Bíbójútó Àwọn Àgbàlagbà—Ojúṣe Àwọn Kristẹni
“Àní títí di ọjọ́ ogbó ènìyàn, Ẹnì kan náà ni mí; àti títí di ìgbà orí ewú ènìyàn èmi fúnra mi yóò máa rù ú.”—AÍSÁYÀ 46:4.
1, 2. Báwo ni àbójútó Baba wa ọ̀run ṣe yàtọ̀ sí àbójútó àwọn obí tó jẹ ènìyàn?
ÀWỌN òbí tó mọṣẹ́ níṣẹ́ máa ń tọ́ àwọn ọmọ wọn láti ìgbà ọmọdé jòjòló di ìgbà tọ́mọ bá tójúúbọ́, àní títí dìgbà tí wọ́n bá bàlágà. Kódà nígbà táwọn ọmọ bá dàgbà tán, táwọn náà ní ìdílé tiwọn, bàbá àti ìyá wọn ṣì máa ń fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn, tí wọ́n sì máa ń ṣèrànwọ́ fún wọn.
2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ohun tí ẹ̀dá èèyàn lè ṣe fáwọn ọmọ mọ níwọ̀n, ṣùgbọ́n ní ti Baba wa ọrun, ìgbà gbogbo ni ó máa ń fi ìfẹ́ bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà tí Jèhófà ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ tó yàn láyé àtijọ́ sọ̀rọ̀, ó sọ pé: “Àní títí di ọjọ́ ogbó ènìyàn, Ẹnì kan náà ni mí; àti títí di ìgbà orí ewú ènìyàn, èmi fúnra mi yóò máa rù ú.” (Aísáyà 46:4) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí mà fi àwọn Kristẹni àgbàlagbà lọ́kàn balẹ̀ o! Jèhófà kì í fàwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sí i sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣèlérí pé òun yóò máa pèsè fún wọn, òun yóò dúró tì wọ́n, àti pé òun yóò máa tọ́ wọn sọ́nà jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn, àní dọjọ́ ogbó wọn.— Sáàmù 48:14.
3. Kí la fẹ́ gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà nípa bó ṣe ń fìfẹ́ bójú tó àwọn àgbàlagbà? (Éfésù 5:1, 2) Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí àwọn ọmọ, àwọn alábòójútó nínú ìjọ àti gbogbo Kristẹni lẹ́nìkọ̀ọ̀kan lè gbà bójú tó àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé.
Ojúṣe Àwọn Ọmọ
4. Kí ni ojúṣe àwọn ọmọ Kristẹni sáwọn òbí wọn?
4 “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” (Éfésù 6:2; Ẹ́kísódù 20:12) Ìmọ̀ràn tó ṣe kedere ṣùgbọ́n tó ṣe pàtàkì tá a fà yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù yìí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi rán àwọn ọmọ létí ojúṣe wọn sí àwọn òbí wọn. Ṣùgbọ́n báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe kan bíbójútó àwọn àgbàlagbà? Àpẹẹrẹ rere àwọn kan tó ṣe bẹ́ẹ̀ láyé ìgbà tí ẹ̀sìn Kristẹni ò tíì dé yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè yìí?
5. (a) Kí ló fi hàn pé Jósẹ́fù ò gbàgbé ohun tó yẹ kóun ṣe gẹ́gẹ́ bí ọmọ? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti bọlá fún òbí ẹni, àpẹẹrẹ rere wo sì ni Jósẹ́fù fi lélẹ̀ nínú èyí?
5 Fún ohun tó ju ogun ọdún lọ ni Jósẹ́fù kò fi rí bàbá rẹ̀ tó ti dàgbà, ìyẹn Jékọ́bù baba ńlá. Àmọ́ ṣá ó, ó hàn kedere pé okùn ìfẹ́ bàbá àtọmọ tó wà láàárín Jósẹ́fù àti Jékọ́bù kò tíì já. Kódà, nígbà tí Jósẹ́fù jẹ́ káwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mọ ẹni tóun jẹ́ gan-an, ó bi wọ́n pé: “Ṣé baba mi ṣì wà láàyè?” (Jẹ́nẹ́sísì 43:7, 27; 45:3) Nígbà yẹn, ìyàn ńlá kan mú ní ilẹ̀ Kénáánì. Nítorí èyí, Jósẹ́fù ránṣẹ́ sí bàbá rẹ̀ pé: “Sọ̀ kalẹ̀ wá sọ́dọ̀ mi. Má ṣe jáfara. Kí ìwọ sì máa gbé ilẹ̀ Góṣénì, kí o sì máa bá a lọ nítòsí mi . . . Èmi yóò sì pèsè oúnjẹ fún ọ níbẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 45:9-11; 47:12) Bẹ́ẹ̀ ni o, bíbọlá fáwọn òbí wa tó ti dàgbà tún kan dídáàbò bò wọ́n àti pípèsè fún wọn nípa tara nígbà tí wọn ò bá lágbára láti tọ́jú ara wọn. (1 Sámúẹ́lì 22:1-4; Jòhánù 19:25-27) Tayọ̀tayọ̀ ni Jósẹ́fù fi ṣe ojúṣe rẹ̀.
6. Báwo ni Jósẹ́fù ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ bàbá òun dáadáa, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
6 Nítorí pé Jèhófà bù kún Jósẹ́fù, ó di ọ̀kan lára àwọn tó lọ́rọ̀ tó sì lágbára jù lọ ní Íjíbítì. (Jẹ́nẹ́sísì 41:40) Ṣùgbọ́n kò ka ara rẹ̀ sí pàtàkì jù, bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ kí ọwọ́ òun dí jù tí kò fi ní ráyè bọlá fún bàbá rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àádóje ọdún. Bó ṣe gbọ́ pé Jékọ́bù (tàbí Ísírẹ́lì) ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé, “Jósẹ́fù múra kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gòkè lọ láti pàdé Ísírẹ́lì baba rẹ̀ ní Góṣénì. Nígbà tí ó yọ sí i, lójú-ẹsẹ̀ ni ó gbórí lé e lọ́rùn, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí da omijé sí i lọ́rùn léraléra.” (Jẹ́nẹ́sísì 46:28, 29) Irú ìkíni-káàbọ̀ yìí kì í wulẹ̀ ṣe bíbọ̀wọ̀ fúnni lọ́nà àṣà ṣákálá kan lásán. Jósẹ́fù nífẹ̀ẹ́ bàbá rẹ̀ tó ti dàgbà gan-an, kò sì tì í lójú láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Báwa náà bá ní àwọn òbí tó ti dàgbà, ṣé àwa náà máa ń fi ìfẹ́ hàn sí wọn gan-an?
7. Kí nìdí tí Jékọ́bù fi fẹ́ kí wọ́n sin òun sí Kénáánì?
7 Ìfọkànsìn Jékọ́bù sí Jèhófà ṣì wà digbí títí Jékọ́bù fi kú. (Hébérù 11:21) Nítorí pé Jékọ́bù gba àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́, ó ní kí wọ́n sìn òkú òun sí Kénáánì. Jósẹ́fù bọlá fún bàbá rẹ̀ nípa ṣíṣe ohun tó ní kó ṣe, láìka owó tó máa ná an àti wàhálà tó wà nídìí rẹ̀ sí.—Jẹ́nẹ́sísì 47:29-31; 50:7-14.
8. (a) Kí ni olórí ohun tó ń mú wa tọ́jú àwọn òbí wa àgbàlagbà? (b) Kí lohun tí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan ṣe kó bàa lè tọ́jú àwọn òbí rẹ̀ àgbàlagbà? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 17.)
8 Kí ló mú kí Jósẹ́fù tọ́jú bàbá rẹ̀? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ tó ní fún bàbá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó bí i lọ́mọ tó sì tún wò ó dàgbà wà lára ohun tó mú kó ṣe bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ ó dájú pé ó wù Jósẹ́fù gan-an láti múnú Jèhófà dùn. Ohun tó yẹ kó wà lórí ẹ̀mí tiwa náà nìyẹn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí opó èyíkéyìí bá ní àwọn ọmọ tàbí àwọn ọmọ-ọmọ, kí àwọn wọ̀nyí kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ láti máa fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣe ìwà hù nínú agbo ilé tiwọn, kí wọ́n sì máa san àsanfidípò yíyẹ fún àwọn òbí wọn àti àwọn òbí wọn àgbà, nítorí tí èyí ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run.” (1 Tímótì 5:4) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìfẹ́ fún Jèhófà àti ìbẹ̀rù àtọkànwá fún un ni yóò sún wa láti tọ́jú àwọn òbí wa tó ti dàgbà, láìka wàhálà tó lè wà nídìí rẹ̀ sí.a
Bí Àwọn Alàgbà Ṣe Fi Hàn Pé Àwọn Bìkítà Nípa Àwọn Àgbàlagbà
9. Àwọn wo ni Jèhófà yàn láti bójú tó agbo, títí kan àwọn Kristẹni àgbàlagbà?
9 Nígbà tí ọjọ́ gígún Jékọ́bù fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin, ó pe Jèhófà ní “Ọlọ́run tòótọ́ tí ó ti ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn mi ní gbogbo wíwà mi títí di òní.” (Jẹ́nẹ́sísì 48:15) Lónìí, Jèhófà ń tipasẹ̀ àwọn Kristẹni alábòójútó tàbí àwọn alàgbà ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé, lábẹ́ ìdarí Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, “olórí olùṣọ́ àgùntàn.” (1 Pétérù 5:2-4) Báwo làwọn alábòójútó ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà nínú bíbójú tó àwọn àgbàlagbà tó wà nínú agbo?
10. Kí làwọn kan ti ṣe láti ran àwọn Kristẹni àgbàlagbà lọ́wọ́ nípa tara? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 19.)
10 Kété lẹ́yìn tí wọ́n fìdí ìjọ Kristẹni múlẹ̀, àwọn àpọ́sítélì yan “ọkùnrin méje tí a jẹ́rìí gbè . . . tí wọ́n kún fún ẹ̀mí àti ọgbọ́n” láti máa bójú tó pínpín oúnjẹ ní “ojoojúmọ́” fún àwọn opó Kristẹni tó jẹ́ aláìní. (Ìṣe 6:1-6) Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù fún Tímótì tó jẹ́ alábòójútó nítọ̀ọ́ni láti fi àwọn àgbàlagbà opó tó ní àpẹẹrẹ rere sára àwọn tí wọ́n máa ràn lọ́wọ́ nípa tara. (1 Tímótì 5:3, 9, 10) Bákan náà, àwọn alábòójútó tó wà nínú ìjọ lónìí máa ń múra tán láti bójú tó ríran àwọn Kristẹni àgbàlagbà lọ́wọ́ nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ohun tó wà lẹ́yìn ọ̀fà ju èje lọ lórí ọ̀ràn bíbójútó àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olóòótọ́.
11. Kí ni Jésù sọ nípa opó kan tó jẹ́ aláìní tó ṣètọrẹ kékeré?
11 Lápá ìparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ó jókòó sínú tẹ́ńpìlì “ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkíyèsí bí ogunlọ́gọ̀ náà ṣe ń sọ owó sínú àwọn àpótí ìṣúra.” Ohun kan gbàfiyèsí rẹ̀. Àkọsílẹ̀ yẹn sọ pé: “Òtòṣì opó kan wá, ó sì sọ ẹyọ owó kéékèèké méjì sínú rẹ̀, tí ìníyelórí wọ́n kéré gan-an.” Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì wí fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé òtòṣì opó yìí sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo àwọn tí wọ́n ń sọ owó sínú àwọn àpótí ìṣúra náà; nítorí gbogbo wọn sọ sínú rẹ̀ láti inú àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n, láti inú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní sínú rẹ̀, gbogbo ohun ìní ìgbésí ayé rẹ̀.” (Máàkù 12:41-44) Tó bá jẹ́ pé iye owó yẹn ni a máa wò ni, owó kékeré ni opó náà fi sílẹ̀, ṣùgbọ́n Jésù mọ bí Baba rẹ̀ ọ̀run ṣe mọyì irú ìfọkànsin tí obìnrin náà ní. Bí opó tálákà náà tilẹ̀ jẹ́ àgbàlagbà, Jésù kò gbójú fo ohun tó ṣe dá.
12. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fi ìmoore wọn hàn fún ipa táwọn àgbàlagbà Kristẹni ń kó?
12 Bíi ti Jésù, àwọn Kristẹni alábòójútó kì í gbójú fo ohun táwọn àgbàlagbà ń ṣe láti gbé ìjọsìn tòótọ́ ga. Ó yẹ káwọn alàgbà máa yin àwọn àgbàlagbà fún ipa tí wọ́n ń kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti nípàdé, ipa tó dára tí wọ́n ní lórí ìjọ àti ìfaradà tí wọ́n ní. Ọ̀rọ̀ ìṣírí tòótọ́ á mú káwọn àgbàlagbà rí “ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà” nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wọn, nípa bẹ́ẹ̀ wọn ò ní kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ara wọn látàrí fífi ohun tí wọ́n lè ṣe wé ohun táwọn Kristẹni mìíràn ń ṣe tàbí ohun táwọn fúnra wọn ti ṣe sẹ́yìn.—Gálátíà 6:4.
13. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè jèrè látinú ẹ̀bùn àti ìrírí àwọn àgbàlagbà?
13 Àwọn alàgbà lè fi hàn pé àwọn mọyì ìrànlọ́wọ́ ńlá látọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni àgbàlagbà, nípa jíjèrè látinú ìrírí àti ẹ̀bùn tí wọ́n ní. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a le lo àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ fún àṣefihàn tàbí ká fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Alàgbà kan sọ pé: “Gbogbo àwùjọ ló máa ń jókòó jẹ́ẹ́ tí wọ́n á sì tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ nígbà tí mo bá ń fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu arákùnrin tàbí arábìnrin àgbàlagbà tó ti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ nínú òtítọ́.” Àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ mìíràn ròyìn pé, arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́rin ti ran àwọn akéde Ìjọba náà lọ́wọ́ láti máa ṣe déédéé nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Ó tún fún wọn níṣìírí láti máa ṣe “àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe,” bíi kíka Bíbélì àti ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ àti ṣíṣàṣàrò lórí ohun tí wọ́n bá kà.
14. Báwo ni ẹgbẹ́ àwọn alàgbà kan ṣe fi hàn pé àwọn mọrírì àgbàlagbà kan tó jẹ́ alàgbà bíi tiwọn?
14 Àwọn alàgbà tún máa ń mọyì ipa táwọn àgbàlagbà alábòójútó bíi tiwọn ń kó. José tó ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún tó sì ti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún lọ fún iṣẹ́ abẹ láìpẹ́ yìí. Nítorí pé ó máa pẹ́ díẹ̀ kára rẹ̀ tó kọ́fẹ padà, ó ronú láti fi àǹfààní tó ní láti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó olùṣalága sílẹ̀. José sọ pé: “Ohun táwọn alàgbà tó kù ṣe yà mí lẹ́nu gan-an ni. Dípò kí wọ́n fọwọ́ sí ohun tí mo sọ yẹn, ńṣe ni wọ́n wulẹ̀ béèrè ibi tí mo ti nílò ìrànlọ́wọ́ kí ń bàa lè máa bójú tó ẹrù iṣẹ́ mi lọ.” Alàgbà kan tó kéré lọ́jọ́ orí ràn José lọ́wọ́, ó sì ṣeé ṣe fún un láti máa fi ìdùnnú sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó olùṣalága nìṣó, èyí sì jẹ́ ìbùkún fún gbogbo ìjọ. Ọ̀kan lára àwọn alàgbà yẹn sọ̀ pé: “Àwọn ara ń gbádùn bí José ṣe ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà gan-an ni. Wọ́n fẹ́ràn rẹ̀ wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún un nítorí ìrírí àti àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ìbùkún ńlá ló jẹ́ fún ìjọ wa.”
Bíbójú Tó Ara Wa Lẹ́nì Kìíní Kejì
15. Kí nìdí tó fi yẹ kí ire àwọn àgbàlagbà jẹ gbogbo àwọn Kristẹni lógún?
15 Kì í ṣe àwọn ọmọ tí obí wọn ti darúgbó àtàwọn ìránṣẹ́ tá a yàn sípò nìkan ló yẹ kí ọ̀ràn bíbójútó àwọn àgbàlagbà jẹ lógún o. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fi ìjọ Kristẹni wé ara ènìyàn, ó kọ̀wé pé: “Ọlọ́run pa ara pọ̀ ṣọ̀kan, ní fífi ọlá tí ó pọ̀ jù lọ fún apá kan ara tí ó ṣaláìní, kí ó má bàa sí ìpínyà kankan nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ lè ní aájò kan náà fún ara wọn.” (1 Kọ́ríńtì 12:24, 25) Kí ìjọ Kristẹni tó lè ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ni ìṣọ̀kan, ẹnì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ máa ṣaájò àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́, títí kan àwọn àgbàlagbà.— Gálátíà 6:2.
16. Báwo là ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn àgbàlagbà nígbà tá a bá wà nípàdé Kristẹni?
16 Àwọn ìpàdé Kristẹni jẹ́ ibi tó dára gan-an láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn àgbàlagbà. (Fílípì 2:4; Hébérù 10:24, 25) Ǹjẹ́ a máa ń wá àyè láti bá àwọn àgbàlagbà sọ̀rọ̀ nípàdé? Bí ó tilẹ̀ dára pé ká béèrè àlàáfíà wọn, ǹjẹ́ a “lè fi ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀” fún wọn, bóyá nípa sísọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró tàbí àwọn ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ mìíràn? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ó níbi táwọn àgbàlagbà kan lè rìn dé, ohun tó máa dára ni pé ká lọ bá wọn dípò ká máa retí kí wọ́n wá bá wa. Bó bá jẹ́ pé wọn ò gbọ́rọ̀ dáadáa, a lè fẹ̀lẹ̀ sọ̀rọ̀ ká sì sọ̀rọ̀ sókè ketekete. Bá a bá fẹ́ kí “pàṣípààrọ̀ ìṣírí” wà lóòótọ́, ó yẹ ká máa fetí sílẹ̀ dáadáa sí ohun tàwọn àgbàlagbà bá ń sọ.—Róòmù 1:11, 12.
17. Báwo la ṣe lè ṣaájò àwọn Kristẹni àgbàlagbà tí ò lè jáde kúrò nílé?
17 Bí àwọn àgbàlagbà kan kò bá lè wá sáwọn ìpàdé Kristẹni ńkọ́? Jákọ́bù 1:27 fi hàn pé ojúṣe wa ni “láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn.” Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà tí a túmọ̀ sí “láti máa bójú tó” tún túmọ̀ sí láti lọ “bẹ . . . wò.” (Ìṣe 15:36) Àwọn àgbàlagbà á mà mọrírì rẹ̀ gan-an o bá a bá bẹ̀ wọ́n wò! Nígbà tí Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ “àgbàlagbà” ń ṣẹ̀wọ̀n ní Róòmù ní nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Tiwa, òun nìkan ló wà níbẹ̀. Ó yán hànhàn láti rí Tímótì tó jẹ alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀, ó kọ̀wé pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti wá sọ́dọ̀ mi láìpẹ́.” (Fílémónì 9; 2 Tímótì 1:3, 4; 4:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgbàlagbà kan kò sí lẹ́wọ̀n bíi ti Pọ́ọ̀lù, wọn ò lè jáde kúrò nílé nítorí àìsàn. Nítorí ìyẹn, wọ́n lè máa sọ pé ‘Jọ̀wọ́, sa gbogbo ipá rẹ láti wá bẹ̀ mí wò láìpẹ́.’ Ṣé a máa ń lọ sọ́dọ̀ irú àwọn àgbàlagbà bẹ́ẹ̀?
18. Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú bíbẹ àwọn àgbàlagbà wò?
18 Má ṣe fojú kéré àǹfààní tó wà nínú bíbẹ àwọn àgbàlagbà arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí wò. Nígbà tí Kristẹni kán tó ń jẹ́ Ónẹ́sífórù wà ní Róòmù, taratara ló fi wá Pọ́ọ̀lù, ó rí i, lẹ́yìn tó sì rí i ‘ọ̀pọ̀ ìgbà ló mú ìtura wá bá a.’ (2 Tímótì 1:16, 17) Obìnrin àgbàlagbà kan sọ pé: “Mo máa ń fẹ́ káwọn ọmọdé wà lọ́dọ̀ mi. Ohun tó wù mí jù níbẹ̀ ni bí wọ́n ṣe máa ń ṣe mi bíi pé ara ìdílé wọn ni mí. Ìyẹn wú mi lórí gan-an ni.” Kristẹni àgbàlagbà mìíràn sọ pé: “Mò máa ń mọrírì rẹ̀ gan-an bí ẹnì kan bá fún mi ní káàdì ìkíni, tó bá bá mi sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù fún ìṣẹ́jú díẹ̀, tàbí tó bá bẹ̀ mí wò. Ó máa ń tù mí lára gan-an ni.”
Jèhófà Máa Ń San Èrè Fáwọn Tó Bìkítà
19. Àwọn ìbùkún wo ló wà nínú títọ́jú àwọn àgbàlagbà?
19 Títọ́jú àwọn àgbàlagbà máa ń mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún wá. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ló jẹ́ láti bá àwọn àgbàlagbà kẹ́gbẹ́ ká sì jèrè lára ìmọ̀ àti ìrírí wọn. Àwọn tó bá ń ṣètọ́jú èèyàn máa ń rí ayọ̀ púpọ̀ tó máa ń wá látinú fífúnni, ọkàn wọn máa ń balẹ̀ pé àwọn ṣàṣeyọrí àti pé wọ́n máa ń ní àlàáfíà ọkàn nítorí pé wọ́n ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ ní kí wọ́n ṣe. (Ìṣe 20:35) Kò tán síbẹ̀ o, àwọn tó bá ń ṣètọ́jú àwọn àgbàlagbà kò ní láti bẹ̀rù pé àwọn kò ní rẹ́ni tọ́jú àwọn nígbà táwọn náà bá darúgbó. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé: “A óò mú ọkàn tí ó lawọ́ sanra, ẹni tí ó sì ń bomi rin àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà, a ó bomi rin òun náà ní fàlàlà.”—Òwe 11:25.
20, 21. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó ń tọ́jú àwọn àgbàlagbà, kí sì ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
20 Jèhófà yóò san èrè fáwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run, ì báà jẹ́ àwọn ọmọ, àwọn alábòójútó, àtàwọn Kristẹni mìíràn tó bá bìkítà, nítorí pé wọ́n ń fi àìmọtara-ẹni-nìkan bójú tó àwọn àgbàlagbà tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Irú ẹ̀mí yẹn bá òwe yìí mu pé: “Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín, òun yóò sì san ìlòsíni rẹ̀ padà fún un.” (Òwe 19:17) Bí ìfẹ́ bá sún wa láti ṣojú rere sáwọn ẹni rírẹlẹ̀ àtàwọn tó ṣaláìní, Ọlọ́run yóò kà á sí pé òun ni a yá ní nǹkan, yóò sì fi ọ̀pọ̀ ìbùkún san án padà. Ó tún máa ń san èrè fún wa látàrí pé a ṣìkẹ́ àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olùjọ́sìn bíi tiwa, èyí tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọ́n jẹ́ ‘òtòṣì ní ti ayé ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́.’—Jákọ́bù 2:5.
21 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Ọlọ́run á mà san padà o! Ìyè àìnípẹ̀kun wà lára rẹ̀. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ni yóò gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun yìí nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, níbi tí àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ tí a jogún kò tí ní sí mọ́, tí ara àwọn àgbàlagbà olóòótọ́ yóò sì padà di ti ọ̀dọ́. (Ìṣípayá 21:3-5) Bá a ṣe ń dúró de àkókó ìbùkún yẹn, ǹjẹ́ ká máa bá a lọ láti máa ṣe ojúṣe Kristẹni wa, ìyẹn bíbójú tó àwọn àgbàlagbà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìmọ̀ràn tó ṣeé múlò lórí bí a ṣe lè tọ́jú àwọn òbí àgbàlagbà, wo Jí! February 8, 1994, ojú ìwé 3-10.
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
• Báwo làwọn ọmọ ṣe lè bọlá fáwọn obí wọn tó ti dàgbà?
• Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fi hàn pé àwọn mọrírì àwọn àgbàlagbà tó wà nínú agbo?
• Kí ni Kristẹni kọ̀ọ̀kan lè ṣe láti fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn àgbàlagbà lóòótọ́?
• Àwọn ìbùkún wo ló wà nínú bíbójú tó àwọn Kristẹni àgbàlagbà?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
Ìgbà Tí Òbí Arákùnrin Kan Ń Fẹ́ Ìrànlọ́wọ́
Ní ọdún 1999, Philip ń sìn ní Liberia gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ kọ́lékọ́lé tó yọ̀ǹda ara rẹ̀, ìgbà yẹn ló gbọ́ pé àìsàn ńlá kan ti gbé bàbá rẹ̀ ṣánlẹ̀. Ó gbà pé màmá òun nìkan kò lè dá kojú ìṣòro náà, ó padà sílé láti lọ ṣètò bí bàbá rẹ̀ yóò ṣe máa gbàtọ́jú.
Philip sọ pé: “Kò rọrùn láti padà sílé, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé ṣíṣe àbójútó àwọn obí mi ni ojúṣe mi àkọ́kọ́.” Láàárín ọdún mẹ́tà tó tẹ̀ lé e, ó ní kí àwọn òbí òun ṣí lọ sí ilé tó túbọ̀ dára sí i, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn Kristẹni tó wà nítòsí, ó ṣètò ilé náà kó bàa lè ṣeé gbé fún bàbá rẹ̀ nítorí ipò ẹlẹgẹ́ tó wà.
Ní báyìí, màmá Philip ti wá lè kojú ìṣòro àìsàn ńlá tó ń ṣe bàbá Philip. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó ṣeé ṣe fún Philip láti lọ sìn gẹ́gẹ́ bí olùyọ̀ǹda-ara-ẹni ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Makedóníà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
Bí Ìjọ Kan Ṣe Bójú Tó Obìnrin Àgbàlagbà Kan
Àìsàn dá Kristẹni obìnrin kan tó ń jẹ́ Ada wólẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rin ni nígbà yẹn, àwọn alàgbà ìjọ sì ṣèrànwọ́ fún un. Wọ́n ṣètò àwùjọ àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ tó lè ràn án lọ́wọ́. Inú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọ̀nyí dùn láti ṣe àwọn iṣẹ́ bíi títún ilé ṣe, fífọ aṣọ, dídáná, àti kó lè máa rí wọn rán níṣẹ́.
Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ètò yẹn. Látìgbà yẹn sì rèé, ó ti lé ní ọgbọ̀n àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti ṣèrànwọ́ láti tọ́jú Ada. Wọ́n máa ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n máa ń ka àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì fún un, wọ́n máa ń sọ ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí tí àwọn ará tó wà nínú ìjọ ní fún un, wọ́n sì máa ń gbàdúrà pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
Alàgbà ìjọ kan sọ pé: “Àǹfààní làwọn tó ń tọ́jú Ada ka ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ń ṣe fún un sí. Iṣẹ́ ìsìn tó ti ń fi ìṣòtítọ́ ṣe sì ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, ìyẹn ni kò jẹ́ kí wọ́n má ṣaláì bójú tó o.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ǹjẹ́ a máa ń fi hàn dáadáa pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí wa tó jẹ́ àgbàlagbà?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tiwọn