-
Diutarónómì 4:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 “Ẹ ti fi ojú ara yín rí ohun tí Jèhófà ṣe nínú ọ̀rọ̀ Báálì Péórì; gbogbo ọkùnrin tó tọ Báálì Péórì+ lẹ́yìn ni Jèhófà Ọlọ́run yín pa run kúrò láàárín yín.
-
-
Jóṣúà 22:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ tí a dá ní Péórì kò tíì tó wa ni? A ò tíì wẹ ara wa mọ́ nínú rẹ̀ títí dòní, láìka ti àjàkálẹ̀ àrùn tó jà láàárín àpéjọ Jèhófà.+
-