ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 10/8 ojú ìwé 22-23
  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Hùwà Sí Àwọn Àgbàlagbà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Hùwà Sí Àwọn Àgbàlagbà?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀wọ̀ fún Àwọn Àgbàlagbà
  • Ọlọ́run Kì Í Pa Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Tó Jẹ́ Adúróṣinṣin Tì
  • Àwọn Ìdílé Kristian Ń Ran Àwọn Àgbàlagbà Lọ́wọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Bíbójútó Àwọn Àgbàlagbà—Ojúṣe Àwọn Kristẹni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Jèhófà Ń Ṣìkẹ́ Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Àgbàlagbà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ẹ Máa Bọlá fún Àwọn Àgbàlagbà Tó Wà Láàárín Yín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 10/8 ojú ìwé 22-23

Ojú Ìwòye Bíbélì

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Hùwà Sí Àwọn Àgbàlagbà?

NÍGBÀ ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 2003, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló kú jákèjádò ilẹ̀ Yúróòpù nítorí ìgbì ooru tó tíì hàn wọ́n léèmọ̀ jù lọ tó bì lu Àgbáálá Ilẹ̀ náà. Ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti gbúròó ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ gbẹ̀yìn. Àgbàlagbà ló pọ̀ jù lára àwọn tó kú. Àwọn ìbátan àwọn kan nínú wọn fi àwọn nìkan sílẹ̀ nílé nígbà tí wọ́n lọ gbádùn àkókò ìsinmi. Ìròyìn tiẹ̀ fi tóni létí pé ńṣe ni wọ́n wulẹ̀ pa àwọn kan tì tàbí kó jẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn tàbí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó tí iṣẹ́ ti pá lórí ló gbàgbé wọn. Ìwé ìròyìn Le Parisien, sọ pé ní ìlú Paris nìkan ṣoṣo, àádọ́ta-lé-nírínwó òkú [450] ni wọn ò rẹni wá wẹ́yìn wọn wò. Ìwé ìròyìn náà béèrè nípa ipò àwọn tí ikú pa tí ò sì sẹ́ni tó mọ̀ nípa wọn pé: “Irú ayé wo gan-an là ń gbé nínú ẹ̀ yìí, tó fi di pé a gbàgbé nípa àwọn bàbá, ìyá àti àwọn òbí wa àgbà?”

Nínú ayé kan tí iye àwọn àgbà tọ́jọ́ orí wọn lé ní márùndínláàádọ́rin ti ń pọ̀ sí i níwọ̀n ọ̀kẹ́ mọ́kàndínlógójì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [795,000] lóṣooṣù, lọ́nà tí a kò rí irú rẹ̀ rí, pípèsè ohun táwọn arúgbó ṣaláìní fún wọn ti di ọ̀kan lára ohun tó ń fa àníyàn jù lọ lóde òní. Nancy Gordon, igbá kejì olùdarí ètò ìkànìyàn fún Àjọ Elétò Ìkànìyàn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, sọ pé: “Àwọn èèyàn tó ń darúgbó lágbàáyé túbọ̀ ń pọ̀ sí i níwọ̀n tí a kò rí irú rẹ̀ rí, a sì gbọ́dọ̀ fiyè gidigidi sí ohun tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ń ṣe láti yanjú ìṣòro àwọn tó ń darúgbó àti ohun tí wọ́n ń ṣe kí nǹkan fi lè rọjú fún wọn.”

Ẹlẹ́dàá wa náà kì í fọ̀rọ̀ àwọn arúgbó ṣeré. Kódà, Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀, fún wa ní ìtọ́ni lórí bó ṣe yẹ ká máa hùwà sí wọn.

Ọ̀wọ̀ fún Àwọn Àgbàlagbà

Òfin tí Ọlọ́run fún Mósè là á kalẹ̀ pé ká máa bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbàlagbà. Òfin náà kà pé: “Kí o dìde dúró níwájú orí ewú, kí o sì fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó.” (Léfítíkù 19:32) A retí pé kí àwọn olùjọsìn Ọlọ́run, tí wọ́n jẹ́ onígbọràn “dìde” níwájú àgbàlagbà (1) gẹ́gẹ́ bí àmì ọ̀wọ̀ fún arúgbó náà àti (2) gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé àwọn olùjọsìn náà ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run. Nípa báyìí, a retí pé ká máa bọlá fún àwọn arúgbó, ká sì máa wò wọ́n bíi kòṣeémánìí.—Òwe 16:31; 23:22.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni òde òní ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, àwọn ìlànà inú òfin náà jẹ́ kí wọ́n mọ èrò Jèhófà nípa àwọn arúgbó àti ipò tó tò wọ́n sí, èyí tó mú kó ṣe kedere sí wa pé kò kóyán wọn kéré. Àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní lóye àwọn ìlànà yìí dáadáa. Ẹ̀rí tó fi èyí hàn la lè rí nínú ìwé Ìṣe nínú Bíbélì. Àwọn opó kan tí wọ́n jẹ́ aláìní wà láàárín àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà yẹn. Ó sì dájú pé àwọn mélòó kan lára wọn ti darúgbó. Àwọn àpọ́sítélì yan ọkùnrin méje “tí a jẹ́rìí gbè” láti rí i dájú pé àwọn obìnrin wọ̀nyí ń rí ìpín oúnjẹ ojoojúmọ́ gbà létòlétò, níwọ̀n bí wọ́n ti ka irú àkànṣe àbójútó bẹ́ẹ̀ sí “iṣẹ́ àmójútó tí ó pọndandan” nínú ìjọ.—Ìṣe 6:1-7.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ìlànà ‘dídìde dúró níwájú orí ewú’ fún ìjọ Kristẹni. Ó sọ fún Tímótì, Kristẹni ọ̀dọ́ tó jẹ́ alábòójútó pé: “Má ṣe fi àṣìṣe àgbà ọkùnrin hàn lọ́nà mímúná janjan. Kàkà bẹ́ẹ̀, pàrọwà fún un gẹ́gẹ́ bí baba, . . . àwọn àgbà obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìyá.” (1 Tímótì 5:1, 2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àṣẹ lórí àwọn Kristẹni arúgbó, Pọ́ọ̀lù sọ fún un pé kò gbọ́dọ̀ tẹ́ńbẹ́lú àwọn àgbà ọkùnrin. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún wọn bíi baba. Kó sì tún máa bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbà obìnrin nínú ìjọ. Lọ́rọ̀ kan ṣá, ńṣe ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń gba Tímótì níyànjú láti máa ‘dìde dúró níwájú orí ewú.’ Ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí náà sì tún kan gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni.

Àmọ́ ṣá o, kò dìgbà tẹ́nì kan bá gbé òfin kalẹ̀ káwọn olùfọkànsìn tó máa fọ̀wọ̀ wọ àwọn arúgbó tàbí kí wọ́n tó máa bọlá fún wọn. Ìwọ gbé àpẹẹrẹ ti Jósẹ́fù tó wà nínú Bíbélì yẹ̀ wò, ẹni tí kò kọ òun tó máa ná òun láti mú bàbá rẹ̀ arúgbó wá sí Íjíbítì, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ gba ẹ̀mí Jékọ́bù, ẹni àádóje ọdún là lọ́wọ́ ìyàn tó mú délé dóko. Bí Jósẹ́fù ṣe fojú kan bàbá rẹ̀ tó ti rí láti ohun tó lé ní ogún ọdún sẹ́yìn báyìí, “lójú-ẹsẹ̀ ni ó gbórí lé e lọ́rùn, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí da omijé sí i lọ́rùn léraléra.” (Jẹ́nẹ́sísì 46:29) Kó tó di pé fífi ìyọ́nú bá àwọn arúgbó lò àti bíbọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún wọn di òfin fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Jósẹ́fù ti fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ ká gbà máa ṣe bẹ́ẹ̀.

Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, Jésù fúnra rẹ̀ gba ti àwọn arúgbó rò. Ó dẹ́bi fún àwọn aṣáájú ìsìn tí wọn ò rí ohun tó burú nínú ṣíṣàì kọbi ara sí àwọn òbí wọn àgbà nítorí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ìsìn. (Mátíù 15:3-9) Jésù tún tọ́jú ìyá rẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́, débi pé nígbà tó ń jẹ̀rora lórí òpó igi oró, ó rí i dájú pé òun fa màmá òun tàgbà ti ń dé bá lé àpọ́sítélì Jòhánù, ọmọ ẹ̀yìn tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún un lọ́wọ́, kó lè máa bá òun tọ́jú rẹ̀.—Jòhánù 19:26, 27.

Ọlọ́run Kì Í Pa Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Tó Jẹ́ Adúróṣinṣin Tì

Onísáàmù gbàdúrà pé: “Má ṣe gbé mi sọnù ní àkókò ọjọ́ ogbó; ní àkókò náà tí agbára mi ń kùnà, má ṣe fi mí sílẹ̀.” (Sáàmù 71:9) Ọlọ́run kì í “gbé” àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń fi ìṣòtítọ́ sìn ín “sọnù,” àní nígbà tí àwọn fúnra wọn bá tilẹ̀ ń ronú pé àwọn ò wúlò mọ́. Onísáàmù ò gbà pé Jèhófà ti pa òun tì; kàkà bẹ́ẹ̀, ó mọ̀ pé òun gan-an ló yẹ kóun túbọ̀ gbára lé Ẹlẹ́dàá òun bí òun ti ń dàgbà sí i. Jèhófà máa ń fi hàn pé inú òun dùn sí àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. (Sáàmù 18:25) Àwọn Kristẹni bíi tiwa ni Jèhófà máa ń lò láti pèsè irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀.

Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò tán yìí, ó ṣe kedere pé gbogbo àwọn tó bá fẹ́ bọlá fún Ọlọ́run tún gbọ́dọ̀ bọlá fún àwọn àgbàlagbà. Dájúdájú, àwọn àgbàlagbà ṣeyebíye lójú Ẹlẹ́dàá wa. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tá a dá ní àwòrán rẹ̀, ǹjẹ́ ká máa bá a nìṣó láti máa fi irú ojú kan náà tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn “orí ewú” wò wọ́n.—Sáàmù 71:18.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn Kristẹni máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn arúgbó wọ́n sì máa ń bọlá fún wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́