ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 12/1 ojú ìwé 29-31
  • Ǹjẹ́ Gbogbo Àròyé ni Ó Burú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Gbogbo Àròyé ni Ó Burú?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipa Búburú Tí Ó Ń Ní Lórí Ẹni àti Lórí Àwọn Ẹlòmíràn
  • Ǹjẹ́ Gbogbo Àròyé Ni A Kà Léèwọ̀?
  • Ìjọ Kristẹni
  • Sọ́dọ̀ Aláṣẹ Tí Ó Yẹ
  • Idi Ti Ìpín Aláròyé kìí Fií Ṣe Ọ̀kan Ti Ó Jẹ́ Alayọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Ráhùn?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo Láìsí Ìkùnsínú”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ẹ Máa Sìn Ní Ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 12/1 ojú ìwé 29-31

Ǹjẹ́ Gbogbo Àròyé ni Ó Burú?

Ohun amúnibínú wo ní ń dunni tó èyí tí a kò lè ṣàròyé nípa rẹ̀?—Marquis De Custine, 1790-1857.

FÚN ọdún méjì ni ó ti fara da fífòòró tí òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ń fìbálòpọ̀ fòòró ẹ̀mí rẹ̀. Fífi tí ó fi ẹ̀hónú rẹ̀ hàn yọrí sí sísọ̀rọ̀ èébú sí i àti fífipegi. Másùnmáwo tí ó ti gbára jọ náà ń ṣàkóbá fún ìlera rẹ̀, ṣùgbọ́n kí ni ó lè ṣe? Bákan náà, a lé akẹ́kọ̀ọ́ kan tí ó máa ń ṣe ipò kíní nínú kíláàsì rẹ̀ kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ nítorí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò jẹ́ kí ó kópa nínú ètò ẹ̀kọ́ nípa ọ̀nà ìgbèjà ara ẹni tí ilé ẹ̀kọ́ náà mú ní dandan. Àwọn méjèèjì ronú pé a ti hùwà ìkà sí wọn, ṣùgbọ́n, ó ha yẹ kí wọ́n ṣàròyé bí? Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ha lè máa retí ìtura, àbí yóò túbọ̀ bọ̀rọ̀ jẹ́ sí i ni?

Àwọn àròyé bí ìwọ̀nyí àti àwọn mìíràn wọ́pọ̀ lónìí, níwọ̀n bí a ti ń gbé láàárín àwọn ènìyàn aláìpé, nínú ayé tí kò báradé. Àròyé bẹ̀rẹ̀ látorí sísọ àìtẹ́nilọ́rùn, ẹ̀dùn ọkàn, ìrora, tàbí ìbínú ẹni jáde lórí ipò kan, dóri pípe ẹnì kàn lẹ́jọ́. Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn yàn láti yẹra fún ṣíṣàròyé àti kíkoni lójú; síbẹ̀, ṣé ó yẹ kí ènìyàn máa panu mọ́ nígbà gbogbo? Kí ni ojú ìwòye Bíbélì?

Ipa Búburú Tí Ó Ń Ní Lórí Ẹni àti Lórí Àwọn Ẹlòmíràn

Kò sí àní-àní pé níní ẹ̀mí ṣíṣàròyé ṣáá ń ṣèpalára, Bíbélì kò sì fojú rere wò ó. Aláròyé yóò mú ìpalára nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí wá sórí ara rẹ̀, yóò sì mú inú bí àwọn tí ó ń ṣàròyé nípa wọn. Ní títọ́ka sí aya tí ń ṣàròyé, òwe inú Bíbélì sọ pé: “Òrùlé jíjò tí ń léni lọ ní ọjọ́ òjò àrọ̀-ìdá àti aya alásọ̀ ṣeé fi wéra.” (Òwe 27:15, NW) Ṣíṣàròyé nípa Jèhófà tàbí nípa ọ̀kan nínú àwọn ìpèsè rẹ̀ léwu gidigidi. Nígbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣàròyé nípa mánà àgbàyanu tí a pèsè fún wọn nígbà ìrìn 40 ọdún wọn nínú aginjù, ní pípè é ní “oúnjẹ fútẹ́fútẹ́,” Jèhófà rán àwọn ejò olóró láti fìyà jẹ àwọn aláròyé tí kò fọ̀wọ̀ hàn, ọ̀pọ̀ sì kú.—Númérì 21:5, 6.

Síwájú sí i, Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nímọ̀ràn pé, kí wọ́n má ṣàròyé nípa “ègé koríko” ti ìkù-díẹ̀-káàtó tí wọ́n kíyè sí lára àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, ṣùgbọ́n láti túbọ̀ wà lójúfò sí “igi ìrólé” títóbi ti àbùkù tí àwọn fúnra wọ́n ní. (Mátíù 7:1-5) Lọ́nà kan náà, Pọ́ọ̀lù ka ṣíṣèdájọ́ (irú ìṣàròyé kan) ẹlòmíràn sí ‘àìní àwíjàre, níwọ̀n bí ìwọ tí ń ṣèdájọ́ ti ń fi ohun kan náà ṣèwàhù.’ Ìkìlọ̀ wọ̀nyí tí a fúnni nípa ṣíṣàròyé yẹ kí ó sún wa láti yẹra fún ṣíṣelámèyítọ́ láìnídìí àti mímú ẹ̀mí àròyé dàgbà.—Róòmù 2:1.

Ǹjẹ́ Gbogbo Àròyé Ni A Kà Léèwọ̀?

Nígbà náà, ó ha yẹ kí a parí èrò sí pé gbogbo onírúurú àròyé ni ó yẹ kí a kà léèwọ̀? Rárá, kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀. Bíbélì fi hàn pé ọ̀pọ̀ àìṣèdájọ́ òdodo ni ó ń bẹ nínú ayé tí ó kún fún àbùkù tí a ń gbé, tí ó ń fẹ́ àtúnṣe ní tòótọ́. Nínú àkàwé kan, Jésù mẹ́nu kan aláìṣòdodo onídàájọ́ kan tí ó fi ìlọ́tìkọ̀ rí i pé opó kan tí a ni lára rí ìdájọ́ òdodo gbà, kí ó má baà “máa wá ṣáá kí ó sì máa lù [ú] kíkankíkan dé òpin.” (Lúùkù 18:1-8) Ní àwọn ọ̀nà kan, àwa pẹ̀lú lè ní láti tẹra mọ́ àròyé tí a ń ṣe títí ti a óò fi ṣàtúnṣe ìwà àìtọ́.

Ní rírọ̀ wá láti máa gbàdúrà fún dídé Ìjọba Ọlọ́run, kì í ha ṣe pé Jésù ń ké sí wa láti mọ ìkù-díẹ̀-káàtó ayé ìsinsìnyí, kí a sì ‘kígbe ẹkún’ sí Ọlọ́run fún ojútùú? (Mátíù 6:10) Nígbà tí “igbe ìráhùn” nípa ìwà ibi Sódómù àti Gòmórà ìgbàanì dé etígbọ̀ọ́ rẹ̀, Jèhófà rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti “rí bóyá wọ́n hùwà látòkè délẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú igbe ẹkún tí wọ́n ń ké lé e lórí,” kí wọ́n sì mú ojútùú wá. (Jẹ́nẹ́sísì 18:20, 21, NW) Sí ìtura àwọn tí ó ti ṣàròyé fún un, Jèhófà ṣàtúnṣe ipò náà nípa pípa ìlú méjèèjì àti àwọn olùgbé wọn oníwà pálapàla run.

Ìjọ Kristẹni

Ó ha yẹ kí nǹkan yàtọ̀ láàárín àwọn ará nínú ìjọ Kristẹni bí? Bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ ọkùnrin àti obìnrin aláìpé, àwọn Kristẹni ń sapá gidigidi láti sin Ọlọ́run ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan. Síbẹ̀, àwọn ipò nǹkan yóò dìde láàárín wọn tí yóò mú kí wọ́n ṣàròyé, tí yóò sì fẹ́ ojútùú. Ní ọ̀rúndún kìíní, ipò kan dìde nínú ìjọ àwọn ẹni àmì òróró kété lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì. Ọ̀pọ̀ àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni dúró sí Jerúsálẹ́mù fún ìtọ́ni àti ìṣírí síwájú sí i. Wọ́n ṣàjọpín oúnjẹ tí wọ́n ní. Ṣùgbọ́n, “ìkùnsínú kan dìde níhà ọ̀dọ̀ àwọn Júù tí ń sọ èdè Gíríìkì lòdì sí àwọn Júù tí ń sọ èdè Hébérù, nítorí pé àwọn opó wọn ni a ń gbójúfò dá nínú ìhá-nǹkan-fúnni ojoojúmọ́.” Dípò kíka àwọn aláròyé wọ̀nyí sí adárúgúdù sílẹ̀, àwọn àpọ́sítélì gbégbèésẹ̀ láti ṣàtúnṣe ipò náà. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn alábòójútó nínú ìjọ yóò tẹ́tí sí àròyé tí ó bá lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, tí a ṣe tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, tí a sì ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí tí ó yẹ, wọ́n yóò sì gbé ìgbésẹ̀ lé e lórí.—Ìṣe 6:1-6; Pétérù Kíní 5:3.

Sọ́dọ̀ Aláṣẹ Tí Ó Yẹ

Ìwọ ha kíyè sí i láti inú àwọn àpẹẹrẹ tí ó wà lókè yí pé, ẹ̀mí tí ó tọ́ ni ó yẹ kí a fi ṣàròyé, kí ó sì jẹ́ sọ́dọ̀ aláṣẹ tí ó yẹ? Fún àpẹẹrẹ, kò ní bọ́gbọ́n mu láti ṣàròyé nípa ìnira owó orí fún ọlọ́pàá tàbí nípa àìlera ẹni fún adájọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní bójú mu láti ṣàròyé nípa ipò nǹkan yálà nínú ìjọ tàbí lóde ìjọ fún ẹni tí kò ní ọlá àṣẹ tàbí tí kò ní agbára àtiṣèrànlọ́wọ́.

Ní ọ̀pọ̀ jù lọ ilẹ̀ lónìí, ilé ẹjọ́ àti àwọn aláṣẹ yíyẹ mìíràn wà, tí a lè fẹjọ́ sùn pẹ̀lú ìrètí gbígba ìtura díẹ̀. Nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí gbé àròyé rẹ̀ lọ síwájú ilé ẹjọ́, adájọ́ dá a láre, wọ́n sì gbà á pa dà sí ilé ẹ̀kọ́ náà, ilé ẹ̀kọ́ náà sì tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ̀. Bákan náà, obìnrin òṣìṣẹ́ tí a fi ìbálòpọ̀ fòòró rí ìtura nípasẹ̀ àjọ àwọn obìnrin tí ń ṣiṣẹ́. Ẹ̀ka tí ń bójú tó ilé ẹ̀kọ́ tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn agbanisíṣẹ́ rẹ̀ gbé ìgbésẹ̀ láti fòpin sí fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹni.

Ṣùgbọ́n, kò yẹ ki a retí pé gbogbo àròyé ni yóò rí irú àbájáde kan náà yí. Ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ pé: “Èyí tí ó wọ́, a kò lè mú un tọ́.” (Oníwàásù 1:15) Ó dára bí a bá lóye pé àwọn ọ̀ràn kan yóò ní láti dúró dé Ọlọ́run láti wá ojútùú sí i ní àkókò rẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn alàgbà ń tẹ́tí sí àwọn àròyé tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ lé e lórí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́