pe: “Gbogbo awọn wọnyi ni o kú ni igbagbọ, lairi ileri wọnni gbà, ṣugbọn ti wọn ri wọn ni okeere réré, ti wọn sì gbá wọn mú.”—Heberu 11:13.
Lonii a ti sunmọ imuṣẹ awọn ileri wọnyi pẹkipẹki. Ṣugbọn a ní awọn alaisan ati awọn agbalagba laaarin wa ti wọn kò ní idaniloju pe awọn yoo walaaye lati ri opin eto-igbekalẹ buburu yii funraawọn. Boya diẹ ninu awọn wọnyi yoo tun kú ni igbagbọ laini rí ki gbogbo ileri naa ni imuṣẹ ni akoko igbesi-aye wọn isinsinyi. Fun iru awọn ẹni bẹẹ ni ọ̀rọ̀ Paulu ni 2 Korinti 4:16-18, lè jẹ́ iṣiri ńláǹlà.
Jehofa ranti gbogbo awọn aduroṣinṣin rẹ̀, titikan awọn alaisan ati awọn agbalagba. (Heberu 6:10) Awọn agbalagba oluṣotitọ ni a mẹnukan lọna ọlá ni awọn ibi melookan ninu Bibeli, ati ninu Ofin Mose, ọlá ti a nilati fihàn fun awọn ọlọ́jọ́-ogbó ni a mẹnukan lọ́nà akanṣe. (Lefitiku 19:32; Orin Dafidi 92:12-15; Owe 16:31) Laaarin awọn Kristian ijimiji, awọn agbalagba ni a bá lò pẹlu ọ̀wọ̀ giga. (1 Timoteu 5:1-3; 1 Peteru 5:5) Iwe Bibeli kan ní apejuwe ti o dara nipa abojuto onifẹẹ ati ifara-ẹni-rubọ ti o wọnilọkan ti ọdọbinrin kan fihàn si ìyakọ rẹ̀ arugbo. Iwe naa fi pẹlu ẹ̀tọ́ jẹ́ orukọ ọdọbinrin yẹn, Rutu.
Oluranlọwọ ti O Faramọni
Igbesi-aye korò fun Naomi arugbo. Ìyàn ti fipa mú un, papọ pẹlu idile rẹ̀ kekere, lati fi awọn ọ̀rẹ́ ati ogún silẹ sẹhin ni Judah ki wọn sì lọ gbé ni ila-oorun Odò Jordani ni ilẹ Moabu. Nihin-in ni ọkọ Naomi ti kú, ní fífi í silẹ ni oun nikan pẹlu awọn ọdọmọkunrin wọn meji. Awọn wọnyi, bi akoko ti ń lọ, dagba wọn sì gbeyawo, ṣugbọn nigba ti o ṣe awọn pẹlu kú. Naomi ni a fi silẹ laini ajogun kankan lati bojuto o.
Ó ti dagba ju lati bẹrẹ idile titun kan, igbesi-aye rẹ̀ kò sì dabi eyi ti o ni pupọ ninu fun un. Lọna aimọtara-ẹni-nikan, ó fẹ́ lati dá Rutu ati Orpa, opó awọn ọmọkunrin rẹ̀ mejeeji, pada sile awọn ìyá ti o bí wọn lọmọ ki wọn baa lè rí ọkọ fun araawọn. Oun yoo danikan pada si ilẹ ibilẹ rẹ̀. Lonii, pẹlu, awọn agbalagba kan ni isorikọ, ni pataki bi wọn bá ti padanu awọn olólùfẹ́ kan ninu ikú. Bii Naomi, wọn lè nilo ẹnikan lati bojuto wọn, ṣugbọn wọn kò fẹ́ jẹ́ ẹrù-ìnira.
Bi o ti wu ki o ri, Rutu, kò kọ ìyakọ rẹ̀ silẹ. Ó nifẹẹ agbalagba obinrin yii, ó sì nifẹẹ Jehofa, Ọlọrun ti Naomi ń jọsin. (Rutu 1:16) Nitori naa wọn jumọbẹrẹ irin-ajo pada si Juda. Ni ilẹ yẹn, iṣeto onifẹẹ kan wà labẹ Ofin Jehofa pe awọn otoṣi eniyan lè pèéṣẹ́, tabi ṣakojọ, ohunkohun ti o bá ṣẹku ninu pápá lẹhin ti a bá ti kó irè wọle. Rutu, ẹni ti o kere ju, fi tifẹtifẹ yọnda lati ṣe iṣẹ yii, ni sisọ pe: “Jẹ̀ ki emi lọ.” O ṣiṣẹ laiṣaarẹ fun anfaani awọn mejeeji.—Rutu 2:2, 17, 18.
Iṣotitọ Rutu ati ifẹ fun Jehofa jẹ́ iṣiri alagbara kan fun Naomi, ẹni ti o bẹrẹ sii ronu ni ọ̀nà kan ti o tọna ti o sì ní itumọ. Ìmọ̀ rẹ̀ nipa Ofin ati aṣa orilẹ-ede naa wá wulo nisinsinyi. Ó fun oluranlọwọ rẹ̀ ti o faramọ ọn ni imọran ọlọgbọn ki o baa lè jẹ́ pe obinrin ti o kere ju naa, nipasẹ ìsúnilópó, yoo lè jere ọrọ̀-ìní idile naa pada ki o sì ni ọmọkunrin kan lati maa bá ila idile naa lọ. (Rutu, ori 3) Rutu jẹ́ apẹẹrẹ didara kan fun awọn ti wọn yoo ṣe awọn irubọ lati bojuto awọn alaisan tabi awọn agbalagba. (Rutu 2:10-12) Ninu ijọ lonii, pupọ ni a lè ṣe lọna kan-naa lati ran awọn alaisan ati awọn agbalagba lọwọ. Bawo?
Ṣiṣeto Ṣeyebiye
Ninu ijọ Kristian akọkọbẹrẹ, akọsilẹ awọn opó ti wọn nilo itilẹhin ohun-ìní ti ara ni a pamọ. (1 Timoteu 5:9, 10) Bakan naa lonii, ninu awọn ọran kan awọn alagba lè ṣakọsilẹ awọn alaisan ati awọn agbalagba ti wọn nilo akanṣe afiyesi. Ninu awọn ijọ kan a ti fun alagba kan ni iṣẹ lati bojuto eyi gẹgẹ bi olori ẹru-iṣẹ rẹ̀. Niwọn bi o ti jẹ́ pe pupọ awọn agbalagba, bii ti Naomi, ni wọn kò ni itẹsi lati wa iranlọwọ, iru arakunrin bẹẹ yoo nilati jẹ́ olóye ni ṣiṣe ifọsiwẹwẹ ipo-ọran kan ki o sì rí i daju—pẹlu ọgbọn-ẹwẹ ati ọgbọn-inu—pe awọn ohun ti o pọndandan ni a ṣe. Fun apẹẹrẹ, oun lè ṣayẹwo bi Gbọngan Ijọba bá ni ipese pupọ tó fun awọn alaisan ati awọn agbalagba. Bi o bá gbéṣẹ́, oun lè ṣe igbeyẹwo awọn ọ̀ràn bi oju-ọna ti o ṣe gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ fun awọn aga alágbàa-kẹ̀kẹ́, yàrá itura ti o yẹ wẹ́kú, ohun agbọ́rọ̀jáde ti a ń gbékọ́ etí fun awọn ti o lekoko fun lati gbọ́rọ̀, ati ibi kan fun awọn akanṣe aga. Arakunrin yii tun le rii daju pe gbogbo awọn ti wọn kò lè wá si Gbọngan Ijọba lè yá kasẹẹti ti a fi gba ohun silẹ ni awọn ipade tabi ki wọn tẹtisilẹ si wọn lori tẹlifoonu ti a so wọn pọ mọ́.
Aini tun lè wa fun ṣiṣeto ọkọ̀ lọ si awọn ipade ati awọn apejọpọ. Arabinrin agbalagba kan ni iṣoro nitori pe ẹni ti o maa ń gbé e lọ si awọn ipade deedee kò si larọọwọto. Ó nilati késí pupọ awọn eniyan ki o tó wa rí ẹnikan ti yoo gbé e lọ nikẹhin ti ó sì wá tipa bẹẹ nimọlara pe oun jẹ́ inira kan. Iṣeto pẹlu alagba kan ti o lè ri si gbogbo iru awọn ọ̀ràn bẹẹ ìbá ti mú ìmáranini rẹ̀ rọjú.
Alagba yii tun lè beere lọwọ oniruuru idile bi wọn yoo bá fẹ́ lati maa gbọwọ́ lọwọ araawọn ninu ṣiṣebẹwo sọdọ awọn agbalagba naa. Ní ọ̀nà yii awọn ọmọde yoo kẹkọọ pe abojuto fun awọn agbalagba jẹ́ apakan igbesi-aye Kristian kan. O dara fun awọn ọmọde lati kọ́ lati gbé ẹru-iṣẹ yii. (1 Timoteu 5:4) Alaboojuto ayika kan sọ pe: “Ninu iriri mi, awọn ọmọde ti iye wọn kere jọjọ tabi awọn ọ̀dọ́ a maa bẹ awọn agbalagba tabi awọn alaisan wò lati inu idanuṣe tiwọn funraawọn.” Boya wọn kò wulẹ ń ronu nipa rẹ̀ ni, tabi wọn lè nimọlara aidaniloju niti ohun ti wọn nilati ṣe tabi sọ; awọn obi lè kọ́ wọn ni eyi.
Bi o ti wu ki o ri, ranti pe pupọ awọn agbalagba yoo mọriri mímọ̀ ṣaaju pe ọ̀rẹ́ kan ń bọ̀. Eyi ń fun wọn ni afikun ayọ ti rireti alejo kan. Bi awọn alejo naa bá mú awọn ohun ipanu, bii kọfi tabi kéèkì wá, ti wọn sì tètè palẹmọ lẹhin-naa, afikun inira ni a kò ni gbe ka agbalagba naa lori. Awọn tọkọtaya agbalagba kan, ti wọn ṣì ni ilera kikun, ní ọjọ kan pato ní ọsọọsẹ ti wọn maa ń kó ẹrù sinu apẹ̀rẹ̀ ijade igbafẹ kekere kan ti wọn yoo si jade lọ ṣe awọn ikesini lati ibi kan si ekeji sọdọ awọn agbalagba ti wọn wà ninu ijọ naa. Awọn ikesini wọn ni a mọriri lọna giga.
Fun anfaani awọn agbalagba, awọn ijọ pupọ ní awọn Ikẹkọọ Iwe Ijọ ti a ń ṣe ní ojumọmọ. Ní ibikan awọn idile diẹ ati awọn akede ti wọn jẹ́ àpọ́n ni a bi leere bi wọn yoo bá nifẹẹ sí ati bi yoo bá ṣeeṣe fun wọn lati ṣe itilẹhin fun iru awujọ bẹẹ, iyọrisi rẹ̀ sì jẹ́ awujọ ikẹkọọ iwe ijọ kan nibi tí awọn agbalagba ati awọn ọmọde ti lè bikita fun araawọn ẹnikinni keji.
A kò gbọdọ fi i silẹ fun awọn alagba nikan lati lo idanuṣe ni agbegbe yii. Gbogbo wa gbọdọ wà lojufo nipa aini awọn alaisan ati awọn agbalagba. A lè kí wọn ní Gbọngan Ijọba ki a sì lo akoko lati bá wọn sọrọ. Ikesini sibi ibakẹgbẹpọ alaijẹ-bi-aṣa ni a lè tẹwọgba. Tabi a lè késí wọn lati bá wa lọ nigba ijade igbafẹ kan tabi nigba isinmi kan. Ẹlẹ́rìí kan sábà maa ń gbe awọn akede agbalagba pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ-ayọkẹlẹ rẹ̀ nigba ti o ba ń ti inu ilu lọ fun ipe iṣẹ́. O ṣe pataki lati ran awọn agbalagba lọwọ lati maa baa lọ lati nimọlara pe a kà wọn kun. Maṣe jẹ́ ki wọn fasẹhin, bi Naomi ti ní itẹsi lati ṣe, eyi ti yoo mú kí ilana idarugbo ati arán ṣíṣe yara sii.
Awọn ọ̀dọ́ ti wọn jẹ́ abirun tabi ti wọn ń ṣaisan pẹlu nilo afiyesi. Ẹlẹ́rìí kan ti o ní awọn ọmọdekunrin mẹta ti wọn ń ṣaisan ti kò ṣee wosan, ti meji ninu wọn ti kú, wi pe: “O lè ṣoro fun ijọ kan lati maa tẹsiwaju ni fifi ibikita hàn nigba ti ẹnikan bá ni aisan kan ti ń baa lọ fun akoko gigun kan. Eeṣe ti ẹ kò yanṣẹ́ fun awọn akede ọ̀dọ́ diẹ ti wọn ṣeegbarale lati jiroro ẹsẹ ojoojumọ ki wọn sì ka akori kan lati inu Bibeli lojoojumọ pẹlu ọ̀rẹ́ wọn ti ń ṣaisan naa? Awọn ọ̀dọ́, ti o ní awọn aṣaaju-ọna ninu, lè maa gba iṣẹ naa ṣe.”
Nigba Ti Iku Ba Dabi Ohun ti Kò See Yẹsilẹ
Awọn iranṣẹ Jehofa ti sábà maa ń fi igboya dojukọ ikú, boya ó jẹ́ nitori aisan ni tabi iṣẹniniṣẹẹ. Nigba ti awọn ti a ń pọnloju bá bẹrẹ sii nimọlara pe ikú lè ti sunmọtosi, o jẹ́ ohun ti o bá iwa ẹda mu fun wọn lati ni iriri awọn ero-imọlara ti o yatọsira. Lẹhin ikú wọn, awọn ibatan wọn pẹlu yoo la ìgbà iṣatunṣe, ibanujẹ, ati itẹwọgba kọja. Nitori naa o sábà maa ń dara fun alaisan naa lati sọrọ sita nipa ikú, gẹgẹ bi Jakọbu, Dafidi, ati Paulu ti ṣe.—Genesisi, ori 48 ati 49; 1 Ọba 2:1-10; 2 Timoteu 4:6-8.
Ẹlẹ́rìí kan ti o jẹ́ oniṣegun kọwe pe: “A gbọdọ sọ otitọ nipa koko ọ̀ràn yii. Ninu iṣẹ igbesi-aye mi emi kò tii ríi rí pe o ti ṣe agbatọju kan ni rere lati fi otitọ naa pamọ pe aisan oun lè yọrisi ikú.” Bi o tilẹ ri bẹẹ, a nilati lóye ohun ti agbatọju naa funraarẹ ń fẹ́ lati mọ̀, ati ìgbà ti oun ń fẹ́ lati mọ eyi. Awọn agbatọju kan fihàn ni kedere pe wọn mọ̀ nipa bi ikú ti sunmọtosi tó, wọn sì nilati jiroro awọn ironu ati imọlara wọn nipa eyi. O dabi ẹni pe awọn miiran maa ń tẹpẹlẹ mọ́ nini ireti, awọn ọ̀rẹ́ wọn sì ṣe daradara lati ni ireti pẹlu wọn.—Fiwe Romu 12:12-15.
Ó lè ti rẹ ẹnikan ti o wà ni bebe ikú tabi ki o ni idaamu ọkàn gidigidi pe o ṣoro fun oun lati gbadura. O ṣeeṣe ki iru agbatọju bẹẹ ri itunu nipa mímọ̀ lati inu Romu 8:26, 27 pe Ọlọrun loye “irora ti a kò lè fi ẹnu sọ.” Jehofa mọ pe labẹ iru masunmawo bẹẹ ó lè ṣoro fun ẹnikan lati wá ọ̀rọ̀ rí fun adura.
Nigba ti o bá ṣeeṣe, o ṣe pataki lati gbadura pẹlu alaisan kan. Arakunrin kan sọ bayii: “Nigba ti iya mi ń ku lọ ti kò sì lokun lati sọrọ mọ́, a maa ṣapejuwe pe oun fẹ́ ki a gbadura pẹlu rẹ̀ nipa didi ọwọ́ rẹ̀ pọ̀. Lẹhin adura wa, awa a maa kọ ọ̀kan lara awọn orin Ijọba naa, nitori pe iya mi sábà maa ń jẹ́ ẹni ti o nifẹẹ si orin. Lakọọkọ, a ń fimú kọ ohùn rẹ̀, lẹhin naa a kọ awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní kẹlẹkẹlẹ. Ó gbadun rẹ̀ ni kedere. Laiṣiyemeji, awọn orin wọnyi ti a sopọ mọ igbesi-aye wa gẹgẹ bi Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣakopọ awọn imọlara tí ì ba ti lekoko lati ṣalaye ni ọ̀nà miiran.”
Sisọrọ pẹlu ẹnikan ti ń ku lọ beere ifẹ, ọgbọn-ẹwẹ, ati imọlara. Alejo kan lè mura awọn ọ̀ràn ti ń ru igbagbọ soke ti o sì ń gbeniro silẹ lati mẹnukan, oun sì gbọdọ wa lojufo lati yẹra fun ọ̀rọ̀ odi nipa awọn ẹlomiran ati awọn iṣoro wọn. Bakan-naa, gígùn akoko ibẹwo naa ni a nilati mú bá ohun ti o lọgbọn-ninu ti o sì yẹ mu. Bi o bá dabi ẹni pe agbatọju naa dákú, o dara lati ranti pe ó ṣì tun lè gbọ́ ohun ti a bá sọ. Nitori naa ṣọra nipa ohun ti o bá ń sọ.
Ẹru-Iṣẹ kan ti A Ṣajọpin
Ṣiṣabojuto awọn alaisan ati awọn agbalagba jẹ́ ẹru-iṣẹ wiwuwo kan. Fun awọn ti wọn sunmọ agbatọju naa julọ, o jẹ́ eyi ti ń beere akoko, nipa ti ara ati niti ero-imọlara. Wọn nilo wọn sì lẹtọọ sí òye ati iranlọwọ lati ọ̀dọ̀ awọn yooku ninu ijọ. Awọn wọnni ti wọn ń bojuto awọn mẹmba idile ti ń ṣaisan tabi awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn ń ṣe ohun ti o tọ́, koda bi o bá tumọsi pe wọn ń padanu awọn ipade kan tabi pe ipin wọn ninu iṣẹ-ojiṣẹ pápá dinku fun akoko kan. (Fiwe 1 Timoteu 5:8.) Iṣarasihuwa ìgbọ́niyé ti ijọ fihàn yoo fun wọn lokun. Ni awọn ìgbà miiran o lè ṣeeṣe fun arakunrin tabi arabinrin kan lati gbọwọ fun akoko diẹ ki olufunni ni itọju deedee naa baa lè lọ si ipade tabi gbadun awọn wakati atunilara diẹ ninu iṣẹ iwaasu.
Niti tootọ, bi o bá jẹ pe iwọ funraarẹ ni alaisan naa, iwọ pẹlu lè ṣe ohun kan. Wíwà bi alainireti ati alainiranlọwọ ni ibamu pẹlu amodi rẹ lè mú ki o banujẹ, ṣugbọn ìkorò ọkàn ń mu ki ẹnikan dá wà ó sì ń lé awọn miiran sá. Dipo eyi iwọ lè gbiyanju lati fi imọriri hàn ki o sì fọwọsowọpọ. (1 Tessalonika 5:18) Gbadura fun awọn ẹlomiran ti wọn wà ninu irora. (Kolosse 4:12) Ṣaṣaro lori awọn agbayanu otitọ Bibeli, ki o sì jiroro iwọnyi pẹlu awọn alejo. (Orin Dafidi 71:17, 18) Maa fi pẹlu iharagaga mu araarẹ mọ àmọ̀dájú nipa itẹsiwaju afungbagbọ lokun ti awọn eniyan Ọlọrun. (Orin Dafidi 48:12-14) Fi ọpẹ́ fun Jehofa fun awọn idagbasoke alayọ wọnyi. Ṣiṣaṣaro lori iru awọn ọ̀ràn bẹẹ lè, fun awọn ọjọ ti o kẹhin iwalaaye wa ni gbogbo ẹwà wọn gẹgẹ bi òòrùn kan ti ń wọ̀ ti mu ki imọlẹ ti o lọ́wọ́ọ́wọ́ ti o sì ṣú dùdù ṣíji bolẹ̀ ju òòrùn ọ̀sán lọ.
Gbogbo wa gbọdọ ṣagbára lati pa ireti naa ti ń daabobo ero-inu wa bi àṣíborí kan paapaa julọ ni awọn akoko ti ń danniwo. (1 Tessalonika 5:8) O dara lati ṣaṣaro lori ireti ajinde naa ati ipilẹ rẹ̀ alagbara. Awa lè fojusọna pẹlu idaniloju ati ifojusọna onihaaragaga fun ọjọ naa nigba ti aisan tabi ailera ara kì yoo si mọ́ nitori ọjọ ogbó. Nigba naa, gbogbo eniyan yoo ní ilera. Àní awọn oku paapaa yoo pada wá. (Johannu 5:28, 29) “Awọn ohun airi” wọnyi ni awa ń ri pẹlu oju igbagbọ ati ọkan-aya wa. Maṣe gbójú fò wọn dá.—Isaiah 25:8; 33:24; Ìfihàn 21:3, 4.