ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ie ojú ìwé 19-20
  • Ọkàn Gẹ́gẹ́ Bí Bíbélì Ṣe Fi Í Hàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọkàn Gẹ́gẹ́ Bí Bíbélì Ṣe Fi Í Hàn
  • Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ọkàn” Gẹ́gẹ́ Bí Ẹ̀dá Alààyè
  • “Ọkàn” Gẹ́gẹ́ Bí Ìwàláàyè Ẹ̀dá
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Kí Ni Ọkàn?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú—Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ọkàn
    Jí!—2016
Àwọn Míì
Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
ie ojú ìwé 19-20

Ọkàn Gẹ́gẹ́ Bí Bíbélì Ṣe Fi Í Hàn

“Ọkùnrin náà . . . wá di alààyè ọkàn.”—JẸ́NẸ́SÍSÌ 2:7.

1. Kí ni a ní láti ṣàyẹ̀wò láti lè mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ọkàn?

GẸ́GẸ́ bí a ti ṣe rí i, ọ̀pọ̀ jáǹrẹrẹ àti onírúurú ni ìgbàgbọ́ nípa ọkàn jẹ́. Kódà láàárín àwọn tí wọ́n sọ pé wọ́n gbé ìgbàgbọ́ wọn karí Bíbélì, ìyàtọ̀ wà nínú èrò wọn nípa ọkàn àti ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí i tí a bá kú. Ṣùgbọ́n kí tilẹ̀ ni Bíbélì fi kọ́ni nípa ọkàn? Láti lè mọ̀, a ní láti ṣàyẹ̀wò àwọn ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù àti ti Gíríìkì tí a túmọ̀ sí “ọkàn” nínú Bíbélì.

“Ọkàn” Gẹ́gẹ́ Bí Ẹ̀dá Alààyè

2, 3. (a) Ọ̀rọ̀ wo ni a túmọ̀ sí “ọkàn” nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, kí sì ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí gan-an? (b) Báwo ni Jẹ́nẹ́sísì 2:7 ṣe fi ẹ̀rí pé ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” lè túmọ̀ sí ènìyàn lódindi múlẹ̀?

2 Ọ̀rọ̀ Hébérù tí a túmọ̀ sí “ọkàn” ni neʹphesh, ìgbà 754 ni ó sì fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù (tí a sábà máa ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé). Kí ni neʹphesh túmọ̀ sí? Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Dictionary of Bible and Religion ṣe wí, ó “sábà máa ń tọ́ka sí ẹ̀dá alààyè náà látòkè délẹ̀, ẹni náà lódindi.”

3 Bí àpẹẹrẹ, Jẹ́nẹ́sísì 2:7 sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run . . . bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá ọkùnrin náà láti inú ekuru ilẹ̀, ó sì fẹ́ èémí ìyè sínú ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.” Ṣàkíyèsí pé kì í ṣe pé Ádámù ní ọkàn; òun jẹ́ ọkàn—gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tí ó di dókítà ṣe jẹ́ dókítà. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn,” lè tọ́ka sí ènìyàn lódindi.

4, 5. (a) Fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ láti fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn,” lè tọ́ka sí ènìyàn lódindi. (b) Báwo ni ìwé náà, The Dictionary of Bible and Religion, ṣe ti òye náà pé ènìyàn jẹ́ ọkàn lẹ́yìn?

4 A ti òye yìí lẹ́yìn jálẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, níbi tí a ti rí gbólóhùn ọ̀rọ̀ bí “bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkàn kan ṣẹ̀” (Léfítíkù 5:1), “ọkàn èyíkéyìí tí yóò ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí” (Léfítíkù 23:30), “bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a rí ọkùnrin kan tí ó jí ọkàn kan . . . gbé” (Diutarónómì 24:7), “ọkàn rẹ̀ kò lélẹ̀” (Àwọn Onídàájọ́ 16:16), “yóò ti pẹ́ tó tí ẹ óò máa sún ọkàn mi bínú?” (Jóòbù 19:2), àti “ọkàn mi kò lè sùn nítorí ẹ̀dùn-ọkàn.”—Sáàmù 119:28.

5 Kò sí ohun tí ó fi hàn nínú àwọn àyọkà wọ̀nyí pé ọkàn jẹ́ òjìji kan tí ó ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú. Ìwé The Dictionary of Bible and Religion, sọ pé: “Láti lo gbólóhùn wa náà pé ṣe ni ‘ọkàn’ olólùfẹ́ wa lọ bá Olúwa tàbí láti sọ̀rọ̀ nípa ‘àìleèkú ọkàn’ kò lè yéni rárá tí a bá fojú ohun tí a gbà gbọ́ gẹ́gẹ́ bí àṣà nínú [Májẹ̀mú Láéláé] wò ó.”

6, 7. Ọ̀rọ̀ wo ni a túmọ̀ sí “ọkàn” nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, kí sì ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí gan-an?

6 Ọ̀rọ̀ tí a tú sí “ọkàn” níye ìgbà tí ó ju ọgọ́rùn-ún lọ nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì (tí a sábà máa ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun) ni psy·kheʹ. Bí ti neʹphesh, ọ̀rọ̀ yìí sábà máa ń tọ́ka sí ènìyàn lódindi. Bí àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí: “Ọkàn mi dààmú.” (Jòhánù 12:27) “Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí ba olúkúlùkù ọkàn.” (Ìṣe 2:43) “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga.” (Róòmù 13:1) “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) “A gbé àwọn ènìyàn díẹ̀ la omi já láìséwu, èyíinì ni, ọkàn mẹ́jọ.” (1 Pétérù 3:20)

7 Bí ti neʹphesh, ó ṣe kedere pé psy·kheʹ tọ́ka sí ènìyàn lódindi. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà, Nigel Turner, ṣe wí, ọ̀rọ̀ yìí “dúró fún gbogbo ànímọ́ tí a fi ń peni ní ènìyàn, ẹni náà fúnra rẹ̀, ara ìyára tí Ọlọ́run mí rûaḥ [ẹ̀mí] rẹ̀ sí nínú. . . . Ẹni náà lódindi ni a ń tẹnu mọ́.”

8. Àwọn ẹranko ha jẹ́ ọkàn bí? Ṣàlàyé.

8 Nínú Bíbélì, ènìyàn nìkan kọ́ ni a lo ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn,” fún, a tún ń lò ó fún àwọn ẹranko. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jẹ́nẹ́sísì 1:20 ń ṣàpèjúwe bí a ṣe dá àwọn ẹ̀dá inú òkun, ó sọ pé Ọlọ́run pàṣẹ pé: “Kí omi mú àwọn alààyè ọkàn agbáyìn-ìn máa gbá yìn-ìn.” Ní ọjọ́ ìṣẹ̀dá tí ó sì tẹ̀ lé e, Ọlọ́run sọ pé: “Kí ilẹ̀ ayé mú alààyè ọkàn jáde ní irú tiwọn, ẹran agbéléjẹ̀ àti ẹran tí ń rìn ká àti ẹranko ìgbẹ́ ilẹ̀ ayé ní irú tirẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:24; fi wé Númérì 31:28.) Nítorí náà, “ọkàn” lè tọ́ka sí ẹ̀dá alààyè, ì báà ṣe ènìyàn tàbí ẹranko.

“Ọkàn” Gẹ́gẹ́ Bí Ìwàláàyè Ẹ̀dá

9. (a) Ìtumọ̀ síwájú sí i wo ni a lè fún ọ̀rọ̀ náà “ọkàn”? (b) Èyí ha tako èrò náà pé ènìyàn fúnra rẹ̀ ní ọkàn bí?

9 Nígbà mìíràn, ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn” lè tọ́ka sí ìwàláàyè tí ènìyàn tàbí ẹranko ní. Èyí kò mú ìyípadà bá ohun tí Bíbélì sọ pé ọkàn jẹ́, ìyẹn ni ènìyàn kan tàbí ẹranko kan. Láti ṣàpèjúwe rẹ̀: A lè sọ pé ẹnì kan wà láàyè, tí ó túmọ̀ sí pé ó jẹ́ alààyè. A sì tún lè sọ pé ìwàláàyè wà nínú rẹ̀. Lọ́nà kan náà, alààyè jẹ́ ọkàn. Síbẹ̀, nígbà tí ó bá wà láàyè, a lè sọ̀rọ̀ nípa “ọkàn” gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó wà nínú rẹ̀.

10. Fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ láti fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” lè tọ́ka sí ìwàláàyè tí ènìyàn tàbí ẹranko ní.

10 Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Gbogbo ènìyàn tí ń dọdẹ ọkàn rẹ ti kú.” (Ẹ́kísódù 4:19) Ní kedere, ṣe ni àwọn ọ̀tá Mósè fẹ́ gbẹ̀mí rẹ̀. A rí ìlò ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” lọ́nà kan náà nínú àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí. “Àyà sì fò wá gidigidi fún ọkàn wa.” (Jóṣúà 9:24) “Wọ́n . . . ń sá lọ nítorí ọkàn wọn.” (2 Àwọn Ọba 7:7) “Olódodo ń bójú tó ọkàn ẹran agbéléjẹ̀ rẹ̀.” (Òwe 12:10) “Ọmọ ènìyàn ti wá, . . . kí ó [lè] fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) “Ó . . . sún mọ́ bèbè ikú, ó fi ọkàn rẹ̀ wewu.” (Fílípì 2:30) Nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan, ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” túmọ̀ sí “ìwàláàyè.”a

11. Kí ni a lè sọ nípa ìlò tí Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà “ọkàn”?

11 Nítorí náà, ọ̀rọ̀ náà “ọkàn,” ní bí a ṣe lò ó nínú Bíbélì, tọ́ka sí ènìyàn tàbí ẹranko tàbí sí ìwàláàyè tí ènìyàn tàbí ẹranko ní. Ohun tí Bíbélì pe ọkàn rọrùn, ó ṣọ̀kan délẹ̀, kò sì ní àwọn ẹ̀kọ́ adẹ́rùpọkọ̀ ti ọgbọ́n èrò orí àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ti ènìyàn, tí ó ṣòro lóye, nínú. Àmọ́, kí ní ń ṣẹlẹ̀ sí ọkàn nígbà ikú? Láti dáhùn ìbéèrè náà, a ní láti kọ́kọ́ lóye ìdí tí a fi ń kú.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Mátíù 10:28 pẹ̀lú lo ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” láti túmọ̀ sí “ìwàláàyè.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Gbogbo wọ́n jẹ́ ọkàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́