ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóṣúà 20:2, 3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ yan àwọn ìlú ààbò fún ara yín,+ èyí tí mo ní kí Mósè sọ fún yín nípa rẹ̀, 3 kí ẹni tí kò bá mọ̀ọ́mọ̀ pààyàn tàbí tó ṣèèṣì pa èèyàn* lè sá lọ síbẹ̀. Àwọn ìlú náà á sì jẹ́ ìlú ààbò fún yín lọ́wọ́ ẹni tó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀.+

  • Jóṣúà 20:7, 8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Torí náà, wọ́n ya Kédéṣì+ ní Gálílì sọ́tọ̀* ní agbègbè olókè Náfútálì, Ṣékémù+ ní agbègbè olókè Éfúrémù àti Kiriati-ábà,+ ìyẹn Hébúrónì, ní agbègbè olókè Júdà. 8 Ní agbègbè Jọ́dánì, lápá ìlà oòrùn Jẹ́ríkò, wọ́n yan Bésérì+ ní aginjù tó wà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú* látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Rámótì+ ní Gílíádì látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Gádì àti Gólánì+ ní Báṣánì látinú ilẹ̀ ẹ̀yà Mánásè.+

  • Jóṣúà 21:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Wọ́n fún àwọn ọmọ àlùfáà Áárónì ní ìlú ààbò tí ẹni tó bá pààyàn máa sá lọ,+ ìyẹn Hébúrónì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Líbínà+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀,

  • Jóṣúà 21:21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 Wọ́n fún wọn ní ìlú ààbò tí ẹni tó bá pààyàn máa sá lọ,+ ìyẹn Ṣékémù+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ ní agbègbè olókè Éfúrémù, Gésérì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀,

  • Jóṣúà 21:27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 Látinú ìpín ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè, wọ́n fún àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì+ tí wọ́n jẹ́ ìdílé ọmọ Léfì ní ìlú ààbò tí ẹni tó bá pààyàn máa sá lọ, ìyẹn Gólánì+ ní Báṣánì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Bééṣítérà pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú méjì.

  • Jóṣúà 21:32
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 Látinú ìpín ẹ̀yà Náfútálì: ìlú ààbò+ tí ẹni tó bá pààyàn máa sá lọ, ìyẹn Kédéṣì+ ní Gálílì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Hamoti-dórì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀ àti Kátánì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, ó jẹ́ ìlú mẹ́ta.

  • Jóṣúà 21:36
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 36 Látinú ìpín ẹ̀yà Rúbẹ́nì: Bésérì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Jáhásì pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀,+

  • Jóṣúà 21:38
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 38 Látinú ìpín ẹ̀yà Gádì:+ ìlú ààbò tí ẹni tó bá pààyàn máa sá lọ, ìyẹn Rámótì ní Gílíádì+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀, Máhánáímù+ pẹ̀lú àwọn ibi ìjẹko rẹ̀,

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́