Ojú Ìwòye Bíbélì
Ìṣẹ́ra-Ẹni-Níṣẹ̀ẹ́ Ha Ni Ọ̀nà Àtilọ́gbọ́n Bí?
“ÀWỌN ayẹrafẹ́gbẹ́ wọ ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ onírin, ọ̀gbàrà ẹ̀wọ̀n, àmùrè irin ẹlẹ́nu ṣóńṣóṣóńṣó àti ọrùn aṣọ onírin ṣóńṣó létí . . . Àwọn mìíràn tí wọ́n wé ẹ̀gún òun ọ̀gàn mọ́ra fọwọ́ ara wọn fa kí kòkòrò wá ta wọ́n, wọ́n sun ara wọn, wọ́n sì yún egbò wọn tí kò fi yé ṣọyún. Wọ́n ń febi para wọn ní jíjẹ oúnjẹ ṣín-ún, àwọn kan ṣe ju èyí lọ nípa jíjẹ oúnjẹ jíjẹrà tàbí èyí tí ń ríni lára nìkan.”—The Saints, tí Edith Simon kọ.
Àwọn wọ̀nyí jẹ́ aṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́. Kí ló dé tí wọ́n ń ṣe irú aburú bẹ́ẹ̀ sí ara wọn? Nínú ìwé náà, For the Sake of the World—The Spirit of Buddhist and Christian Monasticism, àwọn òǹkọ̀wé náà ṣàlàyé pé, “láti ìgbà ayé Socrates (ọ̀rúndún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Tiwa) ó kéré tán, àwọn ènìyàn ti lóye rẹ̀ níbi gbogbo pé ìgbésí ayé tí a rẹ̀ sílẹ̀ pátápátá, tí a kò fi ìgbádùn afẹ́ àti ohun ti ara dí lọ́wọ́, jẹ́ ohun àbèèrèfún kí a tó ní ojúlówó ọgbọ́n.” Àwọn tí ń ṣẹ́ ara wọn níṣẹ̀ẹ́ lérò pé fífi ara sábẹ́ ìjìyà yóò mú kí wọ́n túbọ̀ wà lójúfò nípa tẹ̀mí, yóò sì ṣamọ̀nà sí ìlàlóye tòótọ́.
Ó ṣòro láti sọ ìtúmọ̀ ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ ní pàtó. Sí àwọn kan, ó wulẹ̀ túmọ̀ sí ìkára-ẹni-lọ́wọ́kò tàbí ìfiǹkan-dura-ẹni. Àwọn Kristẹni ìjímìjí mọyì irú ìwà funfun bẹ́ẹ̀. (Gálátíà 5:22, 23; Kólósè 3:5) Jésù Kristi fúnra rẹ̀ dámọ̀ràn ìgbésí ayé ṣebóotimọ tí a kò fi àwọn àníyàn tí ìgbésí ayé onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì lè mú wá dí lọ́wọ́. (Mátíù 6:19-33) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń so ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ mọ́ ìgbésẹ̀ ṣebóotimọ gan-an tí ó sì sábà máa ń jẹ́ lọ́nà aláṣejù, bí àwọn tí a ṣàpèjúwe lókè. Àwọn àṣà ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ wọ̀nyí, ní pàtàkì ní irú èyí tó mú àṣejù lọ́wọ́, ha ni ọ̀nà àtilọ́gbọ́n ní gidi bí?
Wọ́n Gbé E Karí Èrò Èké
Lára àwọn ọgbọ́n èrò orí tí ó ṣokùnfà ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ ni èrò náà pé àwọn ohun ti ara àti fàájì ti ara kò dára, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìdíwọ́ fún ìlọsíwájú nípa tẹ̀mí. Èròǹgbà míràn tí ó ṣínà sílẹ̀ fún ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ ni èrò ìgbàgbọ́ tí a tẹ́wọ́ gbà níbi púpọ̀ náà pé ara kan àti ọkàn kan ni ó para pọ̀ di ènìyàn kan. Àwọn tí wọ́n ń ṣẹ́ ara wọn níṣẹ̀ẹ́ gbà gbọ́ pé ara ìyára ní àhámọ́ tí ọkàn wà nínú rẹ̀ àti pé ẹran ara jẹ́ ọ̀tá rẹ̀.
Kí ni Bíbélì wí? Ìwé Mímọ́ fi hàn pé nígbà tí Ọlọ́run parí ìṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé, ó wí pé gbogbo ohun tí òun ti ṣe—gbogbo ohun gidi tí ó dá, tó ṣeé fojú rí—“dáradára” ni. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Ète Ọlọ́run fún ọkùnrin àti obìnrin nínú ọgbà Édẹ́nì jẹ́ láti gbádùn àwọn ohun ti ara. Orúkọ náà gan-an, Édẹ́nì, túmọ̀ sí “Fàájì” tàbí “Inúdídùn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:8, 9) Ádámù àti Éfà jẹ́ ẹni pípé, wọ́n sì gbádùn ipò ìbátan rere pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wọn kí wọ́n tó dẹ́ṣẹ̀. Láti ìgbà yẹn, àìpé wá di ohun ìdènà láàárín Ọlọ́run àti ènìyàn. Síbẹ̀, títẹ́ ìfẹ́ ọkàn ẹ̀dá tó bẹ́tọ̀ọ́ mu lọ́rùn tàbí gbígbádùn àwọn fàájì tí Ọlọ́run fi fúnni nípa ti ara, tí a bá ṣe é ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin ìwà rere Ọlọ́run, kò lè mú ìdíwọ́ bá àjọṣe láàárín Ọlọ́run àti àwọn olùjọ́sìn rẹ̀!—Orin Dáfídì 145:16.
Ní àfikún sí i, Bíbélì fi kọ́ni kedere pé, ènìyàn, tí a fi erùpẹ̀ ṣẹ̀dá, tí ó sì jẹ́ ẹlẹ́ran ara, jẹ́ ọkàn kan. Ìwé Mímọ́ kò ti ìrònú náà lẹ́yìn pé ọkàn jẹ́ irú ohun àìlèkú kan tí a kò lè rí, tí a sé mọ́ inú ara ìyára, bẹ́ẹ̀ ni kò ti èrò pé lọ́nà kan ẹran ara ń ṣèdíwọ́ fúnni láti ní ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run lẹ́yìn.—Jẹ́nẹ́sísì 2:7.
Ní kedere, èròǹgbà ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ gbé ìtúmọ̀ tí a lọ́ lọ́rùn nípa ipò ìbátan ènìyàn pẹ̀lú Ọlọ́run jáde. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni kan yóò fẹ́ àwọn ọgbọ́n èrò orí ẹ̀dá ènìyàn tí ń tanni jẹ ju àwọn òtítọ́ ìpìlẹ̀ Bíbélì lọ. (Tímótì Kíní 4:1-5) Nípa àwọn kan tí wọ́n ní irú èrò yí, òpìtàn kan nípa ìsìn sọ pé: “Èrò ìgbàgbọ́ náà pé ohun àfojúrí jẹ́ ibi . . . àti pé ọkàn àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ bọ́ lọ́wọ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun àfojúrí, ṣokùnfà ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ bíburú jáì tí ó ka jíjẹ ẹran, ìbálòpọ̀ takọtabo àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ léèwọ̀, tí kìkì ‘àwọn ẹni pípé’ ọ̀tọ̀kùlú tàbí perfecti tí wọ́n ń ṣe àkànṣe ààtò ìsìn fún lè tẹ̀ lé.” Bíbélì kò ti irú ọ̀nà ìrònú yìí lẹ́yìn, kì í sì í ṣe èrò ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni ìjímìjí.—Òwe 5:15-19; Kọ́ríńtì Kíní 7:4, 5; Hébérù 13:4.
Kò Sí Ìdí fún Ìṣẹ́ra-Ẹni-Níṣẹ̀ẹ́
Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kì í ṣe aṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́. Wọ́n forí ti onírúurú ìdánwò àti inúnibíni, ṣùgbọ́n àwọn inúnibíni wọ̀nyí kò fìgbà kan jẹ́ àfọwọ́fà ara ẹni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni láti ṣọ́ra kí a má baà fi àwọn ọgbọ́n èrò orí ẹ̀dá ènìyàn tí ń tanni jẹ tàn wọ́n lọ kúrò nínú òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí ó sì ṣamọ̀nà wọn sínú àwọn àṣà aláṣejù, tí kò bọ́gbọ́n mu. Ní pàtó, Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan “ìfìyàjẹ ara.” Ó wí pé: “Àwọn ohun wọnnì gan-an, ní tòótọ́, ní ìrísí ọgbọ́n nínú irú ọ̀nà ètò ìjọsìn àdábọwọ́ ara ẹni àti ìrẹ̀lẹ̀ ẹlẹ́yà, ìfìyàjẹ ara; ṣùgbọ́n wọn kò níye lórí rárá ní gbígbógunti títẹ́ ẹran ara lọ́rùn.” (Kólósè 2:8, 23) Ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ kì í ṣamọ̀nà sí ipò àkànṣe ìjẹ́mímọ́ kan tàbí ìlàlóye gidi.
Lótìítọ́, ipa ọ̀nà ìgbọ́ràn Kristẹni túmọ̀ sí sísakun àti ìkára-ẹni-lọ́wọ́kò. (Lúùkù 13:24; Kọ́ríńtì Kíní 9:27) Ẹnì kan gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára láti jèrè ìmọ̀ Ọlọ́run. (Òwe 2:1-6) Bákan náà, Bíbélì ní ìṣítí tí ó lágbára lòdì sí dídi ẹrú “ìfẹ́ ọkàn àti adùn” àti dídi “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (Títù 3:3; Tímótì Kejì 3:4, 5) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn àyọkà Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí kò fọwọ́ sí àṣà ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́. Jésù Kristi, tí ó jẹ́ ọkùnrin pípé, gbádùn àwọn àṣeyẹ onífàájì títí kan oúnjẹ, ọtí, orin, àti ijó.—Lúùkù 5:29; Jòhánù 2:1-10.
Ọgbọ́n tòótọ́ ń fòye báni lò, kì í ṣe àṣejù. (Jákọ́bù 3:17) Jèhófà Ọlọ́run dá ara wa tí ó ṣeé fojú rí pẹ̀lú agbára láti gbádùn ọ̀pọ̀ fàájì nínú ìgbésí ayé. Ó fẹ́ kí a láyọ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí fún wa pé: “Èmi mọ̀ pé kò sí rere nínú wọn, bí kò ṣe kí ènìyàn kí ó máa yọ̀, kí ó sì máa ṣe rere ní àyà rẹ̀; Àti pẹ̀lú kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa jẹ kí ó sì máa mu, kí ó sì máa jadùn gbogbo làálàá rẹ̀, ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”—Oníwàásù 3:12, 13.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 20]
Saint Jerome in the Cavern/The Complete Woodcuts of Albrecht Dürer/Dover Publications, Inc.