ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 25
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nọ́ńbà

      • Ísírẹ́lì bá àwọn obìnrin Móábù ṣèṣekúṣe (1-5)

      • Fíníhásì ṣe ohun tó tọ́ (6-18)

Nọ́ńbà 25:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 2:1; Mik 6:5
  • +Nọ 31:16; 1Kọ 10:8; Ifi 2:14

Nọ́ńbà 25:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:15; 1Kọ 10:20
  • +Ẹk 20:5

Nọ́ńbà 25:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “so ara rẹ̀ mọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:3; Joṣ 22:17; Sm 106:28, 29; Ho 9:10

Nọ́ńbà 25:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “orí.”

  • *

    Ní Héb., “níwájú oòrùn.”

Nọ́ńbà 25:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “so ara wọn mọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 18:21
  • +Ẹk 22:20; 32:25, 27; Di 13:6-9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2004, ojú ìwé 29

Nọ́ńbà 25:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 25:14, 15

Nọ́ńbà 25:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aṣóró.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 6:25; Joṣ 22:30

Nọ́ńbà 25:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 106:30

Nọ́ńbà 25:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 25:4; Di 4:3; 1Kọ 10:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    ‘Ìfẹ́ Ọlọ́run’, ojú ìwé 97-98

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2004, ojú ìwé 29

    7/15/1992, ojú ìwé 4-5

Nọ́ńbà 25:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 25:7
  • +Sm 106:30, 31
  • +Ẹk 20:5; 34:14; Di 4:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2004, ojú ìwé 27

    10/15/2002, ojú ìwé 29

    3/1/1995, ojú ìwé 16-17

Nọ́ńbà 25:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 6:4; Ẹsr 7:1, 5; 8:1, 2
  • +1Ọb 19:10

Nọ́ńbà 25:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 31:7, 8; Joṣ 13:21
  • +1Kr 1:32, 33

Nọ́ńbà 25:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 31:1, 2

Nọ́ńbà 25:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 25:3; 31:16
  • +Nọ 25:8, 15
  • +Nọ 25:9

Àwọn míì

Nọ́ń. 25:1Joṣ 2:1; Mik 6:5
Nọ́ń. 25:1Nọ 31:16; 1Kọ 10:8; Ifi 2:14
Nọ́ń. 25:2Ẹk 34:15; 1Kọ 10:20
Nọ́ń. 25:2Ẹk 20:5
Nọ́ń. 25:3Di 4:3; Joṣ 22:17; Sm 106:28, 29; Ho 9:10
Nọ́ń. 25:5Ẹk 18:21
Nọ́ń. 25:5Ẹk 22:20; 32:25, 27; Di 13:6-9
Nọ́ń. 25:6Nọ 25:14, 15
Nọ́ń. 25:7Ẹk 6:25; Joṣ 22:30
Nọ́ń. 25:8Sm 106:30
Nọ́ń. 25:9Nọ 25:4; Di 4:3; 1Kọ 10:8
Nọ́ń. 25:11Nọ 25:7
Nọ́ń. 25:11Sm 106:30, 31
Nọ́ń. 25:11Ẹk 20:5; 34:14; Di 4:24
Nọ́ń. 25:131Kr 6:4; Ẹsr 7:1, 5; 8:1, 2
Nọ́ń. 25:131Ọb 19:10
Nọ́ń. 25:15Nọ 31:7, 8; Joṣ 13:21
Nọ́ń. 25:151Kr 1:32, 33
Nọ́ń. 25:17Nọ 31:1, 2
Nọ́ń. 25:18Nọ 25:3; 31:16
Nọ́ń. 25:18Nọ 25:8, 15
Nọ́ń. 25:18Nọ 25:9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Nọ́ńbà 25:1-18

Nọ́ńbà

25 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé ní Ṣítímù,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọbìnrin Móábù+ ṣe ìṣekúṣe. 2 Àwọn obìnrin náà pè wọ́n síbi àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú sí àwọn ọlọ́run+ wọn, àwọn èèyàn náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ, wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún àwọn ọlọ́run+ wọn. 3 Bí Ísírẹ́lì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn jọ́sìn* Báálì Péórì+ nìyẹn, inú sì bí Jèhófà gidigidi sí Ísírẹ́lì. 4 Torí náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Mú gbogbo àwọn olórí* nínú àwọn èèyàn yìí, kí o sì gbé wọn kọ́ síwájú Jèhófà ní ọ̀sán gangan,* kí inú tó ń bí Jèhófà gidigidi sí Ísírẹ́lì lè rọlẹ̀.” 5 Mósè wá sọ fún àwọn onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì+ pé: “Kí kálukù yín pa àwọn èèyàn rẹ̀ tó bá wọn jọ́sìn* Báálì Péórì.”+

6 Ìgbà yẹn gan-an ni ọmọ Ísírẹ́lì kan wá mú obìnrin+ Mídíánì kan wá sí tòsí ibi tí àwọn èèyàn rẹ̀ wà, níṣojú Mósè àti gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì, nígbà tí wọ́n ń sunkún ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 7 Nígbà tí Fíníhásì+ ọmọ Élíásárì ọmọ àlùfáà Áárónì rí i, ojú ẹsẹ̀ ló dìde láàárín àpéjọ náà, ó sì mú ọ̀kọ̀* kan dání. 8 Ló bá tẹ̀ lé ọkùnrin Ísírẹ́lì náà wọnú àgọ́, ó sì gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ, ó gún ọkùnrin Ísírẹ́lì náà àti obìnrin náà níbi ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀. Bí àjàkálẹ̀ àrùn tó kọ lu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe dáwọ́ dúró+ nìyẹn. 9 Iye àwọn tí àjàkálẹ̀ àrùn náà pa jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógún (24,000).+

10 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 11 “Fíníhásì+ ọmọ Élíásárì ọmọ àlùfáà Áárónì ti jẹ́ kí inú tó ń bí mi sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rọlẹ̀ torí pé kò fàyè gba bíbá mi díje rárá láàárín wọn.+ Ìdí nìyẹn ti mi ò fi pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì run bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo sọ fún wọn pé èmi nìkan ṣoṣo ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa sìn.+ 12 Torí náà, sọ pé, ‘Màá bá a dá májẹ̀mú àlàáfíà. 13 Yóò sì jẹ́ májẹ̀mú iṣẹ́ àlùfáà tó máa wà pẹ́ títí fún òun àti àtọmọdọ́mọ rẹ̀,+ torí pé kò fàyè gba bíbá Ọlọ́run+ rẹ̀ díje, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”

14 Ó ṣẹlẹ̀ pé, orúkọ ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n pa pẹ̀lú ọmọbìnrin Mídíánì náà ni Símírì ọmọ Sálù, ìjòyè agbo ilé bàbá àwọn ọmọ Síméónì. 15 Orúkọ obìnrin ọmọ Mídíánì tí wọ́n pa ni Kọ́síbì ọmọ Súúrì+ tó jẹ́ olórí àwọn agbo ilé, ní ìdílé kan ní Mídíánì.+

16 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 17 “Ẹ lọ gbéjà ko àwọn ọmọ Mídíánì, kí ẹ sì ṣá wọn balẹ̀,+ 18 torí wọ́n ti ń dọ́gbọ́n gbéjà kò yín bí wọ́n ṣe fi ẹ̀tàn mú yín nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Péórì+ àti ọ̀rọ̀ Kọ́síbì ọmọ ìjòyè Mídíánì, arábìnrin wọn tí ẹ pa+ lọ́jọ́ tí àjàkálẹ̀ àrùn kọ lù yín torí ọ̀rọ̀ Péórì.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́