ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 35
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nọ́ńbà

      • Ìlú àwọn ọmọ Léfì (1-8)

      • Àwọn ìlú ààbò (9-34)

Nọ́ńbà 35:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:1; 36:13

Nọ́ńbà 35:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 49:7; Di 18:1; Joṣ 14:4
  • +Le 25:32-34; Joṣ 21:3; 2Kr 11:14

Nọ́ńbà 35:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.

Nọ́ńbà 35:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 20:2, 3, 7, 8; 21:13, 21, 27, 32, 36, 38
  • +Di 4:42

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1703

Nọ́ńbà 35:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 21:3

Nọ́ńbà 35:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 49:7
  • +Nọ 26:54; 33:54

Nọ́ńbà 35:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:8; 23:23; Nọ 34:2

Nọ́ńbà 35:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “apààyàn.”

  • *

    Tàbí “pa ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 21:12, 13; Di 4:42; 19:4, 5

Nọ́ńbà 35:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 35:19; Di 19:6
  • +Di 19:11, 12; Joṣ 20:5, 9

Nọ́ńbà 35:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:41-43
  • +Di 19:8, 9; Joṣ 20:7

Nọ́ńbà 35:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pa ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:49; Le 19:34; Nọ 15:16
  • +Joṣ 20:2, 3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    11/15/1995, ojú ìwé 10-14, 16-17

Nọ́ńbà 35:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 9:5; Ẹk 21:12; Le 24:17; Di 19:11, 12

Nọ́ńbà 35:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    11/2017, ojú ìwé 9

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    11/15/1995, ojú ìwé 11

Nọ́ńbà 35:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “tó lúgọ dè é.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 21:14; Di 19:11, 12

Nọ́ńbà 35:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “láì lúgọ dè é.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 21:12, 13; Di 19:4, 5; Joṣ 20:2, 3

Nọ́ńbà 35:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 35:12; Joṣ 20:4, 5

Nọ́ńbà 35:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:4, 7

Nọ́ńbà 35:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 20:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    11/15/1995, ojú ìwé 13-14, 18-19

Nọ́ńbà 35:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

  • *

    Ní Héb., “fi ẹnu sí i.”

  • *

    Tàbí “ọkàn èyíkéyìí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 9:6; Ẹk 20:13
  • +Di 17:6; 19:15; Heb 10:28

Nọ́ńbà 35:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 9:5; Ẹk 21:14; Di 19:13

Nọ́ńbà 35:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 4:8, 10; Sm 106:38; Lk 11:50
  • +Jẹ 9:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2004, ojú ìwé 27

Nọ́ńbà 35:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 25:8; Le 26:12

Àwọn míì

Nọ́ń. 35:1Nọ 22:1; 36:13
Nọ́ń. 35:2Jẹ 49:7; Di 18:1; Joṣ 14:4
Nọ́ń. 35:2Le 25:32-34; Joṣ 21:3; 2Kr 11:14
Nọ́ń. 35:6Joṣ 20:2, 3, 7, 8; 21:13, 21, 27, 32, 36, 38
Nọ́ń. 35:6Di 4:42
Nọ́ń. 35:7Joṣ 21:3
Nọ́ń. 35:8Jẹ 49:7
Nọ́ń. 35:8Nọ 26:54; 33:54
Nọ́ń. 35:10Ẹk 3:8; 23:23; Nọ 34:2
Nọ́ń. 35:11Ẹk 21:12, 13; Di 4:42; 19:4, 5
Nọ́ń. 35:12Nọ 35:19; Di 19:6
Nọ́ń. 35:12Di 19:11, 12; Joṣ 20:5, 9
Nọ́ń. 35:14Di 4:41-43
Nọ́ń. 35:14Di 19:8, 9; Joṣ 20:7
Nọ́ń. 35:15Ẹk 12:49; Le 19:34; Nọ 15:16
Nọ́ń. 35:15Joṣ 20:2, 3
Nọ́ń. 35:16Jẹ 9:5; Ẹk 21:12; Le 24:17; Di 19:11, 12
Nọ́ń. 35:20Ẹk 21:14; Di 19:11, 12
Nọ́ń. 35:22Ẹk 21:12, 13; Di 19:4, 5; Joṣ 20:2, 3
Nọ́ń. 35:24Nọ 35:12; Joṣ 20:4, 5
Nọ́ń. 35:25Ẹk 29:4, 7
Nọ́ń. 35:28Joṣ 20:6
Nọ́ń. 35:30Jẹ 9:6; Ẹk 20:13
Nọ́ń. 35:30Di 17:6; 19:15; Heb 10:28
Nọ́ń. 35:31Jẹ 9:5; Ẹk 21:14; Di 19:13
Nọ́ń. 35:33Jẹ 4:8, 10; Sm 106:38; Lk 11:50
Nọ́ń. 35:33Jẹ 9:6
Nọ́ń. 35:34Ẹk 25:8; Le 26:12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Nọ́ńbà 35:1-34

Nọ́ńbà

35 Jèhófà sọ fún Mósè ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ní Móábù, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì+ ní Jẹ́ríkò pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú tí wọ́n á máa gbé látinú ogún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gbà,+ kí wọ́n sì fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ibi ìjẹko tó yí àwọn ìlú+ náà ká. 3 Wọ́n á máa gbé àwọn ìlú náà, ibi ìjẹko náà á sì wà fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, àwọn ẹrù wọn àti gbogbo ẹran wọn yòókù. 4 Kí ibi ìjẹko tó yí àwọn ìlú tí ẹ máa fún àwọn ọmọ Léfì ká jẹ́ ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́* láti ògiri ìlú náà yí ká. 5 Ní ẹ̀yìn ìlú náà, kí ẹ wọn ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá ìlà oòrùn, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá gúúsù, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá ìwọ̀ oòrùn àti ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́ ní apá àríwá, kí ìlú náà wà ní àárín. Ìwọ̀nyí ló máa jẹ́ ibi ìjẹko àwọn ìlú náà.

6 “Ìlú mẹ́fà ni kí ẹ fún àwọn ọmọ Léfì láti fi ṣe ìlú ààbò,+ tí ẹ máa ní kí apààyàn sá lọ,+ kí ẹ sì tún fún wọn ní ìlú méjìlélógójì (42) míì. 7 Kí àpapọ̀ àwọn ìlú tí ẹ máa fún àwọn ọmọ Léfì jẹ́ méjìdínláàádọ́ta (48), pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko+ wọn. 8 Látinú ohun ìní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ ni kí ẹ ti fún wọn ní àwọn ìlú náà. Kí ẹ gba púpọ̀ lọ́wọ́ àwùjọ tó pọ̀, kí ẹ sì gba díẹ̀+ lọ́wọ́ àwùjọ tó kéré. Kí àwùjọ kọ̀ọ̀kan fún àwọn ọmọ Léfì lára àwọn ìlú rẹ̀ bí ogún tó gbà bá ṣe pọ̀ tó.”

9 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 10 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ máa sọdá Jọ́dánì sí ilẹ̀ Kénáánì.+ 11 Kí ẹ yan àwọn ìlú tó rọ̀ yín lọ́rùn láti fi ṣe ìlú ààbò, tí ẹni* tó bá ṣèèṣì pa èèyàn* máa sá lọ.+ 12 Kí àwọn ìlú yìí jẹ́ ìlú ààbò fún yín lọ́wọ́ ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀,+ kí apààyàn náà má bàa kú kí wọ́n tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níwájú àpéjọ+ náà. 13 Ohun tí àwọn ìlú mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ẹ yàn pé kó jẹ́ ibi ààbò máa wà fún nìyẹn. 14 Kí ẹ yan ìlú mẹ́ta ní apá ibí yìí ní Jọ́dánì,+ kí ẹ sì yan ìlú mẹ́ta ní ilẹ̀ Kénáánì+ láti fi ṣe ìlú ààbò. 15 Ìlú mẹ́fà yìí máa jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àjèjì+ àtàwọn tí wọ́n jọ ń gbé, ibẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tó bá ṣèèṣì pa èèyàn*+ máa sá wọ̀.

16 “‘Àmọ́ tó bá jẹ́ ohun tí wọ́n fi irin ṣe ni ẹnì kan fi lu ẹnì kejì rẹ̀, tó sì kú, apààyàn ni. Ẹ gbọ́dọ̀ pa apààyàn náà.+ 17 Tó bá jẹ́ òkúta tó lè pààyàn ló sọ lu ẹni náà, tó sì kú, apààyàn ni. Ẹ gbọ́dọ̀ pa apààyàn náà. 18 Tó bá sì jẹ́ ohun tí wọ́n fi igi ṣe tó lè pààyàn ló fi lù ú, tó sì kú, apààyàn ni. Ẹ gbọ́dọ̀ pa apààyàn náà.

19 “‘Ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ló máa pa apààyàn náà. Tó bá ti ṣe kòńgẹ́ rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ ló máa pa á. 20 Tí ẹnì kan bá kórìíra ẹnì kejì rẹ̀, tó sì tì í tàbí tó ń gbèrò ibi+ sí i,* tó sì ju nǹkan lù ú, tí ẹni náà wá kú, 21 tàbí tó kórìíra ẹnì kejì rẹ̀, tó sì fi ọwọ́ lù ú, tí ẹni náà wá kú, ṣe ni kí ẹ pa ẹni tó lu ẹnì kejì rẹ̀ pa. Apààyàn ni. Ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ máa pa apààyàn náà tó bá ti ṣe kòńgẹ́ rẹ̀.

22 “‘Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ńṣe ló ṣèèṣì tì í, tí kì í ṣe pé ó kórìíra rẹ̀ tàbí tó ju nǹkan lù ú láì gbèrò ibi+ sí i,* 23 tàbí tó ṣèèṣì sọ òkúta lù ú láìmọ̀ pé ó wà níbẹ̀, tí kì í sì í ṣe pé ọ̀tá rẹ̀ ni tàbí pé ó fẹ́ ṣe é léṣe, tí ẹni náà sì kú, 24 kí àpéjọ náà tẹ̀ lé ìdájọ́+ wọ̀nyí láti dá ẹjọ́ ẹni tó pààyàn àti ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀. 25 Kí àpéjọ náà wá gba apààyàn náà sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀, kí wọ́n sì dá a pa dà sí ìlú ààbò rẹ̀ tó sá lọ, kó sì máa gbé níbẹ̀ títí ọjọ́ tí àlùfáà àgbà tí wọ́n fi òróró mímọ́+ yàn fi máa kú.

26 “‘Àmọ́ tí apààyàn náà bá kọjá ààlà ìlú ààbò rẹ̀ tó sá wọ̀, 27 tí ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ sì rí i lẹ́yìn ààlà ìlú ààbò rẹ̀, tó sì pa á, kò jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. 28 Torí ìlú ààbò rẹ̀ ló gbọ́dọ̀ máa gbé títí àlùfáà àgbà fi máa kú. Àmọ́ tí àlùfáà àgbà bá ti kú, apààyàn náà lè pa dà sí ilẹ̀ rẹ̀.+ 29 Kí ìwọ̀nyí jẹ́ àṣẹ tí ẹ ó máa tẹ̀ lé láti ṣe ìdájọ́ jálẹ̀ àwọn ìran yín ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé.

30 “‘Kí ẹ tó pa ẹnikẹ́ni tó bá pa èèyàn,* àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ jẹ́rìí sí i* pé apààyàn+ ni; àmọ́ ẹ má pa ẹnikẹ́ni* tó bá jẹ́ pé ẹnì kan péré ló jẹ́rìí+ sí i. 31 Ẹ ò gbọ́dọ̀ gba ìràpadà fún ẹ̀mí* apààyàn tí ikú tọ́ sí, ṣe ni kí ẹ pa á.+ 32 Ẹ ò sì gbọ́dọ̀ gba ìràpadà fún ẹnì kan tó sá lọ sí ìlú ààbò rẹ̀ pé kó wá máa gbé ní ilẹ̀ rẹ̀ nígbà tí àlùfáà àgbà ò tíì kú.

33 “‘Ẹ má sọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé di ẹlẹ́gbin, torí ẹ̀jẹ̀ máa ń sọ ilẹ̀+ di ẹlẹ́gbin, kò sì sí ètùtù fún ẹ̀jẹ̀ tí ẹnì kan ta sórí ilẹ̀ àyàfi ẹ̀jẹ̀ ẹni náà tó ta á sílẹ̀.+ 34 Ẹ má sọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé di aláìmọ́, ilẹ̀ tí mò ń gbé; torí èmi Jèhófà ń gbé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́