Èrè Jìngbìnnì Fún Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́wọ̀
Gẹ́gẹ́ bí Harry Bloor ṣe sọ ọ́
Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, bàbá mi àgbà jẹ́ ògbóṣáṣá mẹ́ńbà Ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́tọ́díìsì. Ó tún jẹ́ oníwàásù ọmọ ìjọ tí a bọ̀wọ̀ fún, tí ó ṣètìlẹyìn dáradára fún ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì kéékèèké tí ó wà ní Stoke-on-Trent, ìlú tí wọ́n ti ń mọ amọ̀ ní England. Lẹ́yìn náà, ọ̀dá owó dá a. Láti ran Bàbá Àgbà lọ́wọ́, bàbá mi ṣètò ṣíṣí ṣọ́ọ̀bù kékeré kan sí abúlé fún un. Ṣọ́ọ̀bù náà ní ìwé àṣẹ fún títa ọtí, nígbà tí àwọn ẹlẹ́sìn Mẹ́tọ́díìsì sì gbọ́ nípa èyí, kíá ni wọ́n yọ Bàbá Àgbà lẹ́gbẹ́.
INÚ bí bàbá mi gidigidi, ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun kò ní ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìsìn mọ́ láé—ó sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Ọlọ́pàá ni tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n, nígbà tí ó yá, ó di ọ̀gá ilé ọtí. Nítorí náà, a tọ́ mi dàgbà láàárín òórùn àti èéfín sìgá ibẹ̀. Ìsìn kò kó ipa kankan nínú ìgbésí ayé mi, ṣùgbọ́n mo kọ́ láti kó ipa nínú ọ̀pọ̀ jù lọ eré ayò dáradára! Ṣùgbọ́n, nítorí ipa tí Bàbá Àgbà ti ní lórí mi ní ìbẹ̀rẹ̀, mo ṣì ní ọ̀wọ̀ tí ó ga fún Bíbélì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí mo mọ̀ nínú rẹ̀ kò tó nǹkan.
Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Bíbélì
Ní 1923, nígbà tí mo jẹ́ ẹni ọdún 24, mo ṣí lọ sí ìlà oòrùn ní Nottingham, mo sì ń fẹ́ Mary, tí ń gbé ní nǹkan bí 40 kìlómítà, ní abúlé Whetstone, ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Leicester sọ́nà. Bàbá rẹ̀, Arthur Rest, ti fìgbà kan jẹ́ aludùùrù ní ṣọ́ọ̀ṣì kékeré tí ó wà ládùúgbò, ṣùgbọ́n ní àkókò yí, ó ti di ògbóṣáṣá Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, orúkọ tí a ń pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà náà. Gbogbo ìgbà ni Arthur máa ń bá mi sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀ tuntun—ìyọrísí bíńtín ni èyí ní. Ṣùgbọ́n, a ru ìfẹ́ mi sókè nígbà tí mo tẹ̀ lé e lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Baptist kékeré tí ó wà ní àdúgbò, ní ọ̀sán Sunday, July 13, 1924, láti lọ gbọ́ àsọyé láti ẹnu mẹ́ńbà ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, tí ó jẹ́ ẹni pàtàkì nínú ẹ̀sìn Baptist. Kókó ẹ̀kọ́ rẹ̀, “A Gbé Ẹ̀kọ́ Pásítọ̀ Russell Yẹ̀ Wò Lójú Ìwòye Ìwé Mímọ́,” ru ọkàn mi sókè. Mo ṣì ní ìwé tí mo kọ̀rọ̀ sí lọ́wọ́.
Àwọn Baptist kọ̀ láti jẹ́ kí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbèjà ìgbàgbọ́ wọn. Inú bí mi gidigidi sí èyí, mo sì pinnu láti wá ibòmíràn tí a óò ti pe irú ìpàdé bẹ́ẹ̀. Abà kan tí ó wà nítòsí dára láti lò. A gbá a mọ́ tónítóní, a gbọn gbogbo jàǹkárìwọ̀ ibẹ̀, a ti àwọn ẹ̀rọ ìpakà sí ẹ̀gbẹ́ kan, gbogbo wá sì wà ní sẹpẹ́. A kó 70 àga jọ, a sì tẹ ìwé ìléwọ́.
Nígbà tí Frank Freer dé láti Leicester láti sọ àsọyé náà, gbogbo ìjókòó ti kún, àwọn 70 mìíràn sì wà nídùúró! Bí Frank ṣe lo Ìwé Mímọ́ láti múni ronú lọ́nà tí ó ṣe kedere fa ọkàn mi mọ́ra, bí ó ti fa ti ọ̀pọ̀ ènìyàn míràn tí ó pésẹ̀ síbẹ̀ mọ́ra pẹ̀lú. Láti ìgbà yẹn lọ, ìjọ kékeré ti Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ó wà ní Blaby nítòsí Leicester, yára gbèrú. Ó tún jẹ́ àkókò ìyípadà ńlá nínú ìgbésí ayé mi—àti nínú ti Mary pẹ̀lú. Ní 1925, àwa méjèèjì ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a ṣe ìrìbọmi, a sì ṣe ìgbéyàwó.
Ìbùkún Tẹ̀mí
Ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, a yàn mi ṣe olùdarí iṣẹ́ ìsìn ní Ìjọ Blaby. Èmi àti aya mi fẹ́ láti tẹ̀ lé ipasẹ̀ àwọn olùpín ìwé ìsìn kiri, kí a sì di ajíhìnrere alákòókò kíkún, ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí a fi mọ̀ pé ìlera Mary kò ní yọ̀ǹda fún un láti dójú ìwọ̀n irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ó nílò okun púpọ̀ bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ aláìlera títí di ìgbà tí ó fi kú ní 1987, ó jẹ́ alájọṣepọ̀ àtàtà àti òjíṣẹ́ títayọ lọ́lá, tí ó jẹ́ ògbógi nínú jíjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà àti bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìrọ̀lẹ́ ni a fi ń lọ sí àwọn ìpàdé tàbí ni a fi ń ṣàjọpín òtítọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wa.
Onímọ̀ ẹ̀rọ ni mí, mo sì ń bá ilé iṣẹ́ tí ń rọ ẹ̀rọ ìlagi ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ mi ń mú mi rìnrìn àjò káàkiri Britain, àti France, Mary sì sábà máa ń bá mi lọ. Àwọn ìrìn àjò wọ̀nyí fún wa láǹfààní láti jẹ́rìí lọ́nà gbígbòòrò.
Ìpìlẹ̀ fún Ìmúgbòòrò
Ní 1925, a kọ́ ilé dáradára kan láti máa ṣèpàdé wa ní Blaby, a sì ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún ìjẹ́rìí gbígbéṣẹ́ láti ibẹ̀. Ní gbogbo òwúrọ̀ Sunday, a máa ń háyà bọ́ọ̀sì, tí ó máa ń gbé wa lọ sí àwọn abúlé àti ìletò tí ó wà káàkiri. A máa ń já àwọn akéde sílẹ̀ lọ́nà láti wàásù, tí a óò sì pa dà gbé wọn nígbà tí a bá ń bọ̀. Láàárín àwọn oṣù ẹ̀ẹ̀rùn, a máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìrọ̀lẹ́ Sunday, a máa ń lo ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ lọ́ọ́lọ́ọ́. Lẹ́yìn náà, ní agogo mẹ́jọ, a máa ń pàdé ní ọjà Leicester fún àsọyé ìtagbangba. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, 200 ènìyàn ni ó tẹ́tí sí i. Ìgbòkègbodò yí fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ìjọ tí ó wà nísinsìnyí ní Leicester àti àyíká rẹ̀.
Ní 1926, a ṣe àpéjọpọ̀ mánigbàgbé kan pa pọ̀ ní Ààfin Alexandra ní London àti Gbọ̀ngàn Royal Albert. Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, Joseph F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, mú ìwé Deliverance jáde. A tẹ ìpinnu náà, “Ẹ̀rí fún Àwọn Olùṣàkóso Ayé,” àti àsọyé lílágbára tí Arákùnrin Rutherford sọ, “Ìdí Tí Àwọn Agbára Ayé Fi Ń Ta Gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n—Oògùn Àtúnṣe Náà,” látòkè délẹ̀, sínú òléwájú ìwé agbéròyìnjáde kan, ní ọjọ́ kejì. Iye tí ó lé ní 10,000 ni ó gbọ́ àsọyé fún gbogbo ènìyàn náà, a sì pín 50,000,000 ẹ̀dà ìpinnu náà kiri jákèjádò ayé lẹ́yìn náà. Àpéjọpọ̀ yẹn mú kí iṣẹ́ ìwàásù ní Britain yá kánkán.
Àpéjọpọ̀ Ńlá Lákòókò Ogun
Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀ ní September 1939, nígbà tí yóò fi di 1941, ogun náà ti gbóná. Tọ̀sán tòru ni àwọn ará Germany tí ń ju bọ́ǹbù ń ju bọ́ǹbù wọn, a sì fi gbogbo orílẹ̀-èdè náà sínú òkùnkùn biribiri. Oúnjẹ wọ́n gógó, a sì rọra ń pín ìwọ̀nba tí ó wà láàárín àwọn ènìyàn. Ètò ìrìnnà fàlàlà kò sí, àní nípasẹ̀ ọkọ̀ ojú irin pàápàá. Láìka àwọn ohun tí ó jọ bí èyí tí kò ṣeé borí wọ̀nyí sí, a ṣe àpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ márùn-ún fún gbogbo orílẹ̀-èdè náà ní September 3 sí 7, 1941.
A yan Gbọ̀ngàn De Montfort ní Leicester láti ṣe àpéjọpọ̀ náà nítorí Leicester wà ní àárín gbùngbùn England. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ iṣẹ́ gẹdú ni mo ń ṣe, ó ṣeé ṣe fún mi láti fi kíkan àwọn pákó ìsọfúnni tí ń polongo àpéjọpọ̀ náà ṣèrànwọ́. Mo tún ṣe ètò ìrìnnà fún àwọn alápèéjọpọ̀. Nípa ríra tíkẹ́ẹ̀tì ṣáájú àkókò àti sísan iye tí ó ju owó ọkọ̀ lọ, ó ṣeé ṣe fún wa láti mú kí àwọn ọkọ̀ ojú irin ajé ìgboro Leicester ṣiṣẹ́ àní ní ọjọ́ Sunday pàápàá.
Nítorí tí a fòfin de rírìnrìn àjò, ìrètí wa ni pé bóyá a óò rí tó 3,000 Ẹlẹ́rìí tí yóò wá. Ẹ wo bí inú wa ti dùn tó nígbà tí iye tí ó lé ní 10,000 sọ pé àwọn yóò wà níbẹ̀! Ṣùgbọ́n, ibo ni wọn yóò dé sí? Àwọn aráàlú Leicester fi inú rere ké sí ọ̀pọ̀ láti dé sí ilé wọn. Ní àfikún sí i, a fi nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan wọ̀ sí inú àwọn àgọ́ tí a pa sí pápá kan, tí ó tó kìlómítà mẹ́ta sí ilẹ̀ àpéjọpọ̀. Àgọ́ Gídíónì, gẹ́gẹ́ bí orúkọ tí a fún un, di ohun àpéwò ní àdúgbò.
A háyà àwọn àgọ́ funfun ńlá láti lò fún àwọn ilé iṣẹ́ ní àpéjọpọ̀, àti láti lò gẹ́gẹ́ bí ilé gbígbé fún èrò tí ó ya wá. Nígbà tí a rí i pé, nínú ìmọ́lẹ̀ òṣùpá rekete, àwọn àgọ́ náà lè di ojúsùn àwọn Nazi tí ń ju bọ́ǹbù, kíá ni a dọ́gbọ́n sí wọn. Ogun náà, pàápàá àìkópa Àwọn Ẹlẹ́rìí nínú rẹ̀, jẹ́ ọ̀ràn tí gbogbo ènìyàn ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Lákòókò náà, ọgọ́rọ̀ọ̀rún Àwọn Ẹlẹ́rìí ni ó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ipò àìdásí tọ̀túntòsì, tí a gbé ka orí Bíbélì, tí wọ́n dì mú.—Aísáyà 2:4; Jòhánù 17:16.
Ìwé agbéròyìnjáde The Leicester Mercury, ti September 7, 1941, ròyìn pé: “Ó jẹ́ ohun tí ń ṣeni ní kàyéfì láti rí 10,000 ènìyàn, tí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn jẹ́ ọ̀dọ́, tí ń lo ọ̀sẹ̀ kan ní sísọ̀rọ̀ nípa ìsìn láìmẹ́nu kan ogun, àyàfi gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn àyàbá.
“Mo béèrè bóyá Àwọn Ẹlẹ́rìí ní mẹ́ńbà ní Germany. Wọ́n sọ fún mi pé, bẹ́ẹ̀ ni, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo wọn, nǹkan bí 6,000, ni ó wà nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.”
Oníròyìn náà fi kún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, òtítọ́ ni pé ìjọba Nazi jẹ́ ọ̀tá, ṣùgbọ́n, kò fi bẹ́ẹ̀ sí ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe nípa wọn, yàtọ̀ sí títa ìwé àṣàrò kúkúrú àti títẹ́tí sí àwọn àsọyé.”
Ní gbogbogbòò, ohun tí a kọ sínú àwọn ìwé agbéròyìnjáde nípa wa kò dára, àwọn alátakò tilẹ̀ yíjú sí lílo ìwà ipá nínú ìgbìdánwò fíforíṣánpọ́n láti da àpéjọpọ̀ wa rú. Síbẹ̀, ìwé agbéròyìnjáde ti London náà, Daily Mail, lọ́ tìkọ̀ láti sọ pé: “Ètò náà gún régé, kò máriwo lọ́wọ́, ó sì gbéṣẹ́.”
Wọ́n fẹ̀sùn kàn wá pé àwa ni a fa àìfibẹ́ẹ̀ sí sìgá ní ìlú náà. Ṣùgbọ́n ìwé agbéròyìnjáde The Daily Mail ṣàlàyé pé: “Ìlú Leicester àti Olùṣekòkárí Sìgá kò lè ṣàròyé pé Àwọn Ẹlẹ́rìí ni kò jẹ́ kí sìgá Leicester tó. Wọn kì í mu sìgá.” Pẹ̀lúpẹ̀lù, àròyé náà pé Àwọn Ẹlẹ́rìí ń fi oúnjẹ du àwọn aládùúgbò ni a fọwọ́ rọ́ tì nígbà ti a ṣàlàyé pé ṣe ni wọ́n gbé ọ̀pọ̀ jù lọ nínú oúnjẹ wọn wá. Ní tòótọ́, ní ìparí àpéjọpọ̀ náà, kìlógíráàmù 1.8 búrẹ́dì ni a fi tọrẹ fún Ilé Ìtọ́jú Aláìsàn ti Aláyélúwà ti Leicester—ọrẹ ńlá ní àwọn àkókò tí oúnjẹ wọ́n gógó wọ̀nyẹn.
Àpéjọpọ̀ náà pèsè ìrusókè ńlá nípa tẹ̀mí fún Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó tó nǹkan bí 11,000 tí ó wà ní Britain. Inú wọ́n dùn pé nǹkan bí 12,000 ni ó pé jọ! Àwọn tí wọ́n wá sí àpéjọpọ̀ náà fi ìdùnnú lọ́wọ́ nínú ìjẹ́rìí òpópónà lọ́nà tí a kò ṣe rí ní Leicester, wọ́n sì ṣèbẹ̀wò sí àwọn abúlé jíjìnnà réré pẹ̀lú ìgbékalẹ̀ ohun èlò agbóhùnjáde.
Àwọn àsọyé tí a gbà sílẹ̀ nígbà àpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ márùn-ún ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní St. Louis, Missouri, U.S.A., ní oṣù tí ó ṣáájú, ni lájorí àsọyé àpéjọpọ̀ náà. Ọ̀rọ̀ àsọyé Arákùnrin Rutherford tí a gbà sílẹ̀, “Àwọn Ọmọ Ọba Náà,” ni pàtàkì àpéjọpọ̀ náà. Níwọ̀n bí kò ti ṣeé ṣe láti kó àwọn ẹ̀dà ìwé náà, Children, tí a mú jáde ní St. Louis wọ̀lú, a ṣe ẹ̀dà ìwé náà tí ó jẹ́ ẹlẹ́yìn fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ jáde lẹ́yìn náà ní Britain. A fi ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan rẹ̀ ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ọmọdé tí ó ti wá sí àpéjọpọ̀ náà.
Ìpàdé Ọdọọdún Aláìlẹ́gbẹ́ ní Leicester
Lẹ́yìn ogun, ìbísí àwọn olùpòkìkí Ìjọba ní Britain ga lọ́lá! Nígbà tí yóò fi di ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1980, iye ìjọ ní Leicester ti lọ sókè sí mẹ́wàá. Lẹ́yìn náà, a sọ fún wa pé Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pinnu láti ṣe ìpàdé ọdọọdún ti Watch Tower Bible and Tract Society ní Leicester ní 1983. Gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ìlú Leicester, kò pẹ́ tí ọwọ́ mi fi dí fọ́fọ́ fún mímúrasílẹ̀, títí kan híháyà Gbọ̀ngàn De Montfort lẹ́ẹ̀kan sí i.
Mẹ́ńbà 13 ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ni ó wá láti orílé-iṣẹ́ Society ní Brooklyn, fún ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Àròpọ̀ 3,671 tí wọ́n wá—lọ́tẹ̀ yí, káàkiri àgbáyé, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọ́n jẹ́ àwọn tí ó ti pẹ́ nínú ètò—kún inú gbọ̀ngàn àpéjọ náà. Àwọn 1,500 ní àfikún sí i tẹ́tí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ tí ó wà nítòsí.
Albert D. Schroeder, tí ó bójú tó ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society ní London nígbà àpéjọpọ̀ tí a ṣe ní Leicester, nígbà tí ogun ń lọ lọ́wọ́, ni ó ṣalága ìpàdé ọdọọdún yìí. Ní wíwẹ̀yìn pa dà sí àpéjọpọ̀ ọdún 1941 náà, Arákùnrin Schroeder béèrè pé: “Ẹ̀yin mélòó tí ẹ wà pẹ̀lú wa lónìí ni ó wà níbẹ̀ nígbà náà?” Iye tí ó ju ìdajì lọ nínú àwùjọ náwọ sókè. Ó kígbe pé: “Èyí bùáyà! Ẹ wo irú àǹfààní pípàdépọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i tí èyí jẹ́ fún ẹ̀yin olùṣòtítọ́ adúróṣinṣin ènìyàn!” Ó jẹ́ ìrírí mánigbàgbé kan ní tòótọ́.
Ní ẹni ọdún 98, mo ṣì ń sìn gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé nínú ìjọ wa tí mo sì ń sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orí ìjókòó ni mo ti máa ń sọ ọ́ báyìí. Lẹ́yìn tí Mary kú ní 1987, mo fẹ́ Bettina, opó kan tí èmi àti Mary ti mọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Mo dúpẹ́ pé a tọ́jú mi dáradára, nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí. Láìka ìkálọ́wọ́kò tí àìlera Mary mú wá, àti ọjọ́ ogbó mi nísinsìnyí sí, mo ti rí i pé níní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ nígbà gbogbo máa ń mú ìbùkún jìngbìnnì wá.—Kọ́ríńtì Kíní 15:58.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Mo múra láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní àwọn ọdún 1920
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn ìran àpéjọpọ̀ ní Leicester