ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 8/1 ojú ìwé 4-8
  • Ìrètí Tí Ó Sàn Jù fún Ọkàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrètí Tí Ó Sàn Jù fún Ọkàn
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọkàn Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù
  • Agbára Ìdarí Àwọn Gíríìkì
  • Ojú Ìwòye Àwọn Kristẹni Ìjímìjí Nípa Ọkàn
  • Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ẹ̀kọ́ Ìgbàgbọ́ Náà Gan-an
  • Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú—Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Báwo Ni Ìgbàgbọ́ Rẹ Nínú Àjíǹde Ti Lágbára Tó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ọkàn Gẹ́gẹ́ Bí Bíbélì Ṣe Fi Í Hàn
    Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 8/1 ojú ìwé 4-8

Ìrètí Tí Ó Sàn Jù fún Ọkàn

ÀWỌN ọmọ ogun Róòmù kò retí èyí. Bí wọ́n ṣe bo ibi ìsádi òke Màsádà bí ìtá ti í bo ẹyìn, ibi ìsádi tí ó ṣẹ́ kù fún agbo ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ ti àwọn Júù, wọ́n gbara dì fún pípa àwọn ọ̀tá wọn nípakúpa, fún igbe àwọn jagunjagun, fún igbe ẹkún àwọn obìnrin àti ọmọdé. Dípò èyí kìkì ìró iná tí ń sọ kẹ̀ù nìkan ni wọ́n gbọ́. Bí wọ́n ti ń yẹ ibi ìsádi tí iná ti ń sọ náà wò, àwọn ará Róòmù kọ́ òtítọ́ tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀: àwọn ọ̀tá wọn—nǹkan bí 960 ènìyàn—ti kú! Lọ́kọ̀ọ̀kan, àwọn jagunjagun Júù ti pa ìdílé wọn nípakúpa, lẹ́yìn náà wọ́n pa ara wọn ẹnì kíní kejì. Ọkùnrin kan tí ó ṣẹ́ kù ti pa ara rẹ̀.a Kí ni ó sún wọn sí ìṣìkàpànìyàn rẹpẹtẹ àti ìpara ẹni yìí?

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí òpìtàn tí ó gbé ayé nígbà náà, Josephus sọ, kókó abájọ pàtàkì kan ni èrò ìgbàgbọ́ náà pé ọkàn jẹ́ àìleèkú. Eleazar Ben Jair, aṣáájú àwọn Onítara Ìsìn ní Màsádà, ti kọ́kọ́ gbìyànjú láti yí àwọn ọkùnrin rẹ̀ lérò padà pé, ìpara ẹni yóò lọ́lá ju ikú láti ọwọ́ àwọn ará Róòmù tàbí kí wọ́n kó àwọn lẹ́rú lọ. Nígbà tí ó rí i pé wọ́n ń lọ́ tìkọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ onítara nípa ọkàn. Ó sọ fún wọn pé ara wulẹ̀ jẹ́ ìdènà lásán, ọgbà ẹ̀wọ̀n kan fún ọkàn. Ó ń bá a nìṣó pé: “Ṣùgbọ́n, nígbà tí a bá tú u sílẹ̀ kúrò nínú ará tí ó gbé e wọnú ilẹ̀ ayé, tí ó sì ń gbé e kiri, ọkàn yóò padà sí àyè rẹ̀, lẹ́yìn náà ní ti gidi ó ń nípìn-ín nínú agbára tí a bù kún àti okun tí kò láàlà, ní dídi ohun tí ẹ̀dá ènìyàn kò lè fojú rí mọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run Fúnra Rẹ̀.”

Kí ni ìhùwàpadà wọn sí ọ̀rọ̀ yìí? Josephus ròyìn pé lẹ́yìn tí Eleazar ti sọ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ lọ́nà yìí, “gbogbo àwọn olùgbọ́ rẹ̀ dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, wọ́n sì fi pẹ̀lú ìtara tí kò ṣee ṣàkóso ṣe ohun tí ó ní kí wọ́n ṣe kíákíá.” Josephus fi kún un pé: “Bí ẹni tí ẹ̀mí èṣù bà lé, olúkúlùkù ń hára gàgà ṣe é, kí ó lè yára ṣe é ṣáájú ẹnì kejì, . . . ọkàn-ìfẹ́ tí kò ṣeé ṣàkóso ti mú wọn láti pa aya wọn, ọmọ wọn, àti ara wọn.”

Àpẹẹrẹ búburú yìí ṣàkàwé bí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àìleèkú ọkàn ṣe lè yí ojú ìwòye tí ó bọ́gbọ́n mu, tí ẹ̀dá ènìyàn ní nípa ikú padà lọ́nà gíga lọ́lá tó. A kọ́ àwọn tí ó gbà á gbọ́ láti wo ikú, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ènìyàn tí ó burú jù lọ, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹnubodè kan lásán tí ń fún ọkàn lómìnira láti gbádùn ìwàláàyè gíga lọ́lá jù lọ. Ṣùgbọ́n èé ṣe tí àwọn Júù Onítara Ìsìn wọ̀nyẹn ṣe gbà gbọ́ lọ́nà yìí? Ọ̀pọ̀ yóò rò pé àkọsílẹ̀ ìwé mímọ́ wọn, Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, kọ́ni pé ènìyàn ní ẹ̀mí tí ó dá nǹkan mọ̀ nínú rẹ̀, ọkàn tí ń jàjàbọ́ láti máa wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú. Ṣe bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí?

Ọkàn Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù

Lọ́rọ̀ kan, kò rí bẹ́ẹ̀. Nínú ìwé àkọ́kọ́ gan-an nínú Bíbélì, Jẹ́nẹ́sísì, a sọ fún wa pé ọkàn kì í ṣe ohun kan tí o ní, ó jẹ́ ohun kan tí o jẹ́. A kà nípa ìṣẹ̀dá Ádámù, ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ pé: “Ènìyàn sì di alààyè ọkàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Ọ̀rọ̀ Hébérù tí a lo níhìn-ín fún ọkàn, neʹphesh, fara hàn nígbà tí ó lé ní 700 nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, kò fìgbà kankan gbé èrò ohun kan nínú ènìyàn, tí ó dá wà lọ́tọ̀, tí ó jẹ́ ti ọ̀run, tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí yọ. Ní òdì kejì pátápátá, ọkàn jẹ́ ohun pàtó, ohun gidi, tí a lè fojú rí.

Yẹ àwọn ẹsẹ tí a yàn wọ̀nyí wò nínú ẹ̀dà Bíbélì rẹ, nítorí a rí ọ̀rọ̀ Hébérù náà, neʹphesh, nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n fi hàn kedere pé, ọkàn lè fara wewu, ó lè dojú kọ ewu, a sì lè jí i gbé (Diutarónómì 24:7; Onídàájọ́ 9:17; Sámúẹ́lì Kìíní 19:11); ó lè fọwọ́ kan nǹkan (Jóòbù 6:7); a lè tì í mọ inú irin (Orin Dáfídì 105:18); ó lè yán hànhàn fún oúnjẹ, ààwẹ̀ lè gbò ó, ebi àti òùngbẹ sì lè mú òòyì kọ́ ọ, ó sì lè ṣàìsàn tí ń múni rù tàbí àìróorunsùntó nítorí ẹ̀dùn ọkàn. (Diutarónómì 12:20; Orin Dáfídì 35:13; 69:10; 106:15; 107:9; 119:28) Ní èdè míràn, nítorí ìwọ ni ọkàn rẹ, ìwọ alára, ọkàn rẹ lè ní ìrírí ohun tí ìwọ́ lè ní ìrírí rẹ̀.b

Nígbà náà, ìyẹ́n ha túmọ̀ sí pé, ọkàn lè kú ní tòótọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí jíjẹ́ àìleèkú, a sọ̀rọ̀ nípa ọkàn ẹ̀dá ènìyàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù gẹ́gẹ́ bí èyí tí “a . . . ké kúrò” tàbí tí a pa, nítorí ìwà àìtọ́, tí a kọlù lọ́nà ṣíṣekúpani, tí a ṣìkà pa, tí a parun, tí a sì fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. (Ẹ́kísódù 31:14; Diutarónómì 19:6; 22:26; Orin Dáfídì 7:2) Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4 sọ pé: “Ọkàn tí ó bá ṣẹ̀, òun óò kú.” Ó ṣe kedere pé, ikú ni òpin tí ó sábà máa ń dé bá ọkàn ẹ̀dá ènìyàn, níwọ̀n bí gbogbo wa ti dẹ́ṣẹ̀. (Orin Dáfídì 51:5) A sọ fún ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù, pé ikú ni yóò jẹ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀—kì í ṣe bíbọ́ sínú ilẹ̀ ọba ẹ̀mí àti àìleèkú. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Nígbà tí ó sì dẹ́ṣẹ̀, a kéde ìyà rẹ̀ pé: “Erùpẹ̀ sáà ni ìwọ, ìwọ óò sì padà di erùpẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Nígbà tí Ádámù àti Éfà kú, wọ́n wulẹ̀ di ohun tí Bíbélì sábà máa ń tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí ‘òkú ọkàn’ tàbí ‘ọkàn tí ó ti kú.’—Númérì 5:2; 6:6.

Abájọ nígbà náà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana fi sọ nípa ọkàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù pé: “Ìpìlẹ̀ èrò Májẹ̀mú Láéláé nípa ènìyàn jẹ́ ti wíwà pa pọ̀ ohun kan ṣoṣo, kì í ṣe àpapọ̀ ọkàn àti ara.” Ó fi kún un pé: “A kò fìgbà kankan rí ronú nípa nefesh . . . gẹ́gẹ́ bí ohun tí ń dá ṣiṣẹ́ lọ́tọ̀ tí ó yàtọ̀ sí ara.”

Nítorí náà, kí ni àwọn Júù olùṣòtítọ́ gbà gbọ́ pé ikú jẹ́? Ní ṣókí, wọ́n gbà gbọ́ pé, ikú ni òdì kejì ìyè. Orin Dáfídì 146:4 sọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹ̀mí, tàbí ipá ìwàláàyè, bá fi ẹ̀dá ènìyàn sílẹ̀ lọ pé: “Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ náà gan-an, ìrò inú rẹ̀ run.”c Lọ́nà kan náà, Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé pé àwọn òkú “kò mọ ohun kan.”—Oníwàásù 9:5.

Nígbà náà, èé ṣe tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní, irú bí àwọn Onítara Ìsìn ní Màsádà, fi nígbàgbọ́ pé ọkàn jẹ́ àìleèkú?

Agbára Ìdarí Àwọn Gíríìkì

Àwọn Júù rí èrò yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn Gíríìkì, kì í ṣe láti inú Bíbélì. Láàárín ọ̀rúndún keje àti ìkarùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa, ó dà bíi pé ìpìlẹ̀ èrò náà ti gba inú àdììtú ẹgbẹ́ awo ìsìn Gíríìkì wọnú ọgbọ́n èrò orí Gíríìkì. Èrò ìwàláàyè lẹ́yìn ikú, níbi tí àwọn ọkàn búburú yóò ti gba ìpín onírora, ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́kàn mọ́ra fún ìgbà pípẹ́, èrò náà ti fìdí múlẹ̀, ó sì gbalégbòde. Àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí ti jiyàn ranpantan lórí ohun tí ọkàn jẹ́ gan-an. Homer sọ pé ọkàn máa ń tètè fi ara sílẹ̀ nígbà ikú, tí ìró rẹ̀ máa ń kùn yunmun, tí ó máa ń dún fíntínfíntín, tàbí tí ó ń kùn bọ̀n-ùn. Epicurus wí pé, ọkàn ní ìwọ̀n, nítorí náà, ó jẹ́ ara tí ó kéré gan-an.d

Ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé alágbàwí tí ó mú ipò iwájú jù lọ nípa àìleèkú ọkàn ni ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì ọlọ́gbọ́n èrò orí náà, Plato, ti ọ̀rúndún kẹrin ṣááju Sànmánì Tiwa. Bí ó ṣe ṣàpèjúwe ikú olùkọ́ rẹ̀, Socrates, ṣí ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fara jọ ti àwọn Onítara Ìsìn ti Màsádà ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tí ó tẹ̀ lé e payá. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Oscar Cullmann ṣe sọ ọ́, “Plato fi hàn wá bí Socrates ṣe fọwọ́ rọrí kú. Ikú Socrates mà dára o. Kò sí ohunkóhun bíi ìpayà ikú níhìn-ín. Socrates kò bẹ̀rù ikú, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ó máa ń sọ wa di òmìnira kúrò lọ́wọ́ ara. . . . Ikú ni ọ̀rẹ́ tí ọkàn fẹ́ràn jù lọ. Ohun tí ó fi kọ́ni nìyẹn; nítorí náà, ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ́nà yíyani lẹ́nu, ó ṣe bẹ́ẹ̀ kú.”

Ó hàn gbangba ní sáà àwọn Mákábíìsì, ní ọ̀rúndún kejì ṣáájú Kristi, àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí gba ẹ̀kọ́ yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn Gíríìkì. Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, Josephus sọ fún wa pé àwọn Farisí àti àwọn Essene—àwọn ògúnná gbòǹgbò nínú àwùjọ ìsìn àwọn Júù—gbárùkù ti ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ yìí. Àwọn ewì kan tí a kọ ní sànmánì yẹn fi èrò ìgbàgbọ́ kan náà hàn.

Ṣùgbọ́n, kí ni nípa ti Jésù Kristi? Òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ha fi èrò ìsìn àwọn Gíríìkì yìí kọ́ni lọ́nà kan náà bí?

Ojú Ìwòye Àwọn Kristẹni Ìjímìjí Nípa Ọkàn

Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kò fi ojú tí àwọn Gíríìkì fi wo ọkàn wò ó. Fún àpẹẹrẹ, gbé ikú ọ̀rẹ́ Jésù, Lásárù, yẹ̀ wò. Bí Lásárù bá ní àìleèkú ọkàn tí ó fò jáde bọ̀n-ùn, tí ó dòmìnira, tí ó sì láyọ̀, nígbà ikú, àkọsílẹ̀ Jòhánù orí 11 kò ha ti ní yàtọ̀ gidigidi bí? Dájúdájú, Jésù ì bá ti sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bí Lásárù bá wà láàyè, tí ara rẹ̀ le, tí ó sì mọ nǹkan ní ọ̀run; ní òdì kejì pátápátá, o ṣàtúnsọ ohun tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ, ó sì sọ fún wọn pé, Lásárù ń sùn ni, kò mọ nǹkan kan. (Ẹsẹ 11) Dájúdájú, inú Jésù ì bá ti dùn bí ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá ń gbádùn ìwàláàyè àgbàyanu tuntun; dípò èyí, a rí i tí ó ń sọkún ní gbangba nítorí ikú rẹ̀. (Ẹsẹ 35) Dájúdájú, bí ọkàn Lásárù bá ti wà ní ọ̀run, tí ó ń yọ̀tọ̀mì níbi ìgbádùn àìleèkú, Jésù ì bá ti jẹ́ òǹrorò tó bẹ́ẹ̀ láti pè é wá láti wà láàyè fún ọdún díẹ̀ sí i nínú “ọgbà ẹ̀wọ̀n” ara àìpé tí a lè fojú rí láàárín aráyé tí ń ṣàìsàn, tí ó sì ń kú.

Lásárù ha mú ìròyìn aládùn wá láti inú ikú, nípa àwọn ọjọ́ mẹ́rin àgbàyanu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí olómìnira, tí ó fi ara sílẹ̀ bí? Rárá o, kò ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn onígbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn yóò dáhùn pé, èyí jẹ́ nítorí pé ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ ìrírí tí ọkùnrin náà ni kọjá sísọ. Ṣùgbọ́n àríyànjiyàn yẹn kò lè yíni lérò padà; ó ṣe tán, kò ha ṣeé ṣe fún Lásárù síbẹ̀ láti sọ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ó kéré tán—pé òún ní ìrírí àgbàyanu tí kò ṣeé fẹnu sọ bí? Dípò èyí, Lásárù kò sọ ohunkóhun nípa ìrírí tí ó ní nígbà ikú rẹ̀. Ronú nípa rẹ̀—kò sọ ohunkóhun lórí kókó ẹ̀kọ́ kan tí ó jẹ́ olórí àfiyèsí, tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ń tọ pinpin rẹ̀ ju ohunkóhun mìíràn lọ: bí ikú ṣe rí! A lè ṣàlàyé àìsọ ohunkóhun yẹn lọ́nà kan ṣoṣo. Kò sí ohunkóhun láti sọ. Àwọn okú ń sùn, wọn kò mọ ohunkóhun.

Nítorí náà, Bíbélì ha sọ̀rọ̀ ikú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ ọkàn, ààtò lásán ti lílọ láti ìpele kan sí ìpele mìíràn láàárín ìpele ìwàláàyè bí? Rárá o! Lójú ìwòye àwọn Kristẹni tòótọ́, àwọn bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ikú kì í ṣe ọ̀rẹ́ rárá; ó jẹ́ “ọ̀tá ìkẹyìn.” (Kọ́ríńtì Kìíní 15:26) Àwọn Kristẹni kò ka ikú sí ohun tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu, ṣùgbọ́n wọ́n kà á sí ohun ìríra, ohun tí kò bá ìwà ẹ̀dá mu, nítorí ó jẹ́ ìyọrísí tààràtà ti ẹ̀ṣẹ̀ àti ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (Róòmù 5:12; 6:23) Kò fìgbà kankan jẹ́ apá kan ète ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí Ọlọ́run ní fún aráyé.

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Kristẹni tòótọ́ kò wà láìnírètí nígbà tí ó bá di ọ̀ràn ikú ọkàn. Àjíǹde Lásárù jẹ́ ọ̀kan nínú ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ Bíbélì tí ó fi ìrètí tòótọ́ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu tí àwọn ọkàn tí ó ti kú ní hàn wá ní kedere—àjíǹde. Bíbélì kọ́ni nípa oríṣi àjíǹde méjì tí ó yàtọ̀ síra. Fún ọ̀pọ̀ yamùrá nínú aráyé tí wọ́n ti sùn nínú ibojì, yálà olódodo tàbí aláìṣòdodo, ìrètí àjíǹde sí ìyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín ń bẹ. (Lúùkù 23:43; Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Fún àwùjọ kéréje tí Jésù tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí “agbo kékeré” òun, àjíǹde sí ìyè àìleèkú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí ní ọ̀run ń bẹ. Àwọn wọ̀nyí, tí wọ́n ní àwọn àpọ́sítélì Kristi nínú, yóò ṣàkóso pẹ̀lú Kristi Jésù lórí aráyé, wọn yóò sì mú wọn padà bọ̀ sí ìjẹ́pípé.—Lúùkù 12:32; Kọ́ríńtì Kìíní 15:53, 54; Ìṣípayá 20:6.

Nígbà náà, èé ṣe tí a fi rí i tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù kò fi fi àjíǹde kọ́ni, bí kò ṣe àìleèkú ọkàn ẹ̀dá ènìyàn? Ronú lórí ìdáhùn tí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, Werner Jaeger, sọ nínú The Harvard Theological Review nígbà náà lọ́hùn-ún ní 1959 pé: “Òkodoro òtítọ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìtàn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Kristẹni ni pé, bàbá ẹ̀kọ́ ìsìn Kristẹni, Origen, jẹ́ ọlọ́gbọ́n èrò orí Plato ní ilé ẹ̀kọ́ ti Alexandria. Ó fi àwọn ẹ̀kọ́ gbígbòòrò nípa àìleèkú ọkàn kún ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Kristẹni, èyí tí ó gbà láti ọ̀dọ̀ Plato.” Nítorí náà, ṣọ́ọ̀ṣì ṣe ohun tí àwọn Júù ṣe gẹ́lẹ́ ní àwọn ọ̀rúndún tí ó ṣáájú! Wọ́n kọ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì sílẹ̀ láti fàyè gba ọgbọ́n èrò orí Gíríìkì.

Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ẹ̀kọ́ Ìgbàgbọ́ Náà Gan-an

Wàyí o, àwọn kan lè béèrè, ní gbígbèjà ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àìleèkú ọkàn pé, Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ ìsìn ayé fi ń fi irú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ kan náà kọ́ni, ní ọ̀nà kan tàbí ọ̀nà míràn? Ìwé Mímọ́ fúnni ní ìdí yíyè kooro tí ẹ̀kọ́ yìí fi gbalégbòde bẹ́ẹ̀ nínú àwùjọ ìsìn ayé yìí.

Bíbélì sọ fún wa pé, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” ó sì fi Sátánì hàn ní pàtó gẹ́gẹ́ bí “olùṣàkóso ayé yìí.” (Jòhánù Kìíní 5:19; Jòhánù 12:31) Ní kedere, àwọn ìsìn ayé kò ní àjẹsára lòdì sí agbára ìdarí Sátánì. Ní òdì kejì pátápátá, wọ́n ti dá kún wàhálà àti gbọ́nmisi-omi-ò-to tí ó wà nínú ayé lónìí. Àti lórí ọ̀ràn ọkàn, ó dà bíi pé wọ́n fi èrò inú Sátánì ní kedere gan-an hàn. Lọ́nà wo?

Rántí irọ́ àkọ́kọ́ pàá. Ọlọ́run ti sọ fún Ádámù àti Éfà pé bí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀ sí òun, yóò yọrí sí ikú. Ṣùgbọ́n Sátánì fi ọkàn Éfà balẹ̀ pé: “Ẹ̀yin kì yóò kú ikú kíkú kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:4) Àmọ́ ṣáá o, Ádámù àti Éfà kú ní tòótọ́; wọ́n padà sí erùpẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí. Sátánì, “bàbá irọ́,” kò fi irọ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ sílẹ̀. (Jòhánù 8:44) Nínú àìmọye ìsìn tí ó ti ya pa kúrò nínú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Bíbélì tàbí tí ó ti pa á tì pátápátá, èrò kan náà ṣì ń jà rànyìn pé: ‘Ìwọ kì yóò kú ikú kan. Ara rẹ lè kú, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ yóò máa wà láàyè nìṣó, títí láé—bíi ti Ọlọ́run!’ Ó dùn mọ́ni pé, Sátánì tún sọ fún Éfà pé yóò “dà bí Ọlọ́run”!—Jẹ́nẹ́sísì 3:5.

Ẹ wo bí ó ti dára tó láti ní ìrètí tí a gbé karí òtítọ́, kì í ṣe lórí irọ́ tàbí ọgbọ́n èrò orí ẹ̀dá ènìyàn. Ẹ wo bí ó ti dára tó láti ní ìgbọ́kànlé pé, àwọn olólùfẹ́ wa tí wọ́n ti kú kò mọ ohunkóhun mọ́ nínú ibojì kàkà tí à bá fi máa ṣàníyàn nípa ibi tí àwọn ọkàn àìleèkú wà! Oorun àwọn òkú wọ̀nyí kò yẹ kí ó kó ìpayà bá wa tàbí mú wa sorí kọ́. Lọ́nà kan, a lè wo àwọn òkú bí ẹni tí ó wà ní ibi ìsinmi tí ó láàbò. Èé ṣe tí ó fi láàbò? Nítorí pé, Bíbélì mú un dá wa lójú pé, àwọn òkú tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wà láàyè lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. (Lúùkù 20:38) Wọ́n wà nínú agbára ìrántí rẹ̀. Ìyẹ́n jẹ́ èrò ìtùnú gidigidi nítorí pé, agbára ìrántí rẹ̀ kò láàlà. Ó ń hára gàgà láti mú àìmọye àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn olùfẹ́ ọ̀wọ́n wá sí ìyè, kí ó sì fún wọn ní àǹfààní láti wà láàyè títí láé lórí párádísè ilẹ̀ ayé kan.—Fi wé Jóòbù 14:14, 15.

Ọjọ́ ológo ti àjíǹde yóò dé, nítorí tí gbogbo ìlérí Jèhófà gbọ́dọ̀ ní ìmúṣẹ. (Aísáyà 55:10, 11) Tilẹ̀ ronú nípa bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí yóò ṣe ní ìmúṣẹ ná: “Ṣùgbọ́n àwọn òkú rẹ wà láàyè, ara wọn yóò jí dìde lẹ́ẹ̀kan sí i. Àwọn tí wọ́n sùn nínú ilẹ̀ ayé yóò jí, wọn yóò sì hó fún ìdùnnú; nítorí ìrì ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn yanran ni ìrì rẹ̀, ilẹ̀ ayé yóò sì bí àwọn tí wọ́n ti kú tipẹ́ padà.” (Aísáyà 26:19, The New English Bible) Nítorí náà, ààbò àwọn òkú tí ń sùn nínú ibojì dà bíi ààbò ọmọdé jòjòló kan nínú ilé ọlẹ̀ ìyá rẹ̀. A óò “bí” wọn padà sí ìyè lórí párádísè ilẹ̀ ayé kan láìpẹ́!

Ìrètí wo ni ó tún lè sàn ju ìyẹn lọ?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ròyìn pé obìnrin méjì àti ọmọdé márùn-ún là á já níbi tí wọ́n fara pamọ́ sí. Lẹ́yìn náà ni àwọn obìnrin náà sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ fún àwọn ará Róòmù tí ó kó wọn lẹ́rú.

b Àmọ́ ṣáá o, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó ní ìtumọ̀ gbígbòòrò, ọ̀rọ̀ náà, neʹphesh, tún ní àwọn ìtumọ̀ míràn tí ó yàtọ̀. Fún àpẹẹrẹ, ó lè tọ́ka sí ẹni ti inú lọ́hùn-ún, ní pàtàkì nígbà tí a bá ń tọ́ka sí ìmọ̀lára jíjinlẹ̀. (Sámúẹ́lì Kìíní 18:1) Ó tún lè tọ́ka sí ìwàláàyè tí ẹnì kan ń gbádùn gẹ́gẹ́ bí ọkàn kan.—Àwọn Ọba Kìíní 17:21-23.

c Ọ̀rọ̀ Hébérù náà fún “ẹ̀mí,” ruʹach, túmọ̀ sí “èémí” tàbí “atẹ́gùn.” Tí a bá lò ó fún ẹ̀dá ènìyàn, kò tọ́ka sí ẹ̀mí kan gédégbé tí ó dá nǹkan mọ̀ ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè náà, The New International Dictionary of New Testament Theology, ṣe sọ ọ́, ó ń tọ́ka sí “ipá ìwàláàyè ẹnì kọ̀ọ̀kan.”

d Òun nìkan kọ́ ni ó ronú lọ́nà ṣíṣàjèjì yìí. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ ní ti gidi pé, òún ti wọn ọkàn àwọn onírúurú ènìyàn wò nípa yíyọ ìwọ̀n wọn kété lẹ́yìn ikú kúrò nínú ìwọ̀n wọn kété ṣáájú ikú.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn Onítara Ìsìn Júù ní Màsádà gbà gbọ́ pé ikú yóò dá ọkàn wọn sílẹ̀ lómìnira

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́